Book of Common Prayer
Fún adarí orin. Ti ohùn “Àdàbà lórí Óákù òkè réré.” Ti Dafidi. Miktamu. Nígbà tí àwọn ará Filistini ka mọ́ ní Gati.
56 Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run, nítorí àwọn ènìyàn ń fi ìgbónára lépa mi;
ní gbogbo ọjọ́ ni wọn ń kọjú ìjà
sí mi, wọn ń ni mi lára.
2 Àwọn ọ̀tá mi ń lé mi ní gbogbo ọjọ́,
àwọn ènìyàn ń kọjú ìjà sí mi nínú ìgbéraga wọn.
3 Nígbà tí ẹ̀rù bà ń bà mí,
èmi o gbẹ́kẹ̀lé ọ.
4 Nínú Ọlọ́run èmi yóò máa yìn ọ̀rọ̀ rẹ,
nínú Ọlọ́run ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi; ẹ̀rù kì yóò bà mí
kí ni ẹran-ara lè ṣe sí mi?
5 Wọn ń yí ọ̀rọ̀ mí ní gbogbo ọjọ́,
wọn ń gbèrò nígbà gbogbo láti ṣe mí níbi.
6 Wọn kó ara wọn jọ, wọ́n ba
Wọ́n ń ṣọ́ ìgbésẹ̀ mi
wọn ń làkàkà láti gba ẹ̀mí mi.
7 San ẹ̀san iṣẹ́ búburú wọ́n fún wọn;
Ní ìbínú rẹ, Ọlọ́run, wọ́ àwọn ènìyàn náà bọ́ sílẹ̀.
8 Kọ ẹkún mi sílẹ̀;
kó omijé mi sí ìgò rẹ,
wọ́n kò ha sí nínú ìkọ̀sílẹ̀ rẹ bí?
9 Nígbà náà ni àwọn ọ̀tá mi yóò pẹ̀yìndà
nígbà tí mo bá pè fún ìrànlọ́wọ́
nípa èyí ni mo mọ̀ pé Ọlọ́run ń bẹ fún mi.
10 Nínú Ọlọ́run, ẹni tí mo yìn ọ̀rọ̀ rẹ̀
nínú Olúwa, ẹni tí mo yin ọ̀rọ̀ rẹ̀:
11 Nínú Ọlọ́run ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi:
ẹ̀rù kì yóò bà mí.
Kí ni ènìyàn lè ṣe sí mi?
12 Mo jẹ́ ẹ̀jẹ́ lábẹ́ rẹ Ọlọ́run:
èmi o mú ìyìn mi wá fún ọ.
13 Nítorí ìwọ tí gbà mí lọ́wọ́ ikú
àti ẹsẹ̀ mi lọ́wọ́ ìṣubú,
kí èmí lè máa rìn níwájú Ọlọ́run
ní ìmọ́lẹ̀ àwọn alààyè.
Fún adarí orin. Ní ohùn “Má ṣe parun.” Ti Dafidi. Miktamu. Nígbà tí ó sá níwájú Saulu lọ sínú ihò òkúta.
57 Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run, ṣàánú fún mi,
nítorí nínú rẹ ni ààbò ọkàn mí wà.
Èmi o fi ààbò mí sí ibi ìyẹ́ apá rẹ
títí tí ewu yóò fi kọjá lọ.
2 Mo kígbe sókè sí Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo jùlọ,
sí Ọlọ́run tó ń pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́ fún mi.
3 Òun yóò ránṣẹ́ láti ọ̀run wá,
yóò sì gbà mí, bí ẹni tí ń fẹ́ gbé mi mì
tilẹ̀ ń kẹ́gàn mi.
Ọlọ́run yóò rán àánú rẹ̀ àti òdodo rẹ̀ jáde.
4 Mo wà ní àárín àwọn kìnnìún;
mo dùbúlẹ̀ ni abẹ́ àwọn ẹ̀dá búburú,
àwọn ènìyàn tí eyín wọn dàbí ọ̀kọ̀ àti ọfà
ẹni tí ahọ́n rẹ̀ jẹ́ idà mímú.
5 Kí a yìn ọ́ Ọlọ́run, ju ọ̀run lọ,
kí ògo rẹ kò ju ti gbogbo ayé lọ.
6 Wọ́n ti ta àwọ̀n sílẹ̀ fún ẹsẹ̀ mi:
a tẹ orí ọkàn mi ba nínú ìtìjú,
wọ́n gbẹ́ kòtò sí ọ̀nà mi:
ṣùgbọ́n wọ́n ti jì síbẹ̀ fún ara wọn.
