Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 146-147

146 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Fi ìyìn fún Olúwa, ìwọ ọkàn mi.

Èmi yóò yin Olúwa ní gbogbo ayé mi;
    Èmi yóò kọrin ìyìn sí Ọlọ́run, níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láààyè.
Ẹ má ṣe ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn ọmọ-aládé,
    àní, ọmọ ènìyàn,
    lọ́wọ́ ẹni tí kò sí ìrànlọ́wọ́.
Ẹ̀mí rẹ jáde lọ, ó padà sí erùpẹ̀:
    Ní ọjọ́ náà gan, èrò wọn yóò di òfo:
Ìbùkún ni fún ẹni tí
    Ọlọ́run Jakọbu ń ṣe ìrànlọ́wọ́ rẹ̀
    tí ìrètí rẹ̀ wà nínú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀.

Ẹni tí ó dá ọ̀run àti ayé,
    òkun àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn,
    ẹni tí ó pa òtítọ́ mọ́ títí ayé.
Ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ àwọn tí a ni lára
    tí ó fi oúnjẹ fún àwọn tí ebi ń pa
Olúwa, tú àwọn oǹdè sílẹ̀ (ẹlẹ́wọ̀n)
    Olúwa mú àwọn afọ́jú ríran,
Olúwa, gbé àwọn tí a rẹ̀ sílẹ̀ ga,
    Olúwa fẹ́ràn àwọn olódodo.
Olúwa ń dá ààbò bo àwọn àlejò
    ó sì ń dá àwọn aláìní baba àti opó sí
    ṣùgbọ́n ó ba ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú jẹ́.

10 Olúwa jẹ ọba títí láé;
    Ọlọ́run rẹ, ìwọ Sioni, àti fún gbogbo ìran.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
147 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Nítorí ohun rere ni láti máa kọrin ìyìn sí Ọlọ́run wa,
    ó yẹ láti kọrin ìyìn sí i!

Olúwa kọ́ Jerusalẹmu;
    Ó kó àwọn Israẹli tí a lé sọnù jọ.
Ó wo àwọn tí ọkàn wọ́n bàjẹ́ sàn
    ó sì di ọgbẹ́ wọ́n.
Ó ka iye àwọn ìràwọ̀
    ó sì pe ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní orúkọ
Títóbi ni Olúwa wa ó sì pọ̀ ní agbára
    òye rẹ̀ kò sì ní òpin.
Olúwa wa pẹ̀lú àwọn onírẹ̀lẹ̀
    bẹ́ẹ̀ ni ó rẹ̀ àwọn ènìyàn búburú sílẹ̀.

Fi ọpẹ́ kọrin sí Olúwa
    fi ohun èlò orin olókùn yin Ọlọ́run.

Ó fi ìkùùkuu bo àwọ̀ sánmọ̀
    ó rọ òjò sí orílẹ̀ ayé
    ó mú kí koríko hù lórí àwọn òkè
Ó pèsè oúnjẹ fún àwọn ẹranko
    àti fún àwọn ọmọ ẹyẹ ìwò ní ìgbà tí wọ́n bá ń ké.

10 Òun kò ní inú dídùn nínú agbára ẹṣin
    bẹ́ẹ̀ ni Òun kò ní ayọ̀ sí ẹ̀ṣẹ̀ ọkùnrin
11 Olúwa ni ayọ̀ nínú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
    sí àwọn tí ó ní ìrètí nínú àánú rẹ̀.

12 Yin Olúwa, ìwọ Jerusalẹmu
    yin Ọlọ́run rẹ, ìwọ Sioni.

13 Nítorí tí ó ti mú ọ̀pá ìdábùú ibodè rẹ̀ lágbára;
    Òun sì ti bùkún fún àwọn ọmọ rẹ̀ nínú rẹ
14 Òun jẹ́ kí àlàáfíà wà ní àwọn ẹnu ibodè rẹ̀
    òun sì fi jéró dáradára tẹ́ ọ lọ́rùn.

15 Òun sì rán àṣẹ rẹ̀ sí ayé
    ọ̀rọ̀ rẹ̀ sáré tete.
16 Ó fi yìnyín fún ni bi irun àgùntàn
    ó sì fọ́n ìrì dídì ká bí eérú
17 Ó rọ òjò yìnyín rẹ̀ bí òkúta wẹ́wẹ́
    ta ni ó lè dúró níwájú òtútù rẹ̀
18 Ó rán ọ̀rọ̀ rẹ̀ jáde ó sì mú wọn yọ̀
    ó mú kí afẹ́fẹ́ rẹ̀ fẹ́
    ó sì mú odò rẹ̀ sàn.

