Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Isaiah 60:1-6

Ògo Sioni

60 “Dìde, tànmọ́lẹ̀, nítorí ìmọ́lẹ̀ rẹ ti dé,
    ògo Olúwa sì ràdàbò ọ́.
Kíyèsi i, òkùnkùn bo ilẹ̀ ayé
    òkùnkùn biribiri sì wà lórí àwọn ènìyàn,
ṣùgbọ́n Olúwa ràn bò ọ́
    ògo rẹ̀ sì farahàn lórí i rẹ.
Àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá sí ìmọ́lẹ̀ rẹ,
    àti àwọn ọba sí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ rẹ.

“Gbé ojú rẹ sókè, kí o sì wò:
    Gbogbo wọn ṣa ara jọ pọ̀, wọ́n sì wá sọ́dọ̀ rẹ;
àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin yóò wá láti ọ̀nà jíjìn,
    àwọn ọmọ rẹ obìnrin ni a ó tọ́jú ní ẹ̀gbẹ́ rẹ.
Nígbà náà ni ìwọ yóò wò tí ojú rẹ yóò máa dán,
    ọkàn rẹ yó fò, yó sì kún fún ayọ̀;
ọrọ̀ inú Òkun ni a ó kò wá sọ́dọ̀ rẹ,
    sí ọ̀dọ̀ rẹ ni ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá.
(A)Ọ̀wọ́ ìbákasẹ yóò bo gbogbo ilẹ̀ rẹ,
    àwọn ọ̀dọ́ ìbákasẹ Midiani àti Efani.
Àti gbogbo wọn láti Ṣeba yóò wá,
    wọn yóò mú wúrà àti tùràrí lọ́wọ́
    tí wọn yóò sì máa kéde ìyìn Olúwa.

Saamu 72:1-7

Ti Solomoni

72 Fi ìdájọ́ fún àwọn ọba, Ọlọ́run,
    ọmọ-aládé ni ìwọ fi òdodo rẹ fún
Yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú òdodo,
    yóò sì máa fi ẹ̀tọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn tálákà rẹ̀.

Àwọn òkè ńlá yóò máa mú àlàáfíà fún àwọn ènìyàn
    àti òkè kéékèèkéé nípa òdodo
Yóò dáàbò bo àwọn tí a pọ́n lójú láàrín àwọn ènìyàn
    yóò gba àwọn ọmọ aláìní;
    yóò sì fa àwọn aninilára ya.
Àwọn òtòṣì àti aláìní
    yóò máa fi ọ̀wọ̀ ńlá fún ọ nígbà gbogbo,
níwọ̀n ìgbà tí oòrùn àti òṣùpá bá ń ràn,
    yóò ti pẹ́ tó, láti ìrandíran.
Yóò dàbí òjò tí ó ń rọ̀ sórí pápá ìrẹ́mọ́lẹ̀
    Bí ọwọ́ òjò tó ń rin ilẹ̀
Àwọn olódodo yóò gbilẹ̀ ni ọjọ́ rẹ̀
    ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà yóò sì wà;
    títí tí òṣùpá kò fi ní sí mọ́.

Saamu 72:10-14

10 Àwọn ọba Tarṣiṣi àti ti erékùṣù
    wọn yóò mú ọrẹ wá fún un;
àwọn ọba Ṣeba àti Seba
    wọn ó mú ẹ̀bùn wá fún un.
11 Gbogbo ọba yóò tẹríba fún un
    àti gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sìn ín.

12 Nítorí yóò gba àwọn aláìní
    nígbà tí ó bá ń ké,
tálákà àti ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́.
13 Yóò káàánú àwọn aláìlera àti aláìní
    yóò pa aláìní mọ́ kúrò nínú ikú.
14 Yóò ra ọkàn wọn padà lọ́wọ́ ẹ̀tàn àti ipá
    nítorí ẹ̀jẹ̀ wọn ṣọ̀wọ́n níwájú rẹ̀.

Efesu 3:1-12

Paulu jẹ́ oníwàásù sí àwọn aláìkọlà

Nítorí èyí náà ni èmi Paulu ṣe di òǹdè Jesu Kristi nítorí ẹ̀yin aláìkọlà.

(A)Lóòtítọ́ ẹ̀yin tilẹ̀ ti gbọ́ ti iṣẹ́ ìríjú oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, tí a fi fún mi fún yín; bí ó ti ṣe pé nípa ìfihàn ni ó ti fi ohun ìjìnlẹ̀ hàn fún mi gẹ́gẹ́ bí mo ti kọ ṣáájú ni ṣókí, Nígbà tí ẹ̀yin bá kà á, nípa èyí tí ẹ̀yin o fi lè mọ òye mi nínú ìjìnlẹ̀ Kristi. Èyí tí a kò í tí ì fihàn àwọn ọmọ ènìyàn rí nínú ìran mìíràn gbogbo, bí a ti fi wọ́n hàn nísinsin yìí fún àwọn aposteli rẹ̀ mímọ́ àti àwọn wòlíì nípa Ẹ̀mí; (B)pé, àwọn aláìkọlà jẹ́ àjùmọ̀jogún àti ẹ̀yà ara kan náà, àti alábápín ìlérí nínú Kristi Jesu nípa ìhìnrere.

