Book of Common Prayer
Orin. Saamu ti Asafu.
83 Ọlọ́run, má ṣe dákẹ́;
Má ṣe dákẹ́, Ọlọ́run má ṣe dúró jẹ́ẹ́.
2 Wo bí àwọn ọ̀tá rẹ ti ń rọ́kẹ̀kẹ̀ lọ,
bi àwọn ọ̀tá rẹ ti ń gbé ohùn wọn sókè.
3 Pẹ̀lú àrékérekè ni wọn dìtẹ̀ sí àwọn ènìyàn rẹ;
wọn sí dìtẹ̀ mọ́ àwọn tí o fẹ́.
4 Wọn wí pé, “wá, ẹ jẹ́ kí á pa wọ́n run bí orílẹ̀-èdè,
kí orúkọ Israẹli ma bá a sí ní ìrántí mọ́.”
5 Wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ pẹ̀lú ọkàn kan;
wọ́n ṣe àdéhùn láti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ
6 Àgọ́ Edomu àti ti àwọn ará Iṣmaeli,
ti Moabu àti ti Hagari
7 Gebali, Ammoni àti Amaleki,
Filistia, pẹ̀lú àwọn ènìyàn Tire.
8 Asiria pẹ̀lú ti darapọ̀ mọ́ wọn
láti ran àwọn ọmọ Lọti lọ́wọ́. Sela.
9 Ṣe sí wọn bí ìwọ ti ṣe sí Midiani
bí o ti ṣe sí Sisera àti Jabini ní odò Kiṣoni,
10 Ẹni tí ó ṣègbé ní Endori
tí wọn sì dàbí ààtàn ní orí ilẹ̀.
11 Ṣe àwọn ọlọ́lá wọn bí Orebu àti Seebu,
àwọn ọmọ-aládé wọn bí Seba àti Salmunna,
12 Tí ó wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a gbà ní ìní
àní pápá oko tútù Ọlọ́run.”
13 Ìwọ Ọlọ́run, ṣe wọ́n bí ààjà,
bí ìyàngbò níwájú afẹ́fẹ́.
14 Bí iná ti í jó igbó,
àti bí ọ̀wọ́-iná ti ń mú òkè ńlá gbiná,
15 Bẹ́ẹ̀ ni kí o fi ẹ̀fúùfù líle rẹ lépa wọn
dẹ́rùbà wọn lójú pẹ̀lú ìjì rẹ.
16 Fi ìtìjú kún ojú wọn,
kí àwọn ènìyàn bá à lè ṣe àfẹ́rí orúkọ rẹ àti kí o fi ìjì líle rẹ dẹ́rùbà, ìwọ Olúwa.
17 Jẹ́ kí ojú kí ó tì wọ́n, kí wọ́n sì dààmú láéláé
kí wọ́n ṣègbé sínú ẹ̀gàn
18 Jẹ́ kí wọn mọ̀ pé ìwọ, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa:
pé ìwọ nìkan ní Ọ̀gá-ògo jùlọ lórí gbogbo ayé.
Tí Dafidi. Nígbà tí ó díbọ́n bí ẹni tí ń ṣe wèrè níwájú Abimeleki, ẹni tí ó lé e lọ, ó sì jáde lọ.
34 Èmi yóò máa fi ìbùkún fún Olúwa nígbà gbogbo;
ìyìn rẹ̀ yóò máa wà ní ẹnu mi títí láé.
2 Ọkàn mí yóò máa ṣògo nínú Olúwa;
jẹ́ kí àwọn onírẹ̀lẹ̀ gbọ́ kí inú wọn kí ó sì máa dùn.
3 Gbé Olúwa ga pẹ̀lú mi;
kí ẹ sì jẹ́ kí a jọ gbé orúkọ rẹ̀ lékè.
4 Èmi wá Olúwa, ó sì dá mi lóhùn;
Ó sì gbà mí kúrò nínú ìbẹ̀rù mi gbogbo.
5 Wọ́n wò ó, ìmọ́lẹ̀ sì mọ́ wọn;
ojú kò sì tì wọ́n.
6 Ọkùnrin olùpọ́njú yí kígbe, Olúwa sì gbóhùn rẹ̀;
ó sì gbà á là kúrò nínú gbogbo ìpọ́njú rẹ̀.
7 Angẹli Olúwa yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ká
ó sì gbà wọ́n.
