Book of Common Prayer
Saamu ti Dafidi. Nígbà tí ó wà nínú aginjù Juda.
63 Ọlọ́run, ìwọ ni Ọlọ́run mi,
nígbà gbogbo ni mo ń ṣàfẹ́rí rẹ,
òǹgbẹ rẹ ń gbẹ ọkàn mi,
ara mi fà sí ọ,
ní ilẹ̀ gbígbẹ àti ilẹ̀ tí ń ṣàárẹ̀
níbi tí kò sí omi.
2 Èmi ti rí ọ ní ibi mímọ́,
mo rí agbára àti ògo rẹ.
3 Nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ayé lọ,
ètè mi yóò fògo fún ọ.
4 Èmi ó yìn ọ́ níwọ̀n ìgbà tí mo wà láààyè,
èmi ó gbé ọwọ́ sókè, èmi ó sì pe orúkọ rẹ.
5 A ó tẹ́ ọkàn mi lọ́rùn bí ọlọ́ràá oúnjẹ;
pẹ̀lú ètè ìyìn, ẹnu mi yóò yìn ọ́.
6 Nígbà tí mo rántí rẹ lórí ibùsùn mi;
èmi ń ronú rẹ títí ìṣọ́ òru.
7 Nítorí ìwọ ni ìrànlọ́wọ́ mi,
mo kọrin níbi òjìji ìyẹ́ apá rẹ.
8 Ọkàn mí fà sí ọ:
ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbé mi ró.
9 Àwọn tí ó ń wá ọkàn mí ni a ó parun;
wọn ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé.
10 Wọn ó ti ọwọ́ idà ṣubú
wọn ó sì di jíjẹ fún kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀.
11 Ṣùgbọ́n ọba yóò yọ̀ nínú Ọlọ́run
ẹni tí ó fi orúkọ Ọlọ́run búra yóò ṣògo
ṣùgbọ́n ẹnu àwọn òpùrọ́ la ó pamọ́.
98 Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa,
nítorí tí ó ṣe ohun ìyanu;
ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti apá mímọ́ rẹ̀
o ṣe iṣẹ́ ìgbàlà fún un
2 Olúwa ti sọ ìgbàlà rẹ̀ di mí mọ̀
o fi òdodo rẹ̀ han àwọn orílẹ̀-èdè.
3 Ó rántí ìfẹ́ rẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ fún àwọn ará ilé Israẹli;
gbogbo òpin ayé ni ó ti rí
iṣẹ́ ìgbàlà Ọlọ́run wa.
4 Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Olúwa, gbogbo ayé,
ẹ bú sáyọ̀, ẹ kọrin ìyìn
5 Ẹ fi dùùrù kọrin sí Olúwa, pẹ̀lú dùùrù àti ìró ohùn orin mímọ́,
6 Pẹ̀lú ìpè àti fèrè
ẹ hó fún ayọ̀ níwájú Olúwa ọba.
7 Jẹ́ kí Òkun kí ó hó pẹ̀lú gbogbo
ohun tí ó wà nínú rẹ̀,
Gbogbo ayé àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.
8 Ẹ jẹ́ kí odo kí ó ṣápẹ́,
ẹ jẹ́ kí òkè kí ó kọrin pẹ̀lú ayọ̀;
9 Ẹ jẹ́ kí wọn kọrin níwájú Olúwa
Nítorí tí yóò wá ṣèdájọ́ ayé
bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè nínú òdodo
àti àwọn ènìyàn ní àìṣègbè pẹ̀lú.
Ti Dafidi.
103 Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi; àti gbogbo ohun tí ó wà nínú mi, yín orúkọ rẹ̀ mímọ́.
2 Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi, kí o má ṣe gbàgbé gbogbo oore rẹ̀
3 Ẹni tí ó dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì ọ́
tí ó sì wo gbogbo ààrùn rẹ̀ sàn,
4 Ẹni tí ó ra ẹ̀mí rẹ padà kúrò nínú kòtò ikú
ẹni tí ó fi ìṣeun ìfẹ́ àti ìyọ́nú dé ọ ní adé,
5 Ẹni tí ó fi ohun dídára tẹ́ ọ lọ́rùn
kí ìgbà èwe rẹ̀ lè di ọ̀tún bí ti ẹyẹ idì.
