Book of Common Prayer
Fún adarí orin. Ohun èlò orin olókùn. Ti Dafidi.
61 Gbọ́ ẹkún mi, Ọlọ́run;
Tẹ́tí sí àdúrà mi.
2 Láti òpin ayé wá ni èmi yóò pè ọ́,
mo pè nígbà àyà mi ń ṣàárẹ̀;
mú mi lọ sí ibi àpáta tí ó ga jù mí lọ.
3 Nítorí ìwọ ti jẹ́ ibi ààbò mi,
ilé ìṣọ́ agbára àwọn ọ̀tá.
4 Mo ń lépa láti máa gbé nínú àgọ́ rẹ títí láé
kí n sì rí ààbò níbi ìyẹ́ apá rẹ.
5 Nítorí ìwọ ti gbọ́ àwọn ẹ̀jẹ́ mi, Ọlọ́run;
Ìwọ ti fún mi ní ogún àwọn tí ó bẹ̀rù orúkọ rẹ.
6 Jẹ́ kí ẹ̀mí ọba kí ó gùn,
ọdún rẹ̀ fún ìrandíran.
7 Kí ó máa jẹ ọba níwájú Ọlọ́run títí láé;
pèsè àánú àti òtítọ́ rẹ tí yóò máa ṣe ìtọ́jú rẹ.
8 Nígbà náà ni èmi ó máa kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ títí láé
kí n san ẹ̀jẹ́ mi ní ojoojúmọ́.
Fún adarí orin. Fun Jedutuni. Saamu Dafidi.
62 Nínú Ọlọ́run nìkan ni ọkàn mi ti rí ìsinmi;
ìgbàlà mi ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá.
2 Òun nìkan ní àpáta mi àti ìgbàlà mi;
Òun ni ààbò mi, a kì yóò sí mi ní ipò padà.
3 Ẹ̀yin ó ti máa kọ́lú ènìyàn kan pẹ́ tó?
Gbogbo yín ni ó fẹ́ pa á,
bí ògiri tí ó fẹ́ yẹ̀, àti bí ọgbà tí ń wó lọ?
4 Kìkì èrò wọn ni láti bì ṣubú
kúrò nínú ọlá rẹ̀;
inú wọn dùn sí irọ́.
Wọ́n ń fi ẹnu wọn súre,
ṣùgbọ́n wọ́n ń gégùn ún nínú ọkàn wọn. Sela.
5 Nínú Ọlọ́run nìkan ni ìsinmi wà, ìwọ Ọlọ́run mi.
Ìrètí mi wá láti ọ̀dọ̀ rẹ.
6 Òun nìkan ní àpáta àti ìgbàlà mi;
Òun ni ààbò mi, a kì yóò ṣí mi ní ipò.
7 Ìgbàlà mi àti ògo mi dúró nínú Ọlọ́run;
Òun ní àpáta ńlá mi, àti ààbò mi.
8 Gbẹ́kẹ̀lé ní gbogbo ìgbà, ẹ̀yin ènìyàn;
tú ọkàn rẹ jáde sí i,
nítorí Ọlọ́run ni ààbò wa.
9 Nítòótọ́, asán ni àwọn ọmọ ènìyàn, èké
sì ni àwọn olóyè, wọ́n gòkè nínú ìwọ̀n,
lápapọ̀ wọ́n jẹ́ èémí.
10 Má ṣe gbẹ́kẹ̀lé ìnilára,
tàbí gbéraga nínú olè jíjà,
nítòótọ́ bí ọrọ̀ rẹ̀ ń pọ̀ sí i,
má ṣe gbẹ́kẹ̀ rẹ lé wọn.
11 Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kejì, ni mo
gbọ́ èyí pé, ti Ọlọ́run ni agbára
12 (A)Pẹ̀lúpẹ̀lú, Olúwa, tìrẹ ni àánú
nítorí tí ìwọ san án fún olúkúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.
Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu. Orin.
68 Kí Ọlọ́run kí ó dìde, kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ kí ó fọ́nká;
kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ kí ó sá níwájú rẹ̀.
2 Bí ìjì ti ń fẹ́ èéfín lọ,
kí ó fẹ́ wọn lọ;
bí ìda ti í yọ́ níwájú iná,
kí olùṣe búburú ṣègbé níwájú Ọlọ́run.
3 Ṣùgbọ́n kí inú olódodo kí ó dùn
kí ó sì kún fún ayọ̀ níwájú Ọlọ́run;
kí inú wọn kí ó dùn, kí ó sì kún fún ayọ̀.