8 Tọ́ ọ wò kí o sì rí i wí pé Olúwa dára;
ẹni ayọ̀ ni ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé ààbò nínú rẹ̀.
9 Ẹ bẹ̀rù Olúwa, ẹ̀yin ènìyàn rẹ̀ mímọ́,
nítorí pé kò sí àìní fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.
10 Àwọn ọmọ kìnnìún a máa ṣe aláìní ebi a sì máa pa wọ́n;
ṣùgbọ́n àwọn tí ó wá Olúwa kì yóò ṣe aláìní ohun tí ó dára.
11 Wá, ẹ̀yin ọmọ mi, fi etí sí mi;
èmi yóò kọ́ ọ yín ní ẹ̀rù Olúwa.
12 (A)Ta ni nínú yín tí ń fẹ́ ìyè, tí ó sì ń fẹ́ ọjọ́ púpọ̀;
kí ó lè gbádùn ọjọ́ rere?
13 Pa ahọ́n rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi
àti ètè rẹ̀ kúrò ní ẹ̀tàn sísọ.
14 Yà kúrò nínú ibi kí o sì ṣe rere;
wá àlàáfíà, kí o sì lépa rẹ̀.
15 Ojú Olúwa ń bẹ lára àwọn olódodo;
etí i rẹ̀ sì ṣí sí ẹkún wọn.
16 Ojú Olúwa korò sí àwọn tí ń ṣe búburú;
láti ké ìrántí wọn kúrò lórí ilẹ̀.
17 Nígbà tí olódodo bá ké fún ìrànlọ́wọ́,
Olúwa a máa gbọ́, a sì yọ wọ́n jáde láti inú gbogbo wàhálà wọn.
18 Olúwa súnmọ́ etí ọ̀dọ̀ àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn;
ó sì gba irú àwọn tí í ṣe oníròra ọkàn là.
19 Ìpọ́njú àwọn olódodo pọ̀,
ṣùgbọ́n Olúwa gbà wọ́n kúrò nínú gbogbo rẹ̀.
20 Ó pa gbogbo egungun wọn mọ́;
kò sí ọ̀kan tí ó dá nínú wọn.
21 Ibi ni ó mú ikú ìkà wá,
àti àwọn tí ó kórìíra olódodo ni yóò jẹ̀bi.
22 Olúwa ra ọkàn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ padà;
kò sí ọ̀kan nínú àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé tí yóò jẹ̀bi.
Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu.
85 Ìwọ fi ojúrere hàn fún ilé rẹ, Olúwa;
ìwọ mú ohun ìní Jakọbu bọ̀ sí ipò.
2 Ìwọ dárí àìṣedéédéé àwọn ènìyàn rẹ jì
ìwọ sì bó ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀. Sela.
3 Ìwọ fi àwọn ìbínú rẹ sápá kan
ìwọ sì yípadà kúrò nínú ìbínú gbígbóná rẹ.
4 Yí wa padà, Ọlọ́run ìgbàlà wa,
kí o sì yí ìbínú rẹ̀ padà kúrò lọ́dọ̀ wa.
5 Ìwọ yóò ha máa bínú sí wa títí láé?
Ìwọ yóò ha mú ìbínú rẹ pẹ́ yí gbogbo ìran ká?
6 Ìwọ kì yóò ha sọ wá jí padà mọ́,
pé kí àwọn ènìyàn rẹ lè yọ nínú rẹ?
7 Fi ìfẹ́ rẹ tí kò le è kùnà hàn wá, Olúwa,
Kí o sì fún wa ní ìgbàlà rẹ.
8 Èmi ó gbọ́ ohun tí Olúwa Ọlọ́run yóò wí;
ó ṣèlérí àlàáfíà fún àwọn ènìyàn rẹ̀, àní ẹni mímọ́ rẹ̀:
Ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí wọn padà sí àìmoye.
9 Nítòótọ́ ìgbàlà rẹ̀ súnmọ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
pé kí ògo rẹ̀ kí ó lè gbé ní ilẹ̀ wa.
10 Ìfẹ́ àti òtítọ́ parapọ̀;
òdodo àti àlàáfíà fẹnu ko ara wọn.
11 Òtítọ́ ń sun jáde láti ilẹ̀ wá
òdodo sì bojú wolẹ̀ láti ọ̀run.
12 Olúwa yóò fi ohun dídára fún ni nítòótọ́,
ilẹ̀ wa yóò sì mú ìkórè rẹ̀ jáde.
