Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 50

Saamu ti Asafu

50 Olúwa, Ọlọ́run alágbára
    sọ̀rọ̀ kí o sì pe ayé jọ
    láti ìlà-oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀.
Láti Sioni wá, pípé ni ẹwà,
    Ọlọ́run tí ń tan ìmọ́lẹ̀
Ọlọ́run ń bọ̀,
    bẹ́ẹ̀ ni kì yóò dákẹ́,
iná yóò máa jó níwájú rẹ̀,
    àti ní àyíká rẹ̀ ni ẹ̀fúùfù líle yóò ti máa jà ká.
Yóò sì pe àwọn ọ̀run láti òkè wá jọ àti ayé,
    kí o le máa ṣe ìdárò àwọn ènìyàn rẹ̀.
“Kó àwọn ènìyàn mímọ́ jọ fún mi
    àwọn tí wọn fi ẹbọ dá májẹ̀mú fún mi.”
Àwọn ọ̀run yóò sì sọ̀rọ̀ òdodo rẹ̀,
    Nítorí Ọlọ́run fúnrarẹ̀ ni onídàájọ́.

“Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ènìyàn mi, èmi yóò si sọ̀rọ̀, ìwọ Israẹli, èmi yóò jẹ́rìí sí ọ:
    èmi ní Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ.
Èmi kí yóò bá ọ wí
    nítorí àwọn ìrúbọ rẹ,
tàbí ọrẹ ẹbọ sísun rẹ, èyí tí ó wà níwájú mi
    ní ìgbà gbogbo.
Èmí kò fẹ́ kí ó mú akọ màlúù láti inú ilé tí o kọ́ fún un,
    tàbí kí o mú òbúkọ láti
inú agbo ẹran rẹ̀
10 Nítorí gbogbo ẹran igbó ni tèmi
    àti ẹran ọ̀sìn lórí ẹgbẹ̀rún òkè.
11 Èmi mọ gbogbo ẹyẹ ní orí àwọn òkè ńlá
    àti gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà ní orí ilẹ̀ ni tèmi
12 Bí ebi tilẹ̀ ń pa mí, èmi kì yóò sọ fún ọ,
    nítorí ayé ni tèmi àti ohun gbogbo
tí ó wa ní inú rẹ̀.
13 Ǹjẹ́ èmi yóò ha jẹ ẹran akọ màlúù tàbí
    mú ẹ̀jẹ̀ òbúkọ?

14 “Rú ẹbọ ọpẹ́ sí Ọlọ́run,
    kí o sì san ẹ̀jẹ́ rẹ fún Ọ̀gá-ògo.
15 Kí o sì pè mí ní ọjọ́ ìpọ́njú,
    èmi yóò gbà ọ́, ìwọ yóò sì bu ọlá fún mi.”

16 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ fún àwọn, ènìyàn búburú:

“Kí ní ẹ̀tọ́ tí o ní tí ìwọ fi ń tún àwọn ìlànà mi sọ,
    tàbí tí ìwọ sì ń sọ májẹ̀mú mi ní ẹnu rẹ?
17 Ìwọ kórìíra àṣẹ mi,
    ìwọ sì ṣá ọ̀rọ̀ mí tì sí apá kan.
18 Nígbà tí ìwọ rí olè, ìwọ dára pọ̀ mọ́ ọn,
    ìwọ sì da ara rẹ dé àwọn alágbèrè.
19 Ìwọ lo ẹnu rẹ fún aburú,
    ìwọ sì ń fi ahọ́n rẹ pète ẹ̀tàn.
20 Ní ìgbà gbogbo ìwọ ń sọ̀rọ̀ sí arákùnrin rẹ,
    ìwọ sì ń ba orúkọ ọmọ ìyá rẹ jẹ́.
21 Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ìwọ ti ṣe, mo sì dákẹ́;
    ìwọ rò pé mo jẹ́ irú kan náà bí ìrẹ,
ṣùgbọ́n èmi yóò bá ọ wí,
    èmi yóò sì fi ẹ̀sùn kàn ọ́ ní ojú ara rẹ.

22 “Ǹjẹ́ ìwọ ro èyí wò, ẹ̀yin tí ó gbàgbé Ọlọ́run.
    Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ èmi yóò fa yin ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, láìsí ẹni tí yóò gbà yin sílẹ̀.
23 Ẹni tí ó ba ní ẹbọ ọrẹ-ọpẹ́ bu ọlá fún mi; kí ó sì tún ọ̀nà rẹ̀ ṣe,
    kí èmi kí ó le fi ìgbàlà Ọlọ́run hàn án.”

