Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 29

Saamu ti Dafidi.

29 Ẹ fi fún Olúwa, ẹ̀yin ẹ̀dá ọ̀run,
    Ẹ fi fún Olúwa, ògo àti alágbára.
Fi fún Olúwa, àní ògo orúkọ rẹ̀;
    sin Olúwa nínú ẹwà ìwà mímọ́.

Ohùn Olúwa n ré àwọn omi kọjá;
    Ọlọ́run ògo sán àrá,
    Olúwa san ara.
Ohùn Olúwa ní agbára;
    ohùn Olúwa kún fún ọláńlá.
Ohùn Olúwa fa igi kedari;
    Olúwa náà ló fọ́ igi kedari Lebanoni ya.
Ó mú Lebanoni fo bí i ọmọ màlúù,
    àti Sirioni bí ọmọ àgbáǹréré.
Ohùn Olúwa ń ya
    bí ọwọ́ iná mọ̀nà
Ohùn Olúwa ń mi aginjù.
    Olúwa mi aginjù Kadeṣi.
Ohùn Olúwa ní ó lọ igi óákù, ó n mú abo àgbọ̀nrín bí,
    ó sì bọ́ igi igbó sí ìhòhò.
Àti nínú tẹmpili rẹ̀ gbogbo ohùn wí pé “Ògo!”

10 Olúwa jókòó, Ó sì jẹ ọba lórí ìṣàn omi;
    Olúwa jókòó lórí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba títí láéláé.
11 Olúwa fi agbára fún àwọn ènìyàn rẹ̀;
    bùkún àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú àlàáfíà.

Jobu 38:39-39:12

39 “Ìwọ ha dẹ ọdẹ fún abo kìnnìún bí?
    Ìwọ ó sì tẹ ebi ẹgbọrọ kìnnìún lọ́rùn,
40 Nígbà tí wọ́n bá mọ́lẹ̀ nínú ihò
    tí wọ́n sì ba ní ibùba de ohun ọdẹ?
41 Ta ni ó ń pèsè ohun jíjẹ fún ẹyẹ ìwò,
    nígbà tí àwọn ọmọ rẹ ń ké pe Ọlọ́run,
    tí wọ́n sì máa ń fò kiri nítorí àìní ohun jíjẹ?

Agbára Ọlọ́run

39 “Ìwọ mọ àkókò ìgbà tí àwọn ewúrẹ́ orí àpáta ń bímọ?
    Ìwọ sì lè kíyèsi ìgbà tí abo àgbọ̀nrín ń bímọ?
Ìwọ lè ka iye òṣùpá tí wọn ń pé,
    ìwọ sì mọ àkókò ìgbà tí wọn ń bímọ,
Wọ́n tẹ ara wọn ba, wọ́n bímọ,
    wọ́n sì mú ìkáàánú wọn jáde.
Àwọn ọmọ wọn rí dáradára, wọ́n dàgbà nínú ọ̀dàn;
    wọ́n jáde lọ, wọn kò sì tún padà wá sọ́dọ̀ wọn.

“Ta ni ó jọ̀wọ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ oko lọ́wọ́?
    Tàbí ta ní ó tú ìdè kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó,
Èyí tí mo fi aginjù ṣe ilé fún,
    àti ilẹ̀ iyọ̀ ní ibùgbé rẹ̀.
Ó rẹ́rìn-ín sí ariwo ìlú,
    bẹ́ẹ̀ ni òun kò sì gbọ́ igbe darandaran.
Orí àtòlé òkè ńlá ni ibùjẹ oko rẹ̀,
    Òun a sì máa wá ewé tútù gbogbo rí.

“Àgbáǹréré ha jẹ́ sìn ọ́ bí?
    Tàbí ó jẹ́ dúró ní ibùjẹ ẹran rẹ ní òru?
10 Ìwọ le fi Òkun tata de àgbáǹréré nínú aporo?
    Tàbí ó jẹ́ máa fa ìtulẹ̀ nínú aporo oko tọ̀ ọ́ lẹ́yìn?
11 Ìwọ ó gbẹ́kẹ̀lé e nítorí agbára rẹ̀ pọ̀?
    Ìwọ ó sì fi iṣẹ́ rẹ lé e lọ́wọ́?
12 Ìwọ le gbẹ́kẹ̀lé pé, yóò mú èso oko rẹ̀ wá sílé,
    àti pé yóò sì kó ọ jọ sínú àká rẹ?

1 Kọrinti 12:1-3

Ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́

12 Ní ti Ẹ̀mí Mímọ́ ẹ̀yin ará, kò yẹ́ kí ẹ jẹ́ òpè. (A)Ẹ̀yin kò mọ̀ pé nígbà tí ẹ̀yin jẹ́ kèfèrí, a fà yín lọ sọ́dọ̀ àwọn odi òrìṣà. (B)Nítorí náà, èmí ń sọ fún un yín pé kò sí ẹni ti ń sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ẹ̀mí Ọlọ́run tí ó lè wí pé, “Ẹni ìfibú ni Jesu,” àti pé kò sí ẹni tí ó lè sọ pé, “Olúwa ni Jesu,” bí kò ṣe nípasẹ̀ Ẹ̀mí mímọ́.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.