Book of Common Prayer
148 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
Ẹ fi ìyìn fún Olúwa láti ọ̀run wá,
Ẹ fi ìyìn fún un níbi gíga.
2 Ẹ fi ìyìn fún un,
gbogbo ẹ̀yin angẹli rẹ̀
Ẹ fi ìyìn fún un,
gbogbo ẹ̀yin ọmọ-ogun rẹ̀
3 Ẹ fi ìyìn fún un,
oòrùn àti òṣùpá
Ẹ fi ìyìn fún un,
gbogbo ẹ̀yin ìràwọ̀ ìmọ́lẹ̀.
4 Ẹ fi ìyìn fún un,
ẹ̀yin ọ̀run àti àwọn ọ̀run gíga
àti ẹ̀yin omi tí ń bẹ ní òkè ọ̀run.
5 Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwa
nítorí ó pàṣẹ a sì dá wọn
6 Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ láé àti láéláé
ó sì ti ṣe ìlànà kan tí kì yóò já.
7 Ẹ yin Olúwa láti ilẹ̀ ayé wá
ẹ̀yin ẹ̀dá inú Òkun títóbi
àti ẹ̀yin ibú Òkun
8 Mọ̀nàmọ́ná àti òjò yìnyín
ìdí omi àti àwọn ìkùùkuu,
ìjì líle tí ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ;
9 Òkè ńlá àti gbogbo òkè kéékèèkéé,
igi eléso àti gbogbo igi kedari,
10 Àwọn ẹranko ńlá àti ẹran ọ̀sìn
gbogbo ohun afàyàfà àti àwọn ẹyẹ abìyẹ́:
11 Àwọn ọba ayé àti ènìyàn ayé gbogbo
àwọn ọmọ-aládé àti gbogbo àwọn onídàájọ́ ayé,
12 Ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin
àwọn arúgbó àti àwọn ọmọdé.
13 Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwa
nítorí orúkọ rẹ̀ nìkan ni ó ní ọlá
ògo rẹ̀ kọjá ayé àti ọ̀run
14 Ó sì gbé ìwo kan sókè fún àwọn ènìyàn rẹ̀,
ìyìn fún gbogbo ènìyàn mímọ́ rẹ̀ àní fún àwọn ọmọ Israẹli,
àwọn ènìyàn tí ó súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀.
Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
149 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa.
Ẹ yìn ín ní àwùjọ àwọn ènìyàn mímọ́.
2 Jẹ́ kí Israẹli kí ó ní inú dídùn sí ẹni tí ó dá a
jẹ́ kí àwọn ọmọ Sioni kí ó ní
ayọ̀ nínú ọba wọn.
3 Jẹ́ kí wọn kí ó fi ijó yin orúkọ rẹ̀
jẹ́ kí wọn kí ó fi ohun èlò orin kọrin ìyìn sí i.
4 Nítorí Olúwa ní inú dídùn sí àwọn ènìyàn rẹ̀
ó fi ìgbàlà dé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ládé
5 Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mímọ́ kí ó yọ̀ nínú ọlá rẹ̀
kí wọn kí ó máa kọrin fún ayọ̀ ní orí ibùsùn wọn.
6 Kí ìyìn Ọlọ́run kí ó wà ní ẹnu wọn
àti idà olójú méjì ní ọwọ́ wọn.
7 Láti gba ẹ̀san lára àwọn orílẹ̀-èdè,
àti ìjìyà lára àwọn ènìyàn,
8 Láti fi ẹ̀wọ̀n de àwọn ọba wọn
àti láti fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀
irin de àwọn ọlọ́lá wọn.
9 Láti ṣe ìdájọ́ tí àkọsílẹ̀ rẹ̀ sí wọn
èyí ni ògo àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀.
Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
150 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
Ẹ fi ìyìn fún Ọlọ́run ní ibi mímọ́ rẹ̀
Ẹ yìn ín nínú agbára ọ̀run rẹ̀.
2 Ẹ yìn ín fún iṣẹ́ agbára rẹ̀.
Ẹ yìn ín fún títóbi rẹ̀ tí ó tayọ̀.
3 Ẹ fi ohùn ìpè yìn ín.
Ẹ fi ohun èlò orin yìn ín.
