Book of Common Prayer
137 Ní ẹ̀bá odò Babeli, níbẹ̀ ni àwa gbé jókòó
àwa sì sọkún nígbà tí àwa rántí Sioni.
2 Àwa fi dùùrù wa kọ́ sí orí igi wílò,
tí ó wà láàrín rẹ̀.
3 Nítorí pé níbẹ̀ ni àwọn
tí ó kó wa ní ìgbèkùn béèrè orin lọ́wọ́ wa,
àti àwọn tí ó ni wá lára béèrè ìdárayá wí pé;
ẹ kọ orin Sioni kan fún wa.
4 Àwa ó ti ṣe kọ orin
Olúwa ní ilẹ̀ àjèjì
5 Jerusalẹmu, bí èmi bá gbàgbé rẹ
jẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó gbàgbé ìlò rẹ̀.
6 Bí èmi kò bá rántí rẹ,
jẹ́ kí ahọ́n mi kí ó lẹ̀ mọ́ èrìgì mi;
bí èmi kò bá fi Jerusalẹmu ṣáájú
olórí ayọ̀ mi gbogbo.
7 Olúwa rántí ọjọ́ Jerusalẹmu,
lára àwọn ọmọ Edomu,
àwọn ẹni tí ń wí pé,
“Wó o palẹ̀, wó o palẹ̀ dé ìpìlẹ̀ rẹ̀!”
8 Ìwọ, ọmọbìnrin Babeli, ẹni tí a ó parun;
ìbùkún ni fún ẹni tí ó san án fún ọ
bí ìwọ ti rò sí wa.
9 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó mú ọmọ wẹ́wẹ́ rẹ
tí ó sì fi wọ́n ṣán òkúta.
Ti Dafidi.
144 Ìyìn sí Olúwa àpáta mi,
ẹni tí ó kọ́ ọwọ́ mi fún ogun,
àti ìka mi fún ìjà.
2 Òun ni Ọlọ́run ìfẹ́ mi àti odi alágbára mi,
ibi gíga mi àti olùgbàlà mi, asà mi,
ẹni tí èmi gbẹ́kẹ̀lé,
ẹni tí ó tẹrí àwọn ènìyàn ba lábẹ́ mi.
3 Olúwa, kí ni ènìyàn tí ìwọ fi ń ṣàníyàn fún un,
tàbí ọmọ ènìyàn tí ìwọ fi ń ronú nípa rẹ̀?
4 Ènìyàn rí bí èmi;
ọjọ́ rẹ̀ rí bí òjìji tí ń kọjá lọ.
5 Tẹ ọ̀run rẹ ba, Olúwa, kí o sì sọ̀kalẹ̀;
tọ́ àwọn òkè ńlá wọn yóò sí rú èéfín.
6 Rán mọ̀nàmọ́ná kí ó sì fọ́n àwọn ọ̀tá ká;
ta ọfà rẹ kí ó sì dà wọ́n rú.
7 Na ọwọ́ rẹ sílẹ̀ láti ibi gíga;
gbà mí kí o sì yọ mí nínú ewu
kúrò nínú omi ńlá:
kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ àjèjì.
8 Ẹnu ẹni tí ó kún fún èké
ẹni tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ jẹ́ ìrẹ́jẹ.
9 Èmi yóò kọ orin tuntun sí ọ
Ọlọ́run; lára ohun èlò orin
olókùn mẹ́wàá èmi yóò
kọ orin sí ọ
10 Òun ni ó fi ìgbàlà fún àwọn ọba,
ẹni tí ó gba Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ idà ìpanilára.
Lọ́wọ́ pípanirun. 11 Gbà mí kí o sì yọ mí nínú ewu
kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ àjèjì
tí ẹnu wọn kún fún èké,
tí ọwọ́ ọ̀tún wọn jẹ́ ọwọ́ ọ̀tún èké.
12 Kí àwọn ọmọkùnrin wa
kí ó dàbí igi gbígbìn tí ó dàgbà ni ìgbà èwe wọn,
àti ọmọbìnrin wa yóò dàbí òpó ilé
tí a ṣe ọ̀nà sí bí àfarawé ààfin.
13 Àká wa yóò kún
pẹ̀lú gbogbo onírúurú oúnjẹ
àgùntàn wa yóò pọ̀ si ní ẹgbẹ̀rún,
ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní oko wa:
14 Àwọn màlúù wa yóò ru ẹrù wúwo
kí ó má sí ìkọlù,
kí ó má sí ìkólọ sí ìgbèkùn,
kí ó má sí i igbe ìpọ́njú ní ìgboro wa.