13 Òdodo síwájú rẹ lọ
o sì pèsè ọ̀nà fún ìgbésẹ̀ rẹ̀.
Adúra ti Dafidi.
86 Gbọ́, Olúwa, kí o sì dá mi lóhùn,
nítorí mo jẹ́ tálákà àti aláìní.
2 Dáàbò bò ayé mi, nítorí a ti yà mí sọ́tọ̀ fún ọ:
ìwọ ni Ọlọ́run mi,
gbà ìránṣẹ́ rẹ là
tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ.
3 Ṣàánú fún mi, Olúwa,
nítorí èmi ń pè ọ́ ní gbogbo ọjọ́.
4 Mú ayọ̀ wà fún ìránṣẹ́ rẹ,
nítorí ìwọ, Olúwa,
ni mo gbé ọkàn mí sókè sí.
5 Ìwọ ń dáríjì, ìwọ sì dára, Olúwa,
ìwọ sì ṣàánú fún gbogbo àwọn tí ń ké pè ọ́,
6 Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa;
tẹ́tí sí ẹkún mi fún àánú.
7 Ní ọjọ́ ìpọ́njú mi èmi yóò pè ọ́,
nítorí ìwọ yóò dá mi lóhùn.
8 Nínú àwọn òrìṣà kò sí ẹni tí ó dàbí i rẹ, Olúwa:
kò sí àwọn iṣẹ́ tí a lè fiwé tìrẹ.
9 Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ dá
yóò wá, láti wá jọ́sìn níwájú rẹ, Olúwa;
wọn ó mú ògo wà fún orúkọ rẹ̀.
10 Nítorí pé ìwọ tóbi, ìwọ sì ń ṣe ohun ìyanu;
ìwọ nìkan ni Ọlọ́run.
11 Kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, Olúwa,
èmi ó sì máa rìn nínú òtítọ́ rẹ;
fún mi ní ọkàn tí kì í yapa,
kí èmi kí ó ba lè bẹ̀rù orúkọ rẹ.
12 Èmi ó yìn ọ́, Olúwa Ọlọ́run mi, pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi;
èmi ó fògo fún orúkọ rẹ títí láé
13 Nítorí títóbi ni ìfẹ́ rẹ si mi;
ìwọ ti gbà mí kúrò nínú ọ̀gbun isà òkú.
14 Àwọn onígbèéraga ń dojúkọ mí, Ọlọ́run;
àti ìjọ àwọn alágbára ń wá
ọkàn mi kiri,
wọn kò sì fi ọ́ pè.
15 Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, jẹ́ aláàánú àti Ọlọ́run olójúrere,
Ó lọ́ra láti bínú, Ó sì pọ̀ ní ìfẹ́ àti òtítọ́.
16 Yípadà sí mi kí o sì ṣàánú fún mi;
fún àwọn ènìyàn rẹ ní agbára
kí o sì gba ọ̀dọ́mọkùnrin ìránṣẹ́bìnrin rẹ là.
17 Fi ààmì hàn mí fún rere,
kí àwọn tí ó kórìíra mi lè ri,
kí ojú lè tì wọ́n, nítorí ìwọ Olúwa
ni ó ti tù mí nínú.
Miriamu Àti Aaroni tako Mose
12 Miriamu àti Aaroni sọ̀rọ̀-òdì sí Mose nítorí pé ó fẹ́ obìnrin ará Etiopia. 2 Wọ́n sì wí pé, “Nípa Mose nìkan ni Olúwa ti sọ̀rọ̀ bí, kò ha ti ipa wa sọ̀rọ̀ bí?” Olúwa sì gbọ́ èyí.
3 (Mose sì jẹ́ ọlọ́kàn tútù ju gbogbo ènìyàn tó wà lórí ilẹ̀ ayé lọ).
4 Lẹ́ẹ̀kan náà ni Olúwa sọ fún Mose, Aaroni àti Miriamu pé, “Ẹ̀yin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, jáde wá sínú àgọ́ ìpàdé.” Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sì jáde síta. 5 Nígbà náà ni Olúwa sọ̀kalẹ̀ nínú ọ̀wọ́n ìkùùkuu, ó sì dúró ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́, ó ké sí Aaroni àti Miriamu. Àwọn méjèèjì sì bọ́ síwájú, 6 Ó wí pé, “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi:
“Bí wòlíì Olúwa bá wà láàrín yín
Èmi Olúwa a máa fi ara à mi hàn án ní ojúran,
Èmi a máa bá a sọ̀rọ̀ nínú àlá.
