Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 28

Ti Dafidi.

28 Ìwọ Olúwa,
    mo ké pe àpáta mi;
    Má ṣe kọ etí dídi sí mi.
Tí ìwọ bá dákẹ́ sí mi,
    èmí yóò dàbí àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun.
Gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi fún àánú,
    bí mo ṣe ń ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́,
bí mo ṣe gbé àwọn ọwọ́ mi sókè
    sí ibi mímọ́ rẹ jùlọ.

Má ṣe fà mí lọ pẹ̀lú ènìyàn búburú àti,
    pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀,
tí ń sọ̀rọ̀ àlàáfíà sí aládùúgbò wọn
    ṣùgbọ́n tí ìwà ìkà ń bẹ nínú wọn.
San ẹ̀san wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn
    àti fún iṣẹ́ ibi wọn;
gba ẹ̀san wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn;
    kí o sì san ẹ̀san wọn bí ó ti tọ́.

Nítorí pé wọn kò ka iṣẹ́ Olúwa sí,
    tàbí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀
òun ó rún wọn wọlẹ̀
    kì yóò sì gbé wọn ró mọ́.

Alábùkún fún ni Olúwa!
    Nítorí pé ó ti gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.
Olúwa ni agbára mi àti asà mi;
    nínú rẹ̀ ni mo gbẹ́kẹ̀lé; àní, ó sì ràn mí lọ́wọ́.
Ọkàn mi sì gbé sókè fún ayọ̀
    àní pẹ̀lú orin mi mo fi ọpẹ́ fún un.

Olúwa ni agbára àwọn ènìyàn rẹ̀
    òun ni odi ìgbàlà àwọn ẹni ààmì òróró rẹ̀.
Ìwọ gba àwọn ènìyàn rẹ là, kí o sì bùkún àwọn ajogún rẹ;
    di olùṣọ́-àgùntàn wọn, kí o sì gbé wọn lékè títí ayérayé.

Jeremiah 31:10-14

10 “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin orílẹ̀-èdè
    ẹ kéde rẹ̀ ní erékùṣù jíjìn;
‘Ẹni tí ó bá tú Israẹli ká yóò kójọ,
    yóò sì ṣọ́ agbo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùntàn.’
11 Nítorí Olúwa ti tú Jakọbu sílẹ̀, o sì rà á padà
    ní ọwọ́ àwọn tí ó lágbára jù ú lọ
12 Wọn yóò wá, wọn ó sì hó ìhó ayọ̀ lórí òkè Sioni;
    wọn yóò yọ ayọ̀ níbi oore Olúwa.
Àlìkámà ni, ọtí wáìnì tuntun àti òróró
    ọ̀dọ́-àgùntàn àti ọ̀dọ́ ọ̀wọ́ ẹran.
Wọn ó dàbí ọgbà àjàrà tí a bomirin,
    ìkorò kò ní bá wọn mọ́.
13 Àwọn wúńdíá yóò jó, wọn ó sì kún fún ayọ̀,
    bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ọkùnrin àti obìnrin.
Èmi yóò sọ ọ̀fọ̀ wọn di ayọ̀,
    dípò ìkorò èmi yóò tù wọ́n nínú.
    Èmi ó sì fún wọn ní ayọ̀.
14 Èmi ó tẹ́ àwọn àlùfáà lọ́rùn pẹ̀lú ọ̀pọ̀;
    àwọn ènìyàn mi yóò sì kún fún oore mi,”
    ni Olúwa wí.

Johanu 5:19-40

19 (A)Nígbà náà ni Jesu dáhùn, ó sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ọmọ kò lè ṣe ohunkóhun fún ara rẹ̀, bí kò ṣe ohun tí ó bá rí pé Baba ń ṣe: nítorí ohunkóhun tí baba bá ń ṣe, ìwọ̀nyí ni ọmọ náà sì ń ṣe pẹ̀lú. 20 (B)Nítorí Baba fẹ́ràn ọmọ, ó sì ti fi ohun gbogbo tí ó ń ṣe hàn án, òun yóò sì fi iṣẹ́ tí ó tóbi jù wọ̀nyí lọ hàn án, kí ẹnu lè yà yín. 21 (C)Nítorí pé gẹ́gẹ́ bí Baba ti ń jí òkú dìde, tí ó sì ń sọ wọ́n di alààyè: bẹ́ẹ̀ ni ọmọ ń sọ àwọn tí ó fẹ́ di alààyè pẹ̀lú. 22 Nítorí pé Baba kì í ṣe ìdájọ́ ẹnikẹ́ni, ṣùgbọ́n ó ti fi gbogbo ìdájọ́ lé ọmọ lọ́wọ́: 23 (D)Kí gbogbo ènìyàn lè máa fi ọlá fún ọmọ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ń fi ọlá fún Baba. Ẹnikẹ́ni tí kò bá fi ọlá fún ọmọ, kò fi ọlá fún Baba tí ó ran an.