15 Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn náà tí ó wà ní irú ipò bẹ́ẹ̀,
Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn náà,
tí ẹni tí Ọlọ́run Olúwa ń ṣe.
104 Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi.
Olúwa Ọlọ́run mi, ìwọ tóbi jọjọ;
ọlá àti ọláńlá ni ìwọ wọ̀ ní aṣọ.
2 Ìwọ fi ìmọ́lẹ̀ bo ara rẹ gẹ́gẹ́ bí aṣọ;
ó tẹ ọ̀run bí títẹ́ ẹní
3 Ìwọ tí ó fi omi ṣe ìtì igi àjà ìyẹ̀wù rẹ.
Ìwọ tí o ṣe àwọsánmọ̀ ní kẹ̀kẹ́ ogun rẹ
ìwọ tí ó ń rìn lórí apá ìyẹ́ afẹ́fẹ́.
4 (A)Ó fi ẹ̀fúùfù ṣe àwọn ìránṣẹ́ rẹ,
Ọ̀wọ́-iná ni àwọn olùránṣẹ́ rẹ.
5 O fi ayé gúnlẹ̀ lórí àwọn ìpìlẹ̀;
tí a kò le è mì láéláé.
6 Ìwọ fi ibú omi bò ó mọ́lẹ̀ bí aṣọ;
àwọn omi sì dúró lórí àwọn òkè ńlá.
7 Ṣùgbọ́n nípa ìbáwí rẹ ni àwọn omi lọ,
nípa ohùn àrá rẹ ni wọ́n sálọ;
8 Wọ́n sàn kọjá lórí àwọn òkè,
wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀,
sí ibi tí ìwọ ti yàn fún wọn.
9 Ìwọ gbé òpin tí wọn kò lè kọjá rẹ̀ kálẹ̀;
láéláé ni wọ́n kò ní lè bo ayé mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i.
10 Ìwọ mú kí ìsun da omi sí àwọn Àfonífojì;
tí ó ń sàn láàrín àwọn òkè.
11 Wọ́n fún gbogbo àwọn ẹranko igbó ní omi
àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ń pa òǹgbẹ wọn.
12 Àwọn ẹyẹ ojú òfúrufú tẹ́ ìtẹ́ wọn lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi
wọ́n ń kọrin láàrín àwọn ẹ̀ka.
13 Ó bu omi rin àwọn òkè láti ìyẹ̀wù rẹ̀ wá;
a tẹ́ ayé lọ́rùn nípa èso iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
14 Ó mú kí koríko hù jáde fún àwọn ẹranko láti jẹ
àti àwọn ewébẹ̀ fún ènìyàn láti lò
kí ó lè mú oúnjẹ jáde láti ilẹ̀ wá:
15 Ọtí wáìnì tí ó ń mú ọkàn ènìyàn yọ̀,
òróró láti mú ojú rẹ̀ tan,
àti àkàrà láti ra ọkàn rẹ̀ padà.
16 Àwọn igi Olúwa ni a bu omi rin dáradára,
kedari ti Lebanoni tí ó gbìn.
17 Níbẹ̀ ní àwọn ẹyẹ ṣe ìtẹ́ wọn
bí ó ṣe tí àkọ̀ ni, orí igi gíga ni ilé rẹ̀.
18 Àwọn òkè gíga ni ààbò fún àwọn ewúrẹ́ igbó;
àti àwọn àlàpà jẹ́ ààbò fún àwọn ehoro.
19 Òṣùpá jẹ́ ààmì fún àkókò
oòrùn sì mọ ìgbà tí yóò wọ̀.
20 Ìwọ mú òkùnkùn wá, ó sì di òru,
nínú èyí tí gbogbo ẹranko igbó ń rìn kiri.
21 Kìnnìún ń bú ramúramù fún ohun ọdẹ wọn
wọ́n sì ń wá oúnjẹ wọn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.
22 Oòrùn ràn, wọ́n sì kó ara wọn jọ,
wọn padà lọ dùbúlẹ̀ sí ihò wọn.
23 Ọkùnrin jáde lọ sí iṣẹ́ wọn,
àti sí làálàá rẹ̀ títí di àṣálẹ́.
24 Iṣẹ́ rẹ ti pọ̀ tó, Olúwa!
Nínú ọgbọ́n ni ìwọ ṣe gbogbo wọn:
ayé kún fún àwọn ìṣẹ̀dá á rẹ.
25 Bẹ́ẹ̀ ni Òkun yìí tí ó tóbi, tí ó sì ni ìbú,
tí ó kún fún àwọn ẹ̀dá alààyè ní ìsàlẹ̀ láìníye
ohun alààyè tí tóbi àti kékeré.
