Book of Common Prayer
Fún adarí orin. Saamu Dafidi.
41 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ń ro ti aláìní:
Olúwa yóò gbà á ní ìgbà ìpọ́njú.
2 Olúwa yóò dáàbò bò ó yóò sì pa ọkàn rẹ̀ mọ́:
yóò bùkún fún un ní orí ilẹ̀
kò sì ní fi sílẹ̀ fún ìfẹ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀.
3 Olúwa yóò gbà á lórí àkéte àìsàn rẹ̀
yóò sì mú un padà bọ̀ sípò kúrò nínú àìsàn rẹ̀.
4 Ní ti èmi, mo wí pé “Olúwa, ṣàánú fún mi;
wò mí sàn, nítorí pé mo ti ṣẹ̀ sí ọ”.
5 Àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀ mi nínú àrankàn, pé
“Nígbà wo ni yóò kú, ti orúkọ rẹ̀ yóò sì run?”
6 Nígbàkígbà tí ẹnìkan bá wá wò mí,
wọn ń sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn, nígbà tí àyà rẹ̀ bá kó ẹ̀ṣẹ̀ jọ sí ara rẹ̀;
nígbà tí ó bá jáde lọ yóò sì máa tàn án kálẹ̀.
7 Àwọn ọ̀tá mi gbìmọ̀ papọ̀ nípa mi;
èmi ni wọ́n ń gbìmọ̀ ibi sí,
8 wọ́n wí pé, “Ohun búburú ni ó dì mọ́ ọn ṣinṣin
àti ní ibi tí ó dùbúlẹ̀ sí,
kì yóò dìde mọ́.”
9 (A)Pàápàá, ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́, ẹni tí mo gbẹ́kẹ̀lé,
ẹni tí ó ń jẹ nínú oúnjẹ mi,
tí gbé gìgísẹ̀ rẹ̀ sókè sí mi.
10 Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa, ṣàánú fún mi;
gbé mi sókè, kí ń ba lè san fún wọn.
11 Èmi mọ̀ pé inú rẹ̀ dùn sí mi,
nítorí ọ̀tá mi kò borí mi.
12 Bí ó ṣe tèmi ni
ìwọ dì mímú nínú ìwà òtítọ́ mi
ìwọ sì gbé mi kalẹ̀ níwájú rẹ títí láé.
13 Olùbùkún ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli
láé àti láéláé.
Àmín àti Àmín.
Fún adarí orin. Maskili ti Dafidi. Nígbà tí Doegi ará Edomu tọ Saulu lọ láti sọ fún pé, “Dafidi wà ní ilé Ahimeleki.”
52 Èéṣe tí ìwọ fi ń ṣe féfé nínú ìwà ìkà, ìwọ alágbára ọkùnrin?
Èéṣe tí ìwọ fi ń gbéraga nígbà gbogbo,
ìwọ ẹni ẹ̀gàn níwájú Ọlọ́run?
2 Ahọ́n rẹ̀ ń gbìmọ̀ ìparun;
ó dàbí abẹ mímú,
ìwọ ẹni tí ń hùwà ẹ̀tàn.
3 Ìwọ fẹ́ràn ibi ju ìre lọ,
àti èké ju kí ó sọ òtítọ́ lọ.
4 Ìwọ fẹ́ràn ọ̀rọ̀ ìpanilára gbogbo,
ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn!
5 Ọlọ́run yóò sì lù ọ́ bolẹ̀ láéláé,
yóò sì dì ọ́ mú,
yóò sì já ọ kúrò ni ibùjókòó rẹ,
yóò sì fà ọ́ tu kúrò lórí ilẹ̀ alààyè. Sela.
6 Àwọn olódodo yóò rí, wọn yóò sì bẹ̀rù
wọn yóò sì rẹ́rìn-ín rẹ̀, wí pé,
7 “Èyí ni ọkùnrin náà ti kò fi Ọlọ́run ṣe agbára rẹ̀,
bí kò ṣe ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ rẹ̀ ni ó gbẹ́kẹ̀lé,
ó sì mu ara rẹ̀ le nínú ìwà búburú rẹ̀.”
8 Ṣùgbọ́n èmi dàbí igi Olifi
tí ó gbilẹ̀ nínú ilé Ọlọ́run;
Èmi gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í kùnà
láé àti láéláé.
9 Èmi yóò yìn ọ títí fún ohun tí ó ti ṣe;
èmi ní ìrètí nínú orúkọ rẹ,
nítorí orúkọ rẹ dára.
Èmi yóò yìn ọ́ níwájú àwọn ènìyàn mímọ́.
Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Maskili.
44 À ti fi etí wa gbọ́, Ọlọ́run
àwọn baba wa tí sọ fún wa
ohun tí ìwọ ṣe ní ọjọ́ wọn,
ní ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn.
