Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 148-150

148 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa láti ọ̀run wá,
    Ẹ fi ìyìn fún un níbi gíga.
Ẹ fi ìyìn fún un,
    gbogbo ẹ̀yin angẹli rẹ̀
Ẹ fi ìyìn fún un,
    gbogbo ẹ̀yin ọmọ-ogun rẹ̀
Ẹ fi ìyìn fún un,
    oòrùn àti òṣùpá
Ẹ fi ìyìn fún un,
    gbogbo ẹ̀yin ìràwọ̀ ìmọ́lẹ̀.
Ẹ fi ìyìn fún un,
    ẹ̀yin ọ̀run àti àwọn ọ̀run gíga
    àti ẹ̀yin omi tí ń bẹ ní òkè ọ̀run.

Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwa
    nítorí ó pàṣẹ a sì dá wọn
Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ láé àti láéláé
    ó sì ti ṣe ìlànà kan tí kì yóò já.

Ẹ yin Olúwa láti ilẹ̀ ayé wá
    ẹ̀yin ẹ̀dá inú Òkun títóbi
    àti ẹ̀yin ibú Òkun
Mọ̀nàmọ́ná àti òjò yìnyín
    ìdí omi àti àwọn ìkùùkuu,
    ìjì líle tí ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ;
Òkè ńlá àti gbogbo òkè kéékèèkéé,
    igi eléso àti gbogbo igi kedari,
10 Àwọn ẹranko ńlá àti ẹran ọ̀sìn
    gbogbo ohun afàyàfà àti àwọn ẹyẹ abìyẹ́:
11 Àwọn ọba ayé àti ènìyàn ayé gbogbo
    àwọn ọmọ-aládé àti gbogbo àwọn onídàájọ́ ayé,
12 Ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin
    àwọn arúgbó àti àwọn ọmọdé.

13 Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwa
    nítorí orúkọ rẹ̀ nìkan ni ó ní ọlá
    ògo rẹ̀ kọjá ayé àti ọ̀run
14 Ó sì gbé ìwo kan sókè fún àwọn ènìyàn rẹ̀,
    ìyìn fún gbogbo ènìyàn mímọ́ rẹ̀ àní fún àwọn ọmọ Israẹli,
    àwọn ènìyàn tí ó súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
149 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa.
    Ẹ yìn ín ní àwùjọ àwọn ènìyàn mímọ́.

Jẹ́ kí Israẹli kí ó ní inú dídùn sí ẹni tí ó dá a
    jẹ́ kí àwọn ọmọ Sioni kí ó ní
    ayọ̀ nínú ọba wọn.
Jẹ́ kí wọn kí ó fi ijó yin orúkọ rẹ̀
    jẹ́ kí wọn kí ó fi ohun èlò orin kọrin ìyìn sí i.
Nítorí Olúwa ní inú dídùn sí àwọn ènìyàn rẹ̀
    ó fi ìgbàlà dé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ládé
Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mímọ́ kí ó yọ̀ nínú ọlá rẹ̀
    kí wọn kí ó máa kọrin fún ayọ̀ ní orí ibùsùn wọn.

Kí ìyìn Ọlọ́run kí ó wà ní ẹnu wọn
    àti idà olójú méjì ní ọwọ́ wọn.
Láti gba ẹ̀san lára àwọn orílẹ̀-èdè,
    àti ìjìyà lára àwọn ènìyàn,
Láti fi ẹ̀wọ̀n de àwọn ọba wọn
    àti láti fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀
irin de àwọn ọlọ́lá wọn.
Láti ṣe ìdájọ́ tí àkọsílẹ̀ rẹ̀ sí wọn
    èyí ni ògo àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
150 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Ẹ fi ìyìn fún Ọlọ́run ní ibi mímọ́ rẹ̀
    Ẹ yìn ín nínú agbára ọ̀run rẹ̀.
Ẹ yìn ín fún iṣẹ́ agbára rẹ̀.
    Ẹ yìn ín fún títóbi rẹ̀ tí ó tayọ̀.
Ẹ fi ohùn ìpè yìn ín.
    Ẹ fi ohun èlò orin yìn ín.
Ẹ fi ohun èlò orin àti ijó yìn ín
    fi ohun èlò orin olókùn àti ìpè yìn ín
Ẹ yìn ín pẹ̀lú aro olóhùn òkè,
    Ẹ yìn ín lára aro olóhùn gooro.

Jẹ́ kí gbogbo ohun tí ó ní ẹ̀mí yin Olúwa.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Saamu 114-115

114 Nígbà tí Israẹli jáde ní Ejibiti,
    ilé Jakọbu láti inú ènìyàn àjèjì èdè
Juda wà ní ibi mímọ́,
    Israẹli wà ní ìjọba.