26 Níbẹ̀ ni ọkọ̀ ń lọ síwá sẹ́yìn,
àti Lefitani, tí ìwọ dá láti ṣe àríyá nínú rẹ̀.
27 Àwọn wọ̀nyí ń wò ọ́
láti fún wọn ní oúnjẹ wọn lákòókò rẹ̀.
28 Nígbà tí ìwọ bá fi fún wọn,
wọn yóò kó jọ;
nígbà tí ìwọ bá la ọwọ́ rẹ̀,
a tẹ́ wọn lọ́rùn pẹ̀lú ohun rere.
29 Nígbà tí ìwọ bá pa ojú rẹ mọ́
ara kò rọ̀ wọ́n
nígbà tí ìwọ bá mú ẹ̀mí wọn lọ,
wọn ó kú, wọn ó sì padà sí erùpẹ̀.
30 Nígbà tí ìwọ rán ẹ̀mí rẹ,
ni a dá wọn,
ìwọ sì tún ojú ayé ṣe.
31 Jẹ́ kí ògo Olúwa wà pẹ́ títí láé;
kí inú Olúwa kí ó dùn ní ti iṣẹ́ rẹ̀
32 Ẹni tí ó wo ayé, tí ó sì wárìrì,
ẹni tí ó fọwọ́ tọ́ àwọn òkè, tí wọ́n yọ èéfín.
33 Ní gbogbo ayé mi ní n ó kọrin sí Olúwa:
èmi ó kọrin ìyìn sí Olúwa
níwọ̀n ìgbà tí mo wà láààyè.
34 Jẹ́ kí ẹ̀kọ́ mi kí ó tẹ́ ọ lọ́rùn
bí mo ti ń yọ̀ nínú Olúwa.
35 Ṣùgbọ́n kí ẹlẹ́ṣẹ̀ kúrò láyé
kí ènìyàn búburú má sì sí mọ́.
Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi.
Yin Olúwa.
12 Èyí ni yóò sì jẹ́ ààrùn tí Olúwa yóò fi kọlu gbogbo àwọn ènìyàn ti ó tí ba Jerusalẹmu jà; ẹran-ara wọn yóò rù nígbà tí wọn dúró ni ẹsẹ̀ wọn, ojú wọn yóò sì rà ni ihò wọn, ahọ́n wọn yóò sì bàjẹ́ ni ẹnu wọn. 13 Yóò sì ṣe ni ọjọ́ náà, ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ńlá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá yóò wà láàrín wọn; wọn ó sì di ọwọ́ ara wọn mú, ọwọ́ èkínní yóò sì dìde sì ọwọ́ èkejì rẹ̀. 14 Juda pẹ̀lú yóò sì jà ni Jerusalẹmu: ọrọ̀ gbogbo àwọn kèfèrí tí ó wà káàkiri ni a ó sì kójọ, wúrà àti fàdákà, àti aṣọ, ní ọ̀pọ̀lọpọ̀. 15 Bẹ́ẹ̀ ni ààrùn ẹṣin, ìbáaka, ìbákasẹ, àti tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, yóò sì wà, àti gbogbo ẹranko tí ń bẹ nínú àgọ́.
16 Yóò sì ṣe, olúkúlùkù ẹni tí o kù nínú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó dìde sí Jerusalẹmu yóò máa gòkè lọ lọ́dọọdún láti sìn ọba, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, àti láti ṣe àjọyọ̀ àsè àgọ́ náà. 17 Yóò sì ṣe, ẹnikẹ́ni tí kì yóò gòkè wá nínú gbogbo ìdílé ayé sí Jerusalẹmu láti sín ọba, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, òjò kì yóò rọ̀ fún wọn. 18 (A)Bí ìdílé Ejibiti kò bá sì gòkè lọ, tí wọn kò sì wá, fi ara wọn hàn tí wọn kò ní òjò; ààrùn náà yóò wà, tí Olúwa yóò fi kọlù àwọn kèfèrí tí kò gòkè wá láti ṣe àjọyọ̀ àsè àgọ́ náà 19 Èyí ni yóò sì jẹ́ ìyà Ejibiti, àti ìyà gbogbo orílẹ̀-èdè tí kò gòkè wá láti pa àsè àgọ́ mọ́.