19 Ó sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ di mí mọ̀ fún Jakọbu
    àwọn òfin àti ìlànà rẹ̀ fún Israẹli
20 Òun kó tí ṣe irú èyí sí orílẹ̀-èdè kan rí, Bí ó ṣe ti ìdájọ́ rẹ̀
    wọn ko mọ òfin rẹ̀.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Saamu 111-113

111 Ẹ máa yin Olúwa.

Èmi yóò máa yin Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi,
    ní àwùjọ àwọn olóòtítọ́, àti ní ìjọ ènìyàn.

Iṣẹ́ Olúwa tóbi, àwọn tí ó ní inú dídùn, ń ṣe àṣàrò nínú rẹ̀.
Iṣẹ́ rẹ̀ ni ọláńlá àti ògo:
    àti òdodo rẹ̀ dúró láéláé.
Ó ti ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, láti máa rántí:
    Olúwa ni olóore-ọ̀fẹ́ àti pé ó kún fún àánú.
Ó ti fi oúnjẹ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀:
    òun ń rántí májẹ̀mú rẹ̀.

Ó ti fihan àwọn ènìyàn rẹ̀ agbára iṣẹ́ rẹ̀
    láti fún wọn ní ilẹ̀ ìlérí ní ìní
Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ jẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ́;
    gbogbo òfin rẹ̀ sì dájú.
Wọ́n dúró láé àti láé,
    ní òtítọ́ àti òdodo ni a ṣe wọ́n.
Ó rán ìràpadà sí àwọn ènìyàn rẹ̀:
    ó pàṣẹ májẹ̀mú rẹ̀ títí láé:
    Mímọ́ àti ọ̀wọ̀ ni orúkọ rẹ̀.

10 Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọgbọ́n:
    òye dáradára ni yóò máa ṣe òfin rẹ̀,
    ìyìn rẹ̀ dúró láé.
112 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run,
    tí ó ní inú dídùn ńlá sí àwọn òfin rẹ̀.

Irú-ọmọ rẹ̀ yóò jẹ́ alágbára ní ayé:
    ìran àwọn olóòtítọ́ ni a ó bùkún fún.
Ọlá àti ọrọ̀ yóò wà nínú ilé rẹ̀;
    òdodo rẹ̀ sì dúró láé.
Fún olóòótọ́ ni ìmọ́lẹ̀ yóò tàn fún ní òkùnkùn:
    olóore-ọ̀fẹ́ àti aláàánú àti òdodo.
Ènìyàn rere fi ojúrere hàn,
    a sì wínni;
    ìmòye ni yóò máa fi la ọ̀nà iṣẹ́ rẹ̀.

Dájúdájú a kì yóò le yí ní ipò padà láéláé:
    olódodo ni a ó máa ṣe ìrántí rẹ láéláé.
Òun kì yóò béèrè ìyìn búburú:
    ọkàn rẹ̀ ti dúró, ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa.
Ó ti mú ọkàn rẹ̀ gbilẹ̀, ẹ̀rù kí yóò bà á,
    títí yóò fi rí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀.
(A)Ó ti pín ká, ó ti fi fún àwọn olùpọ́njú;
    Nítorí òdodo rẹ̀ dúró láé;
    ìwo rẹ̀ ní a ó gbé sókè pẹ̀lú ọlá.

10 Ènìyàn búburú yóò ri, inú wọn yóò sì bàjẹ́,
    yóò sì pa eyín keke, yó sì yọ dànù:
    èròǹgbà ọkàn ènìyàn búburú ni yóò ṣègbé.
113 Ẹ máa yin Olúwa.

Yìn ín ẹ̀yin ìránṣẹ́ Olúwa,
ẹ yin orúkọ Olúwa.
Fi ìbùkún fún orúkọ Olúwa láti
    ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.
Láti ìlà-oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀
    orúkọ Olúwa ni kí a máa yìn.

