Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 101

Ti Dafidi. Saamu.

101 Èmi yóò kọrin ìfẹ́ àti òdodo;
    sí ọ Olúwa, èmi yóò máa kọrin ìyìn.
Èmi yóò máa rin ìrìn mi pẹ̀lú ọgbọ́n láìlẹ́ṣẹ̀,
    ìgbà wo ni ìwọ yóò wá sí ọ̀dọ̀ mi?

Èmi yóò máa rìn ní ilé mi
    pẹ̀lú àyà pípé.
Èmi kì yóò gbé ohun búburú sí iwájú mi:
    iṣẹ́ àwọn tí ó yapa ni èmi kórìíra.

    Wọn kì yóò rọ̀ mọ́ mi.
Agídí ọkàn yóò kúrò lọ́dọ̀ mi;
    Èmi kì yóò mọ ènìyàn búburú.

Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ ẹnìkejì rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀,
    òun ní èmi yóò gé kúrò
ẹni tí ó bá gbé ojú rẹ̀ ga tí ó sì ní ìgbéraga àyà,
    òun ní èmi kì yóò faradà fún.

Ojú mi yóò wà lára àwọn olóòtítọ́ lórí ilẹ̀,
    kí wọn kí ó lè máa bá mi gbé;
ẹni tí ó bá n rin ọ̀nà pípé
    òun ni yóò máa sìn mí.

Ẹni tí ó bá ń ṣe ẹ̀tàn, kì yóò gbé ilé mi,
    kò sí ẹni tí ń ṣèké tí yóò dúró ní iwájú mi.

Ní ojoojúmọ́ ní èmi yóò wá máa pa a lẹ́nu mọ
    gbogbo àwọn ènìyàn búburú ilẹ̀ náà;
èmi yóò gé àwọn olùṣe búburú
    kúrò ní ìlú Olúwa.

Saamu 109:1-30

Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu.

109 Ọlọ́run, ti èmi ń fi ìyìn fún
    Má ṣe dákẹ́
Nítorí àwọn ènìyàn búburú àti ẹlẹ́tàn
    ti ya ẹnu wọn sí mi
    wọ́n ti fi ahọ́n èké sọ̀rọ̀ sí mi
Wọ́n fi ọ̀rọ̀ ìríra yí mi káàkiri;
    wọ́n bá mi jà láìnídìí
Nípò ìfẹ́ mi, wọn ń ṣe ọ̀tá mi,
    ṣùgbọ́n èmi ń gba àdúrà.
Wọ́n sì fi ibi san ìre fún mi
    àti ìríra fún ìfẹ́ mi.

Yan àwọn ènìyàn búburú láti dojúkọ
    jẹ́ kí àwọn olùfisùn
    dúró ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.
Kí a dá a lẹ́bi nígbà tí a bá ṣe ìdájọ́
    kí àdúrà rẹ̀ kí ó lè di ìkọ̀sílẹ̀
(A)Kí ọjọ́ rẹ̀ kí ó kúrú
    kí ẹlòmíràn kí ó rọ́pò iṣẹ́ rẹ̀
Kí àwọn ọmọ rẹ̀ di aláìní baba
    kí aya rẹ̀ sì di opó
10 Jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ̀ máa ṣagbe kiri
    kí wọn máa tọrọ oúnjẹ jìnnà sí ibi ahoro wọn
11 Jẹ́ kí alọ́nilọ́wọ́gbà kí ó mú ohun gbogbo tí ó ní
    jẹ́ kí àlejò kí o kó èrè iṣẹ́ rẹ̀ lọ
12 Má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan ṣe àánú fún un
    tàbí kí wọn káàánú lórí
    àwọn ọmọ rẹ̀ aláìní baba
13 Kí a gé àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ kúrò
    kí orúkọ wọn kí ó parẹ́ ní ìran tí ń bọ̀
14 Kí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba rẹ̀ kí
    ó wà ní ìrántí ní ọ̀dọ̀ Olúwa
    Má ṣe jẹ́ kí a yọ ẹ̀ṣẹ̀ ìyá wọn kúrò
15 Jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ wọn kí ó wà ní ìrántí níwájú Olúwa
    kí ó lè gé ìrántí wọn kúrò lórí ilẹ̀.