Saamu 59-60

Fún adarí orin. Tí ohùn orin “Má ṣe parun.” Ti Dafidi. Miktamu. Nígbà tí Saulu rán àwọn olùṣọ́ sí ilé Dafidi kí òun bá le rí i pa.

59 Gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá à mi, Ọlọ́run;
    dáàbò bò mí kúrò lọ́dọ̀ àwọn tí ó dìde sí mi.
Gbà mí lọ́wọ́ àwọn oníṣẹ́ búburú
    kí o sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ènìyàn tí ń pòǹgbẹ ẹ̀jẹ̀.

Wò ó, bí wọ́n ṣe ba ní bùba dè mí!
    Àwọn alágbára ń gbìmọ̀ lòdì sí mi
Kì í ṣe nítorí ìrékọjá mi tàbí ẹ̀ṣẹ̀ mí, Olúwa.
Èmi kò ṣe àìṣedéédéé kan, síbẹ̀ wọ́n sáré wọ́n ṣetán láti kọlù mí.
    Dìde fún ìrànlọ́wọ́ mi, kí o sì wo àìlera mi.
Olúwa Ọlọ́run Alágbára,
    Ọlọ́run Israẹli,
dìde fún ara rẹ kí o sì bá àwọn orílẹ̀-èdè wí;
    má ṣe ṣàánú fún àwọn olùrékọjá búburú nì. Sela.

Wọ́n padà ní àṣálẹ́,
    wọ́n ń gbó bí àwọn ajá,
    wọ́n ń rìn yí ìlú náà káàkiri.
Kíyèsi ohun tí wọ́n tú jáde ní ẹnu:
    wọn ń tú idà jáde láti ètè wọn,
    wọ́n sì wí pé, “Ta ni ó lè gbọ́ ọ̀rọ̀ wa?”
Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, yóò fi wọ́n rẹ́rìn-ín
    Ìwọ ó yọ ṣùtì sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.

Ìwọ agbára mi, èmi ó máa kọrin ìyìn sí ọ;
    nítorí ìwọ Ọlọ́run ni ààbò mi,
10     Ọlọ́run àánú mi ni yóò ṣáájú mi.

Ọlọ́run yóò sì jẹ́ kí èmi rí ìfẹ́ mi lára àwọn ọ̀tá mi.
    Yóò sì jẹ́ kí n yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí ìfẹ́ àwọn ọ̀tá mi.
11 Ṣùgbọ́n má ṣe pa wọ́n, Olúwa asà wa,
    kí àwọn ènìyàn mi má ba à gbàgbé.
Nínú agbára rẹ, jẹ́ kí wọn máa rìn kiri,
    kí o sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀.
12 Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ẹnu wọn,
    ní ọ̀rọ̀ ètè wọn,
    kí a mú wọn nínú ìgbéraga wọn.
Nítorí èébú àti èké tí wọn ń sọ,
13     Pa wọ́n run nínú ìbínú,
    run wọ́n di ìgbà tí wọn kò ní sí mọ́.
Nígbà náà ni yóò di mí mọ̀ dé òpin ayé
    pé Ọlọ́run jẹ ọba lórí Jakọbu. Sela.

14 Wọ́n padà ní àṣálẹ́,
    wọn ń gbó bí àwọn ajá
    wọ́n ń rin ìlú náà káàkiri.
15 Wọ́n ń rin kiri fún oúnjẹ
    wọ́n sì ń yán nígbà tí wọn kò yó.
16 Ṣùgbọ́n èmi ó kọrin agbára rẹ,
    n ó kọrin ìfẹ́ rẹ ní òwúrọ̀;
nítorí ìwọ ni ààbò mi,
    ibi ìsádi mi ní ìgbà ìpọ́njú.

17 Ìwọ agbára mi, èmi ó kọrin ìyìn sí ọ;
    ìwọ, Ọlọ́run, ààbò mi, Ọlọ́run ìfẹ́ mi.

Fún adarí orin. Tí ohùn “Lílì ti Májẹ̀mú.” Miktamu ti Dafidi. Fún ìkọ́ni. Nígbà tí ó bá Aramu-Naharaimu àti Siria-Soba jà, àti nígbà tí Joabu yípadà tí ó sì pa ẹgbẹ̀rún méjìlá àwọn ará Edomu ní Àfonífojì Iyọ̀.

