Book of Common Prayer
Fún adarí orin. Fún ohun èlò orin fífọn. Saamu ti Dafidi.
5 Fi etí sí ọ̀rọ̀ mi, Olúwa,
kíyèsi àròyé mi.
2 Fi etí sílẹ̀ sí igbe mi fún ìrànlọ́wọ́,
ọba mi àti Ọlọ́run mi,
nítorí ìwọ ni mo gba àdúrà sí.
3 Ní òwúrọ̀, Olúwa, ìwọ yóò gbọ́ ohùn mi;
ní òwúrọ̀, èmi yóò gbé ẹ̀bẹ̀ mi sí iwájú rẹ̀
èmi yóò sì dúró ní ìrètí.
4 Nítorí ìwọ kì í ṣe Ọlọ́run tí ó ní inú dídùn sí búburú;
bẹ́ẹ̀ ni ẹni ibi kò le è bá ọ gbé.
5 Àwọn agbéraga kò le è dúró
níwájú rẹ̀.
Ìwọ kórìíra gbogbo àwọn aṣebi;
6 ìwọ yóò pa àwọn tí ń ṣe èké run.
Apani àti ẹni ẹ̀tàn ènìyàn
ni Olúwa yóò kórìíra.
7 Ṣùgbọ́n èmi, nípa títóbi àánú rẹ̀,
èmi yóò wá sínú ilé rẹ̀;
ní tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ni èmi yóò tẹríba
sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ̀.
8 Tọ́ mi, Olúwa, nínú òdodo rẹ,
nítorí àwọn ọ̀tá mi,
mú ọ̀nà rẹ tọ́ níwájú mi.
9 (A)Kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ẹnu wọn tí a lè gbàgbọ́;
ọkàn wọn kún fún ìparun.
Ọ̀nà ọ̀fun wọn ni isà òkú tí ó ṣí sílẹ̀;
pẹ̀lú ahọ́n wọn ni wọ́n ń sọ ẹ̀tàn.
10 Dá wọn lẹ́bi Ọlọ́run!
Jẹ́ kí rìkíṣí wọn jẹ́ ìṣubú wọn.
Lé wọn jáde nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ wọn,
nítorí wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ.
11 Ṣùgbọ́n, jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ó sádi ọ́ kí ó yọ̀;
jẹ kí wọn máa kọrin fún ayọ̀ títí.
Tan ààbò rẹ sórí wọn,
àti àwọn tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ yóò máa yọ̀ nínú rẹ.
12 Dájúdájú, Olúwa, ìwọ bùkún olódodo;
ìwọ fi ojúrere rẹ yí wọn ká bí asà.
Fún adarí orin. Fún ohun èlò orin olókùn. Gẹ́gẹ́ bí ti ṣeminiti. Saamu ti Dafidi.
6 Olúwa, má ṣe bá mi wí nínú ìbínú rẹ
kí ìwọ má ṣe nà mí nínú gbígbóná ìrunú rẹ
2 Ṣàánú fún mi, Olúwa, nítorí èmi ń kú lọ;
Olúwa, wò mí sán, nítorí egungun mi wà nínú ìnira.
3 Ọkàn mi wà nínú ìrora.
Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa, yóò ti pẹ́ tó?
4 Yípadà, Olúwa, kí o sì gbà mí;
gbà mí là nípa ìfẹ́ rẹ tí kì í ṣákì í.
5 Ẹnikẹ́ni kò ni rántí rẹ nígbà tí ó bá kú.
Ta ni yóò yìn ọ́ láti inú isà òkú?
6 Agara ìkérora mi dá mi tán.
Gbogbo òru ni mo wẹ ibùsùn mi pẹ̀lú ẹkún,
mo sì fi omi rin ibùsùn mi pẹ̀lú omijé.
7 Ojú mi di aláìlera pẹ̀lú ìbànújẹ́;
wọ́n kùnà nítorí gbogbo ọ̀tá mi.