16 Nítorí kò rántí láti ṣàánú,
    ṣùgbọ́n ó ṣe inúnibíni sí ọkùnrin tálákà àti olùpọ́njú,
    kí ó lè pa oníròbìnújẹ́ ọkàn.
17 Ó fẹ́ràn láti máa mú ègún wá sí orí rẹ̀:
    bi inú rẹ̀ kò ti dùn si ìre, bẹ́ẹ̀ ni kí ó jìnnà sí.
18 Bí ó ti fi ègún wọ ará rẹ̀ láṣọ bí ẹ̀wù
    bẹ́ẹ̀ ni kí ó wá sí inú rẹ̀ bí omi
19 Jẹ́ kí ó rí fún un bí aṣọ tí a dà bò ó ní
    ara, àti fún àmùrè tí ó fi gba ọ̀já nígbà gbogbo
20 Èyí ni èrè àwọn ọ̀tá mi láti ọwọ́ Olúwa wá;
    àti ti àwọn tí ń sọ̀rọ̀ ibi sí ọkàn mi.

21 Ṣùgbọ́n ìwọ, ìwọ ṣe fún mi Olúwa Olódùmarè,
    ṣe rere fún mi nítorí orúkọ rẹ
    Nítorí tí àánú rẹ dára, ìwọ gbà mí
22 Nítorí pé tálákà àti aláìní ni mí,
    àyà mi sì gbọgbẹ́ nínú mi.
23 Èmi ń kọjá lọ bí òjìji tí àṣálẹ́,
    mo ń gbọ̀n sókè bí eṣú.
24 Eékún mi di aláìlera nítorí àwẹ̀ gbígbà
    ẹran-ara mi sì gbẹ nítorí àìlera mi.
25 (B)Mo dàbí ẹ̀gàn fún àwọn olùfisùn mi;
    nígbà tí wọn wò mí, wọ́n gbọn orí wọn.

26 Ràn mí lọ́wọ́, Olúwa Ọlọ́run mi;
    gbà mí gẹ́gẹ́ bí ìṣeun ìfẹ́ rẹ.
27 Jẹ́ kí wọn mọ̀ pé ọwọ́ rẹ ni èyí
    wí pé ìwọ, Olúwa, ni ó ṣe é.
28 Wọ́n ó máa gégùn ún, ṣùgbọ́n ìwọ máa súre;
    Nígbà tí wọn bá dìde kí ojú kí ó tì wọ́n,
    ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ rẹ yóò yọ̀
29 Jẹ́ kí a wọ àwọn ọ̀tá mi ní aṣọ ìtìjú
    kí á sì fi ìdàrúdàpọ̀ bọ̀ wọ́n lára bí ẹ̀wù.

30 Pẹ̀lú ẹnu mi èmi yóò máa yin Olúwa gidigidi
    ní àárín ọ̀pọ̀ ènìyàn èmi yóò máa yìn ín

Saamu 119:121-144

Olórin pa òfin Olúwa mọ́

121 Èmi ti ṣe ohun tí i ṣe òdodo àti ẹ̀tọ́:
    má ṣe fi mí sílẹ̀ fún àwọn tó ń ni mí lára.
122 Mú kí àlàáfíà ìránṣẹ́ rẹ dájú:
    má ṣe jẹ́ kí àwọn agbéraga ni mi lára.
123 Ojú mi kùnà, fún wíwo ìgbàlà rẹ,
    fún wíwo ìpinnu òdodo rẹ.
124 Ṣe pẹ̀lú ìránṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí dídúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ
    kí o sì kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.
125 Èmi ni ìránṣẹ́ rẹ; ẹ fún mi ní òye
    kí èmi lè ní òye òfin rẹ
126 Ó tó àsìkò fún ọ láti ṣe iṣẹ́, Olúwa;
    nítorí òfin rẹ ti fọ́.
127 Nítorí èmi fẹ́ràn àṣẹ rẹ
    ju wúrà, àní ju wúrà dídára lọ,
128 Nítorí èmi kíyèsi gbogbo ẹ̀kọ́ òtítọ́ rẹ̀,
    èmi kórìíra gbogbo ipa ọ̀nà búburú.

