Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 1-4

ÌWÉ KÌN-ÍN-NÍ

Saamu 1–41

(A)Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà,
    tí kò rìn ní ìmọ̀ àwọn ènìyàn búburú,
ti kò dúró ní ọ̀nà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,
    tàbí tí kò sì jókòó ní ibùjókòó àwọn ẹlẹ́gàn.
Ṣùgbọ́n ayọ̀ inú rẹ̀ wà nínú òfin Olúwa
    àti nínú òfin rẹ̀ ni ó ń ṣe àṣàrò ní ọ̀sán àti òru.
Ó dàbí igi tí a gbìn sí etí odò tí ń sàn,
    tí ń so èso rẹ̀ jáde ní àkókò rẹ̀
tí ewé rẹ̀ kì yóò rẹ̀.
    Ohunkóhun tí ó dáwọ́lé, ni yóò máa yọrí sí rere.

Kò le rí bẹ́ẹ̀ fún àwọn ènìyàn búburú!
    Wọn yóò dàbí ìyàngbò ọkà
    tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ dànù.
Nítorí náà àwọn ènìyàn búburú kì yóò le è dìde dúró ní ìdájọ́,
    bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kì yóò le è dúró ní àwùjọ àwọn olódodo.

Nítorí Olúwa ń ṣọ́ ọ̀nà àwọn olódodo,
    ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ni yóò ṣègbé.
(B)Èéṣe tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń dìtẹ̀,
    àti tí àwọn ènìyàn ń ṣe rìkíṣí asán?
Àwọn ọba ayé péjọpọ̀
    àti àwọn ìjòyè gbìmọ̀ pọ̀
    Olúwa àti sí Ẹni ààmì òróró rẹ̀.
Wọ́n sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí a fa ẹ̀wọ̀n wọn já,
    kí a sì ju ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ wọn nù.”

Ẹni tí ó gúnwà lórí ìtẹ́ lọ́run rẹ́rìn-ín;
    Olúwa fi wọ́n rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà.
Nígbà náà ni yóò bá wọn wí ní ìbínú rẹ̀
    yóò sì dẹ́rùbà wọ́n ní ìrunú rẹ̀, ó wí pé,
“Èmi ti fi ọba mi sí ipò
    lórí Sioni, òkè mímọ́ mi.”

(C)Èmi yóò sì kéde ìpinnu Olúwa:

Ó sọ fún mi pé, “Ìwọ ni ọmọ mi;
    lónìí, èmi ti di baba rẹ.
(D)Béèrè lọ́wọ́ mi,
    Èmi yóò jẹ́ kí orílẹ̀-èdè di ìní rẹ,
    òpin ilé ayé yóò sì jẹ́ ogún rẹ.
Ìwọ yóò fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn
    ìwọ yóò sì rún wọn wómúwómú bí ìkòkò amọ̀.”

10 Nítorí náà, ẹ̀yin ọba, ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n;
    ẹ gbọ́ ìkìlọ̀ ẹ̀yin alákòóso ayé.
11 Ẹ sin Olúwa pẹ̀lú ìbẹ̀rù
    ẹ sì máa yọ̀ pẹ̀lú ìwárìrì.
12 Fi ẹnu ko ọmọ náà ní ẹnu, kí ó má ba à bínú,
    kí ó má ba à pa yín run ní ọ̀nà yín,
nítorí ìbínú rẹ̀ lè ru sókè ní ẹ̀ẹ̀kan.
    Ìbùkún ni fún gbogbo àwọn tí ó fi í ṣe ibi ìsádi wọn.

Saamu ti Dafidi. Nígbà ti ó sá fún ọmọ rẹ̀ Absalomu.

Olúwa, báwo ni àwọn ọ̀tá mi ṣe pọ̀ tó báyìí!
    Báwo ni àwọn ti ó dìde sí mi ṣe pọ̀ tó!
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó ń sọ ní ti tèmi, pé
    “Ọlọ́run kò nígbà á là.” Sela.

Ṣùgbọ́n ìwọ ni asà yí mi ká, Olúwa;
    ìwọ fi ògo fún mi, ìwọ sì gbé orí mi sókè.
Olúwa ni mo kígbe sókè sí,
    ó sì dá mi lóhùn láti orí òkè mímọ́ rẹ̀ wá. Sela.

Èmi dùbúlẹ̀, mo sì sùn;
    mo sì tún padà jí, nítorí Olúwa ni ó ń gbé mi ró.
Èmi kì yóò bẹ̀rù ẹgbẹgbẹ̀rún ènìyàn
    tí wọ́n rọ̀gbà yí mi ká.

Dìde, Olúwa!
    Gbà mí, Ọlọ́run mi!
Lu gbogbo àwọn ọ̀tá mi ní àgbọ̀n;
    kí o sì ká eyín àwọn ènìyàn búburú.

Láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni ìgbàlà ti wá.
    Kí ìbùkún rẹ wà lórí àwọn ènìyàn rẹ. Sela.

Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Saamu ti Dafidi.

Dá mi lóhùn nígbà tí mo bá pè ọ́,
    ìwọ Ọlọ́run òdodo mi,
Fún mi ní ìdáǹdè nínú ìpọ́njú mi;
    ṣàánú fún mi, kí o sì gbọ́ àdúrà mi.

Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó, ẹ̀yin ọmọ ènìyàn, tí ẹ ó ṣe sọ ògo mi di ìtìjú?
    Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó, tí ẹ̀yin yóò ṣe fẹ́ràn ìtànjẹ àti tí ẹ̀yin yóò fi máa wá ọlọ́run èké?
Ṣùgbọ́n kí ẹ mọ̀ pé, Olúwa ti ya ẹni olódodo sọ́tọ̀ fún ara rẹ̀;
    Olúwa yóò gbọ́ nígbà tí mo bá pè é.

(E)Ẹ bínú ẹ má ṣe ṣẹ̀;
    Nígbà tí ẹ bá wà lórí ibùsùn yín,
    ẹ bá ọkàn yín sọ̀rọ̀, kí ó sì dákẹ́ jẹ́.
Ẹ rú ẹbọ òdodo
    kí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló ń béèrè pé, “Ta ni yóò ṣe rere fún wa?”
    Olúwa, Jẹ́ kí ojú rẹ mọ́lẹ̀ sí wa lára,
Ìwọ ti fi ayọ̀ púpọ̀ kún ọkàn mi
    ju ìgbà tí hóró irúgbìn àti wáìnì tuntun wọ́n pọ̀ fún mi lọ.

Èmi yóò dùbúlẹ̀, èmi ó sì sùn ní àlàáfíà,
    nítorí ìwọ nìkan, Olúwa, ni o
    mú mi gbé láìléwu.

Saamu 7

Ṣiggaioni ti Dafidi, èyí tí ó kọ sí Olúwa nípa Kuṣi, ará Benjamini.

Olúwa Ọlọ́run mi, ààbò mi wà nínú rẹ;
    gba mí là kí o sì tú mi sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tó ń lé mi,
kí wọn ó má ba à fa ọkàn mi ya gẹ́gẹ́ bí kìnnìún,
    wọ́n á ya á pẹ́rẹpẹ̀rẹ láìsí ẹni tí yóò gbà mí.

Olúwa Ọlọ́run mi, tí èmi bá ṣe èyí
    tí ẹ̀bi sì wà ní ọwọ́ mi
Bí èmi bá ṣe ibi sí ẹni tí ń wá àlàáfíà pẹ̀lú mi,
    tí mo ja ọ̀tá mi lólè láìnídìí:
Nígbà náà, jẹ́ kí ọ̀tá mi lé mi kí wọn sì mú mi;
    jẹ́ kí òun kí ó tẹ ọkàn mi mọ́lẹ̀
    kí wọn sì mú mi sùn nínú eruku. Sela.

Dìde, Olúwa, nínú ìbínú rẹ;
    dìde lòdì sí ìrunú àwọn ọ̀tá mi.
    Jí, Ọlọ́run mi; kéde òdodo.
Kí ìpéjọ àwọn ènìyàn yíká.
    Jọba lórí wọn láti òkè wá;
    Jẹ́ kí Olúwa ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn.
Ṣe ìdájọ́ mi, Olúwa, gẹ́gẹ́ bí òdodo mi,
    gẹ́gẹ́ bí ìwà òtítọ́, ẹni gíga jùlọ.
(A)Ọlọ́run Olódodo,
    Ẹni tí ó ń wo inú àti ọkàn,
tí ó ń mú òpin sí ìwà ipá ẹni búburú
    tí ó sì ń pa àwọn olódodo mọ́.

10 Ààbò mi ń bẹ lọ́dọ̀ Ọlọ́run,
    ẹni tí ń ṣe ìgbàlà òtítọ́ ní àyà.
11 Ọlọ́run ni onídàájọ́ òtítọ́,
    Ọlọ́run tí ń sọ ìrunú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́.
12 Bí kò bá yípadà,
    Òun yóò pọ́n idà rẹ̀ mú;
    ó ti fa ọrun rẹ̀ le ná, ó ti múra rẹ̀ sílẹ̀.
13 Ó ti pèsè ohun ìjà ikú sílẹ̀;
    ó ti pèsè ọfà iná sílẹ̀.

