Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 26

Ti Dafidi.

26 Ṣe ìdájọ́ mi, Olúwa,
    nítorí tí mo ti ń rìn nínú ìwà òtítọ́ ọ̀ mi,
mo sì ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa
    Ǹjẹ́ ẹsẹ̀ mi kì yóò yẹ̀.
Wádìí mi wò, Ìwọ Olúwa, kí o sì dán mi wò,
    dán àyà àti ọkàn mi wò;
Nítorí ìfẹ́ ẹ̀ rẹ tí ó dúró ṣinṣin ń bẹ níwájú mi,
    èmí sì ti rìn nínú òtítọ́ rẹ.

Èmi kò jókòó pẹ̀lú aláìṣòótọ́,
    bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò bá àwọn àgàbàgebè wọlé;
Èmi ti kórìíra àwùjọ àwọn ènìyàn búburú
    èmi kì yóò sì bá àwọn ènìyàn ìkà jókòó.
Èmí ó wẹ ọwọ́ mi ní àìlẹ́ṣẹ̀,
    bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì yí pẹpẹ rẹ ká Olúwa.
Èmi yóò kọrin sókè àní orin ọpẹ́,
    èmi yóò sì máa sọ iṣẹ́ ìyanu rẹ̀.

Háà Olúwa, èmí ń fẹ́ ilé rẹ níbi tí ìwọ ń gbé,
    àní níbi tí ògo rẹ̀ wà.
Má ṣe gbá mi dànù pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,
    tàbí ẹ̀mí mi pẹ̀lú àwọn ọkùnrin tí òǹgbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ,
10 Àwọn tí ọwọ́ wọn kún fún ìwà ibi,
    tí ọwọ́ ọ̀tún wọn kún fún àbẹ̀tẹ́lẹ̀.
11 Ṣùgbọ́n èmi ó máa rìn nínú ìwà títọ́;
    rà mí padà, kí o sì ṣàánú fún mi.

12 Ẹsẹ̀ mi dúró lórí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú;
    nínú ìjọ ńlá èmi yóò fi ìbùkún fún Olúwa.

Saamu 28

Ti Dafidi.

28 Ìwọ Olúwa,
    mo ké pe àpáta mi;
    Má ṣe kọ etí dídi sí mi.
Tí ìwọ bá dákẹ́ sí mi,
    èmí yóò dàbí àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun.
Gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi fún àánú,
    bí mo ṣe ń ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́,
bí mo ṣe gbé àwọn ọwọ́ mi sókè
    sí ibi mímọ́ rẹ jùlọ.

Má ṣe fà mí lọ pẹ̀lú ènìyàn búburú àti,
    pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀,
tí ń sọ̀rọ̀ àlàáfíà sí aládùúgbò wọn
    ṣùgbọ́n tí ìwà ìkà ń bẹ nínú wọn.
San ẹ̀san wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn
    àti fún iṣẹ́ ibi wọn;
gba ẹ̀san wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn;
    kí o sì san ẹ̀san wọn bí ó ti tọ́.

Nítorí pé wọn kò ka iṣẹ́ Olúwa sí,
    tàbí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀
òun ó rún wọn wọlẹ̀
    kì yóò sì gbé wọn ró mọ́.

Alábùkún fún ni Olúwa!
    Nítorí pé ó ti gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.
Olúwa ni agbára mi àti asà mi;
    nínú rẹ̀ ni mo gbẹ́kẹ̀lé; àní, ó sì ràn mí lọ́wọ́.
Ọkàn mi sì gbé sókè fún ayọ̀
    àní pẹ̀lú orin mi mo fi ọpẹ́ fún un.

Olúwa ni agbára àwọn ènìyàn rẹ̀
    òun ni odi ìgbàlà àwọn ẹni ààmì òróró rẹ̀.
Ìwọ gba àwọn ènìyàn rẹ là, kí o sì bùkún àwọn ajogún rẹ;
    di olùṣọ́-àgùntàn wọn, kí o sì gbé wọn lékè títí ayérayé.