4 Ẹ kọrin sí Ọlọ́run,
ẹ kọrin ìyìn sí i,
ẹ la ọ̀nà fún ẹni tí ń rékọjá ní aginjù.
Olúwa ni orúkọ rẹ̀, kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú rẹ̀.
5 Baba àwọn aláìní baba àti onídàájọ́ àwọn opó ni Ọlọ́run ní ibùgbé
rẹ̀ mímọ́
6 Ọlọ́run gbé aláìlera
kalẹ̀ nínú ìdílé,
ó darí àwọn ẹlẹ́wọ̀n pẹ̀lú orin,
ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́tẹ̀ ní ń gbé nínú ilẹ̀ gbígbẹ.
7 Nígbà tí ìwọ bá jáde lónìí níwájú àwọn ènìyàn rẹ, Ọlọ́run,
tí ń kọjá lọ láàrín aginjù, Sela.
8 Ilẹ̀ mì títí,
àwọn ọ̀run ń rọ òjò jáde,
níwájú Ọlọ́run,
ẹni Sinai,
níwájú Ọlọ́run, Ọlọ́run Israẹli.
9 Ìwọ fún wa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ òjò, Ọlọ́run;
ìwọ tu ilẹ̀ ìní rẹ̀ lára nígbà tí ó rẹ̀ ẹ́ tan.
10 Àwọn ènìyàn rẹ tẹ̀dó síbẹ̀
nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìní rẹ, Ọlọ́run, ìwọ pèsè fún àwọn aláìní.
11 Olúwa ti pàṣẹ ọ̀rọ̀,
púpọ̀ ní ogun àwọn ẹni tí ó ń ròyìn rẹ̀.
12 “Àwọn ọba àti àwọn ológun yára sálọ;
Obìnrin tí ó sì jókòó ni ilé ní ń pín ìkógun náà.
13 Nígbà tí ẹ̀yin dùbúlẹ̀ láàrín agbo ẹran,
nígbà náà ni ẹ̀yin ó dàbí ìyẹ́ àdàbà ti a bò ní fàdákà,
àti ìyẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú wúrà pupa.”
14 Nígbà tí Olódùmarè fọ́n àwọn ọba ká ní ilẹ̀ náà,
ó dàbí òjò dídi ní Salmoni.
15 Òkè Baṣani jẹ́ òkè Ọlọ́run;
òkè tí ó ní orí púpọ̀ ni òkè Baṣani.
16 Kí ló dé tí ẹ̀yin fi ń ṣe ìlara,
ẹ̀yin òkè wúwo, òkè tí Ọlọ́run ti fẹ́ láti jẹ ọba
níbi tí Ọlọ́run fúnrarẹ̀ yóò máa gbé títí láé?
17 Ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ni kẹ̀kẹ́ ogun Ọlọ́run
ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún;
Olúwa ń bẹ láàrín wọn, ní Sinai ni ibi mímọ́ rẹ̀.
18 Ìwọ ti gòkè sí ibi gíga
ìwọ ti di ìgbèkùn ní ìgbèkùn lọ;
ìwọ ti gba ẹ̀bùn fún ènìyàn:
nítòótọ́, fún àwọn ọlọ̀tẹ̀ pẹ̀lú,
Kí Olúwa Ọlọ́run lè máa bá wọn gbé.
19 Olùbùkún ni Olúwa,
Ọlọ́run Olùgbàlà wa,
ẹni tí ó ń fi ojoojúmọ́ gba ẹrù wa rù. Sela.
20 Ọlọ́run wa jẹ́ Ọlọ́run tó ń gbàlà
àti sí Olúwa Olódùmarè ni ó ń gbà wá lọ́wọ́ ikú.
21 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò tẹ orí àwọn ọ̀tá rẹ̀,
àti agbárí onírun àwọn tó ń tẹ̀síwájú nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn
22 Olúwa wí pé, “Èmi ó mú wọn wá láti Baṣani;
èmi ó mú wọn wá láti ibú omi Òkun,
23 Kí ẹsẹ̀ rẹ kí ó le pọ́n ní inú ẹ̀jẹ̀ àwọn ọ̀tá rẹ,
àti ahọ́n àwọn ajá rẹ ní ìpín tiwọn lára àwọn ọ̀tá rẹ.”
24 Wọ́n ti rí ìrìn rẹ, Ọlọ́run,
ìrìn Ọlọ́run mi àti ọba mi ní ibi mímọ́ rẹ̀.