Olúwa ga lórí gbogbo orílẹ̀-èdè,
    àti ògo rẹ̀ lórí àwọn ọ̀run.
Ta ló dàbí Olúwa Ọlọ́run wa,
    tí ó gbé ní ibi gíga.
Tí ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ láti wò
    òun tí ó ń bẹ lọ́run, àti nínú ayé!

Ó gbé òtòṣì dìde láti inú erùpẹ̀, àti pé
    ó gbé aláìní sókè láti inú ààtàn wá.
Kí ó le mú un jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé
    àní pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé àwọn ènìyàn rẹ̀.
Ó mú àgàn obìnrin gbé inú ilé,
    àti láti jẹ́ aláyọ̀ ìyá fún àwọn ọmọ rẹ̀.

Ẹ yin Olúwa.

Jobu 38:1-11

Ọlọ́run pe Jobu níjà

38 Nígbà náà ní Olúwa dá Jobu lóhùn láti inú ìjì àjàyíká wá, ó sì wí pé:

“Ta ni èyí tí ń fi ọ̀rọ̀ àìlóye
    láti fi ṣókùnkùn bo ìmọ̀ mi?
Di ẹ̀gbẹ́ ara rẹ ní àmùrè bí ọkùnrin nísinsin yìí,
    nítorí pé èmi yóò béèrè lọ́wọ́ rẹ
    kí o sì dá mi lóhùn.

“Níbo ni ìwọ wà nígbà tí mo fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀?
    Wí bí ìwọ bá mòye.
Ta ni ó fi ìwọ̀n rẹ lélẹ̀, dájú bí ìwọ bá mọ̀ ọ́n?
    Tàbí ta ni ó ta okùn wíwọ̀n sórí rẹ?
Lórí ibo ni a gbé kan ìpìlẹ̀ rẹ̀ mọ́,
    tàbí ta ni ó fi òkúta igun rẹ̀ lélẹ̀,
Nígbà náà àwọn ìràwọ̀ òwúrọ̀ jùmọ̀ kọrin pọ̀,
    tí gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run hó ìhó ayọ̀?

“Tàbí ta ni ó fi ìlẹ̀kùn sé omi Òkun mọ́,
    nígbà tí ó ya padà bí ẹni pé ó ti inú jáde wá,
Nígbà tí mo fi àwọsánmọ̀ ṣe aṣọ rẹ̀,
    tí mo sì fi òkùnkùn biribiri ṣe ọ̀já ìgbà inú rẹ̀,
10 Nígbà tí mo ti pàṣẹ ìpinnu mi fún un,
    tí mo sì ṣe bèbè àti ìlẹ̀kùn,
11 Tí mo sì wí pé níhìn-ín ni ìwọ ó dé, kí o má sì rékọjá,
    níhìn-ín sì ni ìgbéraga rẹ yóò gbé dúró mọ?

Jobu 42:1-5

Ìrònúpìwàdà Jobu

42 Nígbà náà ní Jobu dá Olúwa lóhùn, ó sì wí pé:

“Èmi mọ̀ pé, ìwọ lè e ṣe ohun gbogbo,
    àti pé, kò si ìrò inú tí a lè fa sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ.
Ìwọ béèrè, ta ni ẹni tí ń fi ìgbìmọ̀ pamọ́ láìní ìmọ̀?
    Nítorí náà ní èmi ṣe ń sọ èyí tí èmi kò mọ̀,
    ohun tí ó ṣe ìyanu jọjọ níwájú mi, ti èmi kò mòye.

“Ìwọ wí pé, ‘gbọ́ tèmi báyìí,
    èmi ó sì sọ; èmi ó béèrè lọ́wọ́ rẹ,
    ìwọ yóò sì dá mi lóhùn.’
Etí mi sì ti gbọ́ nípa rẹ,
    ṣùgbọ́n nísinsin yìí ojú mi ti rí ọ.

Ìfihàn 19:4-16

Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún nì, àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin nì sì wólẹ̀, wọ́n sì foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run tí ó jókòó lórí ìtẹ́, wí pé:

“Àmín, Haleluya!”

(A)Ohùn kan sì ti ibi ìtẹ́ náà jáde wá, wí pé:

“Ẹ máa yin Ọlọ́run wa,
    ẹ̀yin ìránṣẹ́ rẹ̀ gbogbo,
ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
    àti èwe àti àgbà!”