Àdúrà láti lè pa òfin Olúwa mọ́

129 Òfin rẹ̀ ìyanu ni:
    nítorí náà èmi gbà wọ́n gbọ́.
130 Ìṣípayá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú ìmọ́lẹ̀ wá;
    ó fi òye fún àwọn òpè.
131 Èmi ya ẹnu mi mo sì mí hẹlẹ,
    nítorí èmi fojú ṣọ́nà sí àṣẹ rẹ.
132 Yí padà sí mi kí o sì ṣàánú fún mi,
    bí ìwọ ṣe máa ń ṣe nígbà gbogbo sí àwọn
    tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ.
133 Fi ìṣísẹ̀ mi múlẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ rẹ,
    má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ borí mi.
134 Rà mí padà lọ́wọ́ aninilára ènìyàn,
    kí èmi lè gbọ́ ẹ̀kọ́ rẹ.
135 Jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tàn sí ìránṣẹ́ rẹ lára
    kí ó sì kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.
136 Omijé sàn jáde ní ojú mi,
    nítorí wọn kò gba pé òfin rẹ̀ jẹ́ òtítọ́.
137 Olódodo ni ìwọ Olúwa
    ìdájọ́ rẹ sì dúró ṣinṣin
138 Òfin ti ìwọ gbé kalẹ̀ jẹ́ òdodo:
    wọ́n yẹ ni ìgbẹ́kẹ̀lé.
139 Ìtara mi ti pa mí run,
    nítorí àwọn ọ̀tá mi fi ojú fo ọ̀rọ̀ rẹ dá.
140 Wọ́n ti dán ìpinnu rẹ wò pátápátá
    ìránṣẹ́ rẹ sì fẹ́ràn wọ́n.
141 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti ẹni ẹ̀gàn
    èmi kò ni gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ.
142 Òdodo rẹ wà títí láé
    òtítọ́ ni òfin rẹ̀.
143 Ìyọnu àti ìpọ́njú wá sórí mi,
    ṣùgbọ́n àṣẹ rẹ ni inú dídùn mi,
144 Òfin rẹ jẹ́ òtítọ́ láé;
    fún mi ní òye kí èmi lè yè.

Isaiah 4:2-6

Ẹ̀ka Olúwa náà

(A)Ní ọjọ́ náà, ẹ̀ka Olúwa yóò ní ẹwà àti ògo, èso ilẹ̀ náà yóò sì jẹ́ ìgbéraga àti ògo àwọn ti ó sálà ní Israẹli. Àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Sioni, àwọn tí o kù ní Jerusalẹmu, ni a ó pè ní mímọ́, orúkọ àwọn ẹni tí a kọ mọ́ àwọn alààyè ní Jerusalẹmu. Olúwa yóò wẹ ẹ̀gbin àwọn obìnrin Sioni kúrò yóò sì fọ gbogbo àbàwọ́n ẹ̀jẹ̀ kúrò ní Jerusalẹmu pẹ̀lú ẹ̀mí ìdájọ́ àti ẹ̀mí iná. Lẹ́yìn náà, Olúwa yóò dá sórí òkè Sioni àti sórí i gbogbo àwọn tí ó péjọpọ̀ síbẹ̀, kurukuru èéfín ní ọ̀sán àti ìtànṣán ọ̀wọ́-iná ní òru, lórí gbogbo ògo yìí ni ààbò yóò wà. Èyí ni yóò jẹ́ ààbò àti òjìji kúrò lọ́wọ́ ooru ọ̀sán, àti ààbò òun ibi ìsádi kúrò lọ́wọ́ ìjì àti òjò.

Efesu 4:1-16

Ìṣọ̀kan nínú ara Jesu

Nítorí náà, èmi òǹdè nínú Olúwa ń bẹ̀ yín pé kí ẹ̀yin máa gbé ìgbé ayé tí ó yẹ sí ìpè tí a pè yín sí. (A)Pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ gbogbo àti inú tútù, pẹ̀lú ìpamọ́ra, ẹ máa fi ìfẹ́ faradà fún ẹnìkejì yín. Kí ẹ sì máa làkàkà láti pa ìṣọ̀kan Ẹ̀mí mọ́ ni ìdàpọ̀ àlàáfíà. Ara kan ni ń bẹ, àti Ẹ̀mí kan, àní bí a ti pè yín sínú ìrètí kan nígbà tí a pè yín. Olúwa kan, ìgbàgbọ́ kan àti ìtẹ̀bọmi kan. Ọlọ́run kan àti Baba gbogbo aráyé, ẹni tí ó ṣe olórí ohun gbogbo àti nípá gbogbo àti nínú ohun gbogbo.

