Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 118

118 (A)Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó dára;
    àánú rẹ̀ dúró láéláé.

Jẹ́ kí Israẹli wí pé:
    “Àánú rẹ̀ dúró láéláé”.
Jẹ́ kí ilé Aaroni wí pé:
    “Àánú rẹ̀ dúró láéláé”.
Jẹ́ kí àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa wí pé:
    “Àánú rẹ̀ dúró láéláé.”

Nínú ìrora mi, mo sọkún sí Olúwa,
    ó sì dá mi lóhùn nípa pé ó tú mi sílẹ̀.
(B)Olúwa ń bẹ fún èmi; èmi kì yóò bẹ̀rù.
    Kí ni ènìyàn lè ṣe sí mi?
Olúwa ń bẹ fún mi; òun ni olùrànlọ́wọ́ mi
    Nítorí náà ni èmi ó ṣe rí ìṣẹ́gun mi lórí àwọn tí ó kórìíra mi.

Ó dára láti máa gbẹ́kẹ̀lé Olúwa
    ju àti gbẹ́kẹ̀lé ènìyàn lọ.
Ó dára láti máa gbẹ́kẹ̀lé Olúwa
    ju à ti gbẹ́kẹ̀lé àwọn ọmọ-aládé lọ.
10 Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yí mi káàkiri,
    ṣùgbọ́n ní orúkọ Olúwa èmi gé wọn kúrò
11 Wọ́n yí mi káàkiri ní gbogbo ẹ̀gbẹ́,
    ṣùgbọ́n ní orúkọ Olúwa èmi gé wọn dànù
12 Wọ́n gbá yìn ìn yí mi ká bí oyin,
    ṣùgbọ́n wọ́n kú kíákíá bí iná ẹ̀gún;
    ní orúkọ Olúwa èmi ké wọn dànù.
13 Ìwọ tì mí gidigidi kí n lè ṣubú,
    ṣùgbọ́n Olúwa ràn mí lọ́wọ́.
14 Olúwa ni agbára àti orin mi;
    ó sì di ìgbàlà mi.

15 Ohùn ayọ̀ àti ìgbàlà ń bẹ nínú àgọ́ àwọn olódodo:
    “Ọwọ́ ọ̀tún Olúwa ń ṣe ohun agbára!
16 Ọwọ́ ọ̀tún Olúwa ní a gbéga;
    ọwọ́ ọ̀tún Olúwa ń ṣe ohun agbára!”
17 Èmi kì yóò kú, ṣùgbọ́n èmi yóò yè,
    èmi yóò pòkìkí ohun tí Olúwa ṣe.
18 Olúwa bá mi wí gidigidi,
    ṣùgbọ́n òun kò fi mí lé ikú lọ́wọ́.
19 Ṣí ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà òdodo fún mi:
    èmi yóò bá ibẹ̀ wọlé, èmi yóò sì fi ọpẹ́ fún Olúwa.
20 Èyí ni ìlẹ̀kùn Olúwa
    ibẹ̀ ni àwọn olódodo yóò bá wọlé.
21 Èmi yóò fi ọpẹ́ fún ọ, nítorí ó dá mi lóhùn;
    ìwọ sì di ìgbàlà mi.

22 (C)Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀,
    ni ó di pàtàkì igun ilé;
23 Olúwa ti ṣe èyí,
    ó ṣe ìyanu ní ojú wa.
24 Èyí ni ọjọ́ tí Olúwa dá:
    ẹ jẹ́ kí ayọ̀ kí inú wa sì máa dùn nínú rẹ̀.

25 (D)Olúwa, gbà wá;
    Olúwa, fún wa ní àlàáfíà.

26 Ìbùkún ni ẹni tí ń bọ̀ wá ní orúkọ Olúwa.
    Àwa ti fi ìbùkún fún ọ láti ilé Olúwa wá.
27 Olúwa ni Ọlọ́run,
    ó ti mú ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tàn sí wa lára
    pẹ̀lú ẹ̀ka igi ní ọwọ́, ó dára pọ̀ mọ́
ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń wọ́ nínú ayọ̀
    ẹ fi okùn di ẹbọ náà mọ́ ìwo pẹpẹ.

28 Ìwọ ni Ọlọ́run mi, èmi yóò máa fi ọpẹ́ fún ọ;
    ìwọ ni Ọlọ́run mi, èmi yóò gbé ọ ga.

