Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
114 Nígbà tí Israẹli jáde ní Ejibiti,
ilé Jakọbu láti inú ènìyàn àjèjì èdè
2 Juda wà ní ibi mímọ́,
Israẹli wà ní ìjọba.
3 (A)Òkun sì rí i, ó sì wárìrì:
Jordani sì padà sẹ́yìn.
4 Àwọn òkè ńlá ń fò bí àgbò àti
òkè kéékèèkéé bí ọ̀dọ́-àgùntàn.
5 Kí ni ó ṣe ọ́, ìwọ Òkun, tí ìwọ fi wárìrì?
Ìwọ Jordani, tí ìwọ fi padà sẹ́yìn?
6 Ẹ̀yin òkè ńlá kí ló dé ti ẹ fi ń fò bí àgbò,
àti ẹ̀yin òkè kéékèèkéé bí ọ̀dọ́-àgùntàn?
7 Wárìrì, ìwọ ilẹ̀, níwájú Olúwa;
ní iwájú Ọlọ́run Jakọbu
8 tí ó sọ àpáta di adágún omi,
àti òkúta-ìbọn di orísun omi.
14 Olúwa sọ fún Mose pé 2 “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli kí wọn padà sẹ́yìn, kí wọ́n sì pàgọ́ sí tòsí Pi-Hahirotu láàrín Migdoli òun Òkun, kí wọn kí ó pàgọ́ sí ẹ̀bá Òkun, ní òdìkejì Baali-Ṣefoni. 3 Farao yóò ronú pé àwọn ọmọ Israẹli ń ráre káàkiri ní ìdààmú ni àti wí pé aginjù náà ti sé wọn mọ́. 4 Èmi yóò sé ọkàn Farao le ti yóò fi lépa wọn. Ṣùgbọ́n èmi yóò gba ògo fún ará mi láti ìpàṣẹ Farao àti ogun rẹ̀, àti pé àwọn ará Ejibiti yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.” Àwọn Israẹli sì ṣe bẹ́ẹ̀.
5 Nígbà tí wọ́n sọ fún ọba Ejibiti pé àwọn ènìyàn náà ti sálọ, ọkàn Farao àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ yí padà sí àwọn ènìyàn, wọ́n sì wí pé, “Kí ni ohun tí àwa ṣe yìí? Àwa ti jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli kí ó lọ, a sì ti pàdánù ìsìnrú wọn.” 6 Ó sì di kẹ̀kẹ́-ẹṣin rẹ̀, ó sì kó àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, 7 ó mú ẹgbẹ̀ta (600) ọmọ-ogun oníkẹ̀kẹ́ tí ó jáfáfá jùlọ àti gbogbo ọmọ-ogun oníkẹ̀kẹ́ mìíràn ní Ejibiti, olórí sì wà fún olúkúlùkù wọn. 8 (A)Olúwa sé ọkàn Farao ọba Ejibiti le, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lépa àwọn ọmọ Israẹli ti ń jáde lọ ní àìbẹ̀rù. 9 Àwọn ará Ejibiti ń lépa wọn pẹ̀lú gbogbo ẹṣin kẹ̀kẹ́ ogun Farao àti àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀, wọ́n sì lé wọn bá ni ibi tí wọ́n pa àgọ́ sí lẹ́bàá Òkun ní ìhà Pi-Hahirotu, ni òdìkejì Baali-Ṣefoni.
10 Bí Farao ti súnmọ́ tòsí ọ̀dọ̀ wọn, àwọn ọmọ Israẹli gbé ojú wọn sókè, wọn sì rí àwọn ará Ejibiti tó súnmọ́ wọn. Ẹ̀rù ńlá sì bá àwọn ará Israẹli, wọ́n kígbe sókè sí Olúwa. 11 Wọ́n sọ fún Mose pé, “Ṣe nítorí pé kò sí ibojì ni Ejibiti ní ìwọ ṣe mú wa wá láti kú sínú aginjù? Kí ni èyí tí ìwọ ṣe sí wa ti ìwọ fi mú wa jáde láti Ejibiti wá? 12 (B)Ǹjẹ́ èyí kọ́ ni àwa sọ fún ọ ni Ejibiti, ‘Fi wá sílẹ̀, jẹ́ kí àwa máa sin ará Ejibiti’? Nítorí kò bá sàn fún wa kí a sin àwọn ará Ejibiti ju kí a kú sínú aginjù yìí lọ!”
13 Nígbà náà ni Mose sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ má bẹ̀rù, ẹ dúró ṣinṣin kí ẹ sì rí ìdáǹdè tí Olúwa yóò fi fún un yín lónìí; Àwọn ará Ejibiti ti ẹ̀yin rí lónìí ni ẹ kò ni tún padà rí wọn mọ́. 14 Olúwa yóò jà fún un yín; kí ẹ̀yin kí ó sá à mu sùúrù.”
15 Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń ké pè mí? Sọ fún àwọn ará Israẹli kí wọn máa tẹ̀síwájú. 16 Ṣùgbọ́n, gbé ọ̀pá rẹ̀ sókè, kí o sì na ọwọ́ rẹ sí orí omi Òkun, kí ó lè pín ní yà kí àwọn ọmọ Israẹli lè la Òkun kọjá ni orí ìyàngbẹ ilẹ̀. 17 Nígbà náà ni èmi yóò sé ọkàn àwọn ará Ejibiti le, wọn yóò sì máa lépa wọn; Èmi yóò gba ògo fún ara mi lórí Farao; lórí gbogbo ogun rẹ̀, lórí kẹ̀kẹ́ ogun àti lórí àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀. 18 Àwọn ará Ejibiti yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa nígbà ti èmi bá gba ògo fún ara mi lórí Farao: lórí kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ àti lórí àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀.”
9 (A)(B) “Àwọn baba ńlá sí ṣe ìlara Josẹfu, wọ́n sì tà á sí Ejibiti; ṣùgbọ́n Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀, 10 (C)ó sì yọ ọ́ kúrò nínú ìpọ́njú rẹ̀ gbogbo. Ó sì fún Josẹfu ní ọgbọ́n, ó sì mú kí ó rí ojúrere Farao ọba Ejibiti; òun sì fi jẹ baálẹ̀ Ejibiti àti gbogbo ilé rẹ̀.
11 (D)“Ìyàn kan sì mú ni gbogbo ilẹ̀ Ejibiti àti ni Kenaani, àti ìpọ́njú ńlá, àwọn baba wa kò sì rí oúnjẹ. 12 (E)Ṣùgbọ́n nígbà tí Jakọbu gbọ́ pé alikama ń bẹ ni Ejibiti, ó rán àwọn baba wa lọ lẹ́ẹ̀kínní. 13 (F)Nígbà kejì Josẹfu fi ara rẹ̀ hàn fún àwọn arákùnrin rẹ̀, a sì tún fi wọ́n hàn fún Farao. 14 (G)(H)Lẹ́yìn èyí, Josẹfu ránṣẹ́ pe Jakọbu baba rẹ̀, àti àwọn ìbátan rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ, gbogbo wọ́n sì tó àrùndínlọ́gọ́rin ọkàn. 15 Nígbà náà ni Jakọbu sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti, ní ibi tí òun àti àwọn baba wa kú sí. 16 (I)A sì gbé òkú wọn padà wá sí Ṣekemu, a sì tẹ́ wọn sínú ibojì ti Abrahamu rà ni ọwọ́ àwọn ọmọ Amori ní Ṣekemu ní iye owó wúrà kan.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.