Saamu 36

Fún adarí orin. Ti Dafidi ìránṣẹ́ Olúwa

36 (A)Ìré-òfin-kọjá ènìyàn búburú
    jẹ́ kí n mọ̀ nínú ọkàn mi pé;
Ìbẹ̀rù Ọlọ́run kò sí
    níwájú wọn.

Nítorí pé wọ́n pọ́n ara wọn ní ojú ara wọn
    títí tí a kò fi le rí ẹ̀ṣẹ̀ wọn láti kórìíra.
Ọ̀rọ̀ ẹnu wọn ni ẹ̀ṣẹ̀ òhun ẹ̀tàn;
    wọ́n ti fi ọgbọ́n àti ṣíṣe rere sílẹ̀;
Wọ́n gbìmọ̀ ìwà ìkà nígbà tí wọ́n wà lórí ibùsùn wọn:
    wọ́n gba ọ̀nà tí kò dára
    wọn kò sì kọ ọ̀nà ibi sílẹ̀.

Ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ, ìwọ Olúwa, ó ga dé ọ̀run,
    òtítọ́ ọ̀ rẹ ga dé àwọsánmọ̀.
Òdodo rẹ dàbí àwọn òkè Ọlọ́run,
    àwọn ìdájọ́ rẹ dàbí ibú ńlá;
    ìwọ gba ẹranko àti ènìyàn là, Olúwa.
Báwo ni ìṣeun ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ ti tó! Ọlọ́run!
    Kí gbogbo ọmọ ènìyàn le sá sí abẹ́ òjìji ìyẹ́ rẹ.
Àsè ilé rẹ yóò tẹ́ wọn lọ́rùn gidigidi;
    ìwọ yóò sì mú wọn mu nínú odò inú dídùn rẹ.
Nítorí pé pẹ̀lú rẹ ni orísun ìyè wà:
    nínú ìmọ́lẹ̀ rẹ ni àwa yóò rí ìmọ́lẹ̀.

10 Mú ìṣeun ìfẹ́ ẹ̀ rẹ sí àwọn tí ó mọ̀ ọ́n
    àti ìgbàlà rẹ sí àwọn tí ó ní ìdúró ṣinṣin ọkàn!
11 Má ṣe jẹ́ kí ẹsẹ̀ agbéraga kí ó wá sí orí mi,
    kí o má sì jẹ́ kí ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú sí mi ní ipò.
12 Níbẹ̀ ni àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ gbé ṣubú sí:
    a rẹ̀ wọ́n sílẹ̀, wọn kì yóò le è dìde!

Saamu 39

Fún adarí orin. Fún Jedutuni. Saamu Dafidi.

39 Mo wí pé, “èmi yóò ṣọ́ ọ̀nà mi
    kí èmi kí ó má fi ahọ́n mi ṣẹ̀;
èmi yóò fi ìjánu kó ara mi ní ẹnu
    níwọ̀n ìgbà tí ènìyàn búburú bá ń bẹ ní iwájú mi.”
Mo fi ìdákẹ́ ya odi;
    mo tilẹ̀ pa ẹnu mi mọ́ kúrò nínú ọ̀rọ̀ rere;
ìbànújẹ́ mi sì pọ̀ sí i.
    Àyà mi gbóná ní inú mi.
Nígbà tí mo ń ṣàṣàrò, iná ràn;
    nígbà náà ni mo fi ahọ́n mi sọ̀rọ̀:

Olúwa, jẹ́ kí èmi kí ó mọ òpin mi,
    àti ìwọ̀n ọjọ́ mi, bí ó ti rí
    kí èmi kí o le mọ ìgbà tí mó ní níhìn-ín.
Ìwọ ti ṣe ayé mi
    bí ìbú àtẹ́lẹwọ́,
ọjọ́ orí mi sì dàbí asán
    ní iwájú rẹ:
Dájúdájú olúkúlùkù ènìyàn nínú
    ìjókòó rere rẹ̀ jásí asán pátápátá. Sela.

“Nítòótọ́ ni olúkúlùkù ń rìn kiri bí òjìji.
    Nítòótọ́ ni wọ́n ń yọ ara wọn lẹ́nu lórí asán;
wọ́n ń kó ọrọ̀ jọ,
    wọn kò sì mọ ẹni tí yóò ko lọ.

“Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí,
    Olúwa,
kín ni mo ń dúró dè?
    Ìrètí mí ń bẹ ní ọ̀dọ̀ rẹ.
Gbà mí lọ́wọ́ ìrékọjá mi gbogbo.
    Kí o má sì sọ mí di ẹni ẹ̀gàn
àwọn ènìyàn búburú.
Mo dákẹ́ jẹ́ẹ́;
    èmi kò sì ya ẹnu mi,
nítorí wí pé ìwọ ni ó ṣe é.
10 Mú pàṣán rẹ kúrò ní ara mi;
    èmí ṣègbé tán nípa lílù ọwọ́ rẹ.
11 Ìwọ fi ìbáwí kìlọ̀
    fún ènìyàn nítorí ẹ̀ṣẹ̀,
ìwọ a mú ẹwà rẹ parun
    bí kòkòrò aṣọ;
nítòótọ́ asán ni ènìyàn gbogbo.

12 “Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa,
    kí o sì fetí sí igbe mi;
kí o má ṣe di etí rẹ sí ẹkún mi
    nítorí àlejò ni èmi lọ́dọ̀ rẹ
àti àtìpó, bí gbogbo àwọn baba mi ti rí.
13 Dá mi sí, kí èmi lè ní agbára,
    kí èmi tó lọ kúrò níhìn-ín yìí,
    àti kí èmi ó tó ṣe aláìsí.”

Amosi 7:10-17

Amosi àti Amasiah

10 Nígbà náà Amasiah àlùfáà Beteli ránṣẹ́ sí Jeroboamu ọba Israẹli, wí pé: “Amosi ti dìde láti dìtẹ̀ sí ọ ni àárín gbùngbùn Israẹli. Ilẹ̀ kò sì le gba gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀. 11 Nítorí èyí ni ohun ti Amosi ń sọ:

“ ‘Jeroboamu yóò ti ipa idà kú,
    Lóòtítọ́ Israẹli yóò lọ sí ìgbèkùn,
    jìnnà kúrò ní ilẹ̀ ìní wọn.’ ”

12 Nígbà náà ni Amasiah sọ fún Amosi pé, “Lọ jáde, ìwọ aríran! Padà sí ilẹ̀ àwọn Juda. Kí o máa jẹun rẹ níbẹ̀, kí o sì máa sọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ níbẹ̀. 13 Má ṣe sọtẹ́lẹ̀ mọ ni Beteli nítorí ibi mímọ́ ọba ni àti ibi tẹmpili ìjọba rẹ̀.”

14 Amosi dá Amasiah lóhùn pé, “Èmi kì í ṣe wòlíì tàbí àwọn ọmọ wòlíì, ṣùgbọ́n mo jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn, mo sì ń ṣe ìtọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́ sikamore. 15 Ṣùgbọ́n Olúwa mu mi bí mo ti ń tọ́ agbo ẹran lẹ́yìn, ó sì wí fun mi pé, ‘Lọ sọtẹ́lẹ̀ fun àwọn Israẹli ènìyàn mi.’ 16 Nítorí náà nísinsin yìí, gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa. Ìwọ wí pé,

“ ‘Má ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí Israẹli
    Má sì ṣe wàásù sí ilé Isaaki.’

17 “Nítorí náà, èyí ni ohun ti Olúwa wí:

“ ‘Ìyàwó rẹ yóò di panṣágà ni ìlú,
    àwọn ọmọ ọkùnrin àti obìnrin rẹ yóò ti ipa idà ṣubú.
A ó fi okùn wọn ilẹ̀ rẹ, a ó sì pín in
    àti ìwọ pẹ̀lú yóò kú ni ilẹ̀ àìmọ́.
Israẹli yóò sì lọ sí ìgbèkùn,
    kúrò ní ilẹ̀ ìní wọn.’ ”