7 (A)Ọkàn mi ti múra Ọlọ́run;
ọkàn mi ti múra, èmi ó kọrin, èmi ó si máa kọrin ìyìn.
8 Jí, ìwọ ọkàn mi!
Jí, ohun orin èlò àti dùùrù!
Èmi tìkára mi, yóò sì jí ní kùtùkùtù.
9 Èmi ó máa yìn ọ́, Olúwa, láàrín àwọn orílẹ̀-èdè;
èmi ó máa kọrin sí ọ láàrín àwọn ènìyàn.
10 Nítorí títóbi ní ìfẹ́ rẹ, tí ó dé ọ̀run;
òtítọ́ rẹ tàn dé àwọsánmọ̀.
11 Gbígbéga ni ọ́, Ọlọ́run, ju àwọn ọ̀run lọ;
kí ògo rẹ kí ó ju gbogbo ayé lọ.
Fún adarí orin. Tí ohùn “Má ṣe parun.” Ti Dafidi. Miktamu.
58 Ẹ̀yin ha ń sọ òdodo nítòótọ́
ẹ̀yin ìjọ ènìyàn?
Ǹjẹ́ ẹ̀yin ń ṣe ìdájọ́ tí ó ṣe títọ́
ẹ̀yìn ọmọ ènìyàn?
2 Bẹ́ẹ̀ kọ́, nínú ọkàn yín ẹ̀yìn ń gbèrò àìṣòdodo,
ọwọ́ yín sì tú ìwà ipá jáde ni ayé.
3 Ní inú ìyá wọn wá ni ènìyàn búburú tí ṣìnà,
lójúkan náà tí a ti bí wọn, wọn a máa ṣèké.
4 Oró wọn dàbí oró ejò,
wọn dàbí adití ejò paramọ́lẹ̀ tí ó di ara rẹ̀ ni etí,
5 tí kò ní gbọ́ ìpè àwọn atunilójú,
bí ó ti wù kí ó máa fi ọgbọ́n ṣe ìtujú tó.
6 Ká eyín ẹnu wọn, Ọlọ́run;
ní ẹnu wọn,
ká ọ̀gàn àwọn ọmọ kìnnìún, Olúwa.
7 Jẹ́ kí wọn parẹ́ bí omi tó ń sàn lọ;
nígbà tí ó bá fa ọfà rẹ̀, kí ọ̀kọ̀ wọn kí ó ṣẹ́.
8 Jẹ́ kí wọn rí bí ìgbín tí rẹ̀ dànù tí ó sì ṣègbé
bí ọmọ tí oṣù rẹ̀ kò pé, kí wọn má ṣe rí oòrùn.
9 Kí ìkòkò yín kí ó tó mọ ìgbóná ẹ̀gún;
bóyá ní tútù tàbí ní gbígbẹ, yóò fi ìjì gbá wọn lọ.
10 Olódodo yóò yọ̀ nígbà a bá ń gbẹ̀san wọn,
nígbà tí wọn bá wẹ ẹsẹ̀ wọn nínú ẹ̀jẹ̀ ènìyàn búburú.
11 Àwọn ènìyàn yóò wí pé,
“Lóòtítọ́ èrè àwọn ń bẹ fún olódodo;
lóòtítọ́ òun ni Ọlọ́run tí ń ṣe ìdájọ́ ní ayé.”
Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.
64 Gbóhùn mi, Ọlọ́run, bí mo ti ń sọ àròyé mi
pa ọkàn mi mọ́ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀rù àwọn ọ̀tá.
2 Pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ àwọn ènìyàn búburú
kúrò nínú ọ̀pọ̀ igbe lọ́wọ́ ìrúkèrúdò oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.
3 Wọ́n pọ́n ahọ́n wọn bí idà,
wọ́n sì fa ọrun wọn le láti tafà wọn, àní ọ̀rọ̀ kíkorò.
4 Wọ́n tafà ní ìkọ̀kọ̀ sí àwọn aláìlẹ́ṣẹ̀:
wọ́n tafà si lójijì, wọn kò sì bẹ̀rù.
5 Wọ́n, gba ara wọn níyànjú nínú èrò búburú,
wọ́n sọ̀rọ̀ lórí dídẹkùn sílẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀
wọ́n wí pé, “Ta ni yóò rí wa?”