8 (B)Kúrò lọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe iṣẹ́ ibi,
nítorí Olúwa ti gbọ́ igbe mi.
9 Olúwa ti gbọ́ ẹkún mi fún àánú;
Olúwa ti gba àdúrà mi.
10 Gbogbo àwọn ọ̀tá mi lójú yóò tì, wọn yóò sì dààmú;
wọn yóò sì yípadà nínú ìtìjú àìròtẹ́lẹ̀.
10 Èéha ti ṣe, Olúwa, tí ìwọ fi dúró ní òkè réré?
Èéha ti ṣe, tí ìwọ fi ara rẹ pamọ́ ní ìgbà ìpọ́njú?
2 Nínú àrékérekè ni ènìyàn búburú tí mu aláìlera,
ẹni ti ó mú nínú ìdẹ̀kùn àrékérekè rẹ̀.
3 Nítorí ènìyàn búburú ń ṣògo ìfẹ́ inú ọkàn rẹ̀;
Ó bùkún olójúkòkòrò, ó sì ń kẹ́gàn Olúwa
4 Ènìyàn búburú kò lè rí nínú ìgbéraga rẹ̀;
kò sí ààyè fún Ọlọ́run nínú gbogbo èrò rẹ̀;
5 Ọ̀nà rẹ̀ ń gún régé nígbà gbogbo;
òun ń gbéraga, òfin rẹ̀ sì jìnnà sí i;
òun kẹ́gàn àwọn ọ̀tá rẹ̀.
6 O wí fún ara rẹ̀, “Kò sí ohun tí ó lè mì mí;
Inú mi yóò máa dùn nígbà gbogbo, èmi kò sì ní ní wàhálà.”
7 (A)Ẹnu rẹ̀ kún fún ègún àti irọ́ àti ìtànjẹ;
wàhálà àti ohun búburú wà lábẹ́ ahọ́n rẹ̀.
8 Ó lúgọ ní bùba nítòsí ìletò;
Ògo níbi ìkọ̀kọ̀ láti pa aláìṣẹ̀.
Ojú rẹ̀ ń ṣọ́ àwọn tálákà ní ìkọ̀kọ̀.
9 Ó ba ní ní bùba bí i kìnnìún nínú pàǹtí;
Ó ba ní bùba láti mú àwọn aláìní ìrànwọ́;
ó mú àwọn aláìlólùrànlọ́wọ́, ó sì wọ́ wọn lọ sínú àwọ̀n rẹ̀.
10 Ó ba, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀;
kí tálákà ba à le bọ́ sí ọwọ́ agbára rẹ̀.
11 Ó wí fún ara rẹ̀, “Ọlọ́run ti gbàgbé;
Ó pa ojú rẹ̀ mọ́, òun kì yóò rí i láéláé.”
12 Dìde, Olúwa! Gbé ọwọ́ rẹ sókè, Ọlọ́run.
Má ṣe gbàgbé àwọn olùpọ́njú.
13 Èéṣe tí ènìyàn búburú ṣe ń kẹ́gàn Ọlọ́run?
Èéṣe tí o fi wí nínú ọkàn ara rẹ̀,
“Kò ní pè mí láti ṣe ìṣirò”?
14 Ṣùgbọ́n ìwọ, Ọlọ́run, ni ó rí wàhálà àti ìrora;
Ìwọ rò láti fi sí ọwọ́ rẹ.
Tálákà fi ara rẹ̀ jì fún ọ;
Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àwọn aláìní baba.
15 Ṣẹ́ apá àwọn ènìyàn búburú àti ènìyàn ibi;
pè é láti wá ṣírò fún ìwà ìkà rẹ̀
tí a kò le è rí.
16 Olúwa ń jẹ ọba láé àti láéláé;
àwọn orílẹ̀-èdè yóò ṣègbé lórí ilé rẹ.