29 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó ṣeun;
    nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

Saamu 145

Saamu ìyìn. Ti Dafidi.

145 Èmi yóò gbé ọ ga, Ọlọ́run ọba mi;
    Èmi yóò yin orúkọ rẹ̀ láé àti láéláé
Ní ojoojúmọ́ èmi yóò yìn ọ́
    èmi yóò sì pòkìkí orúkọ rẹ láé àti láéláé.

Títóbi ni Olúwa. Òun sì ni ó yẹ láti fi ìyìn fún púpọ̀púpọ̀:
    kò sí ẹni tí ó lè wọn títóbi rẹ̀.
Ìran kan yóò máa yin iṣẹ́ rẹ dé ìran mìíràn;
    wọn yóò máa sọ iṣẹ́ agbára rẹ
Wọn yóò máa sọ ìyìn ọláńlá rẹ tí ó lógo,
    èmi yóò máa ṣe àṣàrò nínú iṣẹ́ ìyanu rẹ.
Wọn yóò sọ iṣẹ́ agbára rẹ tí ó ní ẹ̀rù
    èmi yóò kéde iṣẹ́ ńlá rẹ̀.
Wọn yóò ṣe ìrántí ọ̀pọ̀lọpọ̀
    ìwà rere rẹ àti orin ayọ̀ òdodo rẹ.

Olóore-ọ̀fẹ́ ni Olúwa àti aláàánú
    ó lọ́ra láti bínú ó sì ní ìfẹ́ púpọ̀.

Olúwa dára sí ẹni gbogbo;
    ó ní àánú lórí ohun gbogbo tí ó dá.
10 Gbogbo ohun tí ìwọ ti dá ni
    yóò máa yìn ọ́ Olúwa;
    àwọn ẹni mímọ́ yóò máa pòkìkí rẹ.
11 Wọn yóò sọ ògo ìjọba rẹ
    wọn yóò sì sọ̀rọ̀ agbára rẹ,
12 Kí gbogbo ènìyàn le mọ iṣẹ́ agbára rẹ̀
    àti ọláńlá ìjọba rẹ tí ó lógo.
13 Ìjọba rẹ ìjọba ayérayé ni,
    àti ìjọba rẹ wà ní gbogbo ìrandíran.
14 Olúwa mú gbogbo àwọn tí ó ṣubú ró
    ó sì gbé gbogbo àwọn tí ó tẹríba dìde.
15 Ojú gbogbo ènìyàn ń wò ọ́,
    ó sì fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àkókò tí ó yẹ
16 Ìwọ ṣí ọwọ́ rẹ
    ìwọ sì tẹ́ ìfẹ́ gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.

17 Olúwa jẹ́ olódodo ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀
    àti ìfẹ́ rẹ̀ sí gbogbo ohun tí o dá.
18 Olúwa wà ní tòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é,
    sí gbogbo ẹni tí ń ké pè é ní òtítọ́.
19 Ó mú ìfẹ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ṣẹ;
    ó gbọ́ igbe wọn, ó sì gbà wọ́n.
20 Olúwa dá gbogbo àwọn tí ó ní ìfẹ́ sẹ sí
    ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ẹni
    búburú ní yóò parun.

21 Ẹnu mi yóò sọ̀rọ̀ ìyìn Olúwa.
    Jẹ́ kí gbogbo ẹ̀dá yín orúkọ rẹ̀ mímọ́ láé àti láéláé.

2 Samuẹli 17:1-23

Ahitofeli gbìmọ̀ pé kí a lépa Dafidi

17 Ahitofeli sì wí fún Absalomu pé, “Èmi ó yan ẹgbàafà ọkùnrin èmi ó sì dìde, èmi ó sì lépa Dafidi lóru yìí. Èmi ó sì yọ sí i nígbà tí àárẹ̀ bá mú un tí ọwọ́ rẹ̀ sì ṣe aláìle, èmi ó sì dá a ní ìjì: gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ yóò sì sá, èmi ó sì kọlu ọba nìkan ṣoṣo. Èmi ó sì mú gbogbo àwọn ènìyàn padà sọ́dọ̀ rẹ bi ìgbà tí ìyàwó bá padà sí ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ̀. Ọkàn ẹnìkan ṣoṣo tí ìwọ ń wá yìí ni ó túmọ̀ sí ìpadàbọ̀ gbogbo wọn; gbogbo àwọn ènìyàn yóò sì wà ní àlàáfíà.” Ọ̀rọ̀ náà sì tọ́ lójú Absalomu, àti lójú gbogbo àwọn àgbàgbà Israẹli.