60 Ìwọ ti kọ̀ wá sílẹ̀,
    Ọlọ́run, ìwọ ti tú wa ká,
ìwọ ti bínú nísinsin yìí, tún ara rẹ yípadà sí wa.
Ìwọ ti mú ilẹ̀ wárìrì, ìwọ ti fọ́ ọ;
    mú fífọ́ rẹ̀ bọ̀ sípò, nítorí tí ó mì.
Ìwọ ti fi ìgbà ewu han àwọn ènìyàn rẹ;
    Ìwọ fún wa ní wáìnì tí ó máa ń ta wá gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n.
Àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, ní ìwọ fi ọ̀págun fún
    kí a lè fihàn nítorí òtítọ́. Sela.

(A)Fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbà wá, kí o sì ràn wá lọ́wọ́,
    kí a lè gba àwọn tí o fẹ́ là.
Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ láti ibi mímọ́ rẹ̀:
    “Ní ayọ̀, èmi ó pọ Ṣekemu jáde
    èmi ó sì wọ́n Àfonífojì Sukkoti.
Tèmi ni Gileadi, tèmi sì ni Manase;
    Efraimu ni àṣíborí mi,
    Juda sì ni ọ̀pá àṣẹ mi.
Moabu ní ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi,
    lórí Edomu ní mo bọ́ bàtà mi sí;
    lórí Filistia ni mo kígbe ayọ̀.”

Ta ni yóò mú mi wá sí ìlú olódi nì?
    Ta ni yóò tọ́ mí lọ sí Edomu?
10 Kì í ha ń ṣe ìwọ, Ọlọ́run, tí ó ti kọ̀ wá sílẹ̀
    tí o kò sì bá ogun wa jáde mọ́?
11 Fún wa ní ìrànlọ́wọ́ lórí àwọn ọ̀tá,
    nítorí asán ni ìrànlọ́wọ́ ènìyàn.
12 Nípa Ọlọ́run ni a óò ní ìṣẹ́gun,
    yóò sì tẹ àwọn ọ̀tá wa mọ́lẹ̀.

Saamu 33

33 Ẹ yọ̀ nínú Olúwa, ẹ̀yin olódodo
    ìyìn si yẹ fún ẹni dídúró ṣinṣin.
Ẹ yin Olúwa pẹ̀lú dùùrù;
    ẹ máa fi ohun èlò olókùn mẹ́wàá kọrin sí i.
Ẹ kọ orin tuntun sí i;
    ẹ máa fi ọgbọọgbọ́n lu ohun èlò orin sí i, pẹ̀lú ariwo.

Nítorí pé ọ̀rọ̀ Olúwa dúró ṣinṣin,
    gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ ni à ń ṣe nínú òtítọ́.
Ó fẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ́;
    ilé ayé kún fún ìdúró ṣinṣin àti àánú Olúwa.

Nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Olúwa ni a ṣe dá àwọn ọ̀run,
    àti gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ogun wọn nípa ìmísí ẹnu rẹ̀.
Ó kó àwọn omi Òkun jọ gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó wà nínú ìgò;
    ó sì fi ibú ṣe ilé ìṣúra gbogbo.
Jẹ́ kí gbogbo ayé kí ó bẹ̀rù Olúwa:
    jẹ́ kí gbogbo àwọn olùgbé ayé kí ó wà nínú ìbẹ̀rù rẹ̀.
Nítorí tí ó sọ̀rọ̀, ó sì ti rí bẹ́ẹ̀; ó pàṣẹ
    ó sì dúró ṣinṣin.

10 Olúwa ti mú ìmọ̀ràn àwọn orílẹ̀-èdè wá sí asán;
    ó sì mú àrékérekè àwọn ènìyàn di ṣíṣákì í.
11 Ìgbìmọ̀ Olúwa dúró títí ayérayé,
    àní ìrò inú rẹ̀ láti ìrandíran ni.

12 Ìbùkún ni fún orílẹ̀-èdè náà, Ọlọ́run ẹni tí Olúwa jẹ́ tirẹ̀,
    àti àwọn ènìyàn náà tí ó ti yàn ṣe ìní rẹ̀.
13 Olúwa wò láti ọ̀run wá;
    Ó sì rí gbogbo ìran ènìyàn.
14 Níbi tí ó ti jókòó lórí ìtẹ́
    Ó wo gbogbo àwọn olùgbé ayé
15 ẹni tí ó ṣe àyà wọn bákan náà,
    ó sì kíyèsi ìṣe wọn.

16 A kò gba ọba kan là nípasẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ-ogun;
    kò sì sí jagunjagun tí a gbà sílẹ̀ nípa agbára ńlá rẹ̀.
17 Ohun asán ni ẹṣin fún ìṣẹ́gun;
    bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi agbára ńlá rẹ̀ gbani sílẹ̀.
18 Wò ó, ojú Olúwa wà lára àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
    àti lára àwọn tí ó ní ìrètí nínú ìfẹ́ rẹ̀ tí ó dúró ṣinṣin.
19 Láti gba ọkàn wọn kúrò lọ́wọ́ ikú
    àti láti pa wọ́n mọ́ láààyè lọ́wọ́ ìyàn.

