Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
ÌWÉ KẸRIN
Saamu 90–106
Àdúrà Mose ènìyàn Ọlọ́run
90 Olúwa, ìwọ ti jẹ́ ibùgbé wa ní gbogbo ìran dé ìran.
2 Kí a tó bí àwọn òkè ńlá
àti kí ìwọ tó dá ilẹ̀ àti ayé,
láti ayérayé dé ayérayé ìwọ ni Ọlọ́run.
3 Ìwọ yí ènìyàn padà sí erùpẹ̀,
wí pé “Padà sí erùpẹ̀, ìwọ ọmọ ènìyàn.”
4 (A)Nítorí pé ìgbà tí ẹgbẹ̀rún ọdún bá kọjá lójú rẹ,
bí àná ni ó rí, bí ìgbà ìṣọ́ kan lóru.
5 Ìwọ gbá ènìyàn dànù nínú oorun ikú;
wọ́n dàbí koríko tuntun ní òwúrọ̀.
6 Lóòtítọ́, ní òwúrọ̀, ó yọ tuntun
ní àṣálẹ́ ni yóò gbẹ, tí yóò sì rẹ̀ dànù.
7 A pa wá run nípa ìbínú rẹ
nípa ìbínú rẹ ara kò rọ̀ wá.
8 Ìwọ ti gbé ẹ̀ṣẹ̀ wa ka iwájú rẹ,
àti ohun ìkọ̀kọ̀ wa nínú ìmọ́lẹ̀ iwájú rẹ,
9 Gbogbo ọjọ́ wa ń kọjá lọ lábẹ́ ìbínú rẹ;
àwa ń lo ọjọ́ wa lọ bí àlá tí à ń rọ́.
10 Àádọ́rin ọdún ni iye ọjọ́ ọdún wá,
bi ó sì ṣe pé nípa agbára
tí wọn bá tó ọgọ́rin ọdún,
agbára nínú làálàá pẹ̀lú ìbànújẹ́ ni,
nítorí pé a kò ní pẹ́ gé e kúrò,
àwa a sì fò lọ.
11 Ta ni ó mọ agbára ìbínú rẹ?
Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rù rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ìbínú rẹ.
12 Kọ́ wa bí a ti ń kaye ọjọ́ wa dáradára,
kí àwa ba à lè fi ọkàn wa sípa ọgbọ́n.
13 Yípadà, Olúwa! Yóò ti pẹ́ tó?
Ṣàánú fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ.
14 Tẹ́ wa lọ́rùn ní òwúrọ̀ nínú ìṣeun ìfẹ́ rẹ,
kí àwa kí ó lè kọrin fún ayọ̀
kí inú wa sì dùn ní gbogbo ọjọ́.
15 Mú inú wa dùn bí ọjọ́ tí ìwọ ti pọ́n wa lójú,
fún ọjọ́ púpọ̀ tí àwa ti rí wàhálà.
16 Jẹ́ kí a fi iṣẹ́ rẹ̀ han àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀,
ògo rẹ̀ sí àwọn ọmọ wọn.
17 Jẹ́ kí ẹwà Olúwa Ọlọ́run wa wà lára wa;
fi ìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀ lára wa
bẹ́ẹ̀ ni, kí ó sì fi ìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀.
Àdúrà Dafidi
18 Dafidi ọba sì wọlé lọ, ó sì dúró níwájú Olúwa, ó sì wí pé:
“Olúwa Olódùmarè, ta ni èmi, àti kí sì ni ìdílé mi, tí ìwọ fi mú mi di ìsinsin yìí? 19 Nǹkan kékeré ni èyí sá à jásí lójú rẹ, Olúwa Olódùmarè; ìwọ sì ti sọ nípa ìdílé ìránṣẹ́ rẹ pẹ̀lú ní ti àkókò tí o jìnnà. Èyí ha ṣe ìwà ènìyàn bí, Olúwa Olódùmarè?
20 “Àti kín ní ó tún kù tí Dafidi ìbá tún máa wí fún ọ? Ìwọ, Olúwa Olódùmarè mọ̀ ìránṣẹ́ rẹ. 21 Nítorí ọ̀rọ̀ rẹ, àti gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ọkàn rẹ, ni ìwọ ṣe ṣe gbogbo nǹkan ńlá wọ̀nyí, kí ìránṣẹ́ rẹ lè mọ̀.