Ṣùgbọ́n olúkúlùkù wa ni a fi oore-ọ̀fẹ́ fun gẹ́gẹ́ bi òṣùwọ̀n ẹ̀bùn Kristi. (B)Nítorí náà a wí pé:

“Nígbà tí ó gòkè lọ sí ibi gíga,
    ó di ìgbèkùn ni ìgbèkùn,
    ó sì fi ẹ̀bùn fun ènìyàn.”

(Ǹjẹ́ ní ti pé, “Ó gòkè lọ!” Kín ni ó túmọ̀ sí, bí kò ṣe pé ó kọ́ sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú lọ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀? 10 Ẹni tí ó ti sọ̀kalẹ̀, Òun kan náà ni ó sì ti gòkè rékọjá gbogbo àwọn ọ̀run, kí ó lè kún ohun gbogbo.) 11 Nítorí náà ó sì ti fi àwọn kan fún ni bí aposteli; àti àwọn mìíràn bí i wòlíì; àti àwọn mìíràn bí efangelisti, àti àwọn mìíràn bí olùṣọ́-àgùntàn àti olùkọ́ni. 12 Fún àṣepé àwọn ènìyàn mímọ́ fun iṣẹ́ ìránṣẹ́, fún ìmúdàgbà ara Kristi. 13 Títí gbogbo wa yóò fi dé ìṣọ̀kan ìgbàgbọ́ àti ìmọ̀ Ọmọ Ọlọ́run, títí a ó fi di ọkùnrin, títí a ó fi dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìwọ̀n Kristi.

14 Kí àwa má ṣe jẹ́ èwe mọ́, tí a ń fi gbogbo afẹ́fẹ́ ẹ̀kọ́ tì síwá tì sẹ́yìn, tí a sì fi ń gbá kiri, nípa ìtànjẹ ènìyàn, nípa àrékérekè fun ọgbọ́nkọ́gbọ́n àti mú ni ṣìnà; 15 (C)Ṣùgbọ́n ká a máa sọ òtítọ́ ní ìfẹ́, kí a lè máa dàgbàsókè nínú rẹ̀ ní ohun gbogbo ẹni tí i ṣe orí, àní Kristi. 16 (D)Láti ọ̀dọ̀ ẹni ti ara náà tí a ń so ṣọ̀kan pọ̀, tí ó sì ń fi ara mọ́ra, nípasẹ̀ oríkèé kọ̀ọ̀kan tí a ti pèsè, nígbà tí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan bá ń ṣiṣẹ́ dáradára, yóò mú ara dàgbà, yóò sì gbé ara òun tìkára rẹ̀ dìde nínú ìfẹ́.

Matiu 8:28-34

Ìwòsàn ọkùnrin ẹlẹ́mìí èṣù méjì

28 (A)Nígbà ti ó sì dé apá kejì ní ilẹ̀ àwọn ara Gadara, àwọn ọkùnrin méjì ẹlẹ́mìí èṣù ti inú ibojì wá pàdé rẹ̀. Wọn rorò gidigidi tó bẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò le kọjá ní ọ̀nà ibẹ̀. 29 (B)Wọ́n kígbe lóhùn rara wí pé, “Kí ní ṣe tàwa tìrẹ, Ìwọ Ọmọ Ọlọ́run? Ìwọ ha wá láti dá wa lóró ṣáájú ọjọ́ tí a yàn náà?”

30 Agbo ẹlẹ́dẹ̀ ńlá tí ń jẹ ń bẹ ní ọ̀nà jíjìn díẹ̀ sí wọn 31 Àwọn ẹ̀mí èṣù náà bẹ̀ Jesu wí pé, “Bí ìwọ bá lé wa jáde, jẹ́ kí àwa kí ó lọ sínú agbo ẹlẹ́dẹ̀ yìí.”

32 Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa lọ!” Nígbà tí wọn sì jáde, wọn lọ sínú agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà; sì wò ó, gbogbo agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà sì rọ́ gììrì sọ̀kalẹ̀ bèbè odò bọ́ sínú Òkun, wọ́n sì ṣègbé nínú omi. 33 Àwọn ẹni tí ń ṣọ wọn sì sá, wọ́n sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n lọ sí ìlú, wọ́n ròyìn ohun gbogbo, àti ohun tí a ṣe fún àwọn ẹlẹ́mìí èṣù. 34 Nígbà náà ni gbogbo ará ìlú náà sì jáde wá í pàdé Jesu. Nígbà tí wọ́n sì rí i, wọ́n bẹ̀ ẹ́, kí ó lọ kúrò ní agbègbè wọn.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.