20 Ní ọjọ́ náà ni “mímọ́ sí Olúwa” yóò wà lára ṣaworo ẹṣin: àti àwọn ìkòkò ni ilé Olúwa yóò sì dàbí àwọn ọpọ́n tí ń bẹ níwájú pẹpẹ. 21 Nítòótọ́, gbogbo ìkòkò ni Jerusalẹmu àti ni Juda yóò jẹ́ mímọ́ sí Olúwa àwọn ọmọ-ogun: àti gbogbo àwọn tí ń rú ẹbọ yóò wá, wọn ó sì mú ìkòkò díẹ̀, wọn ó sì bọ ẹran wọn nínú rẹ̀, ni ọjọ́ náà ni àwọn Kenaani kò ní sí mọ́ ni ilé Olúwa àwọn ọmọ-ogun.
Kọ́ ìwà ìrẹ̀lẹ̀ Kristi
2 (A)Bí ìwọ bá ní ìmúlọ́kànle nítorí pé ìwọ wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi, bi ìtùnú kan bá wà nínú ìfẹ́ rẹ̀, bí ìdàpọ̀ Ẹ̀mí kan bá wà, bí ìyọ́nú àti ìṣeun bá wà, 2 síbẹ̀ ẹ mú ayọ̀ mi kún nínú ìṣọ̀kan yín, nípa ìfẹ́ kan náà, wíwà ní ẹ̀mí kan náà àti ète kan náà. 3 (B)Ẹ má ṣe ohunkóhun nínú ìlépa ara tàbí ògo asán, ṣùgbọ́n ní ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn kí olúkúlùkù ro àwọn ẹlòmíràn sí ẹni ti ó sàn ju òun lọ. 4 Kí olúkúlùkù yín má ṣe ro ohun ti ara rẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n ti ẹlòmíràn pẹ̀lú.
5 (C)Nínú ìbáṣepọ̀ yin pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, ẹ ni irú ìlépa ọkàn náà bí ti Kristi Jesu.
6 Ẹni tí, bí o tilẹ̀ jẹ́ ìrísí Ọlọ́run,
kò kà á sí ohun tí ìbá fi ìwọra gbámú láti bá Ọlọ́run dọ́gba.
7 Ṣùgbọ́n ó bọ́ ògo rẹ̀ sílẹ̀,
ó sì mú àwọ̀ ìránṣẹ́,
a sì ṣe é ni àwòrán ènìyàn.
8 Ó sì wà ní àwòrán ènìyàn,
ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀,
o sì tẹríba títí de ojú ikú,
àní ikú lórí àgbélébùú.
9 (D)Nítorí náà, Ọlọ́run
ti gbé e ga sí ipele tí ó ga jùlọ,
ó sì ti fi orúkọ kan ti ó borí gbogbo orúkọ fún un
10 Pé ni orúkọ Jesu ni kí gbogbo eékún máa wólẹ̀,
ní ọ̀run, àti ní orí ilẹ̀ ayé àti ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé,
11 Àti pé kí gbogbo ahọ́n jẹ́wọ́ pé, Jesu Kristi ni Olúwa,
fún ògo Ọlọ́run Baba.
41 (A)Nígbà tí ó sì súnmọ́ etílé, ó ṣíjú wo ìlú náà, ó sọkún sí i lórí, 42 Ó ń wí pé, “Ìbá ṣe pé ìwọ mọ̀, lónìí yìí, àní ìwọ, ohun tí í ṣe tí Àlàáfíà rẹ! Ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n pamọ́ kúrò lójú rẹ. 43 (B)Nítorí ọjọ́ ń bọ̀ fún ọ, tí àwọn ọ̀tá rẹ yóò mọ odi bèbè yí ọ ká, àní tí wọn yóò sì yí ọ ká, wọn ó sì ká ọ mọ́ níhà gbogbo. 44 (C)Wọn ó sì wó ọ palẹ̀ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú rẹ; wọn kì yóò sì fi òkúta kan sílẹ̀ lórí ara wọn; nítorí ìwọ kò mọ ọjọ́ ìbẹ̀wò rẹ.”
Jesu nínú tẹmpili
45 (D)Ó sì wọ inú tẹmpili lọ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn tí ń tà nínú rẹ̀ sóde; 46 Ó sì wí fún wọn pé, “A ti kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ilé mi yóò jẹ́ ilé àdúrà?’ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ihò àwọn ọlọsa.”
47 (E)Ó sì ń kọ́ni lójoojúmọ́ ní tẹmpili, Ṣùgbọ́n àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé, àti àwọn olórí àwọn ènìyàn ń wá ọ̀nà láti pa á. 48 Wọn kò sì rí nǹkan kan tí wọn ìbá ṣe; nítorí gbogbo ènìyàn ṣù mọ́ ọn láti gbọ́rọ̀ rẹ̀.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.