6 Olúwa ń ṣe òdodo àti ìdájọ́ fún
gbogbo àwọn tí a ni lára.
7 Ó fi ọ̀nà rẹ̀ hàn fún Mose, iṣẹ́ rẹ̀ fun àwọn ọmọ Israẹli;
8 (A)Olúwa ni aláàánú àti olóore,
ó lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́.
9 Òun kì í bá ni wí ní ìgbà gbogbo
bẹ́ẹ̀ ni kì í pa ìbínú rẹ mọ́ láéláé;
10 Òun kì í ṣe sí wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ wa
bẹ́ẹ̀ ni kì í san án fún wa gẹ́gẹ́
bí àìṣedéédéé wa.
11 Nítorí bí ọ̀run ṣe ga sílẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ rẹ̀ tóbi sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.
12 Bí ìlà-oòrùn ti jìnnà sí ìwọ̀-oòrùn
bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú ìrékọjá wá jìnnà sí wa.
13 Bí baba ti ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ rẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀;
14 Nítorí tí ó mọ dídá wa,
ó rántí pé erùpẹ̀ ni wá.
15 Bí ó ṣe ti ènìyàn ni, ọjọ́ rẹ̀ dàbí koríko,
ó gbilẹ̀ bí ìtànná ewéko igbó;
16 Afẹ́fẹ́ fẹ́ kọjá lọ lórí rẹ̀,
kò sì rántí ibùjókòó rẹ̀ mọ́.
17 (B)Ṣùgbọ́n láti ayérayé ni ìfẹ́
Olúwa ti wà pẹ̀lú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
àti òdodo rẹ̀ wà láti ọmọdọ́mọ
18 Sí àwọn tí ó pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́
àti àwọn tí ó rántí òfin rẹ̀ láti ṣe wọ́n.
19 Olúwa ti pèsè ìtẹ́ rẹ̀ nínú ọ̀run,
ìjọba rẹ̀ ní ó sì borí ohun gbogbo.
20 Yin Olúwa, ẹ̀yin angẹli rẹ̀,
tí ó ní ipá, tí ó pa òfin ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́
21 Yin Olúwa, ẹ̀yin ogun ọ̀run rẹ̀ gbogbo,
ẹ̀yin ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀.
22 Yin Olúwa, gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ ní
ibi gbogbo ìjọba rẹ̀.
Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi.
Sí àwọn alàgbà àti àwọn ọ̀dọ́kùnrin
5 Àwọn alàgbà tí ń bẹ láàrín yín ni mo gbànímọ̀ràn, èmi ẹni tí ń ṣe alàgbà bí ẹ̀yin, àti ẹlẹ́rìí ìyà Kristi, àti alábápín nínú ògo tí a ó fihàn: 2 Ẹ máa tọ́jú agbo Ọlọ́run tí ń bẹ láàrín yín, ẹ máa bojútó o, kì í ṣe àfipáṣe, bí kò ṣe tìfẹ́tìfẹ́; kó má sì jẹ́ fún èrè ìjẹkújẹ, bí kò ṣe pẹ̀lú ìpinnu tí ó múra tan. 3 Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe bí ẹni tí ń lo agbára lórí ìjọ, ṣùgbọ́n kí ẹ ṣe ara yín ní àpẹẹrẹ fún agbo. 4 Nígbà tí olórí Olùṣọ́-àgùntàn bá sì fi ara hàn, ẹ̀yin ó gba adé ògo ti kì í sá.
5 (A)Bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú, ẹ̀yin ọ̀dọ́, ẹ tẹríba fún àwọn alàgbà. Àní, gbogbo yín ẹ máa tẹríba fún ara yín kí ẹ fi ìrẹ̀lẹ̀ wọ ara yín ní aṣọ: nítorí,
“Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn agbéraga,
ṣùgbọ́n ó ń fi oore-ọ̀fẹ́ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.”
6 Nítorí náà, ẹ rẹ ara yin sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára Ọlọ́run, kí òun lè gbe yín ga lákokò. 7 (B)Ẹ máa kó gbogbo àníyàn yín lé e; nítorí tí òun ń ṣe ìtọ́jú yín.