(A)Òkun sì rí i, ó sì wárìrì:
    Jordani sì padà sẹ́yìn.
Àwọn òkè ńlá ń fò bí àgbò àti
    òkè kéékèèkéé bí ọ̀dọ́-àgùntàn.

Kí ni ó ṣe ọ́, ìwọ Òkun, tí ìwọ fi wárìrì?
    Ìwọ Jordani, tí ìwọ fi padà sẹ́yìn?
Ẹ̀yin òkè ńlá kí ló dé ti ẹ fi ń fò bí àgbò,
    àti ẹ̀yin òkè kéékèèkéé bí ọ̀dọ́-àgùntàn?

Wárìrì, ìwọ ilẹ̀, níwájú Olúwa;
    ní iwájú Ọlọ́run Jakọbu
tí ó sọ àpáta di adágún omi,
    àti òkúta-ìbọn di orísun omi.
115 Kì í ṣe fún wa, Olúwa kì í ṣe fún wa,
    ṣùgbọ́n fún orúkọ rẹ ni a fi ògo fún,
    fún àánú àti òtítọ́ rẹ.

Torí kí ni àwọn kèfèrí yóò ṣe sọ pé,
    níbo ni Ọlọ́run wa wà.
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wa wà lọ́run:
    tí ó ń ṣe èyí tí ó wù ú.
(B)Fàdákà òun wúrà ni èrè àwọn aláìkọlà,
    iṣẹ́ ọwọ́ ènìyàn ni,
Wọ́n ní ẹnu, ṣùgbọ́n wọn kò le sọ̀rọ̀,
    wọ́n ní ojú, ṣùgbọ́n wọn kò fi ríran.
Wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbọ́rọ̀:
    wọ́n ní imú, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbóòórùn
Wọ́n ní ọwọ́, ṣùgbọ́n wọn kò lò ó,
    wọ́n ní ẹsẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò rìn;
    bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sọ̀rọ̀ nínú òfin wọn.
Àwọn tí ń ṣe wọ́n dàbí wọn;
    gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé wọn.

Ìwọ Israẹli gbẹ́kẹ̀lé Olúwa:
    òun ni ìrànwọ́ àti ààbò wọn
10 Ẹ̀ yin ilé Aaroni, gbẹ́kẹ̀lé Olúwa:
    òun ni ìrànwọ́ àti ààbò wọn
11 Ẹ̀ yin tí ó bẹ̀rù Olúwa, gbẹ́kẹ̀lé Olúwa:
    òun ní ìrànwọ́ àti ààbò wọn.

12 Olúwa tí ń ṣe ìrántí wa; yóò bùkún ilé Israẹli;
    yóò bùkún ilé Aaroni.
13 (C)Ìbùkún ni fún àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa,
    àti kékeré àti ńlá.

14 Olúwa yóò mú ọ pọ̀ sí i síwájú àti síwájú,
    ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ̀.
15 Ẹ fi ìbùkún fún Olúwa
    ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé.

16 Ọ̀run àní ọ̀run ni ti Olúwa:
    ṣùgbọ́n ayé ló fi fún ọmọ ènìyàn.
17 Òkú kò lè yìn Olúwa,
    tàbí ẹni tí ó ti lọ sí ìsàlẹ̀ ìdákẹ́ jẹ́ẹ́.
18 Ṣùgbọ́n àwa ó fi ìbùkún fún Olúwa
    láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.

Ẹ yin Olúwa.

Daniẹli 4:1-18

Nebukadnessari lá àlá nípa igi

Nebukadnessari ọba,

Sí gbogbo ènìyàn, orílẹ̀ àti onírúurú èdè, tí ó ń gbé ní àgbáyé:

Kí àlàáfíà máa pọ̀ sí i fún un yín.

Kí ẹ ṣe rere tó pọ̀!

Ó jẹ́ ìdùnnú fún mi láti fi iṣẹ́ ààmì àti ìyanu tí Ọlọ́run Ọ̀gá-Ògo ti ṣe fún mi hàn.

Báwo ni ààmì rẹ̀ ti tóbi tó,
    Báwo ni ìyanu rẹ̀ ṣe pọ̀ tó!
Ìjọba rẹ̀, ìjọba títí ayé ni;
    ilẹ̀ ọba rẹ̀ láti ìran dé ìran ni.