14 Ẹni tí ó lóyún ohun búburú,
    tí ó sì lóyún wàhálà, ó bí èké jáde.
15 Ẹni tí ó gbẹ́ ọ̀fìn, tí ó kó o jáde
    jì sí kòtò tí ó gbẹ́ sílẹ̀.
16 Wàhálà tí ó fà padà sórí rẹ̀;
    Ìwà ipá rẹ̀ padà sórí ara rẹ̀.

17 Èmi ó fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí òdodo rẹ̀,
    Èmi ó kọrin ìyìn sí Olúwa Ọ̀gá-ògo jùlọ.

Isaiah 40:12-23

12 Ta ni ó tiwọn omi nínú kòtò ọwọ́ rẹ̀,
    tàbí pẹ̀lú ìbú ọwọ́ rẹ̀
tí ó wọn àwọn ọ̀run?
    Ta ni ó ti kó erùpẹ̀ ilẹ̀ ayé jọ nínú apẹ̀rẹ̀,
tàbí kí ó wọn àwọn òkè ńlá lórí ìwọ̀n
    àti òkè kéékèèkéé nínú òṣùwọ̀n?
13 (A)Ta ni ó ti mọ ọkàn Olúwa,
    tàbí tí ó ti tọ́ ọ ṣọ́nà gẹ́gẹ́ bí olùdámọ̀ràn rẹ̀?
14 Ta ni Olúwa ké sí kí ó là á lọ́yẹ
    àti ta ni ó kọ́ òun ní ọ̀nà tí ó tọ́?
Ta ni ẹni náà tí ó kọ́ ọ ní ọgbọ́n
    tàbí tí ó fi ipa ọ̀nà òye hàn án?

15 Nítòótọ́ àwọn orílẹ̀-èdè dàbí i ẹ̀kún omi
    nínú garawa;
a kà wọ́n sí gẹ́gẹ́ bí eruku lórí ìwọ̀n;
    ó wọn àwọn erékùṣù àfi bí eruku múnúmúnú ni wọ́n.
16 Lebanoni kò tó fún pẹpẹ iná,
    tàbí kí àwọn ẹranko rẹ̀ kí ó tó fún ẹbọ sísun.
17 Níwájú rẹ̀ ni gbogbo orílẹ̀-èdè dàbí ohun tí kò sí;
    gbogbo wọn ló kà sí ohun tí kò wúlò
    tí kò tó ohun tí kò sí.

18 Ta ni nígbà náà tí ìwọ yóò fi Ọlọ́run wé?
    Ère wo ni ìwọ yóò fi ṣe àkàwé rẹ̀?
19 Ní ti ère, oníṣọ̀nà ni ó dà á,
    ti alágbẹ̀dẹ wúrà sì fi wúrà bò ó
    tí a sì ṣe ẹ̀wọ̀n ọ̀nà sílífà fún un.
20 Ọkùnrin kan tí ó tálákà jù kí ó lè mú
    irú ọrẹ bẹ́ẹ̀ wá,
wá igi tí kò le è rà.
    Ó wá oníṣọ̀nà tí ó
    láti ṣe àgbékalẹ̀ ère tí kì yóò le è ṣubú.

21 Ǹjẹ́ o kò tí ì mọ̀
    ìwọ kò tí ì gbọ́?
A kò tí ì sọ fún ọ láti ìbẹ̀rẹ̀ wá?
    Ìwọ kò tí ì mọ láti ìgbà ìpìlẹ̀ ayé?
22 Òun jókòó lórí ìtẹ́ ní òkè òbírí ilẹ̀ ayé,
    àwọn ènìyàn rẹ̀ sì dàbí i láńtata.
Ó ta àwọn ọ̀run bí ìbòrí ìgúnwà,
    ó sì nà wọ́n jáde gẹ́gẹ́ bí àgọ́ láti gbé.
23 Ó sọ àwọn ọmọ ọba di asán
    àti àwọn aláṣẹ ayé yìí ni ó ti sọ dòfo.

Efesu 1:1-14

Paulu, aposteli Jesu Kristi nípa ìfẹ́ Ọlọ́run,

Sí àwọn ènìyàn mímọ́ tí ó wà ní Efesu, àti sí àwọn olóòtítọ́ nínú Kristi Jesu:

Oore-ọ̀fẹ́ sí yín àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wá àti Jesu Kristi Olúwa.