Huṣai fi ọgbọ́n yí ìmọ̀ náà po

Absalomu sì wí pé, “Ǹjẹ́ pe Huṣai ará Arki, àwa ó sì gbọ́ èyí tí ó wà lẹ́nu rẹ̀ pẹ̀lú.” Huṣai sì dé ọ̀dọ̀ Absalomu, Absalomu sì wí fún un pé, “Báyìí ni Ahitofeli wí, kí àwa ṣe bí ọ̀rọ̀ rẹ bí? Bí ko bá sì tọ́ bẹ́ẹ̀, ìwọ wí.”

Huṣai sì wí fún Absalomu pé, “Ìmọ̀ tí Ahitofeli gbà yìí, kò dára nísinsin yìí.” Huṣai sì wí pé, “Ìwọ mọ baba rẹ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pé alágbára ni wọ́n, wọ́n sì wà ní kíkorò ọkàn bí àmọ̀tẹ́kùn tí a gbà ní ọmọ ni pápá: baba rẹ sì jẹ́ jagunjagun ọkùnrin kì yóò bá àwọn ènìyàn náà gbé pọ̀ lóru. Kíyèsi i, ó ti fi ara rẹ̀ pamọ́ nísinsin yìí ni ihò kan, tàbí ní ibòmíràn: yóò sì ṣe, nígbà tí díẹ̀ nínú wọn bá kọ́ ṣubú, ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ yóò sì wí pé, ‘Ìparun sì ń bẹ́ nínú àwọn ènìyàn tí ń tọ Absalomu lẹ́yìn.’ 10 Ẹni tí ó sì ṣe alágbára, tí ọkàn rẹ̀ sì dàbí ọkàn kìnnìún, yóò sì rẹ̀ ẹ́: nítorí gbogbo Israẹli ti mọ̀ pé alágbára ni baba rẹ, àti pé, àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ jẹ́ alágbára.

11 “Nítorí náà èmi dámọ̀ràn pé: Kí gbogbo Israẹli wọ́jọ pọ̀ sọ́dọ̀ rẹ, láti Dani títí dé Beerṣeba, gẹ́gẹ́ bí iyanrìn létí Òkun fún ọ̀pọ̀lọpọ̀; àti pé, kí ìwọ tìkára rẹ̀ ó lọ sí ogun náà. 12 Àwa ó sì yọ sí i níbikíbi tí àwa o gbé rí i, àwa ó sì yí i ká bí ìrì ti ń ṣẹ̀ sí ilẹ̀ àní, ọkàn kan kì yóò kù pẹ̀lú rẹ̀ nínú gbogbo àwọn ọmọkùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀. 13 Bí o bá sì bọ́ sí ìlú kan, gbogbo Israẹli yóò mú okùn wá sí ìlú náà, àwa ó sì fà á lọ sí odò, títí a kì yóò fi rí òkúta kéékèèkéé kan níbẹ̀.”

14 Absalomu àti gbogbo ọkùnrin Israẹli sì wí pé, “Ìmọ̀ Huṣai ará Arki sàn ju ìmọ̀ Ahitofeli lọ! Nítorí Olúwa fẹ́ láti yí ìmọ̀ rere ti Ahitofeli po.” Nítorí kí Olúwa lè mú ibi wá sórí Absalomu.