7 (A)Ṣùgbọ́n èyí kò rí bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Mose ìránṣẹ́ mi:
ó jẹ́ olóòtítọ́ nínú gbogbo ilé mi.
8 (B)Mo sì ń bá a sọ̀rọ̀ ní ojúkojú,
ọ̀rọ̀ yékéyéké tí kì í ṣe òwe,
ó rí àwòrán Olúwa
Kí ló wá dé tí ẹ̀yin kò ṣe bẹ̀rù
láti sọ̀rọ̀-òdì sí Mose ìránṣẹ́ mi?”
9 Ìbínú Olúwa sì ru sókè sí wọn Olúwa sì fi wọ́n sílẹ̀.
10 Nígbà tí ìkùùkuu kúrò lórí àgọ́ lójijì ni Miriamu di adẹ́tẹ̀, ó funfun bí i yìnyín. Aaroni sì padà wo Miriamu ó sì rí i pé ó ti di adẹ́tẹ̀, 11 Aaroni sì wí fún Mose pé, “Jọ̀wọ́ olúwa mi, má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀, èyí tí a fi ìwà òmùgọ̀ dá sí wa lọ́rùn. 12 Má ṣe jẹ́ kí ó dàbí òkú ọmọ tí a bí, tí ìdajì ara rẹ̀ ti rà dànù.”
13 Torí èyí Mose sì kígbe sí Olúwa, “Ọlọ́run, jọ̀wọ́, mú un láradá!”
14 (C)Olúwa sì dá Mose lóhùn, “Bí baba rẹ̀ bá tutọ́ sí i lójú, ojú kò wa ní í tì í fún ọjọ́ méje? Dá a dúró sí ẹ̀yìn ibùdó fún ọjọ́ méje, lẹ́yìn èyí ki a tó ó le mú wọlé.” 15 Miriamu sì dúró sí ẹ̀yìn ibùdó fún ọjọ́ méje, àwọn ènìyàn kò sì tẹ̀síwájú nínú ìrìnàjò wọn títí tí Miriamu fi wọ inú ibùdó padà.
16 Lẹ́yìn èyí, àwọn ènìyàn kúrò ní Haserotu, wọ́n sì pa ibùdó sí Aginjù Parani.
12 (A)Gbogbo àwọn tí ó ṣẹ̀ ní àìlófin wọn ó sì ṣègbé láìlófin: àti iye àwọn tí ó ṣẹ̀ lábẹ́ òfin, àwọn ni a ó fi òfin dá lẹ́jọ́; 13 (B)Nítorí kì í ṣe àwọn olùgbọ́ òfin ni ẹni ìdáláre lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n àwọn olùṣe òfin ni a ó dá láre. 14 Nítorí nígbà tí àwọn aláìkọlà, tí kò ní òfin, bá ṣe ohun tí ó wà nínú òfin nípa ìwà ẹ̀dá, àwọn wọ̀nyí, jẹ́ òfin fún ara wọn bí wọn kò tilẹ̀ ní òfin. 15 Àwọn ẹni tí ó fihàn pé, a kọ̀wé iṣẹ́ òfin sí wọn lọ́kàn, tí ẹ̀rí ọkàn wọn pẹ̀lú sì tún ń jẹ́ wọn lẹ́rìí, àti pé, èrò ọkàn wọn tí ó jẹ́ ọ̀nà ìfinisùn, sì ń gbè wọ́n lẹ́yìn ní ìsinsin yìí. 16 (C)Èyí yóò farahàn ní ọjọ́ náà nígbà tí Ọlọ́run yóò tipasẹ̀ Jesu Kristi ṣe ìdájọ́ àwọn àṣírí ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìhìnrere mi.