17 Ìwọ́ gbọ́, Olúwa, ìfẹ́ àwọn tí a ni lára;
Ìwọ gbà wọ́n níyànjú, ó sì gbọ́ igbe wọn,
18 Láti ṣe ìdájọ́ àwọn aláìní baba àti àwọn ti a ni lára,
kí ọkùnrin, tí ó wà ní ayé,
kí ó má ṣe dẹ́rùbà ni mọ́.
Fún adarí orin. Ti Dafidi.
11 Ìgbẹ́kẹ̀lé mi wà nínú Olúwa.
Báwo ní ẹ̀yin ó ṣe sọ fún ọkàn mi pé:
“Fò gẹ́gẹ́ bi ẹyẹ lọ si orí òkè rẹ.
2 Wò ó nítorí náà, ènìyàn búburú fa ọfà rẹ̀;
wọn ti fi ọfà wọn sí ojú okùn
láti tafà níbi òjìji
sí àyà ẹni ìdúró ṣinṣin.
3 Nígbà tí ìpìlẹ̀ bá bàjẹ́
kí ni olódodo yóò ṣe?”
4 Olúwa ń bẹ nínú tẹmpili mímọ́ rẹ̀;
Olúwa ń bẹ lórí ìtẹ́ rẹ̀ ní ọ̀run.
Ó ń wo àwọn ọmọ ènìyàn;
ojú rẹ̀ ń yẹ̀ wọ́n wò.
5 Olúwa ń yẹ olódodo wò,
ṣùgbọ́n ènìyàn búburú àti àwọn tí o fẹ́ ìwà ipá
ni ọkàn rẹ̀ kórìíra.
6 Sí orí àwọn ènìyàn búburú ni yóò rọ̀jò
ẹ̀yín iná àti imí-ọjọ́ tí ń jó;
àti ìjì gbígbóná ní yóò jẹ ìpín wọn.
7 Nítorí, olódodo ní Olúwa,
o fẹ́ràn òdodo;
ẹni ìdúró ṣinṣin yóò sì rí i.
Ìlú fún àwọn ọmọ Lefi
35 (A)Lórí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu ní Jordani tí ó rékọjá láti Jeriko, Olúwa sọ fún Mose pé, 2 “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli láti fún àwọn Lefi ní ilẹ̀ láti gbé lára ogún tí àwọn ọmọ Israẹli yóò jogún. Kí ẹ sì fún wọn ní ilẹ̀ lára pápá oko tútù, káàkiri ìlú. 3 Nígbà náà, wọn yóò ní ìlú tí wọn yóò gbé àti ilẹ̀ pápá oko tútù fún ẹran ọ̀sìn, ọ̀wọ́ ẹran pẹ̀lú gbogbo ìní wọn.
9 (A)Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, 10 “Sọ̀rọ̀ sí àwọn ọmọ Israẹli, kí o sì sọ fún wọn: ‘Nígbà tí ẹ bá rékọjá odò Jordani sí Kenaani, 11 Yan àwọn ìlú kan láti jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìlú ìsásí fún yín, kí apani tó pa ènìyàn ní àìmọ̀ máa sálọ síbẹ̀. 12 Wọn yóò jẹ́ ibi ìsásí kúrò lọ́wọ́ olùgbẹ̀san, kí ẹni tí a fi ẹ̀sùn ìpànìyàn kàn má ba à kú kí ó tó dúró níwájú àwọn ìjọ àwọn ènìyàn ní ìdájọ́. 13 Mẹ́fà nínú ìlú tí ẹ ó fi fún wọn yóò jẹ́ ìlú ààbò fún yín. 14 Yan ìlú mẹ́ta ní ìhà ti Jordani, kí ẹ sì yan ìlú mẹ́ta ní ìhà Kenaani tí yóò máa jẹ́ ìlú ìsásí. 15 Ìlú mẹ́fà yìí yóò jẹ́ ìlú ìsásí fún àwọn ọmọ Israẹli, fún àjèjì àti ẹnikẹ́ni tí ó bá ń gbé láàrín wọn, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ènìyàn ní àìmọ̀ sálọ síbẹ̀.
