Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 120-127

Orin fún ìgòkè.

120 Èmi ké pe Olúwa nínú ìpọ́njú mi,
    ó sì dá mi lóhùn
Gbà mí, Olúwa, kúrò lọ́wọ́ ètè èké
    àti lọ́wọ́ ahọ́n ẹ̀tàn.

Kí ni kí a fi fún ọ?
    Àti kí ni kí a túnṣe fún ọ,
    ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn?
Òun yóò bá ọ wí pẹ̀lú ọfà mímú ológun,
    pẹ̀lú ẹ̀yín iná igi ìgbálẹ̀.

Ègbé ni fún mi tí èmi ṣe àtìpó ní Meṣeki,
    nítorí èmi gbé nínú àgọ́ Kedari!
Ó ti pẹ́ tí èmi ti ń gbé
    láàrín àwọn tí ó kórìíra àlàáfíà.
Ènìyàn àlàáfíà ni mí;
    ṣùgbọ́n nígbà tí mo bá sọ̀rọ̀, ogun ni dúró fun wọn.

Orin fún ìgòkè.

121 Èmi yóò gbé ojú mi sórí òkè wọ̀n-ọn-nì—
    níbo ni ìrànlọ́wọ́ mi yóò ti wá
Ìrànlọ́wọ́ mi tí ọwọ́ Olúwa
    Ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé.

Òun kì yóò jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ kí ó yẹ̀;
    ẹni tí ó pa ọ́ mọ́ kì í tòògbé.
Kíyèsi, ẹni tí ń pa Israẹli mọ́,
    kì í tòògbé bẹ́ẹ̀ ni kì í sùn.

Olúwa ni olùpamọ́ rẹ;
    Olúwa ní òjìji rẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ
Oòrùn kì yóò pa ọ́ ní ìgbà ọ̀sán
    tàbí òṣùpá ní ìgbà òru.

Olúwa yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú ibi gbogbo
    yóò pa ọkàn rẹ mọ́
Olúwa yóò pa àlọ àti ààbọ̀ rẹ mọ́
    láti ìgbà yìí lọ àti títí láéláé.

Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi.

122 Inú mi dùn nígbà tí wọ́n wí fún mi pé
    Ẹ jẹ́ kí á lọ sílé Olúwa.
Ẹsẹ̀ wa yóò dúró ní ẹnu ibodè rẹ,
    ìwọ Jerusalẹmu.

Jerusalẹmu, ìwọ tí a kọ́ bí ìlú
    tí o fi ara mọ́ra pọ̀ ṣọ̀kan
Níbi tí àwọn ẹ̀yà máa ń gòkè lọ,
    àwọn ẹ̀yà Olúwa,
ẹ̀rí fún Israẹli, láti
    máa dúpẹ́ fún orúkọ Olúwa.
Nítorí ibẹ̀ ni a gbé ìtẹ́ ìdájọ́ kalẹ̀,
    àwọn ìtẹ́ ilé Dafidi.

Gbàdúrà fún àlàáfíà Jerusalẹmu;
    àwọn tí ó fẹ́ ọ yóò ṣe rere.
Kí àlàáfíà kí ó wà nínú odi rẹ̀,
    àti ìre nínú ààfin rẹ̀.
Nítorí àwọn ọkùnrin àti àwọn ẹgbẹ́ mi
    èmi yóò wí nísinsin yìí pé,
    kí àlàáfíà kí ó wà nínú rẹ̀;
Nítorí ilé Olúwa Ọlọ́run wa,
    èmi yóò máa wá ìre rẹ̀.

Orin fún ìgòkè.

123 Ìwọ ní mo gbé ojú mí sókè sí,
    ìwọ tí ń gbé inú ọ̀run
Kíyèsi, bí ojú àwọn
    ìránṣẹ́kùnrin ti máa ń wo ọwọ́ àwọn baba wọn,
    àti bí ojú ìránṣẹ́bìnrin ti máa ń wo ọwọ́ ìyá rẹ̀
bẹ́ẹ̀ ni ojú wa ń wo Olúwa Ọlọ́run wa,
    títí yóò fi ṣàánú fún wa.

Olúwa, ṣàánú fún wa, ṣàánú fún wa;
    nítorí tí a kún fún ẹ̀gàn púpọ̀púpọ̀.
Ọkàn wa kún púpọ̀
    fún ẹ̀gàn àwọn onírera,
    àti fún ẹ̀gàn àwọn agbéraga.

Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi.

124 “Ìbá má ṣe pé Olúwa tí ó ti wà fún wa”
    ni kí Israẹli kí ó máa wí nísinsin yìí;
“Ìbá má ṣe pé Olúwa tó wà ní tiwa,”
    Nígbà tí àwọn ènìyàn dúró sí wa:
Nígbà náà ni wọn ò bá gbé wà mì láààyè
    nígbà tí ìbínú wọn ru sí wa
Nígbà náà ni omi
    wọ̀n-ọn-nì ìbá bò wá mọ́lẹ̀
Nígbà náà ni agbéraga
omi ìbá borí ọkàn wa.

Olùbùkún ni Olúwa, tí kò fi wá fún wọ́n
    bí ohun ọdẹ fún eyín wọn.
Ọkàn wa yọ bí ẹyẹ jáde kúrò nínú okùn apẹyẹ;
    okùn já àwa sì yọ.
Ìrànlọ́wọ́ wa ń bẹ ní orúkọ Olúwa,
    tí ó dá ọ̀run òun ayé.

Orin fún ìgòkè.

125 Àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa yóò dàbí òkè Sioni,
    tí a kò lè ṣí ní ìdí, bí kò ṣe pé ó dúró láéláé
Bí òkè ńlá ti yí Jerusalẹmu ká,
    bẹ́ẹ̀ ni Olúwa yí ènìyàn ká
    láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.

Nítorí tí ọ̀pá àwọn ènìyàn búburú
    kì yóò bà lé ìpín àwọn olódodo;
kí àwọn olódodo kí ó máa ba à
    fi ọwọ́ wọn lé ẹ̀ṣẹ̀.

Olúwa ṣe rere fún àwọn ẹni rere,
    àti fún àwọn tí àyà wọn dúró ṣinṣin.
Bí ó ṣe ti irú àwọn tí wọn yà sí ipa ọ̀nà wíwọ́ wọn;
    Olúwa yóò jẹ́ kí wọn lọ pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.

Ṣùgbọ́n àlàáfíà yóò wà lórí Israẹli.

Orin fún ìgòkè.

126 Nígbà tí Olúwa mú ìkólọ Sioni padà,
    àwa dàbí ẹni tí ó ń lá àlá.
Nígbà náà ni ẹnu wa kún fún ẹ̀rín,
    àti ahọ́n wa kọ orin;
nígbà náà ni wọ́n wí nínú àwọn kèfèrí pé,
    Olúwa ṣe ohun ńlá fún wọn.
Olúwa ṣe ohun ńlá fún wa;
    nítorí náà àwa ń yọ̀.

Olúwa mú ìkólọ wa padà,
    bí ìṣàn omi ní gúúsù.
Àwọn tí ń fi omijé fún irúgbìn
    yóò fi ayọ̀ ka.
Ẹni tí ń fi ẹkún rìn lọ,
    tí ó sì gbé irúgbìn lọ́wọ́,
lóòtítọ́, yóò fi ayọ̀ padà wá,
    yóò sì ru ìtí rẹ̀.

Orin fún ìgòkè. Ti Solomoni.

127 Bí kò ṣe pé Olúwa bá kọ́ ilé náà
    àwọn tí ń kọ́ ọ ń ṣiṣẹ́ lásán ni;
    bí kò ṣe pé Olúwa bá pa ìlú mọ́, olùṣọ́ jí lásán.
Asán ni fún ẹ̀yin ti ẹ dìde ní kùtùkùtù
    láti pẹ́ dùbúlẹ̀, láti jẹ oúnjẹ làálàá;
    bẹ́ẹ̀ ni ó ń fi ìre fún olùfẹ́ rẹ̀ lójú ọ̀run.

Kíyèsi i, àwọn ọmọ ni ìní Olúwa:
    ọmọ inú sì ni èrè rẹ̀.
Bí ọfà ti rí ní ọwọ́ alágbára,
    bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ èwe
Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí apó rẹ̀ kún fún wọn;
    ojú kì yóò tì wọ́n,
    ṣùgbọ́n wọn yóò ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá ní ẹnu-ọ̀nà.