Èmi Nebukadnessari wà ní ààfin mi, pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn àti àlàáfíà. Mo lá àlá kan èyí tí ó bà mí lẹ́rù. Nígbà tí mo wà lórí ibùsùn mi, ìran tí ó jáde lọ́kàn mi dẹ́rùbà mí. Nígbà náà, ni mo pàṣẹ pé kí a mú gbogbo àwọn amòye Babeli wá, kí wọn wá sọ ìtumọ̀ àlá náà fún mi. Nígbà tí àwọn apidán, àwọn apògèdè, àwọn awòràwọ̀ àti àwọn aláfọ̀ṣẹ wá, mo sọ àlá náà fún wọn, ṣùgbọ́n wọn kò le è sọ ìtumọ̀ àlá náà fún mi. Ní ìkẹyìn Daniẹli wá síwájú mi, mo sì sọ àlá náà fún (ẹni tí à ń pè ní Belṣassari gẹ́gẹ́ bí orúkọ òrìṣà mi àti pé ẹ̀mí àwọn Ọlọ́run mímọ́ wà nínú rẹ̀.)

Mo wí pé, “Belṣassari, olórí àwọn amòye, èmi mọ̀ wí pé ẹ̀mí Ọlọ́run mímọ́ wà nínú rẹ, kò sì ṣí àṣírí kan tí ó ṣòro jù fún ọ. Sọ àlá mi kí o sì túmọ̀ rẹ̀ fún mi. 10 Èyí ni ìran náà tí mo rí nígbà tí mo wà lórí ibùsùn mi, mo rí igi kan láàrín ayé, igi náà ga gidigidi. 11 Igi náà tóbi, ó sì lágbára, orí rẹ̀ sì ń kan ọ̀run; a sì rí i títí dé òpin ayé. 12 (A)Ewé rẹ̀ lẹ́wà, èso rẹ̀ sì pọ̀, ó sì ń pèsè oúnjẹ fún gbogbo ènìyàn. Abẹ́ ẹ rẹ̀ ni àwọn ẹranko igbó fi ṣe ibùgbé, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ń gbé ní ẹ̀ka rẹ̀, nínú rẹ̀ ni gbogbo alààyè ti ń jẹ.

13 “Lórí ibùsùn mi, mo rí ìran náà, olùṣọ́ kan dúró síwájú u mi, àní ẹni mímọ́ kan, ó ń bọ̀ wá láti ọ̀run 14 ó kígbe sókè wí pé, ‘Gé igi náà kí o sì gé àwọn ẹ̀ka rẹ̀ kúrò; gbọn ewé rẹ̀ ká, kí o sì fọ́n èso rẹ̀ dànù. Jẹ́ kí àwọn ẹranko tí ó wà lábẹ́ rẹ̀ sá àti àwọn ẹyẹ tí ó wà ní ẹ̀ka rẹ̀ kúrò. 15 Ṣùgbọ́n fi kùkùté àti gbòǹgbò rẹ̀ tí a fi irin àti idẹ dè ṣẹ́kù sórí ilẹ̀ àti sí orí koríko igbó.

“ ‘Jẹ́ kí ìrì ọ̀run sẹ̀ sí i lára, kí ó sì jẹ́ kí ìpín in rẹ̀ wà pẹ̀lú àwọn ẹranko igbó láàrín ilẹ̀ ayé. 16 Jẹ́ kí ọkàn rẹ̀ kí ó yí padà kúrò ní ti ènìyàn, kí a sì fún un ní ọkàn ẹranko, títí ìgbà méje yóò fi kọjá lórí i rẹ̀.

17 “ ‘Olùṣọ́ ni ó gbé ìpinnu náà jáde, àṣẹ sì wá láti ọ̀dọ̀ ẹni mímọ́, kí gbogbo alààyè le mọ̀ wí pé, Ọ̀gá-ògo ni olórí ìjọba ènìyàn, ó sì ń fi fún ẹnikẹ́ni tí ó wù ú, òun sì ń gbé onírẹ̀lẹ̀ lórí i wọn.’

18 “Èyí ni àlá tí èmi Nebukadnessari ọba lá. Ní ìsinsin yìí ìwọ Belṣassari, sọ ohun tí ó túmọ̀ sí fún mi, nítorí kò sí amòye kan ní ìjọba mi, tí ó lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi. Ṣùgbọ́n ìwọ lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀, nítorí tí ẹ̀mí Ọlọ́run mímọ́ wà ní inú rẹ.”