30 (A)“ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ènìyàn gbọdọ̀ kú gẹ́gẹ́ bí apànìyàn lórí ìjẹ́rìí àwọn ènìyàn. Ṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí kan ṣoṣo. Kì yóò jẹ́rìí sí ẹnìkan láti pa.
31 “ ‘Má ṣe gba ohun ìràpadà fún ẹ̀mí apànìyàn, tí ó jẹ̀bi kí ó kú. Ṣùgbọ́n pípa ni kí a pa á.
32 “ ‘Má ṣe gba ìràsílẹ̀ fún ẹnikẹ́ni tí ó bá lọ sí ìlú ìsásí, pe kí ó padà máa gbé ní ilẹ̀ tirẹ̀ kí ó tó di ìgbà ikú olórí àlùfáà.
33 “ ‘Má ṣe sọ ilẹ̀ tí ẹ wà di àìmọ́. Ìtàjẹ̀ sílẹ̀ sọ ilẹ̀ náà di àìmọ́. Àtúnṣe kì yóò sí fún ilẹ̀ tí a ti ta ẹ̀jẹ̀ lé lórí, àyàfi ẹ̀jẹ̀ ẹni tí ó ta á sílẹ̀. 34 Má ṣe sọ di àìmọ́, ilẹ̀ tí ẹ ń gbé, àti èyí tí mo ń gbé, nítorí Èmi Olúwa ń gbé láàrín àwọn ọmọ Israẹli.’ ”
Jíju aṣẹ́gun lọ
31 (A)Kí ni àwa yóò wí nísinsin yìí sí nǹkan ìyanu wọ̀nyí? Bí Ọlọ́run bá wà pẹ̀lú wa, ta ni yóò kọjú ìjà sí wa? 32 (B)Níwọ̀n ìgbà tí Ọlọ́run ti fi Ọmọ rẹ̀ fún wa, ǹjẹ́ ó ha tún le ṣòro fún un láti fún wa ní ohunkóhun bí? 33 (C)Ta ni ẹni náà tí ó lè dá wa lẹ́bi, àwa ẹni tí Ọlọ́run ti yàn fún ara rẹ̀. Ǹjẹ́ Ọlọ́run yóò dá wa lẹ́bi? Bẹ́ẹ̀ kọ́! Òun ni ẹni tí ó dáríjì wá, tí ó sì fi wá sípò tí ó dára lọ́dọ̀ rẹ̀. 34 (D)Ta ni ẹni náà tí yóò dá wa lẹ́bi? Kò sí. Kristi Jesu tí ó kú, kí a sá à kúkú wí pé tí a ti jí dìde kúrò nínú òkú, ẹni tí ó sì wà ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run, tó sì ń bẹ̀bẹ̀ fún wa? 35 Ta ni yóò ha yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Kristi? Ìpọ́njú ni, tàbí wàhálà tàbí inúnibíni tàbí ìyàn, tàbí ìhòhò, tàbí ewu tàbí idà? 36 (E)Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:
“Nítorí rẹ̀ ni a ṣe ń pa wá kú ní gbogbo ọjọ́;
À ń kà wá sí bí àgùntàn fún pípa.”
37 (F)Ṣùgbọ́n nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, àwa ju ẹni tí ó ṣẹ́gun lọ nípasẹ̀ Kristi ẹni tí ó fẹ́ wa. 38 Nítorí pé ó dá mi lójú gbangba pé, kì í ṣe ikú tàbí ìyè, kì í ṣe àwọn angẹli tàbí ẹ̀mí èṣù, kì í ṣe ohun ìgbà ìsinsin yìí tàbí ohun tí ó ń bọ̀, tàbí àwọn agbára, 39 tàbí òkè, tàbí ọ̀gbun, tàbí ohunkóhun nínú ìṣẹ̀dá ni yóò le yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó ń bẹ nínú Kristi Jesu, Olúwa wa.