4 Ẹ fi ohun èlò orin àti ijó yìn ín
fi ohun èlò orin olókùn àti ìpè yìn ín
5 Ẹ yìn ín pẹ̀lú aro olóhùn òkè,
Ẹ yìn ín lára aro olóhùn gooro.
6 Jẹ́ kí gbogbo ohun tí ó ní ẹ̀mí yin Olúwa.
Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
114 Nígbà tí Israẹli jáde ní Ejibiti,
ilé Jakọbu láti inú ènìyàn àjèjì èdè
2 Juda wà ní ibi mímọ́,
Israẹli wà ní ìjọba.
3 (A)Òkun sì rí i, ó sì wárìrì:
Jordani sì padà sẹ́yìn.
4 Àwọn òkè ńlá ń fò bí àgbò àti
òkè kéékèèkéé bí ọ̀dọ́-àgùntàn.
5 Kí ni ó ṣe ọ́, ìwọ Òkun, tí ìwọ fi wárìrì?
Ìwọ Jordani, tí ìwọ fi padà sẹ́yìn?
6 Ẹ̀yin òkè ńlá kí ló dé ti ẹ fi ń fò bí àgbò,
àti ẹ̀yin òkè kéékèèkéé bí ọ̀dọ́-àgùntàn?
7 Wárìrì, ìwọ ilẹ̀, níwájú Olúwa;
ní iwájú Ọlọ́run Jakọbu
8 tí ó sọ àpáta di adágún omi,
àti òkúta-ìbọn di orísun omi.
115 Kì í ṣe fún wa, Olúwa kì í ṣe fún wa,
ṣùgbọ́n fún orúkọ rẹ ni a fi ògo fún,
fún àánú àti òtítọ́ rẹ.
2 Torí kí ni àwọn kèfèrí yóò ṣe sọ pé,
níbo ni Ọlọ́run wa wà.
3 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wa wà lọ́run:
tí ó ń ṣe èyí tí ó wù ú.
4 (B)Fàdákà òun wúrà ni èrè àwọn aláìkọlà,
iṣẹ́ ọwọ́ ènìyàn ni,
5 Wọ́n ní ẹnu, ṣùgbọ́n wọn kò le sọ̀rọ̀,
wọ́n ní ojú, ṣùgbọ́n wọn kò fi ríran.
6 Wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbọ́rọ̀:
wọ́n ní imú, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbóòórùn
7 Wọ́n ní ọwọ́, ṣùgbọ́n wọn kò lò ó,
wọ́n ní ẹsẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò rìn;
bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sọ̀rọ̀ nínú òfin wọn.
8 Àwọn tí ń ṣe wọ́n dàbí wọn;
gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé wọn.
9 Ìwọ Israẹli gbẹ́kẹ̀lé Olúwa:
òun ni ìrànwọ́ àti ààbò wọn
10 Ẹ̀ yin ilé Aaroni, gbẹ́kẹ̀lé Olúwa:
òun ni ìrànwọ́ àti ààbò wọn
11 Ẹ̀ yin tí ó bẹ̀rù Olúwa, gbẹ́kẹ̀lé Olúwa:
òun ní ìrànwọ́ àti ààbò wọn.
12 Olúwa tí ń ṣe ìrántí wa; yóò bùkún ilé Israẹli;
yóò bùkún ilé Aaroni.
13 (C)Ìbùkún ni fún àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa,
àti kékeré àti ńlá.
14 Olúwa yóò mú ọ pọ̀ sí i síwájú àti síwájú,
ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ̀.
15 Ẹ fi ìbùkún fún Olúwa
ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé.
16 Ọ̀run àní ọ̀run ni ti Olúwa:
ṣùgbọ́n ayé ló fi fún ọmọ ènìyàn.
17 Òkú kò lè yìn Olúwa,
tàbí ẹni tí ó ti lọ sí ìsàlẹ̀ ìdákẹ́ jẹ́ẹ́.
18 Ṣùgbọ́n àwa ó fi ìbùkún fún Olúwa
láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.
Ẹ yin Olúwa.