2 Ìwọ fi ọwọ́ rẹ lé orílẹ̀-èdè jáde
Ìwọ sì gbin àwọn baba wa;
Ìwọ run àwọn ènìyàn náà
Ìwọ sì mú àwọn baba wa gbilẹ̀.
3 Kì í ṣe nípa idà wọn ni wọ́n gba ilẹ̀ náà,
bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe apá wọn ní ó gbà wọ́n bí kò ṣe;
ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti, apá rẹ;
àti ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ̀, nítorí ìwọ fẹ́ wọn.
4 Ìwọ ni ọba àti Ọlọ́run mi,
ẹni tí ó pàṣẹ ìṣẹ́gun fún Jakọbu.
5 Nípasẹ̀ rẹ ni àwa ó bi àwọn ọ̀tá wa ṣubú;
nípasẹ̀ orúkọ rẹ ni àwa ó tẹ àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí wa mọ́lẹ̀
6 Èmi kì yóò gbẹ́kẹ̀lé ọrun mi
idà mi kì yóò mú ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá wá,
7 Ṣùgbọ́n ìwọ fún wa ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá wa,
ìwọ sì ti dójúti àwọn tí ó kórìíra wa.
8 Nínú Ọlọ́run àwa ń ṣògo ní gbogbo ọjọ́,
àwa ó sì yin orúkọ rẹ títí láé. Sela.
9 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ìwọ ti kọ̀ wá, ìwọ sì ti dójútì wá;
Ìwọ kò sì bá àwọn ọmọ-ogun wa jáde mọ́.
10 Ìwọ ti bá wa jà,
ìwọ sì ti ṣẹ́gun wa níwájú àwọn ọ̀tá wa,
àwọn ọ̀tá wa ti gba ilẹ̀ wa,
wọ́n sì fi ipá gba oko wa.
11 Ìwọ fi wá fún jíjẹ bí ẹran àgùntàn
Ìwọ sì ti tú wa ká sí àárín àwọn kèfèrí.
12 Ìwọ ta àwọn ènìyàn rẹ fún owó kékeré,
Ìwọ kò sì jẹ èrè kankan lórí iye tí ìwọ tà wọ́n.
13 Ìwọ sọ wá di ẹni ẹ̀sín ní ọ̀dọ̀ àwọn aládùúgbò wa,
ẹlẹ́yà àti ẹni àbùkù sí àwọn tí ó yí wa ká.
14 Ìwọ ti sọ wá di ẹni ìfisọ̀rọ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè;
àwọn ènìyàn ń mi orí wọn sí wa.
15 Ìdójútì mi ń bẹ pẹ̀lú mi ní gbogbo ọjọ́,
ìtìjú sì bojú mi mọ́lẹ̀,
16 nítorí ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn àti ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn
ní ojú àwọn ọ̀tá àti olùgbẹ̀san.
17 Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ń ṣẹlẹ̀ sí wa,
síbẹ̀ àwa kò gbàgbé rẹ
bẹ́ẹ̀ ni a kò ṣèké sí májẹ̀mú rẹ̀.
18 Ọkàn wa kò padà sẹ́yìn;
bẹ́ẹ̀ ni ẹsẹ̀ wa kò yẹ̀ kúrò ní ọ̀nà rẹ̀.
19 Ṣùgbọ́n wọ́n kọlù wá,
ìwọ sì sọ wá di ẹran ọdẹ fún àwọn ẹranko búburú,
tí wọn sì fi òkùnkùn biribiri bò wá mọ́lẹ̀.
20 Bí àwa bá ti gbàgbé orúkọ Ọlọ́run wa
tàbí tí a na ọwọ́ wa sí ọlọ́run àjèjì.
21 Ǹjẹ́ Ọlọ́run kì yóò rí ìdí rẹ̀,
níwọ̀n ìgbà tí ó mọ ohun ìkọ̀kọ̀ inú ọkàn?
22 (A)Síbẹ̀, nítorí rẹ̀ àwa da àyà kọ ikú, ní ojoojúmọ́
a ń kà wá sí bí àgùntàn fún pípa.
23 Jí, Olúwa! Èéṣe tí ìwọ ń sùn?
Dìde fúnrarẹ̀! Má ṣe kọ̀ wá sílẹ̀ láéláé.
24 Èéṣe tí ìwọ ń pa ojú rẹ mọ́
tí ìwọ sì gbàgbé ìpọ́njú àti ìnira wa?
25 Nítorí a tẹrí ọkàn wa ba sínú eruku;
ara wa sì dì mọ́ erùpẹ̀ ilẹ̀.
