Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
33 Ẹ yọ̀ nínú Olúwa, ẹ̀yin olódodo
ìyìn si yẹ fún ẹni dídúró ṣinṣin.
2 Ẹ yin Olúwa pẹ̀lú dùùrù;
ẹ máa fi ohun èlò olókùn mẹ́wàá kọrin sí i.
3 Ẹ kọ orin tuntun sí i;
ẹ máa fi ọgbọọgbọ́n lu ohun èlò orin sí i, pẹ̀lú ariwo.
4 Nítorí pé ọ̀rọ̀ Olúwa dúró ṣinṣin,
gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ ni à ń ṣe nínú òtítọ́.
5 Ó fẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ́;
ilé ayé kún fún ìdúró ṣinṣin àti àánú Olúwa.
6 Nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Olúwa ni a ṣe dá àwọn ọ̀run,
àti gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ogun wọn nípa ìmísí ẹnu rẹ̀.
7 Ó kó àwọn omi Òkun jọ gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó wà nínú ìgò;
ó sì fi ibú ṣe ilé ìṣúra gbogbo.
8 Jẹ́ kí gbogbo ayé kí ó bẹ̀rù Olúwa:
jẹ́ kí gbogbo àwọn olùgbé ayé kí ó wà nínú ìbẹ̀rù rẹ̀.
9 Nítorí tí ó sọ̀rọ̀, ó sì ti rí bẹ́ẹ̀; ó pàṣẹ
ó sì dúró ṣinṣin.
10 Olúwa ti mú ìmọ̀ràn àwọn orílẹ̀-èdè wá sí asán;
ó sì mú àrékérekè àwọn ènìyàn di ṣíṣákì í.
11 Ìgbìmọ̀ Olúwa dúró títí ayérayé,
àní ìrò inú rẹ̀ láti ìrandíran ni.
12 Ìbùkún ni fún orílẹ̀-èdè náà, Ọlọ́run ẹni tí Olúwa jẹ́ tirẹ̀,
àti àwọn ènìyàn náà tí ó ti yàn ṣe ìní rẹ̀.
17 (A)Nígbà tí Abramu ti ṣẹ́gun Kedorlaomeri àti àwọn ọba tí ó pẹ̀lú rẹ̀, ọba Sodomu lọ pàdé rẹ̀ ní Àfonífojì Ṣafe (èyí tí ó túmọ̀ sí Àfonífojì Ọba).
18 Melkisedeki ọba Salẹmu (Jerusalẹmu) sì mú oúnjẹ àti ọtí wáìnì jáde wá. Òun ni àlùfáà Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo. 19 Ó sì súre fún Abramu wí pé,
“Ìbùkún ni fún Abramu ti Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo
Ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé.
20 Ìbùkún sì ni fún Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo jùlọ,
tí ó fi àwọn ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́.”
Abramu sì fún un ní ìdámẹ́wàá ohun gbogbo.
21 Ọba Sodomu sì wí fún Abramu pé, “Kó àwọn ènìyàn mi fún mi, ṣùgbọ́n mú àwọn ẹrù fún ara rẹ.”
22 Ṣùgbọ́n Abramu dá ọba Sodomu lóhùn pé, “Mo ti búra fún Olúwa, Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo, tí ó dá ọ̀run àti ayé, mo sì ti gbọ́wọ́ sókè, 23 pé, èmi kì yóò mú láti fọ́nrán òwú títí dé okùn bàtà, àti pé, èmi kí yóò mú ohun kan tí ṣe tìrẹ, kí ìwọ kí ó má ba à wí pé, ‘Mo sọ Abramu di ọlọ́rọ̀.’ 24 Èmi kì yóò gba ohunkóhun yàtọ̀ sí ohun tí àwọn ọkùnrin mi ti jẹ́, ṣùgbọ́n fi ìpín fún àwọn ọkùnrin tí ó bá mi lọ, Aneri, Eṣkolu àti Mamre. Jẹ́ kí wọn kí ó gba ìpín wọn.”
Erékùṣù ni Mẹlita
28 Nígbà tí gbogbo wa sì yọ tan ni àwa tó mọ̀ pé, Mẹlita ni a ń pè erékùṣù náà. 2 Kì í ṣe oore díẹ̀ ni àwọn aláìgbédè náà ṣe fún wa: nítorí ti wọ́n dáná, wọ́n sì gbà gbogbo wa sí ọ̀dọ̀ nítorí òjò ń rọ nígbà náà, àti nítorí òtútù. 3 Nígbà tí Paulu sì ṣa ìdí ìṣẹ́pẹ́ igi jọ, ti ó sì kó o sínú iná, paramọ́lẹ̀ kan ti inú oru-iná jáde, ó di mọ́ ọn ní ọwọ́. 4 Bí àwọn aláìgbédè náà sì ti rí ẹranko olóró náà tí ó dì mọ́ ọn lọ́wọ́, wọ́n bá ara wọn sọ pé, “Dájúdájú apànìyàn ni ọkùnrin yìí, ẹni ti ó yọ nínú Òkun tan, ṣùgbọ́n tí ẹ̀san kò sì jẹ́ kí ó wà láààyè.” 5 Òun sì gbọn ẹranko náà sínú iná ohunkóhun kan kò sì ṣe é. 6 Ṣùgbọ́n wọn ń wòye ìgbà tí yóò wù, tàbí tí yóò sì ṣubú lulẹ̀ láti kú lójijì: nígbà tí wọ́n wò títí, tí wọn kò sì rí nǹkan kan kí ó ṣe é, wọ́n pa èrò wọn dà pé, òrìṣà kan ni ọkùnrin yìí.
7 Ní agbègbè ibẹ̀ ni ilé ọkùnrin ọlọ́lá erékùṣù náà wà, orúkọ ẹni tí a ń pè ní Pọbiliu; ẹni tí ó ti ipa inú rere gbà wá sí ọ̀dọ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta. 8 Ó sì ṣe, baba Pọbiliu dùbúlẹ̀ àìsàn ibà àti ìgbẹ́-ọ̀rìn; ẹni tí Paulu wọlé tọ̀ lọ, tí ó sì gbàdúrà fún, nígbà tí ó sì fi ọwọ́ lé e, ó sì mú un láradá. 9 Nígbà tí èyí sì ṣetán, àwọn ìyókù tí ó ni ààrùn ni erékùṣù náà tọ̀ ọ́ wá, ó sì mú wọn láradá. 10 Wọ́n sì bu ọlá púpọ̀ fún wa; nígbà tí a ń lọ, wọ́n sì fún wa ní ohun púpọ̀ tí a nílò ní ọ̀nà àjò wa.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.