Esekiẹli 33:21-33

A ṣàlàyé ìṣubú Jerusalẹmu

21 Ní ọjọ́ karùn-ún oṣù kẹwàá, ọdún kejìlá ìkólọ wa, ọkùnrin kan tí ó sá kúrò ni Jerusalẹmu wá sọ́dọ̀ mi, ó sì wí pé, “Ìlú ńlá náà ti ṣubú!” 22 Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ tí ó ku ọ̀la tí ẹni tí ó sálọ náà yóò dé, ọwọ́ Olúwa sì níbẹ̀ lára mi, o sì ya ẹnu mi ki ọkùnrin náà tó wá sọ́dọ̀ mi ní òwúrọ̀. Ẹnu mí sì ṣí, èmi kò sì yadi mọ́.

23 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá: 24 “Ọmọ ènìyàn, àwọn ènìyàn tí ó ń gbé nínú ìparun ní ilẹ̀ Israẹli ń wí pé, ‘Abrahamu jẹ́ ọkùnrin kan, síbẹ̀ o gba ilẹ̀ ìní náà. Ṣùgbọ́n àwa pọ̀: Lóòótọ́ a ti fi ilẹ̀ náà fún wa gẹ́gẹ́ bí ìní wa.’ 25 Nítorí náà sọ fún wọn pé, ‘Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Níwọ́n ìgbà tí ẹ̀yin jẹ ẹran pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ni inú rẹ̀, tí ẹ̀yin sì wó àwọn ère yín, tí ẹ sì ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, Ẹ̀yin yóò ha gba ilẹ̀ náà? 26 Ẹ̀yin gbẹ́kẹ̀lé idà yín, ẹ̀yin ṣe nǹkan ìríra, ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú yín ba á obìnrin aládùúgbò rẹ̀ jẹ́. Ẹ̀yin yóò ha gba ilẹ̀ náà?’

27 “Sọ èyí fún wọn: ‘Èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Bí mo ti wà láààyè, àwọn tí ó kúrò nínú ìparun yóò ti ipa idà ṣubú, àwọn tí ẹranko búburú yóò pajẹ, àwọn tí ó sì wà ní ilé ìṣọ́ àti inú ihò òkúta ni àjàkálẹ̀-ààrùn yóò pa. 28 Èmi yóò mú kí ilẹ̀ náà di ahoro, ọ̀ṣọ́ ńlá agbára rẹ̀ kì yóò sí mọ́, àwọn òkè Israẹli yóò sì di ahoro, tí ẹnikẹ́ni kò ní le là á kọjá. 29 Nígbà náà, wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa, nígbà tí mo bá mú ilẹ̀ náà di ahoro nítorí gbogbo ohun ìríra tí wọ́n ti ṣe.’

30 “Ní tìrẹ, ọmọ ènìyàn, àwọn ènìyàn ìlú n sọ̀rọ̀ nípa rẹ ní ẹ̀gbẹ́ ògiri àti ní ẹnu-ọ̀nà ilé wọn, wọ́n ń sọ sí ara wọn wí pé, ‘Ẹ wá gbọ́ iṣẹ́ ti a ran láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá.’ 31 Àwọn ènìyàn mi wá sọ́dọ̀ rẹ, gẹ́gẹ́ bí wọn ṣe ń ṣe, wọn sì jókòó níwájú rẹ láti fetísí ọ̀rọ̀ rẹ, ṣùgbọ́n wọn kò mú wá sí ìṣe. Ẹnu wọn ni wọ́n fi n sọ̀rọ̀ ìfọkànsìn, ṣùgbọ́n ọkàn wọn ní ìwọra èrè tí kò tọ́. 32 Nítòótọ́ lójú wọn, ìwọ jẹ́ ẹni kan tí ó ń kọrin ìfẹ́ pẹ̀lú ohun dídára àti ohun èlò orin kíkọ, nítorí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ ṣùgbọ́n wọn kò mu wá sí ìṣe.

33 “Nígbà tí gbogbo ìwọ̀nyí bá ṣẹ tí yóò sì ṣẹ dandan, nígbà náà wọn yóò mọ̀ pé wòlíì kan ti wa láàrín wọn rí.”

1 Johanu 2:1-11

(A)Ẹ̀yin ọmọ mi ọ̀wọ́n, mo kọ ìwé nǹkan wọ̀nyí sí yín, kí ẹ̀yin má bà á dẹ́ṣẹ̀. Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni bá sì dẹ́ṣẹ̀, àwa ni alágbàwí lọ́dọ̀ Baba: Jesu Kristi, olódodo nìkan. (B)Òun sì ní ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ wa, kì í tilẹ̀ ṣe fún tiwa nìkan ṣùgbọ́n fún ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo aráyé.

