Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Maskili ti Asafu.
78 Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ gbọ́ ẹ̀kọ́ mi;
tẹ́tí rẹ sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi.
2 (A)Èmi ó la ẹnu mi ní òwe,
èmi o sọ ohun ìkọ̀kọ̀, ohun ti ọjọ́ pípẹ́;
3 Ohun tí a ti gbọ́ tí a sì ti mọ̀,
ohun tí àwọn baba wa ti sọ fún wa.
4 Àwa kì yóò pa wọ́n mọ́
kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ,
ní fífi ìyìn Olúwa, àti ipa rẹ̀
àti iṣẹ́ ìyanu tó ti ṣe hàn
fún ìran tí ń bọ̀.
12 Ó ṣe ìyanu níwájú àwọn baba wọn ní ilẹ̀ Ejibiti, ní agbègbè Ṣoani.
13 Ó pín Òkun ní yà, ó sì mú wọn kọjá
Ó mù kí omi naà dúró bi odi gíga.
14 Ní ọ̀sán, ó fi ìkùùkuu àwọsánmọ̀ ṣe amọ̀nà wọn
àti ní gbogbo òru pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ iná.
15 Ó sán àpáta ní aginjù
ó sì fún wọn ní omi mímu lọ́pọ̀lọpọ̀
bí ẹni pé láti inú ibú wá.
16 Ó mú ìṣàn omi jáde láti inú àpáta
omi ṣíṣàn sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí odò.
17 Èyí ni ohun tí Olúwa wí
Olùdáǹdè rẹ, Ẹni Mímọ́ Israẹli:
“Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,
tí ó kọ́ ọ ní ohun tí ó dára fún ọ,
tí ó tọ́ ọ ṣọ́nà tí ó yẹ kí o máa rìn.
18 Bí ó bá ṣe pé ìwọ bá ti tẹ́tí sílẹ̀ sí àṣẹ mi,
àlàáfíà rẹ kì bá ti dàbí ì ti odò,
àti òdodo rẹ bí ìgbì Òkun.
19 Àwọn ọmọ rẹ ìbá ti dàbí iyanrìn,
àwọn ọmọ yín bí i hóró ọkà tí a kò lè kà tán;
orúkọ wọn ni a kì yóò ké kúrò
tàbí kí a pa wọ́n run níwájú mi.”
20 Fi Babeli sílẹ̀,
sá fún àwọn ará Babeli,
ṣe ìfilọ̀ èyí pẹ̀lú ariwo ayọ̀
kí o sì kéde rẹ̀.
Rán an jáde lọ sí òpin ilẹ̀ ayé;
wí pé, “Olúwa ti dá ìránṣẹ́ rẹ̀ Jakọbu nídè.”
21 Òrùngbẹ kò gbẹ wọ́n nígbà tí ó kó wọn
kọjá nínú aginjù;
ó jẹ́ kí omi ó sàn fún wọn láti inú àpáta;
ó fọ́ àpáta
omi sì tú jáde.
11 Ará, ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ ibi sí ara yín. Ẹni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ ibi sí arákùnrin rẹ̀, tí ó ń dá arákùnrin rẹ̀ lẹ́jọ́, ó ń sọ̀rọ̀ ibi sí òfin, ó sì ń dá òfin lẹ́jọ́; ṣùgbọ́n bí ìwọ bá ń dá òfin lẹ́jọ́, ìwọ kì í ṣe olùfẹ́ òfin, bí kò ṣe onídàájọ́. 12 Aṣòfin àti onídàájọ́ kan ṣoṣo ní ó ń bẹ, àní ẹni tí ó lè gbàlà tí ó sì le parun, ṣùgbọ́n ta ni ìwọ tí ó ń dá ẹnìkejì rẹ lẹ́jọ́?
Má ṣe ìlérí nípa ọjọ́ ọ̀la
13 Ẹ wá nísinsin yìí, ẹ̀yin tí ó ń wí pé, “Lónìí tàbí lọ́la àwa ó lọ sí ìlú báyìí, a ó sì ṣe ọdún kan níbẹ̀, a ó sì ṣòwò, a ó sì jèrè.” 14 Nígbà tí ẹ̀yin kò mọ ohun tí yóò hù lọ́la. Kí ni ẹ̀mí yín? Ìkùùkuu sá à ni yín, tí ó hàn nígbà díẹ̀, lẹ́yìn náà a sì túká lọ. 15 Èyí tí ẹ̀ bá fi wí pé, “Bí Olúwa bá fẹ́, àwa yóò wà láààyè, àwa ó sì ṣe èyí tàbí èyí i nì.” 16 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ̀yin ń gbéraga nínú ìfọ́nnu yín, gbogbo irú ìfọ́nnu bẹ́ẹ̀, ibi ni.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.