Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Orin fún ìgòkè.
123 Ìwọ ní mo gbé ojú mí sókè sí,
ìwọ tí ń gbé inú ọ̀run
2 Kíyèsi, bí ojú àwọn
ìránṣẹ́kùnrin ti máa ń wo ọwọ́ àwọn baba wọn,
àti bí ojú ìránṣẹ́bìnrin ti máa ń wo ọwọ́ ìyá rẹ̀
bẹ́ẹ̀ ni ojú wa ń wo Olúwa Ọlọ́run wa,
títí yóò fi ṣàánú fún wa.
3 Olúwa, ṣàánú fún wa, ṣàánú fún wa;
nítorí tí a kún fún ẹ̀gàn púpọ̀púpọ̀.
4 Ọkàn wa kún púpọ̀
fún ẹ̀gàn àwọn onírera,
àti fún ẹ̀gàn àwọn agbéraga.
16 Olúwa sì gbé àwọn onídàájọ́ dìde tí ó gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tí ń kó wọn lẹ́rú. 17 Síbẹ̀síbẹ̀ wọn kò fi etí sí ti àwọn onídàájọ́ wọn, ṣùgbọ́n wọ́n ṣe àgbèrè, wọ́n ń sin òrìṣà. Wọn kò dàbí àwọn baba wọn, kíákíá ni wọ́n yípadà kúrò lọ́nà tí àwọn baba wọ́n ń tọ̀, ọ̀nà ìgbọ́ràn sí àwọn òfin Olúwa. 18 Nígbà kí ìgbà tí Olúwa bá gbé onídàájọ́ dìde fún wọn, Olúwa máa ń wà pẹ̀lú onídàájọ́ náà, a sì gbà wọ́n kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá wọn ní ìwọ̀n ìgbà tí onídàájọ́ náà bá wà láààyè nítorí àánú Olúwa wà ní ara wọn, nígbà tí wọ́n bá ké ìrora lábẹ́ àwọn tí ń tẹrí wọn ba, tí sì ń fi ìyà jẹ wọ́n. 19 Ṣùgbọ́n ní kété tí onídàájọ́ bá ti kú, àwọn ènìyàn náà a sì tún padà sí ọ̀nà ìbàjẹ́ àní ju ti àwọn baba wọn lọ, wọn a tẹ̀lé òrìṣà, wọ́n ń sìn wọ́n, wọn a sì foríbalẹ̀ fún wọn, wọ́n kọ̀ láti yàgò kúrò ní ọ̀nà ibi wọn àti agídí ọkàn wọn.
20 Ìbínú Olúwa yóò sì tún ru sí Israẹli a sì wí pé, “Nítorí tí orílẹ̀-èdè yìí ti yẹ májẹ̀mú tí mo fi lélẹ̀ fún àwọn baba ńlá wọn, tí wọn kò sì fetí sí mi, 21 Èmi kì yóò lé ọ̀kankan nínú àwọn orílẹ̀-èdè tí Joṣua fi sílẹ̀ nígbà tí ó kú jáde. 22 Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀ èmi yóò lo àwọn orílẹ̀-èdè yìí láti fi dán Israẹli wò, láti mọ̀ bóyá wọ́n yóò pa ọ̀nà Olúwa mọ́ àti pé bóyá wọn ó rìn nínú rẹ̀ bí àwọn baba ńlá wọn ti rìn.” 23 Nítorí náà Olúwa fi àwọn orílẹ̀-èdè náà sílẹ̀ ní ilẹ̀ náà kò sì lé wọn jáde, tàbí kí ó jẹ́ kí àwọn Israẹli pa wọ́n run, bẹ́ẹ̀ kò sì fi wọ́n lé Joṣua lọ́wọ́.
8 Ẹ̀kẹrin sì tú ago tirẹ̀ sórí oòrùn; a sì yọ̀ǹda fún un láti fi iná jó ènìyàn lára. 9 A sì fi ooru ńlá jó àwọn ènìyàn lára, wọ́n sì sọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ Ọlọ́run, ẹni tí ó ní agbára lórí ìyọnu wọ̀nyí: wọn kò sì ronúpìwàdà láti fi ògo fún un.
10 (A)Ẹ̀karùnún sì tú ago tirẹ̀ sórí ìtẹ́ ẹranko náà; ilẹ̀ ọba rẹ̀ sì ṣókùnkùn; wọ́n sì ń gé ahọ́n wọn jẹ́ nítorí ìrora. 11 Wọ́n sì sọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run ọ̀run nítorí ìrora wọn àti nítorí egbò wọn, wọ́n kò sì ronúpìwàdà iṣẹ́ wọn.
12 (B)Ẹ̀kẹfà sì tu ìgò tirẹ̀ sórí odò ńlá Eufurate; omi rẹ̀ sì gbẹ, kí a lè pèsè ọ̀nà fún àwọn ọba láti ìlà-oòrùn wá. 13 (C)Mo sì rí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ mẹ́ta bí ọ̀pọ̀lọ́, wọ́n ti ẹnu dragoni náà àti ẹnu ẹranko náà àti ẹnu wòlíì èké náà jáde wá. 14 Nítorí ẹ̀mí èṣù ni wọ́n, tí ń ṣe iṣẹ́ ìyanu, àwọn tí ń jáde lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé, láti gbá wọn jọ sí ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè.
15 (D)“Kíyèsi i; ń bọ̀ bi olè, ìbùkún ni fún ẹni tí ń ṣọ́nà, tí ó sì ń pa aṣọ rẹ̀ mọ́, kí ó má bá a rìn ni ìhòhò, wọn a sì rí ìtìjú rẹ̀.”
16 (E)Ó sì gbá wọn jọ́ sí ibìkan tí a ń pè ní Amagedoni ní èdè Heberu.
17 (F)Èkeje si tú ago tirẹ̀ sí ojú ọ̀run; ohùn ńlá kan sì ti inú tẹmpili jáde láti ibi ìtẹ́, wí pé, “Ó parí!” 18 (G)Mọ̀nàmọ́ná sì kọ, a sì gbọ́ ohùn, àrá sì sán, ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá sì ṣẹ̀, irú èyí tí kò ṣẹ̀ ri láti ìgbà tí ènìyàn ti wà lórí ilẹ̀, irú ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá bẹ́ẹ̀, tí ó sì lágbára tó bẹ́ẹ̀. 19 Ìlú ńlá náà sì pín sí ipa mẹ́ta, àwọn orílẹ̀-èdè sì ṣubú: Babeli ńlá sì wá sí ìrántí níwájú Ọlọ́run, láti fi ago ọtí wáìnì ti ìrunú ìbínú rẹ̀ fún un. 20 Olúkúlùkù erékùṣù sì sálọ, a kò sì ri àwọn òkè ńlá mọ́. 21 (H)Yìnyín ńlá, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan rẹ̀ tó tálẹ́ǹtì ní ìwọ̀n, sì bọ́ lù àwọn ènìyàn láti ọ̀run wà: Àwọn ènìyàn sì sọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run nítorí ìyọnu yìnyín náà; nítorí tí ìyọnu rẹ̀ náà pọ̀ gidigidi.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.