Ègbé ni fún àwọn tí ara rọ̀
6 Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ará rọ̀ ní Sioni
àti ẹ̀yin tí ẹ wà ní abẹ́ ààbò ní òkè Samaria
àti ẹ̀yin olókìkí orílẹ̀-èdè
tí ẹ̀yin ènìyàn Israẹli máa ń tọ̀ ọ́ wá
2 Ẹ lọ Kalne kí ẹ lọ wò ó
kí ẹ sí tí ibẹ̀ lọ sí Hamati ìlú ńlá a nì.
Kí ẹ sì tún sọ̀kalẹ̀ lọ Gati ní ilẹ̀ Filistini
Ǹjẹ́ wọ́n ha dára ju ìpínlẹ̀ yín méjèèjì lọ?
Ǹjẹ́ a ha rí ilẹ̀ tó tóbi ju tiyín lọ bí?
3 Ẹ̀yin sún ọjọ́ ibi síwájú,
ẹ sì mú ìjọba òǹrorò súnmọ́ tòsí
4 Ẹ̀yin sùn lé ibùsùn tí a fi eyín erin ṣe
ẹ sì tẹ́ ara sílẹ̀ ni orí àwọn ibùsùn
ẹyin pa èyí tí o dára nínú àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn yín jẹ
ẹ sì ń pa àwọn ọ̀dọ́ màlúù láàrín agbo wọn jẹ
5 Ẹ̀yin ń lo ohun èlò orin bí i Dafidi
ẹ sì ń ṣe àwọn àpilẹ̀rọ àwọn ohun èlò orin
6 Ẹ̀yin mu wáìnì ẹ̀kún ọpọ́n kan
àti ìkunra tí o dára jùlọ
ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò káàánú ilé Josẹfu tí ó di ahoro
7 Nítorí náà, àwọn ni yóò lọ sí ìgbèkùn
pẹ̀lú àwọn tí ó ti kó lọ sí ìgbèkùn
àsè àwọn tí ń ṣe àṣelékè ni a ó mú kúrò.
Olúwa Kórìíra Ìgbéraga Ọmọ Israẹli
8 Olúwa Olódùmarè ti búra fúnrarẹ̀, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun sì ti wí pé:
“Mo kórìíra ìgbéraga Jakọbu
n kò sì ní inú dídùn sí odi alágbára rẹ̀
Èmi yóò sì fa ìlú náà lé wọn lọ́wọ́
àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀.”
9 Bí Ọkùnrin mẹ́wàá bá ṣẹ́kù nínú ilé kan, àwọn náà yóò kú 10 Bí ẹbí tí ó yẹ kí ó gbé òkú wọn jáde fún sínsin bá wọlé, bí o ba sì béèrè pé ǹjẹ́ ẹnìkan wa tí ó fi ara pamọ́ níbẹ̀, “Ǹjẹ́ ẹnìkankan wà lọ́dọ̀ yín?” tí ó bá sì dáhùn wí pé, “Rárá,” nígbà náà ni yóò wí pé, “Pa ẹnu rẹ mọ́ àwa kò gbọdọ̀ dárúkọ Olúwa.”
11 Nítorí Olúwa tí pa àṣẹ náà,
Òun yóò sì wó ilé ńlá náà lulẹ̀ túútúú
Àti àwọn ilé kéékèèkéé sí wẹ́wẹ́.
12 Ǹjẹ́ ẹṣin a máa sáré lórí àpáta bí?
Ǹjẹ́ ènìyàn a máa fi akọ màlúù kọ ilẹ̀ níbẹ̀?
Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti yí òtítọ́ padà sí májèlé
ẹ sì ti sọ èso òdodo di ìkorò.
13 Ẹ̀yin yọ̀ torí ìṣẹ́gun lórí Lo-Debari
Ẹ̀yin sì wí pé, “Ṣé kì í ṣe agbára wa ni àwa fi gba Karnaimu?”
14 Nítorí Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun wí pé,
“Èmi yóò gbé orílẹ̀-èdè kan dìde sí ọ ìwọ Israẹli,
wọn yóò pọ́n yín lójú ní gbogbo ọ̀nà,
láti Lebo-Hamati, títí dé pẹ̀tẹ́lẹ̀ Arabah.”