25 Àwọn akọrin ní iwájú,
tí wọn ń lu ṣaworo
26 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa ní ẹgbẹgbẹ́;
àní fún Olúwa ẹ̀yin tí ó ti orísun Israẹli wá.
27 Níbẹ̀ ní ẹ̀yà kékeré Benjamini wà, tí ó ń darí wọn,
níbẹ̀ ni àwọn ọmọ-aládé Juda,
níbẹ̀ ni àwọn ọmọ-aládé Sebuluni àti tí Naftali.
28 Pàṣẹ agbára rẹ, Ọlọ́run;
fi agbára rẹ hàn wá, Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti ṣe ní ìṣáájú.
29 Nítorí tẹmpili rẹ ni Jerusalẹmu
àwọn ọba yóò mú ẹ̀bùn wá fún ọ.
30 Bá àwọn ẹranko búburú wí,
tí ń gbé láàrín eèsún
ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn akọ màlúù
pẹ̀lú àwọn ọmọ màlúù
títí olúkúlùkù yóò fi foríbalẹ̀ pẹ̀lú ìwọ̀n fàdákà:
tú àwọn ènìyàn tí ń ṣe inú dídùn sí ogun ká
31 Àwọn ọmọ-aládé yóò wá láti Ejibiti;
Etiopia yóò na ọwọ́ rẹ̀ sí Ọlọ́run.
32 Kọrin sí Ọlọ́run, ẹ̀yin ìjọba ayé,
kọrin ìyìn sí Olúwa, Sela.
33 Sí ẹni tí ń gun ọ̀run dé ọ̀run àtijọ́ lókè,
tó ń fọhùn rẹ̀, ohùn ńlá.
34 Kéde agbára Ọlọ́run,
ọláńlá rẹ̀ wà lórí Israẹli,
tí agbára rẹ̀ wà lójú ọ̀run.
35 Ìwọ ní ẹ̀rù, Ọlọ́run, ní ibi mímọ́ rẹ;
Ọlọ́run Israẹli fi agbára àti okun fún àwọn ènìyàn rẹ.
Olùbùkún ní Ọlọ́run!
Angẹli Olúwa ní Bokimu
2 Ní ọjọ́ kan angẹli Olúwa dìde kúrò láti Gilgali lọ sí Bokimu ó sì wí pé, “Èmi mú un yín gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti wá, èmi sì síwájú yín wá sí ilẹ̀ tí mo ti búra láti fi fún àwọn baba ńlá yín. Èmi sì wí pé, ‘Èmi kì yóò yẹ májẹ̀mú mi pẹ̀lú yín, 2 ẹ̀yin kò gbọdọ̀ bá àwọn ènìyàn ilẹ̀ yí dá májẹ̀mú àlàáfíà, ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò wó pẹpẹ ibi ìsin òrìṣà wọn lulẹ̀.’ Síbẹ̀ ẹ̀yin ṣe àìgbọ́ràn sí mi. Èéṣe tí ẹ̀yin fi ṣe èyí? 3 Ní báyìí, èmi wí fún un yín pé, èmi kì yóò lé àwọn ènìyàn jáde kúrò níwájú yín; ṣùgbọ́n wọn yóò jẹ́ ẹ̀gún ní ìhà yín, àwọn òrìṣà wọn yóò sì jẹ́ ìdánwò fún un yín.”
4 Bí angẹli Olúwa sì ti sọ gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún àwọn ará Israẹli tan, àwọn ènìyàn náà sì gbé ohùn wọn sókè wọ́n sì sọkún kíkorò, 5 wọ́n sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Bokimu (ibi tí àwọn ènìyàn ti sọkún). Wọ́n sì rú ẹbọ sí Olúwa níbẹ̀.
11 Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe ohun tí ó burú níwájú Olúwa, wọ́n sì ń sin òrìṣà Baali. 12 Wọ́n kọ Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn sílẹ̀, ẹni tí ó mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, wọ́n ń tọ àwọn òrìṣà lẹ́yìn, wọ́n sì ń sin àwọn oríṣìíríṣìí òrìṣà àwọn ará ilẹ̀ ibi tí wọ́n ń gbé, wọ́n sì mú Olúwa bínú, 13 nítorí tí wọ́n kọ̀ Olúwa sílẹ̀ àti nítorí pé wọ́n ń sin Baali àti Aṣtoreti. 14 Nínú ìbínú rẹ̀ sí àwọn ọmọ Israẹli Olúwa fi wọ́n lé àwọn akónisìn lọ́wọ́ tí ó kó wọn ní ẹrú, tí ó sì bà wọ́n jẹ́. Ó sì tà wọ́n fún àwọn ọ̀tá wọn tí ó yí wọn ká àwọn ẹni tí wọn kò le dúró dè láti kọ ojú ìjà sí. 15 Nígbàkígbà tí àwọn Israẹli bá jáde lọ sí ojú ogun láti jà, ọwọ́ Olúwa sì wúwo ní ara wọn, àwọn ọ̀tá a sì borí wọn, àní gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún wọn. Wọ́n sì wà nínú ìpọ́njú púpọ̀.