20 Ọkàn wa dúró de Olúwa;
    òun ni ìrànlọ́wọ́ wa àti asà wa.
21 Ọkàn wa yọ̀ nínú rẹ̀,
    nítorí pé, àwa gbẹ́kẹ̀lé orúkọ rẹ mímọ́.
22 Kí àánú rẹ, Olúwa, kí ó wà lára wa,
    àní gẹ́gẹ́ bí àwa ti ń ṣe ìrètí nínú rẹ.

Sekariah 4

Ọ̀pá fìtílà wúrà àti àwọn igi olifi méjì

Angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ sì tún dé, ó sì jí mi, bí ọkùnrin tí a jí lójú oorun rẹ̀, Ó sì wí fún mi pé, “Kí ni ìwọ rí?”

Mo sì wí pé, “Mo wò, sì kíyèsi i, ọ̀pá fìtílà tí gbogbo rẹ̀ jẹ́ wúrà, pẹ̀lú àwokòtò rẹ̀ lórí rẹ̀ pẹ̀lú fìtílà méje rẹ̀ lórí rẹ̀, àti ẹnu méje fún fìtílà méjèèje, tí ó wà lórí rẹ̀: (A)Igi olifi méjì sì wà létí rẹ̀, ọ̀kan ní apá ọ̀tún àwokòtò náà, àti èkejì ní apá òsì rẹ̀.”

Mo sì dáhùn mo sì wí fún angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀, pé, “Kín ni wọ̀nyí, olúwa mi?”

Angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ dáhùn ó sì wí fún mi pé, “Ìwọ kò mọ ohun tí àwọn wọ̀nyí jásí?”

Mo sì wí pé, “Èmi kò mọ̀ ọ́n, olúwa mi.”

Ó sì dáhùn ó sì wí fún mi pé, “Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa sí Serubbabeli tó wí pé: ‘Kì í ṣe nípa ipá, kì í ṣe nípa agbára, bí kò ṣe nípa Ẹ̀mí mi,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

“Ta ni ìwọ, ìwọ òkè ńlá? Ìwọ yóò di pẹ̀tẹ́lẹ̀ níwájú Serubbabeli: òun yóò sì fi ariwo mú òkúta téńté orí rẹ̀ wá, yóò máa kígbe wí pé, ‘Ọlọ́run bùkún fun! Ọlọ́run bùkún fun!’ ”

Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá, wí pé: “Ọwọ́ Serubbabeli ni a ti ṣe ìpìlẹ̀ ilé yìí, ọwọ́ rẹ̀ ni yóò sì parí rẹ̀; ìwọ yóò sì mọ̀ pé, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ó rán mi sí i yín.

10 (B)“Ṣùgbọ́n ta ni ha kẹ́gàn ọjọ́ ohun kékeré? Nítorí wọn ó yọ̀ nígbà ti wọ́n bá rí okùn ìwọ̀n nì lọ́wọ́ Serubbabeli.

“(Àwọn méje wọ̀nyí ni àwọn ojú Olúwa, tí ó ń sáré síhìn-ín sọ́hùn-ún ní gbogbo ayé.)”

11 Mo sì béèrè, mo sì sọ fún un pé, “Kí ni àwọn igi olifi méjì wọ̀nyí jásí, tí ó wà ní apá ọ̀tún fìtílà àti ní apá òsì rẹ̀?”

12 Mo sì tún dáhùn, mo sì sọ fún un pé, “Kí ni àwọn ẹ̀ka méjì igi olifi wọ̀nyí jásí, tí ń tú òróró wúrà jáde nínú ara wọn láti ẹnu ọ̀pá oníhò wúrà méjì.”

13 Ó sì dáhùn, ó wí fún mi pé, “Ìwọ kò mọ ohun tí àwọn wọ̀nyí jásí?”

Mo sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, olúwa à mi.”

14 Ó sì wí pé, “Àwọn méjì wọ̀nyí ni àwọn tí a fi òróró yàn, tí ó dúró ti Olúwa gbogbo ayé.”