22 “Ìwọ sì tóbi, Olúwa Olódùmarè! Kò sì sí ẹni tí ó dàbí rẹ, kò sì sí Ọlọ́run kan lẹ́yìn rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí àwa fi etí wá gbọ́. 23 Orílẹ̀-èdè kan wo ni ó sì ń bẹ ní ayé tí ó dàbí àwọn ènìyàn rẹ, àní Israẹli, àwọn tí Ọlọ́run lọ rà padà láti sọ wọ́n di ènìyàn rẹ̀, àti láti sọ wọ́n ní orúkọ, àti láti ṣe nǹkan ńlá fún un yín, àti nǹkan ìyanu fún ilé rẹ̀, níwájú àwọn ènìyàn rẹ, tí ìwọ ti rà padà fún ara rẹ láti Ejibiti wá, àní àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn òrìṣà wọn. 24 Ìwọ sì fi ìdí àwọn ènìyàn rẹ, àní Israẹli kalẹ̀ fún ara rẹ láti sọ wọ́n di ènìyàn rẹ títí láé; ìwọ Olúwa sì wá di Ọlọ́run fún wọn.
25 “Ǹjẹ́, Olúwa Ọlọ́run, jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà tí ìwọ sọ ní ti ìránṣẹ́ rẹ, àti ní ti ìdílé rẹ̀, kí ó dúró títí láé, kí ó sí ṣe bí ìwọ ti wí. 26 Jẹ́ kí orúkọ rẹ ó ga títí láé, pé, ‘Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni Ọlọ́run lórí Israẹli!’ Sì jẹ́ kí a fi ìdílé Dafidi ìránṣẹ́ rẹ múlẹ̀ níwájú rẹ.
27 “Nítorí pé ìwọ, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli ti sọ létí ìránṣẹ́ rẹ, pé, ‘Èmí ó kọ́ ilé kan fún ọ.’ Nítorí náà ni ìránṣẹ́ rẹ sì ṣe ní i lọ́kàn rẹ̀ láti gbàdúrà yìí sí ọ. 28 Ǹjẹ́, Olúwa Olódùmarè, ìwọ ni Ọlọ́run náà, àwọn ọ̀rọ̀ rẹ sì jásí òtítọ́, ìwọ sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ nǹkan rere yìí fún ìránṣẹ́ rẹ. 29 Ǹjẹ́, jẹ́ kí ó wù ọ́ láti bùkún ìdílé ìránṣẹ́ rẹ, kí ó wà títí láé níwájú rẹ: nítorí ìwọ, Olúwa Olódùmarè, ni ó ti sọ ọ́: sì jẹ́ kí ìbùkún wà ní ìdílé ìránṣẹ́ rẹ títí láé, nípasẹ̀ ìbùkún rẹ.”
12 (A)“Kíyèsi i, èmi ń bọ̀ kánkán; èrè mí sì ń bẹ pẹ̀lú mi, láti sán fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ yóò tí rí. 13 (B)Èmi ni Alfa àti Omega, ẹni ìṣáájú àti ẹni ìkẹyìn, ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti òpin.
14 “Ìbùkún ni fún àwọn ti ń fọ aṣọ wọn, kí wọ́n lè ni ẹ̀tọ́ láti wá sí ibi igi ìyè náà, àti kí wọ́n lè gbà àwọn ẹnu ibodè wọ inú ìlú náà. 15 Nítorí ni òde ni àwọn ajá gbé wà, àti àwọn oṣó, àti àwọn àgbèrè, àti àwọn apànìyàn, àti àwọn abọ̀rìṣà, àti olúkúlùkù ẹni tí ó fẹ́ràn èké tí ó sì ń hùwà èké.
16 “Èmi, Jesu, ni ó rán angẹli mi láti jẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí fún yin ní tí àwọn ìjọ. Èmi ni gbòǹgbò àti irú-ọmọ Dafidi, àti ìràwọ̀ òwúrọ̀ tí ń tàn.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.