16 Olúwa sì gbé àwọn onídàájọ́ dìde tí ó gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tí ń kó wọn lẹ́rú. 17 Síbẹ̀síbẹ̀ wọn kò fi etí sí ti àwọn onídàájọ́ wọn, ṣùgbọ́n wọ́n ṣe àgbèrè, wọ́n ń sin òrìṣà. Wọn kò dàbí àwọn baba wọn, kíákíá ni wọ́n yípadà kúrò lọ́nà tí àwọn baba wọ́n ń tọ̀, ọ̀nà ìgbọ́ràn sí àwọn òfin Olúwa. 18 Nígbà kí ìgbà tí Olúwa bá gbé onídàájọ́ dìde fún wọn, Olúwa máa ń wà pẹ̀lú onídàájọ́ náà, a sì gbà wọ́n kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá wọn ní ìwọ̀n ìgbà tí onídàájọ́ náà bá wà láààyè nítorí àánú Olúwa wà ní ara wọn, nígbà tí wọ́n bá ké ìrora lábẹ́ àwọn tí ń tẹrí wọn ba, tí sì ń fi ìyà jẹ wọ́n. 19 Ṣùgbọ́n ní kété tí onídàájọ́ bá ti kú, àwọn ènìyàn náà a sì tún padà sí ọ̀nà ìbàjẹ́ àní ju ti àwọn baba wọn lọ, wọn a tẹ̀lé òrìṣà, wọ́n ń sìn wọ́n, wọn a sì foríbalẹ̀ fún wọn, wọ́n kọ̀ láti yàgò kúrò ní ọ̀nà ibi wọn àti agídí ọkàn wọn.
20 Ìbínú Olúwa yóò sì tún ru sí Israẹli a sì wí pé, “Nítorí tí orílẹ̀-èdè yìí ti yẹ májẹ̀mú tí mo fi lélẹ̀ fún àwọn baba ńlá wọn, tí wọn kò sì fetí sí mi, 21 Èmi kì yóò lé ọ̀kankan nínú àwọn orílẹ̀-èdè tí Joṣua fi sílẹ̀ nígbà tí ó kú jáde. 22 Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀ èmi yóò lo àwọn orílẹ̀-èdè yìí láti fi dán Israẹli wò, láti mọ̀ bóyá wọ́n yóò pa ọ̀nà Olúwa mọ́ àti pé bóyá wọn ó rìn nínú rẹ̀ bí àwọn baba ńlá wọn ti rìn.” 23 Nítorí náà Olúwa fi àwọn orílẹ̀-èdè náà sílẹ̀ ní ilẹ̀ náà kò sì lé wọn jáde, tàbí kí ó jẹ́ kí àwọn Israẹli pa wọ́n run, bẹ́ẹ̀ kò sì fi wọ́n lé Joṣua lọ́wọ́.
17 (A)Èmí rọ̀ yín, ara, kí ẹ máa sọ àwọn tí ń fa ìyapa, àti àwọn tí ń mú ohun ìkọ̀sẹ̀ wá sí ọ̀nà yín, èyí tí ó lòdì sí ẹ̀kọ́ tí ẹ̀yin kọ́. Ẹ yà kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn. 18 Nítorí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kò sin Kristi Olúwa wa, bí kò ṣe ikùn ara wọn. Nípa ọ̀rọ̀ rere àti ọ̀rọ̀ dídùndídùn ni wọ́n fi ń yí àwọn aláìmọ̀kan ní ọkàn padà. 19 (B)Nítorí ìgbọ́ràn yín tànkálẹ̀ dé ibi gbogbo, nítorí náà mo ní ayọ̀ lórí yín; ṣùgbọ́n èmi fẹ́ kí ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n sí ohun tí ó ṣe rere, kí ẹ sì ṣe òpè sí ohun tí í ṣe búburú.