6 Wọ́n gbìmọ̀ àìṣòdodo, wọ́n wí pé,
“A wa ti parí èrò tí a gbà tán”
lóòótọ́ àyà àti ọkàn ènìyàn kún fún àrékérekè.
7 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò ta wọ́n ní ọfà;
wọn ó sì gbọgbẹ́ lójijì.
8 Ahọ́n wọn yóò sì dojú ìjà kọ wọ́n, yóò sì run wọ́n,
Gbogbo ẹni tí ó bá rí wọn yóò sì mi orí fún wọn.
9 Gbogbo ènìyàn yóò máa bẹ̀rù
wọn ó kéde iṣẹ́ Ọlọ́run
wọn ó dúró lé ohun tí ó ṣe.
10 Jẹ́ kí olódodo kí ó yọ̀ nínú Olúwa
yóò sì rí ààbò nínú rẹ̀.
Gbogbo ẹni ìdúró ṣinṣin ní ọkàn yóò máa yìn ín.
Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. Orin.
65 Ìyìn ń dúró dè ọ́, Ọlọ́run, ní Sioni;
sí ọ ni a ó mú ẹ̀jẹ́ wa ṣẹ.
2 Ìwọ tí ó ń gbọ́ àdúrà,
gbogbo ènìyàn yóò sì wá sọ́dọ̀ rẹ.
3 Ọ̀ràn àìṣedéédéé borí mi bí ó ṣe ti ìrékọjá wa ni!
Ìwọ ni yóò wẹ̀ wọ́n nù kúrò.
4 Ìbùkún ni fún àwọn tí o yàn
tí o mú wa láti máa gbé àgọ́ rẹ!
A tẹ́ wá lọ́rùn pẹ̀lú ohun rere inú ilé rẹ,
ti tẹmpili mímọ́ rẹ.
5 Ìwọ dá wa lóhùn pẹ̀lú ohun ìyanu ti òdodo,
Ọlọ́run olùgbàlà wa,
ẹni tí ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé gbogbo òpin ayé
àti àwọn tí ó jìnnà nínú Òkun,
6 Ìwọ tí ó dá òkè nípa agbára rẹ,
tí odi ara rẹ ní àmùrè agbára
7 Ẹni tí ó mú rírú omi Òkun dákẹ́
ríru ariwo omi wọn,
àti ìdágìrì àwọn ènìyàn
8 Àwọn tí ó ń gbé òkèrè bẹ̀rù,
nítorí ààmì rẹ wọ̀n-ọn-nì;
ìwọ mú ìjáde òwúrọ̀ àti ti àṣálẹ́ yọ̀,
ìwọ pè fún orin ayọ̀.
9 Ìwọ bẹ ayé wò, o sì bomirin;
ìwọ mú un ọ̀rọ̀ púpọ̀.
Odò Ọlọ́run kún fún omi
láti pèsè ọkà fún àwọn ènìyàn,
nítorí ibẹ̀ ni ìwọ ti yàn án.
10 Ìwọ fi bomirin sí aporo rẹ̀
ìwọ tẹ́ ògúlùtu rẹ̀;
ìwọ fi òjò mú ilẹ̀ rẹ̀ rọ̀,
o sì bùkún ọ̀gbìn rẹ̀.
11 Ìwọ fi oore rẹ dé ọdún ní adé,
ọ̀rá ń kán ní ipa ọ̀nà rẹ
12 Pápá tútù ní aginjù ń kan
àwọn òkè kéékèèkéé fi ayọ̀ di ara wọn ní àmùrè.
13 Agbo ẹran ni a fi wọ pápá tútù náà ní aṣọ;
Àfonífojì ni a fi ọkà bò mọ́lẹ̀,
wọ́n hó fún ayọ̀, wọ́n ń kọrin pẹ̀lú.
Àwọn òfin fún agbo ilé Kristi
18 (A)Ẹ̀yin aya, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọkọ yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ nínú Olúwa.
19 Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa fẹ́ràn àwọn aya yín, ẹ má sì ṣe korò sí wọn.
20 Ẹ̀yin ọmọ ẹ máa gbọ́ ti àwọn òbí yín ní ohun gbogbo: nítorí èyí dára gidigidi nínú Olúwa.
21 Ẹ̀yin baba, ẹ má ṣe mú àwọn ọmọ yín bínú, kí wọn má bà á rẹ̀wẹ̀sì.