26 Dìde kí o sì ràn wá lọ́wọ́;
rà wá padà nítorí ìfẹ́ rẹ tí ó dúró ṣinṣin.
Ẹ̀ṣẹ̀ Akani
7 Ṣùgbọ́n àwọn ará Israẹli ṣe àìṣòótọ́ nípa ohun ìyàsọ́tọ̀, Akani ọmọ Karmi, ọmọ Sabdi, ọmọ Sera, ẹ̀yà Juda, mú nínú wọn. Bẹ́ẹ̀ ni ìbínú Olúwa ru sí àwọn ará Israẹli.
2 Joṣua rán àwọn ọkùnrin láti Jeriko lọ sí Ai, tí ó súnmọ́ Beti-Afeni ní ìlà-oòrùn Beteli, ó sì sọ fún wọn pé, “Ẹ gòkè lọ kí ẹ sì ṣe ayọ́lẹ̀wò.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn arákùnrin náà lọ, wọ́n sì yọ́ Ai wò.
3 Nígbà tí wọ́n padà sí ọ̀dọ̀ Joṣua, wọ́n wí pé, “Kì í ṣe gbogbo àwọn ènìyàn ni ó ni láti gòkè lọ bá Ai jà. Rán ẹgbẹ̀rún méjì tàbí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọkùnrin láti gbà á, kí ó má ṣe dá gbogbo àwọn ènìyàn ní agara, nítorí ìba ọkùnrin díẹ̀ ní ó wà níbẹ̀.” 4 Bẹ́ẹ̀ ní àwọn bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọkùnrin lọ; ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Ai lé wọn sá, 5 Àwọn ènìyàn Ai sì pa àwọn bí mẹ́rìn-dínlógójì nínú wọn. Wọ́n sì ń lépa àwọn ará Israẹli láti ibodè ìlú títí dé Ṣebarimu, wọ́n sì pa àwọn tí ń sọ̀kalẹ̀. Àyà àwọn ènìyàn náà sì já, ọkàn wọn sì pami.
6 Joṣua sì fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì dojúbolẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa títí di àṣálẹ́. Àwọn àgbà Israẹli sì ṣe bákan náà, wọ́n ku eruku sí orí wọn. 7 Joṣua sì wí pé, “Háà, Olúwa Olódùmarè, nítorí kín ni ìwọ ṣe mú àwọn ènìyàn yìí kọjá Jordani, láti fi wọ́n lé àwọn ará Amori lọ́wọ́, láti pa wọn run? Àwa ìbá mọ̀ kí a dúró ní òdìkejì Jordani? 8 Olúwa, kín ni èmi yóò sọ nísinsin yìí tí Israẹli sì ti sá níwájú ọ̀tá a rẹ̀? 9 Àwọn Kenaani àti àwọn ènìyàn ìlú tí ó kù náà yóò gbọ́ èyí, wọn yóò sì yí wa ká, wọn yóò sì ké orúkọ wa kúrò ní ayé. Kí ni ìwọ ó ha ṣe fún orúkọ ńlá à rẹ?”
10 Olúwa sì sọ fún Joṣua pé, “Dìde! Kín ni ìwọ ń ṣe tí ó fi dojúbolẹ̀? 11 Israẹli ti ṣẹ̀; Wọ́n sì ti ba májẹ̀mú mi jẹ́, èyí tí mo pàṣẹ fún wọn pé kí wọn pamọ́. Wọ́n ti mú nínú ohun ìyàsọ́tọ̀, wọ́n ti jí, wọ́n pa irọ́, Wọ́n ti fi wọ́n sí ara ohun ìní wọn. 12 Ìdí nì èyí tí àwọn ará Israẹli kò fi lè dúró níwájú àwọn ọ̀tá wọn; wọ́n yí ẹ̀yìn wọn padà, wọ́n sì sálọ níwájú ọ̀tá a wọn nítorí pé àwọn gan an ti di ẹni ìparun. Èmi kì yóò wà pẹ̀lú u yín mọ́, bí kò ṣe pé ẹ̀yin pa ohun ìyàsọ́tọ̀ run kúrò ní àárín yín.
13 “Lọ, ya àwọn ènìyàn náà sí mímọ́. Sọ fún wọn pé, ‘Ẹ ya ara yín sí mímọ́ fún ọ̀la, nítorí báyìí ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli wí: Ohun ìyàsọ́tọ̀ kan ń bẹ ní àárín yín, Israẹli. Ẹ̀yin kì yóò lè dúró níwájú àwọn ọ̀tá a yín títí ẹ̀yin yóò fi mú kúrò.