13 (A)“Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin olùkọ́ òfin àti Farisi, ẹ̀yin àgàbàgebè! Ẹ̀yin sé ìjọba ọ̀run mọ́ àwọn ènìyàn nítorí ẹ̀yin tìkára yín kò wọlé, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò jẹ́ kí àwọn tí ó fẹ́ wọlé ó wọlé.
14 “Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin olùkọ́ òfin àti Farisi, ẹ̀yin àgàbàgebè! Nítorí ẹ̀yin jẹ ilé àwọn opó run, àti nítorí àṣehàn, ẹ̀ ń gbàdúrà gígùn, nítorí náà ni ẹ̀yin yóò ṣe jẹ̀bi púpọ̀.
15 (B)“Ègbé ni fún yín ẹ̀yin olùkọ́ òfin àti Farisi, ẹ̀yin àgàbàgebè! Nítorí ẹ̀yin rin yí ilẹ̀ àti Òkun ká láti yí ẹnìkan lọ́kàn padà, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ń sọ ọ́ di ọmọ ọ̀run àpáàdì ní ìlọ́po méjì ju ẹ̀yin pàápàá.
16 (C)“Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin afọ́jú ti ń fi ọ̀nà han afọ́jú! Tí ó wí pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó ba fi tẹmpili búra kò sí nǹkan kan, ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni bá fi wúrà inú tẹmpili búra, ó di ajigbèsè.’ 17 Ẹ̀yin aláìmòye afọ́jú: èwo ni ó ga jù, wúrà tàbí tẹmpili tí ó ń sọ wúrà di mímọ́? 18 Àti pé, Ẹnikẹ́ni tó bá fi pẹpẹ búra, kò jámọ́ nǹkan, ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni tí ó ba fi ẹ̀bùn tí ó wà lórí rẹ̀ búra, ó di ajigbèsè. 19 Ẹ̀yin aláìmòye afọ́jú wọ̀nyí! Èwo ni ó pọ̀jù: ẹ̀bùn tí ó wà lórí pẹpẹ ni tàbí pẹpẹ fúnrarẹ̀ tí ó sọ ẹ̀bùn náà di mímọ́? 20 Nítorí náà ẹnikẹ́ni tí ó bá ń fi pẹpẹ búra, ó fi í búra àti gbogbo ohun tí ó wà lórí rẹ̀. 21 Àti pé, ẹni tí ó bá fi tẹmpili búra, ó fi í búra àti ẹni tí ń gbé inú rẹ̀. 22 Àti pé, ẹni tí ó bá sì fi ọ̀run búra, ó fi ìtẹ́ Ọlọ́run àti ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ búra.
23 (D)“Ègbé ni fún yín ẹ̀yin olùkọ́ òfin àti Farisi, ẹ̀yin àgàbàgebè! Nítorí ẹ̀yin ń gba ìdámẹ́wàá minti, dili àti kumini, ẹ̀yin sì ti fi ohun tí ó ṣe pàtàkì jùlọ nínú òfin sílẹ̀ láìṣe, ìdájọ́, àánú àti ìgbàgbọ́: Wọ̀nyí ni ó tọ́ tí ẹ̀yin ìbá ṣe, ẹ̀yin kò bá fi wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀ láìṣe. 24 Ẹ̀yin afọ́jú tó ń fi afọ́jú mọ̀nà! Ẹ tu kòkòrò-kantíkantí tó bọ́ sì yín lẹ́nu nù, ẹ gbé ìbákasẹ mì.
25 (E)“Ègbé ni fún yín ẹ̀yin Farisi àti ẹ̀yin olùkọ́ òfin, ẹ̀yin àgàbàgebè. Ẹ̀yin ń fọ òde ago àti àwo ṣùgbọ́n inú rẹ̀ kún fún ìrẹ́jẹ àti ẹ̀gbin gbogbo. 26 Ìwọ afọ́jú Farisi, tètè kọ́ fọ inú ago àti àwo, gbogbo ago náà yóò sì di mímọ́.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.