1 Peteru 4:7-11

Ṣùgbọ́n òpin ohun gbogbo kù sí dẹ̀dẹ̀; nítorí náà kí ẹ̀yin wà ní àìrékọjá, kí ẹ sì máa ṣọ́ra nínú àdúrà. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ẹ ní ìfẹ́ tí ó gbóná láàrín ara yín: nítorí ìfẹ́ ni ń bo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀. Ẹ máa ṣe ara yín ni àlejò láìsí ìkùnsínú. 10 Bí olúkúlùkù ti rí ẹ̀bùn gbà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ máa ṣe ìpín fún ni rẹ̀ láàrín ara yín, bí ìríjú rere tí onírúurú oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run. 11 Bí ẹnikẹ́ni ba ń sọ̀rọ̀, kí o máa sọ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, bí ẹnikẹ́ni bá ń ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́, kí ó ṣe é bí agbára tí Ọlọ́run fi fún un, kí a lè máa yin Ọlọ́run lógo ní ohun gbogbo nípa Jesu Kristi, ẹni tí ògo àti ìjọba wà fún láé àti láéláé. Àmín.

Johanu 21:15-25

Jesu fún Peteru ní iṣẹ́

15 (A)Ǹjẹ́ lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jẹun òwúrọ̀ tan, Jesu wí fún Simoni Peteru pé, “Simoni, ọmọ Jona, ìwọ fẹ́ mi ju àwọn wọ̀nyí lọ bí?”

Ó sì wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa; ìwọ mọ̀ pé, mo fẹ́ràn rẹ.”

Ó wí fún un pé, “Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi.”

16 (B)Ó tún wí fún un nígbà kejì pé, “Simoni ọmọ Jona, ìwọ fẹ́ mi bí?”

Ó wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa; ìwọ mọ̀ pé, mo fẹ́ràn rẹ.”

Ó wí fún un pé, “Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi.”

17 Ó wí fún un nígbà kẹta pé, “Simoni, ọmọ Jona, ìwọ fẹ́ràn mi nítòótọ́ bí?”

Inú Peteru sì bàjẹ́, nítorí tí ó wí fún un nígbà ẹ̀kẹta pé, “Ìwọ fẹ́ràn mi nítòótọ́ bí?” Ó sì wí fún un pé, “Olúwa, ìwọ mọ ohun gbogbo; ìwọ mọ̀ pé, mo fẹ́ràn rẹ.”

Jesu wí fún un pé, “Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi. 18 Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, nígbà tí ìwọ wà ní ọ̀dọ́mọdé, ìwọ a máa di ara rẹ ní àmùrè, ìwọ a sì máa rìn lọ sí ibi tí ìwọ bá fẹ́: ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá di arúgbó, ìwọ yóò na ọwọ́ rẹ jáde, ẹlòmíràn yóò sì dì ọ́ ní àmùrè, yóò mú ọ lọ sí ibi tí ìwọ kò fẹ́.” 19 (C)Jesu wí èyí, ó fi ń ṣe àpẹẹrẹ irú ikú tí yóò fi yin Ọlọ́run lógo. Lẹ́yìn ìgbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó wí fún un pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”

20 (D)Peteru sì yípadà, ó rí ọmọ-ẹ̀yìn náà, ẹni tí Jesu fẹ́ràn, ń bọ̀ lẹ́yìn; ẹni tí ó gbara le súnmọ́ àyà rẹ̀ nígbà oúnjẹ alẹ́ tí ó sì wí fún un pé, “Olúwa, ta ni ẹni tí yóò fi ọ́ hàn?” 21 Nígbà tí Peteru rí i, ó wí fún Jesu pé, “Olúwa, Eléyìí ha ńkọ́?”

22 (E)Jesu wí fún un pé, “Bí èmi bá fẹ́ kí ó dúró títí èmi ó fi dé, kín ni èyí jẹ́ sí ọ? Ìwọ máa tọ̀ mí lẹ́yìn.” 23 Ọ̀rọ̀ yìí sì tàn ká láàrín àwọn arákùnrin pé, ọmọ-ẹ̀yìn náà kì yóò kú: ṣùgbọ́n Jesu kò wí fún un pé, òun kì yóò kú; ṣùgbọ́n, “Bí èmi bá fẹ́ kí ó dúró títí èmi ó fi dé, kín ni èyí jẹ́ sí ọ?”

24 (F)Èyí ni ọmọ-ẹ̀yìn náà, tí ó jẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí, tí ó sì kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí, àwa sì mọ̀ pé, òtítọ́ ni ẹ̀rí rẹ̀.

25 (G)Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun mìíràn pẹ̀lú ni Jesu ṣe, èyí tí bí a bá kọ̀wé wọn ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, mo rò pé gbogbo ayé pàápàá kò lè gba ìwé náà tí a bá kọ ọ́.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.