Huṣai ránṣẹ́ sí Dafidi nípa ìmọ̀ náà

15 Huṣai sì wí fún Sadoku àti fún Abiatari àwọn àlùfáà pé, “Báyìí ni Ahitofeli ti bá Absalomu àti àwọn àgbàgbà Israẹli dámọ̀ràn: báyìí lèmi sì bá a dámọ̀ràn. 16 Nítorí náà yára ránṣẹ́ nísinsin yìí kí o sì sọ fún Dafidi pé, ‘Má ṣe dúró ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ ijù náà lálẹ́ yìí, ṣùgbọ́n yára rékọjá kí a má bá a gbé ọba mì, àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ó ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ.’ ”

17 Jonatani àti Ahimasi sì dúró ní En-Rogeli ọ̀dọ́mọdébìnrin kan sì lọ, ó sì sọ fún wọn, wọ́n sì lọ wọ́n sọ fún Dafidi ọba nítorí pé kí a má bá à rí wọn pé wọ́n wọ ìlú. 18 Ṣùgbọ́n ọ̀dọ́mọdékùnrin kan rí wọn, ó sì wí fún Absalomu: ṣùgbọ́n àwọn méjèèjì sì yára lọ kúrò, wọ́n sì wá sí ilé ọkùnrin kan ní Bahurimu, ẹni tí ó ní kànga kan ní ọgbà rẹ̀, wọ́n sì sọ̀kalẹ̀ sí ibẹ̀. 19 Obìnrin rẹ̀ sì mú nǹkan ó fi bo kànga náà, ó sì sá àgbàdo sórí rẹ̀, a kò sì mọ̀.

20 Àwọn ìránṣẹ́ Absalomu sì tọ obìnrin náà wá sí ilé náà, wọ́n sì béèrè pé, “Níbo ni Ahimasi àti Jonatani gbé wà?”

Obìnrin náà sì wí fún wọn pé, “Wọ́n ti gòkè rékọjá ìṣàn odò náà.” Wọ́n sì wá wọn kiri, wọn kò sì rí wọn, wọ́n sì yípadà sí Jerusalẹmu.

21 Ó sì ṣe lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti lọ tán, àwọn ọkùnrin náà sì jáde kúrò nínú kànga, wọ́n sì lọ wọ́n sì rò fún Dafidi ọba. Wọ́n sọ fún Dafidi pé, “Dìde kí o sì gòkè odò kánkán: nítorí pé báyìí ni Ahitofeli gbìmọ̀ sí ọ.” 22 Dafidi sì dìde, àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì gòkè odò Jordani: kí ilẹ̀ tó mọ́, ènìyàn kò kù tí kò gòkè odò Jordani.

Ahitofeli pokùnso

23 Nígbà tí Ahitofeli sì rí i pé wọn kò fi ìmọ̀ tirẹ̀ ṣe, ó sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ni gàárì, ó sì dìde, ó lọ ilé rẹ̀, ó sì palẹ̀ ilé rẹ̀ mọ̀, ó sì so, ó sì kú, a sì sin ín sí ibojì baba rẹ̀. Absalomu gbógun ti Dafidi.

Galatia 3:6-14

(A)Gẹ́gẹ́ bí Abrahamu “Ó gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un.”

Ẹ jẹ́ kí ó yé é yín nígbà náà pé, àwọn ti ó gbàgbọ́, àwọn náà ní í ṣe ọmọ Abrahamu. (B)Bí ìwé mímọ́ sì tí wí tẹ́lẹ̀ pé, Ọlọ́run yóò dá aláìkọlà láre nípa ìgbàgbọ́, ó tí wàásù ìhìnrere ṣáájú fún Abrahamu, ó ń wí pé, “Nínú rẹ̀ ni a ó bùkún fún gbogbo orílẹ̀-èdè.” (C)Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwọn tí i ṣe tí ìgbàgbọ́ jẹ́ ẹni alábùkún fún pẹ̀lú Abrahamu olódodo.

10 (D)Nítorí pé iye àwọn tí ń bẹ ni ipa iṣẹ́ òfin ń bẹ lábẹ́ ègún: nítorí tí a tí kọ ọ́ pé, “Ìfibú ni olúkúlùkù ẹni tí kò dúró nínú ohun gbogbo tí a kọ sínú ìwé òfin láti máa ṣe wọ́n. 11 (E)Nítorí ó dánilójú pé, a kò dá ẹnikẹ́ni láre níwájú Ọlọ́run nípa iṣẹ́ òfin: nítorí pé, olódodo yóò yè nípa ìgbàgbọ́.” 12 (F)Òfin kì í sì í ṣe ti ìgbàgbọ́: ṣùgbọ́n “Ẹni tí ó ba ṣe, yóò yè nípa wọn.” 13 (G)Kristi ti rà wá padà kúrò lọ́wọ́ ègún òfin, ẹni tí a fi ṣe ègún fún wa: nítorí tí a ti kọ ọ́ pé, “Ìfibú ni olúkúlùkù ẹni tí a fi kọ́ sórí igi.” 14 Ó gbà wá là ki ìbùkún Abrahamu ba à lè wá sórí àwọn aláìkọlà nípa Kristi Jesu; kí àwa ba à lè gba ìlérí Ẹ̀mí nípa ìgbàgbọ́.