Mo sì gbọ́ bí ẹni pé ohùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àti bí ìró omi púpọ̀, àti bí ìró àrá ńláńlá, ń wí pé:

“Haleluya!
Nítorí Olúwa Ọlọ́run wa, Olódùmarè ń jẹ ọba.
(B)Ẹ jẹ́ kí a yọ̀, kí inú wa kí ó sì dùn gidigidi,
    kí a sì fi ògo fún un.
Nítorí pé ìgbéyàwó Ọ̀dọ́-Àgùntàn dé,
    aya rẹ̀ sì ti múra tán.
Òun ni a sì fi fún pé kí ó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀
    wíwẹ́ tí ó funfun gbòò.”

(Nítorí pé aṣọ ọ̀gbọ̀ nì dúró fún iṣẹ́ òdodo àwọn ènìyàn mímọ́.)

Ó sì wí fún mi pé, “Kọ̀wé rẹ̀, ‘Ìbùkún ni fún àwọn tí a pè sí àsè alẹ́ ìgbéyàwó ọ̀dọ́-àgùntàn.’ ” Ó sì wí fún mi pé: “Ìwọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ òtítọ́ Ọlọ́run.”

10 Mo sì wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀ láti foríbalẹ̀ fún un. Ó sì wí fún mi pé, “Wò ó, má ṣe bẹ́ẹ̀: ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ni èmi, àti ti àwọn arákùnrin rẹ̀ tí wọ́n di ẹ̀rí Jesu mú. Foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run: nítorí pé ẹ̀rí Jesu ni ìsọtẹ́lẹ̀.”

Ẹni tó gun ẹṣin funfun

11 (C)Mo sì rí ọ̀run ṣí sílẹ̀, sì wò ó, ẹṣin funfun kan; ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ni à ń pè ní Olódodo àti Olóòtítọ́, nínú òdodo ni ó sì ń ṣe ìdájọ́, tí ó ń jagun. 12 (D)Ojú rẹ̀ dàbí ọ̀wọ́-iná, àti ní orí rẹ̀ ni adé púpọ̀ wà; ó sì ní orúkọ kan tí a kọ, tí ẹnikẹ́ni kò mọ́, bí kò ṣe òun tìkára rẹ̀. 13 A sì wọ̀ ọ́ ní aṣọ tí a tẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀: a sì ń pe orúkọ rẹ̀ ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. 14 Àwọn ogun tí ń bẹ ní ọ̀run tí a wọ̀ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́, funfun àti mímọ́, sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn lórí ẹṣin funfun. 15 (E)Àti láti ẹnu rẹ̀ ni idà mímú ti ń jáde lọ, kí ó lè máa fi sá àwọn orílẹ̀-èdè: “Òun ó sì máa fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn.” Ó sì ń tẹ ìfúntí àti ìbínú Ọlọ́run Olódùmarè. 16 (F)Ó sì ní lára aṣọ rẹ̀ àti ni ìtàn rẹ̀ orúkọ kan tí a kọ:

Johanu 1:29-34

Jesu jẹ́ Ọ̀dọ́-Àgùntàn Ọlọ́run

29 (A)Ní ọjọ́ kejì, Johanu rí Jesu tí ó ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Wò ó, Ọ̀dọ́-àgùntàn Ọlọ́run, ẹni tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ! 30 Èyí ni ẹni tí mo ń sọ nígbà tí mo wí pé, ‘Ọkùnrin kan tí ń bọ̀ wá lẹ́yìn mi, tí ó pọ̀jù mí lọ, nítorí tí ó ti wà ṣáájú mi.’ 31 Èmi gan an kò sì mọ̀ ọ́n, ṣùgbọ́n ìdí tí mo fi wá ń fi omi ṣe ìtẹ̀bọmi ni kí a lè fi í hàn fún Israẹli.”

32 (B)Nígbà náà ni Johanu jẹ́rìí sí i pé: “Mo rí Ẹ̀mí sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá bí àdàbà, tí ó sì bà lé e. 33 Èmí kì bá tí mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe pé ẹni tí ó rán mi láti fi omi bamitiisi sọ fún mi pé, ‘Ọkùnrin tí ìwọ rí tí Ẹ̀mí sọ̀kalẹ̀ tí ó bà lé lórí ni ẹni tí yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ bamitiisi.’ 34 Èmi ti rí i, mo sì jẹ́rìí pé, èyí ni Ọmọ Ọlọ́run.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.