Ìbùkún ti Ẹ̀mí Mímọ́ nínú Kristi

(A)Ògo ni fún Ọlọ́run àti Baba Jesu Kristi Olúwa wa, ẹni tí ó ti bùkún wa láti inú ọ̀run wá pẹ̀lú àwọn ìbùkún ẹ̀mí gbogbo nínú Kristi. Àní, gẹ́gẹ́ bí o ti yàn wá nínú rẹ̀ ṣáájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, láti jẹ́ mímọ́ àti aláìlábùkù níwájú rẹ̀ nínú ìfẹ́ Ẹni tí Ó ti yàn wá tẹ́lẹ̀ sí ìsọdọmọ nípa Jesu Kristi fún ara rẹ̀, ní ìbámu ìdùnnú ìfẹ́ rẹ̀ (B)fún ìyìn ògo oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, èyí tí Ó ti fi fún wa nínú Àyànfẹ́ rẹ̀: (C)Nínú rẹ̀ ni àwa rí ìràpadà gba nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ àti ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, ní ìbámu pẹ̀lú ọrọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run èyí tí ó fún wa lọ́pọ̀lọpọ̀ pẹ̀lú gbogbo ọgbọ́n àti ìmòye, Ó ti sọ ohun ìjìnlẹ̀ ìfẹ́ rẹ̀ di mí mọ̀ fún wa gẹ́gẹ́ bí ìdùnnú rere rẹ̀, èyí ti o pinnu nínú Kristi, 10 (D)èyí tí yóò jẹ jáde ní kíkún àkókò, láti ṣe àkójọpọ̀ àwọn ohun tí ọ̀run àti ti ayé lábẹ́ Kristi.

11 Nínú rẹ̀ ni a yàn wá fẹ́ lẹ́yìn tí ó ti yàn wá tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu ẹni tí ń ṣiṣẹ́ ohun gbogbo ní ìbámu ìfẹ́ rẹ̀, 12 kí àwa kí ó le wà fún ìyìn ògo rẹ̀, àwa tí a ti ni ìrètí ṣáájú nínú Kristi. 13 Àti ẹ̀yin pẹ̀lú darapọ̀ nínú Kristi nígbà tí ẹ̀yin gbọ́ ọ̀rọ̀ òtítọ́ náà àní ìhìnrere ìgbàlà yin. Nígbà tí ẹ̀yin gbàgbọ́, a fi Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe èdìdì ayé yin nínú rẹ, èyí tí a ti ṣe ìlérí rẹ̀ tẹ́lẹ̀, 14 (E)èyí tí ó jẹ́ ìdánilójú àṣansílẹ̀ ogún wa títí yóò fi di àkókò ìràpadà àwọn tí í ṣe ti Ọlọ́run sí ìyìn ògo rẹ̀.

Marku 1:1-13

Johanu onítẹ̀bọmi tún ọ̀nà ṣe sílẹ̀

Ìbẹ̀rẹ̀ ìhìnrere nípa Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọ́run.

(A)(B) Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé wòlíì Isaiah pé:

“Èmi yóò ran oníṣẹ́ mi síwájú rẹ,
    Ẹni tí yóò tún ọ̀nà rẹ ṣe.”
(C)“Ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù,
    ‘Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe,
    ẹ ṣe ojú ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́.’ ”

(D)Johanu dé, ẹni tí ó ń tẹnibọmi ní aginjù, tí ó sì ń wàásù ìtẹ̀bọmi ìrònúpìwàdà fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀. Gbogbo àwọn tí ń gbé ní agbègbè Judea, àti gbogbo ènìyàn Jerusalẹmu jáde tọ̀ ọ́ lọ, a sì ti ọwọ́ rẹ̀ tẹ gbogbo wọn bọ omi ni odò Jordani, wọ́n ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Johanu sì wọ aṣọ irun ìbákasẹ. Ó sì di àmùrè awọ mọ́ ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Eṣú àti oyin ìgàn sì ni oúnjẹ rẹ̀. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù wí pé, “Ẹnìkan tí ó tóbi jù mí lọ ń bọ̀ lẹ́yìn mi, okùn bàtà ẹsẹ̀ ẹni tí èmi kò tó ẹni tí ń tú. Èmi ń fi omi ṣe ìtẹ̀bọmi yín, ṣùgbọ́n Òun yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe ìtẹ̀bọmi yín.”

Ìtẹ̀bọmi àti ìdánwò Jesu

(E)Ó sì ṣe ní ọjọ́ kan Jesu ti Nasareti ti Galili jáde wá, a sì ti ọwọ́ Johanu ṣe ìtẹ̀bọmi fún ní odò Jordani. 10 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tí Jesu ń ti inú omi jáde wá, ó rí ọ̀run tí ó ṣí sílẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ bí àdàbà sọ̀kalẹ̀ lé e lórí. 11 (F)Ohùn kan sì ti ọ̀run wá wí pé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ Ọmọ mi, ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.”

12 (G)Lẹ́sẹ̀kan náà, Ẹ̀mí Mímọ́ sì darí Jesu sí ijù, 13 Ó sì wà ní ogójì ọjọ́ ní aginjù. A sì ti ọwọ́ Satani dán an wò, ó sì wà pẹ̀lú àwọn ẹranko ìgbẹ́. Àwọn angẹli sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún un.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.