Ìránṣẹ́ èyí tí a fi mi ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí a fi fún mi, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ agbára rẹ̀. Fún èmi tí o kéré jùlọ nínú gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́, ní a fi oore-ọ̀fẹ́ yìí fún, láti wàásù àwámárídìí ọ̀rọ̀ Kristi fún àwọn aláìkọlà; (C)àti láti mú kí gbogbo ènìyàn rí ohun tí iṣẹ́ ìríjú ohun ìjìnlẹ̀ náà jásí, èyí tí a ti fi pamọ́ láti ìgbà àtijọ́ nínú Ọlọ́run, ẹni tí ó dá ohun gbogbo nípa Jesu Kristi: 10 Kí a bá à lè fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ onírúurú ọgbọ́n Ọlọ́run hàn nísinsin yìí fún àwọn ìjòyè àti àwọn alágbára nínú àwọn ọ̀run, nípasẹ̀ ìjọ, 11 gẹ́gẹ́ bí ìpinnu ayérayé tí ó ti pinnu nínú Kristi Jesu Olúwa wa: 12 Nínú ẹni tí àwa ní ìgboyà, àti ọ̀nà pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé nípa ìgbàgbọ́ wa nínú rẹ̀.

Matiu 2:1-12

Ìbẹ̀wò àwọn amòye

(A)Lẹ́yìn ìgbà tí a bí Jesu ní Bẹtilẹhẹmu ti Judea, ni àkókò ọba Herodu, àwọn amòye ti ìlà-oòrùn wá sí Jerusalẹmu. (B)Wọ́n si béèrè pé, “Níbo ni ẹni náà tí a bí tí í ṣe ọba àwọn Júù wà? Àwa ti rí ìràwọ̀ rẹ̀ ní ìlà-oòrùn, a sì wá láti foríbalẹ̀ fún un.”

Nígbà tí ọba Herodu sì gbọ́ èyí, ìdààmú bá a àti gbogbo àwọn ara Jerusalẹmu pẹ̀lú rẹ̀ Nígbà tí ó sì pe àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin jọ, ó bi wọ́n léèrè níbi ti a ó gbé bí Kristi? (C)Wọ́n sì wí pé, “Ní Bẹtilẹhẹmu ti Judea, èyí ni ohun tí wòlíì ti kọ ìwé rẹ̀ pé:

(D)“ ‘Ṣùgbọ́n ìwọ Bẹtilẹhẹmu, ní ilẹ̀ Judea,
    ìwọ kò kéré jù láàrín àwọn ọmọ-aládé Juda;
nítorí láti inú rẹ ni Baálẹ̀ kan yóò ti jáde,
    Ẹni ti yóò ṣe ìtọ́jú Israẹli, àwọn ènìyàn mi.’ ”

Nígbà náà ni Herodu ọba pe àwọn amòye náà sí ìkọ̀kọ̀, ó sì wádìí ni ọwọ́ wọn, àkókò náà gan an tí wọ́n kọ́kọ́ rí ìràwọ̀. Ó sì rán wọn lọ sí Bẹtilẹhẹmu, ó sì wí pé, “Ẹ lọ ṣe ìwádìí fínní fínní ní ti ọmọ náà tí a bí. Lẹ́yìn tí ẹ bá sì rí i, ẹ padà wá sọ fún mi, kí èmi náà le lọ foríbalẹ̀ fún un.”

Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ọba, wọ́n mú ọ̀nà wọn pọ̀n, sì wò ó, ìràwọ̀ tí wọ́n ti rí láti ìhà ìlà-oòrùn wá, ó ṣáájú wọn, títí tí ó fi dúró lókè ibi tí ọmọ náà gbé wà. 10 Nígbà tí wọ́n sì rí ìràwọ̀ náà, ayọ̀ kún ọkàn wọn. 11 (E)Bí wọ́n tí wọ inú ilé náà, wọn rí ọmọ ọwọ́ náà pẹ̀lú Maria ìyá rẹ̀, wọ́n wólẹ̀, wọ́n foríbalẹ̀ fún un. Nígbà náà ni wọ́n tú ìṣúra wọn, wọ́n sì ta Jesu lọ́rẹ: wúrà, tùràrí àti òjìá. 12 (F)Nítorí pé Ọlọ́run ti kìlọ̀ fún wọn ní ojú àlá pé kí wọ́n má ṣe padà tọ Herodu lọ mọ́, wọ́n gba ọ̀nà mìíràn lọ sí ìlú wọn.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.