Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
147 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
Nítorí ohun rere ni láti máa kọrin ìyìn sí Ọlọ́run wa,
ó yẹ láti kọrin ìyìn sí i!
2 Olúwa kọ́ Jerusalẹmu;
Ó kó àwọn Israẹli tí a lé sọnù jọ.
3 Ó wo àwọn tí ọkàn wọ́n bàjẹ́ sàn
ó sì di ọgbẹ́ wọ́n.
4 Ó ka iye àwọn ìràwọ̀
ó sì pe ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní orúkọ
5 Títóbi ni Olúwa wa ó sì pọ̀ ní agbára
òye rẹ̀ kò sì ní òpin.
6 Olúwa wa pẹ̀lú àwọn onírẹ̀lẹ̀
bẹ́ẹ̀ ni ó rẹ̀ àwọn ènìyàn búburú sílẹ̀.
7 Fi ọpẹ́ kọrin sí Olúwa
fi ohun èlò orin olókùn yin Ọlọ́run.
8 Ó fi ìkùùkuu bo àwọ̀ sánmọ̀
ó rọ òjò sí orílẹ̀ ayé
ó mú kí koríko hù lórí àwọn òkè
9 Ó pèsè oúnjẹ fún àwọn ẹranko
àti fún àwọn ọmọ ẹyẹ ìwò ní ìgbà tí wọ́n bá ń ké.
10 Òun kò ní inú dídùn nínú agbára ẹṣin
bẹ́ẹ̀ ni Òun kò ní ayọ̀ sí ẹ̀ṣẹ̀ ọkùnrin
11 Olúwa ni ayọ̀ nínú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
sí àwọn tí ó ní ìrètí nínú àánú rẹ̀.
20 Òun kó tí ṣe irú èyí sí orílẹ̀-èdè kan rí, Bí ó ṣe ti ìdájọ́ rẹ̀
wọn ko mọ òfin rẹ̀.
Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
10 Olódodo ènìyàn ń ṣe aájò ohun tí àwọn ohun ọ̀sìn rẹ̀ nílò,
ṣùgbọ́n ìyọ́nú àwọn ènìyàn búburú, ìkà ni.
11 Ẹni tí ó bá dá oko yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ,
ṣùgbọ́n ẹni tí ń lépa òjìji lásán làsàn kò gbọ́n.
12 Ènìyàn búburú ń fẹ́ ìkógun àwọn ènìyàn ìkà
ṣùgbọ́n gbòǹgbò olódodo ń gbilẹ̀.
13 A mú ènìyàn búburú nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀
ṣùgbọ́n olódodo bọ́ kúrò lọ́wọ́ ìdààmú.
14 Láti inú èso rẹ̀, ènìyàn kún fún onírúurú ohun rere
bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ti ń pín in lérè dájúdájú.
15 Ọ̀nà aláìgbọ́n dára lójú ara rẹ̀
ṣùgbọ́n ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa gba ìmọ̀ràn.
16 Aláìgbọ́n ènìyàn fi ìbínú un rẹ̀ hàn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀,
ṣùgbọ́n olóye ènìyàn fojú fo ìyànjẹ.
17 Ẹni tí ó jẹ́ ajẹ́rìí òtítọ́ jẹ́rìí ohun tí ojú rẹ̀ rí
ṣùgbọ́n ajẹ́rìí èké máa ń parọ́.
18 Ọ̀rọ̀ tí a kò rò jinlẹ̀ máa ń gún ni bí ọ̀kọ̀
ṣùgbọ́n ahọ́n ọlọ́gbọ́n ń mú ìwòsàn wá.
19 Ètè tí ń ṣọ òtítọ́ yóò wà láéláé
ṣùgbọ́n ahọ́n tí ń parọ́ kì í tọ́jọ́.
20 Ẹ̀tàn wà nínú ọkàn àwọn tí ń pète búburú
ṣùgbọ́n ayọ̀ wà fún àwọn tí ń mú kí àlàáfíà gbilẹ̀.
21 Ibi kì í ṣubú lu olódodo rárá
ṣùgbọ́n ènìyàn búburú gba ìpín ìyọnu tiwọn.
2 Kíyèsi i, èmi Paulu ni ó wí fún yín pé, bí a bá kọ yín nílà abẹ́, Kristi kì yóò lérè fún yín ní ohunkóhun. 3 Mo sì tún sọ fún olúkúlùkù ènìyàn tí a kọ ní ilà pé, ó di ajigbèsè láti pa gbogbo òfin mọ́. 4 A ti yà yín kúrò lọ́dọ̀ Kristi, ẹ̀yin tí ń fẹ́ kí a dá yín láre nípa òfin; pé ẹ ti ṣubú kúrò nínú oore-ọ̀fẹ́. 5 Nítorí nípa Ẹ̀mí àwa ń fi ìgbàgbọ́ dúró de ìrètí òdodo. 6 (A)Nítorí nínú Kristi Jesu, ìkọlà kò jẹ́ ohun kan, tàbí àìkọlà; ṣùgbọ́n ìgbàgbọ́ ti ń ṣiṣẹ́ nípa ìfẹ́.
7 Ẹ̀yin ti ń sáré dáradára. Ta ni dí yin lọ́wọ́ láti ṣe ìgbọ́ràn sí òtítọ́? 8 Ìyípadà yìí kò ti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó pè yín wá. 9 (B)Ìwúkàrà díẹ̀ ní í mú gbogbo ìyẹ̀fun wú. 10 Mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé sí yín nínú Olúwa pé, ẹ̀yin kì yóò ní èrò ohun mìíràn; ṣùgbọ́n ẹni tí ń yọ yín lẹ́nu yóò ru ìdájọ́ tirẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ó jẹ́. 11 Ṣùgbọ́n, ará, bí èmi bá ń wàásù ìkọlà síbẹ̀, kín ni ìdí tí a fi ń ṣe inúnibíni sí mi síbẹ̀? Ǹjẹ́ ìkọ̀sẹ̀ àgbélébùú ti kúrò. 12 Èmi ìbá fẹ́ kí àwọn tí ń yọ yín lẹ́nu tilẹ̀ gé ẹ̀yà ara wọn kan kúrò.
13 Nítorí a ti pè yín sí òmìnira, ará kìkì pé kí ẹ má ṣe lo òmìnira yín bí àǹfààní sípa ti ara, ṣùgbọ́n ẹ máa fi ìfẹ́ sin ọmọnìkejì yín. 14 (C)Nítorí pé a kó gbogbo òfin já nínú èyí pé, “Ìwọ fẹ́ ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” 15 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ń bu ara yín ṣán, tí ẹ sì ń jẹ ara yín run, ẹ kíyèsára kí ẹ má ṣe pa ara yín run.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.