Ìfihàn 1:9-16

Ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí Ọmọ ènìyàn

Èmi, Johanu, arákùnrin yín àti alábápín pẹ̀lú yín nínú wàhálà àti ìjọba àti sùúrù tí ń bẹ nínú Jesu, wà ní erékúṣù tí a ń pè ní Patmo, nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti nítorí ẹ̀rí Jesu Kristi. 10 Mo wà nínú Ẹ̀mí ní ọjọ́ Olúwa, mo sì gbọ́ ohùn ńlá kan lẹ́yìn mi, bí ìró ìpè, 11 Ó ń wí pé, “Kọ́ ìwé rẹ̀, ohun tí ìwọ rí, kí ó sí fi ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ méje; sí Efesu, àti sí Smirna, àti sí Pargamu, àti sí Tiatira, àti sí Sardi, àti sí Filadelfia, àti sí Laodikea.”

12 Mo sì yí padà láti wo ohùn tí ń bá mi sọ̀rọ̀. Nígbà tí mo yípadà, mo rí ọ̀pá fìtílà wúrà méje; 13 (A)àti láàrín àwọn ọ̀pá fìtílà náà, ẹnìkan tí ó dàbí “ọmọ ènìyàn,” tí a wọ̀ ní aṣọ tí ó kanlẹ̀ dé ẹsẹ̀, tí a sì fi àmùrè wúrà dì ní ẹ̀gbẹ́. 14 Orí rẹ̀ àti irun rẹ̀ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú, ó funfun bí yìnyín; ojú rẹ̀ sì dàbí, ọwọ́ iná; 15 (B)Ẹsẹ̀ rẹ̀ sì dàbí idẹ dáradára, bí ẹni pé a dà á nínú ìléru; ohùn rẹ̀ sì dàbí ìró omi púpọ̀. 16 (C)Ó sì ní ìràwọ̀ méje ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀; àti láti ẹnu rẹ̀ wá ni idà olójú méjì mímú ti jáde: Ojú rẹ̀ sì dàbí oòrùn tí ó ń fi agbára rẹ̀ hàn.

Matiu 22:34-46

Òfin tí ó ga jùlọ

34 (A)Nígbà ti wọ́n sì gbọ́ pé ó ti pa àwọn Sadusi lẹ́nu mọ́, àwọn Farisi pé ara wọn jọ. 35 (B)Ọ̀kan nínú wọn tí ṣe amòfin dán an wò pẹ̀lú ìbéèrè yìí. 36 Ó wí pé, “Olùkọ́ èwo ni ó ga jùlọ nínú àwọn òfin?”

37 (C)Jesu dáhùn pé, “ ‘Fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ, gbogbo ẹ̀mí rẹ àti gbogbo inú rẹ. 38 Èyí ni òfin àkọ́kọ́ àti èyí tí ó tóbi jùlọ. 39 Èkejì tí ó tún dàbí rẹ̀ ní pé, ‘Fẹ́ràn ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’ 40 Lórí àwọn òfin méjèèjì yìí ni gbogbo òfin àti àwọn wòlíì rọ̀ mọ́.”

Ọmọ ta ni Kristi?

41 (D)Bí àwọn Farisi ti kó ara wọn jọ, Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, 42 “Kí ni ẹ rò nípa Kristi? Ọmọ ta ni òun ń ṣe?”

Wọ́n dáhùn pé, “Ọmọ Dafidi.”

43 Ó sì wí fún wọn pé, “Kí lo dé tí Dafidi, tí ẹ̀mí ń darí, pè é ní ‘Olúwa’? Nítorí ó wí pé,

44 “ ‘Olúwa sọ fún Olúwa mi pé,
    “Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi
títí tí èmi yóò fi fi àwọn ọ̀tá rẹ
    sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ.” ’

45 Ǹjẹ́ bí Dafidi bá pè é ni ‘Olúwa,’ báwo ni òun ṣe lè jẹ́ ọmọ rẹ̀?” 46 (E)Kò sí ẹnìkan tí ó lè sọ ọ̀rọ̀ kan ni ìdáhùn, kò tún sí ẹni tí ó tún bí i léèrè ohun kan mọ́ láti ọjọ́ náà mọ́.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.