5 Àwọn nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ẹ̀rí pé òdodo ni ìdájọ́ Ọlọ́run àti pé nítorí èyí ni a ó kà yín yẹ fún ìjọba Ọlọ́run, nítorí èyí tí ẹ̀yin pẹ̀lú ṣe ń jìyà. 6 Olódodo ni Ọlọ́run: Òun yóò pọ́n àwọn tí ń pọ́n yín lójú, lójú, 7 Òun yóò sì fi ìtura fún ẹ̀yin tí a ti pọ́n lójú àti fún àwa náà pẹ̀lú. Èyí yóò sì ṣe nígbà ìfarahàn Jesu Olúwa láti ọ̀run wá fún wá nínú ọwọ́ iná pẹ̀lú àwọn angẹli alágbára. 8 (A)Òun yóò fi ìyà jẹ àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí ń ṣe àìgbọ́ràn sí ìhìnrere Jesu Olúwa wa. 9 A ó fi ìparun àìnípẹ̀kun jẹ wọ́n ní yà, a ó sì ṣe wọn mọ̀ kúrò níwájú Olúwa àti inú ògo agbára rẹ̀ 10 Ní ọjọ́ tí yóò jẹ́ ẹni tí a ó yìn lógo nínú àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ àti ẹni àwòyanu ní àárín gbogbo àwọn tí ó ti gbàgbọ́. Èyí kò yọ yín sílẹ̀, nítorí ẹ ti gba ẹ̀rí tí a jẹ́ sí yín gbọ́.
11 (B)Nítorí èyí, àwa pẹ̀lú ń gbàdúrà fún un yín nígbà gbogbo, pé kí Ọlọ́run wa kí ó lè kà yín yẹ fún ìpè rẹ̀, àti pé nípa agbára rẹ̀, òun yóò mú gbogbo èrò rere yín ṣẹ àti gbogbo ohun tí ìgbàgbọ́ bá rú jáde. 12 Wọ̀nyí ni àdúrà wa, kí orúkọ Jesu Olúwa wa lè di yíyìn lógo nínú yín àti ẹ̀yin nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run àti ti Jesu Kristi Olúwa.
Ìbí Johanu onítẹ̀bọmi
57 Nígbà tí ọjọ́ Elisabeti pé tí yóò bí; ó sì bí ọmọkùnrin kan. 58 Àwọn aládùúgbò, àti àwọn ìbátan rẹ̀ gbọ́ bí Olúwa ti fi àánú ńlá hàn fún un, wọ́n sì bá a yọ̀.
59 (A)Ó sì ṣe, ní ọjọ́ kẹjọ wọ́n wá láti kọ ọmọ náà nílà; wọ́n sì fẹ́ sọ orúkọ rẹ̀ ní Sekariah, gẹ́gẹ́ bí orúkọ baba rẹ̀. 60 Ìyá rẹ̀ sì dáhùn, ó ní, “Bẹ́ẹ̀ kọ́! Johanu ni a ó pè é.”
61 Wọ́n sì wí fún un pé, “Kò sí ọ̀kan nínú àwọn ará rẹ̀ tí à ń pè ní orúkọ yìí.”
62 Wọ́n sì ṣe àpẹẹrẹ sí baba rẹ̀, bí ó ti ń fẹ́ kí a pè é. 63 Ó sì béèrè fún wàláà, ó sì kọ ọ wí pé, “Johanu ni orúkọ rẹ̀.” Ẹnu sì ya gbogbo wọn. 64 Ẹnu rẹ̀ sì ṣí lọ́gán, okùn ahọ́n rẹ̀ sì tú, ó sì sọ̀rọ̀, ó sì ń yin Ọlọ́run. 65 Ẹ̀rù sì ba gbogbo àwọn tí ń bẹ ní agbègbè wọn: a sì ròyìn gbogbo nǹkan wọ̀nyí ká gbogbo ilẹ̀ òkè Judea. 66 Ó sì jẹ́ ohun ìyanu fún gbogbo àwọn tí ó gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n sì tò ó sínú ọkàn wọn, wọ́n ń wí pé, “Irú-ọmọ kín ni èyí yóò jẹ́?” Nítorí tí ọwọ́ Olúwa wà pẹ̀lú rẹ̀.
Orin Ṣakariah
67 Sekariah baba rẹ̀ sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó sì sọtẹ́lẹ̀, ó ní:
68 “Olùbùkún ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli;
nítorí tí ó ti bojú wò, tí ó sì ti dá àwọn ènìyàn rẹ̀ nídè,
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.