24 (E)“Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí ó bá sì gba ẹni tí ó rán mi gbọ́, ó ní ìyè tí kò nípẹ̀kun, òun kì yóò sì wá sí ìdájọ́; ṣùgbọ́n ó ti ré ikú kọjá bọ́ sí ìyè. 25 (F)Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, wákàtí náà ń bọ̀, ó sì dé tán nísinsin yìí, nígbà tí àwọn òkú yóò gbọ́ ohùn ọmọ Ọlọ́run: àwọn tí ó bá gbọ́ yóò sì yè. 26 Nítorí pé gẹ́gẹ́ bí Baba ti ní ìyè nínú ara rẹ̀; gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ó sì fi fún ọmọ láti ní ìyè nínú ara rẹ̀; 27 Ó sì fún un ní àṣẹ láti máa ṣe ìdájọ́ pẹ̀lú, nítorí tí òun jẹ́ ọmọ ènìyàn.

28 “Kí èyí má ṣe yà yín lẹ́nu; nítorí pé wákàtí ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí ó wà ní ibojì yóò gbọ́ ohun rẹ̀. 29 (G)Wọn ó sì jáde wá; àwọn tí ó ṣe rere, sí àjíǹde ìyè; àwọn tí ó sì ṣe búburú sí àjíǹde ìdájọ́. 30 (H)Èmi kò le ṣe ohun kan fún ara mi: bí mo ti ń gbọ́ ni, mo ń dájọ́: òdodo sì ni ìdájọ́ mi; nítorí èmi kò wá ìfẹ́ ti èmi fúnra mi, bí kò ṣe ìfẹ́ ti ẹni tí ó rán mi.

Àwọn ẹ̀rí nípa Jesu

31 (I)“Bí èmi bá ń jẹ́rìí ara mi, ẹ̀rí mi kì í ṣe òtítọ́. 32 Ẹlòmíràn ni ẹni tí ń jẹ́rìí mi; èmi sì mọ̀ pé, òtítọ́ ni ẹ̀rí mi tí ó jẹ́.

33 (J)“Ẹ̀yin ti ránṣẹ́ lọ sọ́dọ̀ Johanu, òun sì ti jẹ́rìí sí òtítọ́. 34 (K)Ṣùgbọ́n èmi kò gba jẹ́rìí lọ́dọ̀ ènìyàn: nǹkan wọ̀nyí ni èmi ń sọ, kí ẹ̀yin lè là. 35 Òun ni fìtílà tí ó ń jó, tí ó sì ń tànmọ́lẹ̀: ẹ̀yin sì fẹ́ fún sá à kan láti máa yọ̀ nínú ìmọ́lẹ̀ rẹ̀.

36 (L)“Ṣùgbọ́n èmi ní ẹ̀rí tí ó pọ̀jù ti Johanu lọ: nítorí iṣẹ́ tí Baba ti fi fún mi láti ṣe parí, iṣẹ́ náà pàápàá tí èmi ń ṣe náà ń jẹ́rìí mi pé, Baba ni ó rán mi. 37 Àti Baba tìkára rẹ̀ tí ó rán mi ti jẹ́rìí mi. Ẹ̀yin kò gbọ́ ohùn rẹ̀ nígbà kan rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò rí ìrísí rẹ̀. 38 Ẹ kò sì ní ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti máa gbé inú yín: nítorí ẹni tí ó rán, òun ni ẹ̀yin kò gbàgbọ́. 39 (M)Ẹ̀yin ń wá ìwé mímọ́ nítorí ẹ̀yin rò pé nínú wọn ni ẹ̀yin ní ìyè tí kò nípẹ̀kun. Wọ̀nyí sì ni àwọn tí ó ń jẹ́rìí mi. 40 Ẹ̀yin kò sì fẹ́ láti wá sọ́dọ̀ mi, kí ẹ̀yin ba à lè ní ìyè.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.