Johanu 5:30-47

30 (A)Èmi kò le ṣe ohun kan fún ara mi: bí mo ti ń gbọ́ ni, mo ń dájọ́: òdodo sì ni ìdájọ́ mi; nítorí èmi kò wá ìfẹ́ ti èmi fúnra mi, bí kò ṣe ìfẹ́ ti ẹni tí ó rán mi.

Àwọn ẹ̀rí nípa Jesu

31 (B)“Bí èmi bá ń jẹ́rìí ara mi, ẹ̀rí mi kì í ṣe òtítọ́. 32 Ẹlòmíràn ni ẹni tí ń jẹ́rìí mi; èmi sì mọ̀ pé, òtítọ́ ni ẹ̀rí mi tí ó jẹ́.

33 (C)“Ẹ̀yin ti ránṣẹ́ lọ sọ́dọ̀ Johanu, òun sì ti jẹ́rìí sí òtítọ́. 34 (D)Ṣùgbọ́n èmi kò gba jẹ́rìí lọ́dọ̀ ènìyàn: nǹkan wọ̀nyí ni èmi ń sọ, kí ẹ̀yin lè là. 35 Òun ni fìtílà tí ó ń jó, tí ó sì ń tànmọ́lẹ̀: ẹ̀yin sì fẹ́ fún sá à kan láti máa yọ̀ nínú ìmọ́lẹ̀ rẹ̀.

36 (E)“Ṣùgbọ́n èmi ní ẹ̀rí tí ó pọ̀jù ti Johanu lọ: nítorí iṣẹ́ tí Baba ti fi fún mi láti ṣe parí, iṣẹ́ náà pàápàá tí èmi ń ṣe náà ń jẹ́rìí mi pé, Baba ni ó rán mi. 37 Àti Baba tìkára rẹ̀ tí ó rán mi ti jẹ́rìí mi. Ẹ̀yin kò gbọ́ ohùn rẹ̀ nígbà kan rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò rí ìrísí rẹ̀. 38 Ẹ kò sì ní ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti máa gbé inú yín: nítorí ẹni tí ó rán, òun ni ẹ̀yin kò gbàgbọ́. 39 (F)Ẹ̀yin ń wá ìwé mímọ́ nítorí ẹ̀yin rò pé nínú wọn ni ẹ̀yin ní ìyè tí kò nípẹ̀kun. Wọ̀nyí sì ni àwọn tí ó ń jẹ́rìí mi. 40 Ẹ̀yin kò sì fẹ́ láti wá sọ́dọ̀ mi, kí ẹ̀yin ba à lè ní ìyè.

41 “Èmi kò gba ògo lọ́dọ̀ ènìyàn. 42 Ṣùgbọ́n èmi mọ̀ pé, ẹ̀yin fúnrayín kò ní ìfẹ́ Ọlọ́run nínú yín. 43 (G)Èmi wá ní orúkọ Baba mi, ẹ̀yin kò sì gbà mí; bí ẹlòmíràn bá wá ní orúkọ ara rẹ̀, òun ni ẹ̀yin yóò gbà. 44 Ẹ̀yin ó ti ṣe lè gbàgbọ́, ẹ̀yin tí ń gba ògo lọ́dọ̀ ara yín tí kò wá ògo tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nìkan wá?

45 (H)“Ẹ má ṣe rò pé, èmi ó fi yín sùn lọ́dọ̀ Baba: ẹni tí ń fi yín sùn wà, àní Mose, ẹni tí ẹ̀yin gbẹ́kẹ̀lé. 46 Nítorí pé ẹ̀yin ìbá gba Mose gbọ́, ẹ̀yin ìbá gbà mí gbọ́: nítorí ó kọ ìwé nípa tèmi. 47 (I)Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá gba ìwé rẹ̀ gbọ́, ẹ̀yin ó ti ṣe gbà ọ̀rọ̀ mi gbọ́?”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.