22 Ẹ̀yin ẹrú, ẹ gbọ́ ti àwọn olówó yín nípa ti ara ní ohun gbogbo; kì í ṣe ní àrọ́júṣe, bí àwọn aláṣehàn ènìyàn; ṣùgbọ́n ní òtítọ́ inú, ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run: 23 (B)Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá ń ṣe, ẹ máa fi tọkàntọkàn ṣe é fún Olúwa, kí í ṣe fún ènìyàn; 24 Kí ẹ mọ̀ pé lọ́wọ́ Olúwa ni ẹ̀yin ó gba èrè: nítorí ẹ̀yin ń sìn Olúwa Kristi. 25 Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe àìṣòdodo, yóò gbà á padà nítorí àìṣòdodo náà tí ó ti ṣe: kò sì ṣí ojúsàájú.
4 (C)Ẹyin ọ̀gá, ẹ máa fi èyí tí ó tọ́ tí ó sì dọ́gba fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ yín; kí ẹ sì mọ̀ pé ẹ̀yin pẹ̀lú ní Olúwa kan ní ọ̀run.
Àwọn ìlànà fún ìjọ
2 Ẹ fi ara yín jì fún àdúrà gbígbà, kí ẹ ṣọ́ra kí ẹ sì máa dúpẹ́; 3 Ẹ máa gbàdúrà fún wa pẹ̀lú, kí Ọlọ́run lè ṣí ìlẹ̀kùn fún wa fún ọ̀rọ̀ náà, láti máa sọ ohun ìjìnlẹ̀ Kristi, nítorí èyí tí mo ṣe wà nínú ìdè pẹ̀lú: 4 Ẹ gbàdúrà pé kí èmi le è máa kéde rẹ̀ kedere gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ fún mi. 5 (D)Ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ti bí ẹ ti ń ṣe pẹ̀lú àwọn tí ń bẹ lóde, kí ẹ sì máa ṣe ṣí àǹfààní tí ẹ bá nílò. 6 Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yín kí ó dàpọ̀ mọ́ oore-ọ̀fẹ́ nígbà gbogbo, èyí tí a fi iyọ̀ dùn, kí ẹ̀yin kí ó le mọ́ bí ẹ̀yin ó tí máa dá olúkúlùkù ènìyàn lóhùn.
Àwọn ìkíni ìkẹyìn
7 (E)Gbogbo bí nǹkan ti rí fún mi ní Tikiku yóò jẹ́ kí ẹ mọ̀. Òun jẹ́ arákùnrin olùfẹ́ àti olóòtítọ́ ìránṣẹ́ àti ẹlẹgbẹ́ nínú Olúwa: 8 Ẹni tí èmí ń rán sí yín nítorí èyí kan náà, kí ẹ̀yin lè mọ́ bí a ti wà, kí òun kí ó lè tu ọkàn yín nínú; 9 (F)Òun sì ń bọ̀ pẹ̀lú Onesimu, arákùnrin olóòtítọ́ àti olùfẹ́, ẹni tí í ṣe ọ̀kan nínú yín. Àwọn ní yóò sọ ohun gbogbo tí à ń ṣe níhìn-ín-yìí fún un yín.
10 (G)Aristarku, ẹlẹgbẹ́ mí nínú túbú kí i yín, àti Marku, ọmọ arábìnrin Barnaba (Nípasẹ̀ ẹni tí ẹ̀yin ti gba àṣẹ; bí ó bá sì wá sí ọ̀dọ̀ yín, ẹ gbà á).
11 Àti Jesu, ẹni tí à ń pè ní Justu, ẹni tí ń ṣe ti àwọn onílà. Àwọn wọ̀nyí nìkan ni olùbáṣiṣẹ́ mí fún ìjọba Ọlọ́run, àwọn ẹni tí ó tí jásí ìtùnú fún mi.
12 Epafira, ẹni tí ń ṣe ọ̀kan nínú yín àti ìránṣẹ́ Kristi Jesu kí i yín. Òun fi ìwàyáàjà gbàdúrà nígbà gbogbo fún un yín, kí ẹ̀yin kí ó lè dúró ní pípé nínú ohun gbogbo nínú ìfẹ́ Ọlọ́run. 13 Nítorí mo jẹ́rìí rẹ̀ pé ó ń ṣiṣẹ́ kárakára fún yín, àti fún àwọn tí ó wà ní Laodikea, àti àwọn tí ó wà ní Hirapoli.
14 (H)Luku, arákùnrin wa ọ̀wọ́n, oníṣègùn, àti Dema ki í yín.