Ẹ jẹ gbèsè ìfẹ́
8 (A)Ẹ má ṣe jẹ ẹnikẹ́ni nígbésè ohun kan, bí kò ṣe pé kí a fẹ́ ọmọ ẹnìkejì ẹni, nítorí ẹni tí ó bá fẹ́ ọmọnìkejì rẹ̀, ó kó òfin já. 9 (B)Àwọn òfin, “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò,” bí òfin mìíràn bá sì wà, ni a papọ̀ ṣọ̀kan nínú òfin kan yìí: “Fẹ́ ẹnìkéjì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ̀.” 10 (C)Ìfẹ́ kì í ṣe ohun búburú sí ọmọnìkejì rẹ̀: nítorí náà ìfẹ́ ni àkójá òfin.
Ọjọ́ Olúwa fẹ́rẹ dé
11 (D)Àti èyí, bí ẹ̀yin ti mọ àkókò pé, ó ti tó wákàtí nísinsin yìí fún yín láti jí lójú orun: nítorí nísinsin yìí ni ìgbàlà wa súnmọ́ etílé ju ìgbà tí àwa ti gbàgbọ́ lọ. 12 (E)Òru bù kọjá tan, ilẹ̀ sì fẹ́rẹ mọ́: nítorí náà ẹ jẹ́ kí a bọ́ ara iṣẹ́ òkùnkùn sílẹ̀, kí a sì gbé ìhámọ́ra ìmọ́lẹ̀ wọ̀. 13 (F)Jẹ́ kí a má rin ìrìn títọ́, bí ní ọ̀sán; kì í ṣe ní ìréde òru àti ní ìmutípara, kì í ṣe ni ìwà èérí àti wọ̀bìà, kì í ṣe ní ìjà àti ìlara. 14 (G)Ṣùgbọ́n ẹ gbé Jesu Kristi Olúwa wọ̀, kí ẹ má sì pèsè fún ara, láti máa mú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀ ṣẹ.
Jesu ní Getsemane
36 (A)Nígbà náà ni Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sí ibi kan ti à ń pè ní ọgbà Getsemane, ó wí fún wọn pé, “Ẹ jókòó níhìn-ín nígbà tí mo bá lọ gbàdúrà lọ́hùn ún ni.” 37 Ó sì mú Peteru àti àwọn ọmọ Sebede méjèèjì Jakọbu àti Johanu pẹ̀lú rẹ̀, ìrora àti ìbànújẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí gba ọkàn rẹ̀. 38 (B)Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé, “Ọkàn mi gbọgbẹ́ pẹ̀lú ìbànújẹ́ títí dé ojú ikú, ẹ dúró níhìn-ín yìí, kí ẹ máa ṣọ́nà pẹ̀lú mi.”
39 (C)Òun lọ sí iwájú díẹ̀ sí i, ó sì dojúbolẹ̀, ó sì gbàdúrà pé, “Baba mi, bí ó bá ṣe é ṣe, jẹ́ kí a mú ago yìí ré mi lórí kọjá, ṣùgbọ́n ìfẹ́ tìrẹ ni mo fẹ́ kí ó ṣẹ, kì í ṣe ìfẹ́ tèmi.”
40 Bí ó ti padà sọ́dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, ó bá wọn, wọ́n ń sùn. Ó kígbe pé, “Peteru, ẹ̀yin kò tilẹ̀ lè bá mi ṣọ́nà fún wákàtí kan? 41 Ẹ máa ṣọ́ra, kí ẹ sì máa gbàdúrà kí ẹ̀yin má ba à bọ́ sínú ìdẹwò. Nítorí Ẹ̀mí ń fẹ́ nítòótọ́, ṣùgbọ́n ó ṣe àìlera fún ara.”
42 (D)Ó tún fi wọ́n sílẹ̀ nígbà kejì, ó sí gbàdúrà pé, “Baba mi, bí ago yìí kò bá lè ré mi lórí kọjá bí kò ṣe pé mo bá mu ún, ìfẹ́ tìrẹ ni kí a ṣe.”
43 Nígbà tí ó tún padà dé sọ́dọ̀ wọn, Ó rí i pé wọn ń sùn, nítorí ojú wọn kún fún oorun. 44 Nítorí náà, ó fi wọn sílẹ̀ ó tún padà lọ láti gbàdúrà nígbà kẹta, ó ń wí ohun kan náà.
45 (E)Nígbà náà ni ó tọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá, ó wí pé, “Àbí ẹ̀yin sì ń sùn síbẹ̀, ti ẹ sì ń sinmi? Wò ó wákàtí náà tí dé ti a ó fi Ọmọ ènìyàn lé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́. 46 Ẹ dìde! Ẹ jẹ́ kí a máa lọ! Ẹ wò ó, ẹni tí yóò fi mi hàn ń bọ̀ wá!”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.