Àwọn Júù àti òfin
17 Ṣùgbọ́n bí a bá ń pe ìwọ ní Júù, tí o sì sinmi lé òfin, tí o sì ń ṣògo nínú ìbálòpọ̀ rẹ̀ sí Ọlọ́run, 18 (D)tí o sì mọ ìfẹ́ rẹ̀, tí o sì fọwọ́sí ohun tí ó dára jùlọ, nítorí tí a ti kọ́ ọ ní òfin; 19 tí o sì dá ara rẹ lójú pé ìwọ ni amọ̀nà àwọn afọ́jú, ìmọ́lẹ̀ fún àwọn tí ó wà ni òkùnkùn, 20 (E)Olùkọ́ àwọn aláìmòye, olùkọ́ àwọn ọmọdé, ẹni tí ó ní ètò ìmọ̀ àti òtítọ́ òfin lọ́wọ́, 21 (F)Ǹjẹ́ ìwọ tí o ń kọ́ ẹlòmíràn, ìwọ kò kọ́ ara rẹ? Ìwọ tí ó ń wàásù kí ènìyàn má jalè, ìwọ ha ń jalè bí? 22 Ìwọ tí o wí pé, kí ènìyàn má ṣe panṣágà, ìwọ ń ṣe panṣágà bí? Ìwọ tí o kórìíra òrìṣà, ìwọ ń ja tẹmpili ní olè bí? 23 Ìwọ ti ń ṣògo nínú òfin, ìwọ ha ń bu Ọlọ́run ni ọlá kù nípa rírú òfin? 24 (G)Nítorí gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́, “Orúkọ Ọlọ́run sá à di ìsọ̀rọ̀-òdì sí láàrín àwọn aláìkọlà nítorí yín.”
Òwe àgùntàn tó sọnù
10 (A)“Ẹ rí i pé ẹ kò fi ojú tẹ́ńbẹ́lú ọ̀kan nínú àwọn kéékèèkéé wọ̀nyí. Lóòótọ́ ni mo wí fún yin pé, nígbà gbogbo ni ọ̀run ni àwọn angẹli ń wo ojú Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run. 11 Nítorí náà, Ọmọ ènìyàn wá láti gba àwọn tí ó nù là.
12 (B)“Kí ni ẹ̀yin rò? Bí ọkùnrin kan bá ni ọgọ́rùn-ún àgùntàn, tí ẹyọ kan nínú wọn sì sọnù, ṣé òun kì yóò fi mọ́kàn-dínlọ́gọ́rùn-ún (99) ìyókù sílẹ̀ sórí òkè láti lọ wá ẹyọ kan tó nù náà bí? 13 Ǹjẹ́ bí òun bá sì wá á rí i, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ǹjẹ́ ẹ̀yin kò mọ̀ pé inú rẹ̀ yóò dùn nítorí rẹ̀ ju àwọn mọ́kàn-dínlọ́gọ́rùn-ún tí kò nù lọ? 14 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ni kì í ṣe ìfẹ́ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run, pé ọ̀kan nínú àwọn kékeré wọ̀nyí kí ó ṣègbé.
Arákùnrin tí ó ṣẹ̀ sí ọ
15 (C)“Bí arákùnrin rẹ bá ṣẹ̀ ọ́, lọ ní ìkọ̀kọ̀ kí o sì sọ ẹ̀bi rẹ̀ fún un. Bí ó bá gbọ́ tìrẹ, ìwọ ti mú arákùnrin kan bọ̀ sí ipò. 16 Ṣùgbọ́n bí òun kò bá tẹ́tí sí ọ, nígbà náà mú ẹnìkan tàbí ẹni méjì pẹ̀lú rẹ, kí ẹ sì tún padà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i, kí ọ̀rọ̀ náà bá le fi ìdí múlẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́rìí méjì tàbí mẹ́ta náà. 17 Bí òun bá sì tún kọ̀ láti tẹ́tí sí wọn, nígbà náà sọ fún ìjọ ènìyàn Ọlọ́run. Bí o bá kọ̀ láti gbọ́ ti ìjọ ènìyàn Ọlọ́run, jẹ́ kí ó dàbí kèfèrí sí ọ tàbí agbowó òde.
18 (D)“Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá dè ní ayé, ni a dè ní ọ̀run. Ohunkóhun ti ẹ̀yin bá sì ti tú ni ayé, á ò tú u ní ọ̀run.
19 (E)“Mo tún sọ èyí fún yín, bí ẹ̀yin méjì bá fi ohùn ṣọ̀kan ní ayé yìí, nípa ohunkóhun tí ẹ béèrè, Baba mi ti ń bẹ ní ọ̀run yóò sì ṣe é fún yín. 20 Nítorí níbi ti ènìyàn méjì tàbí mẹ́ta bá kó ara jọ ni orúkọ mi, èmi yóò wà láàrín wọn níbẹ̀.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.