Àwa mọ̀ pé àwa ti wá mọ̀ ọ́n, bí àwa bá ń pa òfin rẹ̀ mọ́. (C)Ẹni tí ó bá wí pé, “Èmi mọ̀ ọ́n,” tí kò sì pa òfin rẹ̀ mọ́, èké ni, òtítọ́ kò sì ṣí nínú rẹ̀. (D)Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá ń pa òfin rẹ̀ mọ́, lára rẹ̀ ni a gbé mú ìfẹ́ Ọlọ́run pé nítòótọ́. Nípa èyí ni àwa mọ̀ pé àwa ń wà nínú rẹ̀. (E)Ẹnikẹ́ni tí ó bá wí pé òun ń gbé inú rẹ̀, òun náà pẹ̀lú sì yẹ láti máa rìn gẹ́gẹ́ bí Jesu ti rìn.

(F)Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, kì í ṣe òfin tuntun ni mo ń kọ̀wé rẹ̀ sí yín ṣùgbọ́n òfin àtijọ́, èyí tí ẹ̀yin tí gbọ́ ní àtètèkọ́ṣe. Òfin àtijọ́ ni ọ̀rọ̀ náà tí ẹ̀yin tí gbọ́. (G)Pẹ̀lúpẹ̀lú, òfin tuntun ni mo ń kọ̀wé rẹ̀ sí yín; èyí tí í ṣe òtítọ́ nínú rẹ̀ àti nínú yin, nítorí òkùnkùn ń kọjá lọ, ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ sì tí ń tàn.

Ẹni tí ó bá sì wí pé òun ń wà nínú ìmọ́lẹ̀, tí ó sì kórìíra arákùnrin rẹ̀ sì ń bẹ nínú òkùnkùn. 10 (H)Ẹni tí ó ba fẹ́ràn arákùnrin rẹ̀, ó ń gbé inú ìmọ́lẹ̀, kò sì ṣí ohun ìkọ̀sẹ̀ kan nínú rẹ̀. 11 Ṣùgbọ́n ẹni tí o bá kórìíra arákùnrin rẹ̀ ń gbé nínú òkùnkùn, ó sì ń rìn nínú òkùnkùn; kò sì mọ ibi tí òun ń lọ, nítorí tí òkùnkùn tí fọ́ ọ lójú.

Matiu 9:35-10:4

Àwọn Alágbàṣe Kéré

35 (A)Jesu sì rìn yí gbogbo ìlú ńlá àti ìletò ká, ó ń kọ́ni nínú Sinagọgu wọn, ó sì ń wàásù ìhìnrere ìjọba ọrun, ó sì ń ṣe ìwòsàn ààrùn àti gbogbo àìsàn ní ara àwọn ènìyàn. 36 (B)Nígbà tí ó rí ọ̀pọ̀ ènìyàn, àánú wọn ṣe é, nítorí àárẹ̀ mú wọn, wọn kò sì rí ìrànlọ́wọ́, bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́. 37 (C)Nígbà náà ni ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Lóòótọ́ ni ìkórè pọ̀ ṣùgbọ́n àwọn alágbàṣe kò tó nǹkan 38 Nítorí náà, ẹ gbàdúrà sí Olúwa ìkórè kí ó rán àwọn alágbàṣe sínú ìkórè rẹ̀.”

Jesu rán àwọn méjìlá jáde

10 (D)Jesu sì pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá sí ọ̀dọ̀; ó fún wọn ní àṣẹ láti lé ẹ̀mí àìmọ́ jáde àti láti ṣe ìwòsàn ààrùn àti àìsàn gbogbo.

Orúkọ àwọn aposteli méjèèjìlá náà ni wọ̀nyí:

ẹni àkọ́kọ́ ni Simoni ẹni ti a ń pè ni Peteru àti arákùnrin rẹ̀ Anderu;

Jakọbu[a] ọmọ Sebede àti arákùnrin rẹ̀ Johanu.

Filipi àti Bartolomeu;

Tomasi àti Matiu agbowó òde;

Jakọbu ọmọ Alfeu àti Taddeu;

Simoni ọmọ ẹgbẹ́ Sealoti, Judasi Iskariotu, ẹni tí ó da Jesu.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.