8 Ẹ máa wà ni àìrékọjá, ẹ máa ṣọ́ra; nítorí èṣù ọ̀tá yín, bí i kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń rìn káàkiri, ó ń wa ẹni tí yóò pajẹ. 9 Ẹ kọ ojú ìjà sí i pẹ̀lú ìdúró ṣinṣin nínú ìgbàgbọ́, bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé ìyà kan náà ni àwọn ará yín tí ń bẹ nínú ayé ń jẹ.
10 Ọlọ́run oore-ọ̀fẹ́ gbogbo, tí ó ti pè yín sínú ògo rẹ̀ tí kò nípẹ̀kun nínú Kristi Jesu, nígbà tí ẹ̀yin bá ti jìyà díẹ̀, òun tìkára rẹ̀, yóò sì ṣe yín ní àṣepé, yóò fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀, yóò fún yín lágbára, yóò fi ìdí yín kalẹ̀. 11 Tìrẹ ni ògo àti agbára títí láé. Àmín.
Igi àti èso rẹ̀
15 (A)“Ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn èké wòlíì tí wọ́n ń tọ̀ yín wá ní àwọ̀ àgùntàn, ṣùgbọ́n ní inú wọn apanijẹ ìkookò ni wọ́n. 16 Nípa èso wọn ni ẹ̀yin ó fi mọ̀ wọn. Ǹjẹ́ ènìyàn ha lè ká èso àjàrà lára igi ọ̀gàn tàbí èso ọ̀pọ̀tọ́ lára ẹ̀gún òṣùṣú? 17 Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo igi rere a máa so èso rere ṣùgbọ́n igi búburú a máa so èso búburú. 18 Igi rere kò le so èso búburú, bẹ́ẹ̀ ni igi búburú kò lè so èso rere. 19 Gbogbo igi tí kò bá so èso rere, a gé e lulẹ̀, à wọ́ ọ jù sínú iná, 20 Nítorí náà, nípa èso wọn ni ẹ̀yin yóò mọ̀ wọn.
21 (B)“Kì í ṣe gbogbo ẹni tó ń pè mí ní, ‘Olúwa, Olúwa,’ ni yóò wọ ìjọba ọ̀run, bí kò ṣe ẹni tó bá ń ṣe ìfẹ́ baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run. 22 Ọ̀pọ̀ ni yóò wí fún mi ní ọjọ́ náà pé, ‘Olúwa, Olúwa, àwa kò ha sọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ rẹ, àti ní orúkọ rẹ kọ́ ni a fi lé ọ̀pọ̀ ẹ̀mí èṣù jáde, tí a sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu?’ 23 Nígbà náà ni èmi yóò wí fún wọn pé, ‘Èmi kò mọ̀ yín rí, ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi ẹ̀yin oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.’
Ọlọ́gbọ́n àti òmùgọ̀ ọ̀mọ̀lé
24 (C)“Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ tèmi wọ̀nyí, tí ó bá sì ṣe wọn, èmi ó fiwé ọlọ́gbọ́n ènìyàn kan, ti ó kọ́ ilé rẹ̀ sí orí àpáta. 25 Òjò sì rọ̀, ìkún omi sì dé, afẹ́fẹ́ sì fẹ́, wọ́n sí bì lu ilé náà; síbẹ̀síbẹ̀ náà kò sì wó, nítorí tí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ lórí àpáta. 26 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbọ́ ọ̀rọ̀ tèmi wọ̀nyí, tí kò bá sì ṣe wọ́n, òun ni èmi yóò fiwé aṣiwèrè ènìyàn kan tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sí orí iyanrìn. 27 Òjò sì rọ̀, ìkún omi sì dé, afẹ́fẹ́ sì fẹ́, wọ́n sì bì lu ilé náà, ilé náà sì wó; wíwó rẹ̀ sì pọ̀ jọjọ.”
28 (D) Nígbà tí Jesu sì parí sísọ nǹkan wọ̀nyí, ẹnu ya àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn sí ẹ̀kọ́ rẹ̀, 29 Nítorí ó ń kọ́ wọn bí ẹni tí ó ní àṣẹ, kì í ṣe bí i ti olùkọ́ òfin wọn.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.