Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 107:1-3

ÌWÉ KARÙN-ÚN

Saamu 107–150

107 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó ṣeun;
    nítorí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé.

Jẹ́ kí àwọn ẹni ìràpadà Olúwa kí ó wí báyìí, àwọn
    ẹni tí ó rà padà kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá,
Àwọn tí ó kójọ láti ilẹ̀ wọ̀n-ọn-nì
    láti ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn,
    láti àríwá àti Òkun wá.

Saamu 107:17-22

17 Ọ̀pọ̀ di aṣiwèrè nítorí ìrékọjá wọn
    wọ́n sì pọ́n wọn lójú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn
18 Wọ́n kọ gbogbo oúnjẹ
    wọ́n sì súnmọ́ ẹnu-ọ̀nà ikú.
19 Nígbà náà wọ́n kígbe sí Olúwa nínú
    ìṣòro wọn, ó sì yọ wọ́n nínú ìdààmú wọn
20 Ó rán ọ̀rọ̀ rẹ̀, ara wọn sì dá
    ó sì yọ wọ́n nínú isà òkú.
21 Ẹ jẹ́ kí wọ́n fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fún ọmọ ènìyàn.
22 Jẹ́ kí wọn rú ẹbọ ọpẹ́
    kí wọn kí ó fi ayọ̀ sọ̀rọ̀ iṣẹ́ rẹ̀.

Daniẹli 12:5-13

Nígbà náà, ni èmi Daniẹli, wò, ní iwájú mi àwọn méjì mìíràn dúró, ọ̀kan dúró sí apá ìhín ní etí bèbè odò ẹnìkan náà ní apá òdìkejì ọ̀hún etí i bèbè. Ọ̀kan lára wọn sọ fún ọkùnrin tí ó wọ aṣọ àlà, ẹni tí ó wà lórí omi odò pé, “Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó kí àwọn nǹkan ìyanu wọ̀nyí tó wá sí ìmúṣẹ?”

(A)Ọkùnrin tí ó wọ aṣọ àlà, ẹni tí ó wà lórí omi odò, gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti ọwọ́ òsì rẹ̀, mo gbọ́ tí ó fi ẹni tí ó wà títí láé búra, ó sọ wí pé, “Yóò ṣe ní àkókò kan, àkókò méjì àti ààbọ̀. Nígbà tí agbára àwọn ẹni mímọ́ yóò ti fọ́ tán pátápátá, gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò sì parí.”

Èmi gbọ́, ṣùgbọ́n kò yé mi. Nígbà náà ni mo béèrè pé, “Olúwa mi, kí ni yóò jẹ́ àbábọ̀ àwọn nǹkan wọ̀nyí?”

Ó sì dáhùn pé, “Máa lọ ní ọ̀nà rẹ, Daniẹli nítorí tí a ti pa ọ̀rọ̀ náà dé, a sì ti fi èdìdì dì í di ìgbà ìkẹyìn. 10 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni a ó fọ̀ mọ́, wọn yóò wà láìlábàwọ́n, a ó sì tún wọn ṣe, ṣùgbọ́n àwọn ẹni búburú yóò máa ṣe búburú lọ, kò sí ẹni búburú tí òye yóò yé ṣùgbọ́n òye yóò yé àwọn ọlọ́gbọ́n.

11 (B)“Láti àkókò tí a ó mú ẹbọ ojoojúmọ́ kúrò, tí a ó sì gbé ìríra tí ó ń fa ìsọdahoro kalẹ̀ yóò sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún àti igba lé àádọ́rùn-ún ọjọ́ (1,290). 12 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó dúró, ti ó sì di òpin ẹgbẹ̀rún àti ọ̀ọ́dúnrún lé àrùndínlógójì ọjọ́ (1,335).

13 “Ṣùgbọ́n ìwọ, máa lọ ní ọ̀nà rẹ, títí di òpin. Ìwọ yóò sinmi, àti ní òpin ọjọ́ ìwọ yóò dìde láti gba èrè rẹ.”

Efesu 1:7-14

(A)Nínú rẹ̀ ni àwa rí ìràpadà gba nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ àti ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, ní ìbámu pẹ̀lú ọrọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run èyí tí ó fún wa lọ́pọ̀lọpọ̀ pẹ̀lú gbogbo ọgbọ́n àti ìmòye, Ó ti sọ ohun ìjìnlẹ̀ ìfẹ́ rẹ̀ di mí mọ̀ fún wa gẹ́gẹ́ bí ìdùnnú rere rẹ̀, èyí ti o pinnu nínú Kristi, 10 (B)èyí tí yóò jẹ jáde ní kíkún àkókò, láti ṣe àkójọpọ̀ àwọn ohun tí ọ̀run àti ti ayé lábẹ́ Kristi.

11 Nínú rẹ̀ ni a yàn wá fẹ́ lẹ́yìn tí ó ti yàn wá tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu ẹni tí ń ṣiṣẹ́ ohun gbogbo ní ìbámu ìfẹ́ rẹ̀, 12 kí àwa kí ó le wà fún ìyìn ògo rẹ̀, àwa tí a ti ni ìrètí ṣáájú nínú Kristi. 13 Àti ẹ̀yin pẹ̀lú darapọ̀ nínú Kristi nígbà tí ẹ̀yin gbọ́ ọ̀rọ̀ òtítọ́ náà àní ìhìnrere ìgbàlà yin. Nígbà tí ẹ̀yin gbàgbọ́, a fi Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe èdìdì ayé yin nínú rẹ, èyí tí a ti ṣe ìlérí rẹ̀ tẹ́lẹ̀, 14 (C)èyí tí ó jẹ́ ìdánilójú àṣansílẹ̀ ogún wa títí yóò fi di àkókò ìràpadà àwọn tí í ṣe ti Ọlọ́run sí ìyìn ògo rẹ̀.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.