20 (C)Ọlọ́run àlàáfíà yóò sì tẹ Satani mọ́lẹ̀ ní àtẹ́lẹsẹ̀ yín ní lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí.
Oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa wa kí ó wà pẹ̀lú yín.
21 (D)Timotiu alábáṣiṣẹ́ mi, àti Lukiu, àti Jasoni, àti Sosipateru, àwọn ìbátan mi, kí yín.
22 Èmi Tertiu tí ń kọ lẹ́tà yìí, kí yín nínú Olúwa.
23 (E)Gaiu, ẹni tí èmi àti gbogbo ìjọ gbádùn ìtọ́jú wa tí ó ṣe náà fi ìkíni ránṣẹ́.
Erastu, ẹni tí ó jẹ́ olùtọ́jú ìṣúra ìlú, àti arákùnrin wa Kuartu fi ìkíni wọn ránṣẹ́.
24 Ǹjẹ́ kí oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa wa, kí ó wà pẹ̀lú gbogbo yín. Àmín.
25 Ǹjẹ́ fún ẹni tí ó ní agbára láti fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀ nípa ìhìnrere mi àti ìpolongo Jesu Kristi, gẹ́gẹ́ bí ìṣípayá ohun ìjìnlẹ̀ tí a ti pamọ́ láti ìgbà ayérayé, 26 ṣùgbọ́n, nísinsin yìí, a ti fihàn nípa ìwé mímọ́ àwọn wòlíì, àti gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Ọlọ́run ayérayé pa, kí gbogbo orílẹ̀-èdè le ní ìgbọ́ràn tí ó wá láti inú ìgbàgbọ́; 27 kí ògo wà fún Ọlọ́run, Ẹnìkan ṣoṣo tí ọgbọ́n í ṣe tirẹ̀ nípa Jesu Kristi títí láé! Àmín.
A kan Jesu mọ́ àgbélébùú
32 (A)Bí wọ́n sì ti ń jáde, wọ́n rí ọkùnrin kan ará Kirene tí à ń pè ní Simoni. Wọ́n sì mú ọkùnrin náà ní túláàsì láti ru àgbélébùú Jesu. 33 (B)Wọ́n sì jáde lọ sí àdúgbò kan tí à ń pè ní Gọlgọta, (èyí tí í ṣe Ibi Agbárí.) 34 Níbẹ̀ ni wọn ti fún un ni ọtí wáìnì tí ó ní egbòogi nínú láti mu. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó tọ́ ọ wò, ó kọ̀ láti mu ún. 35 (C)Lẹ́yìn tí wọ́n sì ti kàn án mọ́ àgbélébùú, wọ́n dìbò láti pín aṣọ rẹ̀ láàrín ara wọn. 36 Nígbà náà ni wọ́n jókòó yí i ká. Wọ́n ń ṣọ́ ọ níbẹ̀. 37 Ní òkè orí rẹ̀, wọ́n kọ ohun kan tí ó kà báyìí pé:
“èyí ni jesu, ọba àwọn júù”
síbẹ̀. 38 Wọ́n kan àwọn olè méjì pẹ̀lú rẹ̀ ní òwúrọ̀ náà. Ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún, àti èkejì ní ọwọ́ òsì rẹ̀. 39 (D)Àwọn tí ń kọjá lọ sì ń bú u. Wọ́n sì ń mi orí wọn pé: 40 (E)“Ìwọ tí yóò wó tẹmpili, ìwọ tí yóò sì tún un mọ ní ọjọ́ kẹta. Bí ó bá jẹ́ pé Ọmọ Ọlọ́run ni ìwọ, sọ̀kalẹ̀ láti orí igi àgbélébùú, kí ó sì gba ara rẹ là!”
41 Bákan náà àwọn olórí àlùfáà pẹ̀lú àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn àgbàgbà Júù sì fi í ṣe ẹlẹ́yà. 42 Wọ́n kẹ́gàn rẹ̀ pé, “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là, kò sí lè gba ara rẹ̀. Ìwọ ọba àwọn Israẹli? Sọ̀kalẹ̀ láti orí àgbélébùú nísinsin yìí, àwa yóò sì gbà ọ́ gbọ́. 43 Ó gba Ọlọ́run gbọ́, jẹ́ kí Ọlọ́run gbà á là ní ìsinsin yìí tí òun bá fẹ́ ẹ. Ǹjẹ́ òun kò wí pé, èmi ni Ọmọ Ọlọ́run?” 44 Bákan náà, àwọn olè tí a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀ fi í ṣe ẹlẹ́yà.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.