15 Ẹ kí àwọn ará tí ó wà ní Laodikea, àti Nimpa, àti ìjọ tí ó wà ní ilé rẹ̀.
16 Nígbà tí a bá sì ka ìwé yìí ní àárín yín tan, kí ẹ mú kí a kà á pẹ̀lú nínú ìjọ Laodikea; ẹ̀yin pẹ̀lú sì ka èyí tí ó ti Laodikea wá.
17 Kí ẹ sì wí fún Arkippu pe, “Kíyèsi iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ìwọ ti gbà nínú Olúwa kí o sì ṣe é ní kíkún.”
18 (I)Ìkíni láti ọwọ́ èmi Paulu. Ẹ máa rántí ìdè mi. Kí oore-ọ̀fẹ́ kí ó wà pẹ̀lú yín.
A da òróró sí Jesu lára nípasẹ̀ obìnrin ẹlẹ́ṣẹ̀
36 (A)(B) Farisi kan sì rọ̀ ọ́ kí ó wá bá òun jẹun, ó sì wọ ilé Farisi náà lọ ó sì jókòó láti jẹun. 37 Sì kíyèsi i, obìnrin kan wà ní ìlú náà, ẹni tí i ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀, nígbà tí ó mọ̀ pé Jesu jókòó, ó ń jẹun ní ilé Farisi, ó mú ṣágo kékeré alabasita òróró ìkunra wá, 38 Ó sì dúró tì í lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀ lẹ́yìn, ó ń sọkún, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí i fi omijé wẹ̀ ẹ́ ní ẹsẹ̀, ó sì ń fi irun orí rẹ nù ún nù, ó sì ń fi ẹnu kò ó ní ẹsẹ̀, ó sì ń fi òróró kùn wọ́n.
39 (C)Nígbà tí Farisi tí ó pè é sì rí i, ó wí nínú ara rẹ̀ pé, “Ọkùnrin yìí ìbá ṣe wòlíì, ìbá mọ ẹni àti irú ẹni tí obìnrin yìí jẹ́ tí ń fi ọwọ́ kàn an, nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.”
40 Jesu sì dáhùn, ó wí fún un pé, “Simoni, Mo ní ohun kan sọ fún ọ.”
Ó sì dáhùn pé, “Olùkọ́ máa wí.”
41 “Ayánilówó kan wà tí ó ní ajigbèsè méjì: ọ̀kan jẹ ẹ́ ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta owó idẹ, èkejì sì jẹ ẹ́ ní àádọ́ta. 42 (D)Nígbà tí wọn kò sì ní ohun tí wọn ó san, ó dáríjì àwọn méjèèjì. Wí nínú àwọn méjèèjì, ta ni yóò fẹ́ ẹ jù?”
43 (E)Simoni dáhùn wí pé, “Mo ṣe bí ẹni tí ó dáríjì jù ni.”
Jesu wí fún un pé, “Ìwọ ti dájọ́ náà dáradára.”
44 Ó sì yípadà sí obìnrin náà, ó wí fún Simoni pé, “Wo obìnrin yìí? Èmi wọ ilé rẹ, ìwọ kò fi omi wẹ ẹsẹ̀ fún mi: ṣùgbọ́n, omijé rẹ̀ ni ó fi ń rọ̀jò sí mi lẹ́sẹ̀ irun orí ni ó fi ń nù wọ́n nù. 45 Ìwọ kò fi ìfẹnukonu fún mi: ṣùgbọ́n òun, nígbà tí mo ti wọ ilé, kò dẹ́kun ẹnu fífi kò mí lẹ́sẹ̀. 46 Ìwọ kò fi òróró pa mí lórí, ṣùgbọ́n òun ti fi òróró pa mí lẹ́sẹ̀. 47 Ǹjẹ́ mo wí fún ọ, A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó pọ̀ jì í: nítorí tí ó ní ìfẹ́ púpọ̀: ẹni tí a sì dárí díẹ̀ jì, òun náà ni ó ní ìfẹ́ díẹ̀.”
48 (F)Ó sì wí fún un pé, “A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́!”
49 Àwọn tí ó bá a jókòó jẹun sì bẹ̀rẹ̀ sí í rò nínú ara wọn pé, “Ta ni èyí tí ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni pẹ̀lú?”
50 (G)Ó sì dáhùn wí fún obìnrin náà pé, “Ìgbàgbọ́ rẹ gbà ọ́ là; máa lọ ní Àlàáfíà.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.