Ìfihàn 4:9-5:5

(A)Nígbà tí àwọn ẹ̀dá alààyè náà bá sì fi ògo àti ọlá, àti ọpẹ́ fún ẹni tí o jókòó lórí ìtẹ́, tí o ń bẹ láààyè láé àti láéláé. 10 Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún náà yóò sì wólẹ̀ níwájú ẹni tí o jókòó lórí ìtẹ́, wọn yóò sì tẹríba fún ẹni tí ń bẹ láààyè láé àti láéláé, wọn yóò sì fi adé wọn lélẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà, wí pé:

11 “Olúwa àti Ọlọ́run, ìwọ ni o yẹ,
láti gba ògo àti ọlá àti agbára:
nítorí pé ìwọ ni o dá ohun gbogbo,
    àti nítorí ìfẹ́ inú rẹ̀ ni
    wọn fi wà tí a sì dá wọn.”

Ìwé àti Ọ̀dọ́-àgùntàn

(B)Mo sì rí i ni ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà, ìwé kan ti a kọ nínú àti lẹ́yìn, ti a sì fi èdìdì méje dí. Mó sì rí angẹli alágbára kan, ó ń fi ohùn rara kéde pé, “Ta ni ó yẹ láti ṣí ìwé náà, àti láti tu èdìdì rẹ̀?” Kò sì ṣí ẹni kan ní ọ̀run, tàbí lórí ilẹ̀ ayé, tàbí nísàlẹ̀ ilẹ̀, tí ó le ṣí ìwé náà, tàbí ti o lè wo inú rẹ̀. Èmi sì sọkún gidigidi, nítorí tí a kò ri ẹnìkan tí o yẹ láti sí i àti láti ka ìwé náà, tàbí láti wo inú rẹ̀. (C)Ọ̀kan nínú àwọn àgbà náà sì wí fún mi pé, “Má ṣe sọkún: kíyèsi i, kìnnìún ẹ̀yà Juda, Gbòǹgbò Dafidi, tí borí láti ṣí ìwé náà, àti láti tú èdìdì rẹ̀ méjèèje.”

Matiu 25:1-13

Òwe àwọn wúńdíá mẹ́wàá

25 (A)“Nígbà náà ni ó fi ìjọba ọ̀run wé àwọn wúńdíá mẹ́wàá. Ti wọ́n gbé fìtílà wọn láti lọ pàdé ọkọ ìyàwó. Márùn-ún nínú wọn jẹ́ ọlọ́gbọ́n, márùn-ún nínú wọn ni wọ́n jẹ́ aláìgbọ́n. Àwọn tí wọ́n jẹ́ aláìgbọ́n gbé fìtílà wọn ṣùgbọ́n wọn kò mú epo kankan lọ́wọ́. Àwọn ọlọ́gbọ́n mú epo sínú kólòbó lọ́wọ́ pẹ̀lú fìtílà wọn. Nígbà tí ọkọ ìyàwó pẹ́, gbogbo wọn tòògbé wọn sì sùn.

“Nígbà tí ó di ọ̀gànjọ́, igbe ta sókè, ‘Wò ó, ọkọ ìyàwó ń bọ̀, ẹ jáde sóde láti pàdé rẹ̀.’

“Nígbà náà ni àwọn wúńdíá sì tají, wọ́n tún fìtílà wọn ṣe. Àwọn aláìgbọ́n márùn-ún tí kò ní epo rárá bẹ àwọn ọlọ́gbọ́n pé kí wọn fún àwọn nínú èyí tí wọ́n ní nítorí fìtílà wọn ń kú lọ.

“Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n márùn-ún dáhùn pé, bẹ́ẹ̀ kọ́; kí ó má ba à ṣe aláìtó fún àwa àti ẹ̀yin, ẹ kúkú tọ àwọn tí ń tà á lọ, kí ẹ sì rà fún ara yín.

10 (B)“Ní àsìkò tí wọ́n lọ ra epo tiwọn, ni ọkọ ìyàwó dé. Àwọn wúńdíá tí ó múra tán bá a wọlé sí ibi àsè ìgbéyàwó, lẹ́yìn náà, a sì ti ìlẹ̀kùn.

11 (C)“Ní ìkẹyìn ni àwọn wúńdíá márùn-ún ìyókù dé, wọ́n ń wí pé, ‘Olúwa, Olúwa, ṣílẹ̀kùn fún wa.’

12 “Ṣùgbọ́n ọkọ ìyàwó dáhùn pé, ‘Lóòótọ́ ni mo wí fún yín èmi kò mọ̀ yín rí.’

13 (D)“Nítorí náà, ẹ máa ṣọ́nà. Nítorí pé ẹ̀yin kò mọ ọjọ́ tàbí wákàtí tí Ọmọ Ènìyàn yóò dé.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.