Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu. Orin.
68 Kí Ọlọ́run kí ó dìde, kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ kí ó fọ́nká;
kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ kí ó sá níwájú rẹ̀.
2 Bí ìjì ti ń fẹ́ èéfín lọ,
kí ó fẹ́ wọn lọ;
bí ìda ti í yọ́ níwájú iná,
kí olùṣe búburú ṣègbé níwájú Ọlọ́run.
3 Ṣùgbọ́n kí inú olódodo kí ó dùn
kí ó sì kún fún ayọ̀ níwájú Ọlọ́run;
kí inú wọn kí ó dùn, kí ó sì kún fún ayọ̀.
4 Ẹ kọrin sí Ọlọ́run,
ẹ kọrin ìyìn sí i,
ẹ la ọ̀nà fún ẹni tí ń rékọjá ní aginjù.
Olúwa ni orúkọ rẹ̀, kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú rẹ̀.
5 Baba àwọn aláìní baba àti onídàájọ́ àwọn opó ni Ọlọ́run ní ibùgbé
rẹ̀ mímọ́
6 Ọlọ́run gbé aláìlera
kalẹ̀ nínú ìdílé,
ó darí àwọn ẹlẹ́wọ̀n pẹ̀lú orin,
ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́tẹ̀ ní ń gbé nínú ilẹ̀ gbígbẹ.
7 Nígbà tí ìwọ bá jáde lónìí níwájú àwọn ènìyàn rẹ, Ọlọ́run,
tí ń kọjá lọ láàrín aginjù, Sela.
8 Ilẹ̀ mì títí,
àwọn ọ̀run ń rọ òjò jáde,
níwájú Ọlọ́run,
ẹni Sinai,
níwájú Ọlọ́run, Ọlọ́run Israẹli.
9 Ìwọ fún wa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ òjò, Ọlọ́run;
ìwọ tu ilẹ̀ ìní rẹ̀ lára nígbà tí ó rẹ̀ ẹ́ tan.
10 Àwọn ènìyàn rẹ tẹ̀dó síbẹ̀
nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìní rẹ, Ọlọ́run, ìwọ pèsè fún àwọn aláìní.
19 Olùbùkún ni Olúwa,
Ọlọ́run Olùgbàlà wa,
ẹni tí ó ń fi ojoojúmọ́ gba ẹrù wa rù. Sela.
20 Ọlọ́run wa jẹ́ Ọlọ́run tó ń gbàlà
àti sí Olúwa Olódùmarè ni ó ń gbà wá lọ́wọ́ ikú.
16 “Bí mo bá fa ọwọ́ sẹ́yìn fún ìfẹ́ inú tálákà,
tàbí bí mo bá sì mú kí ojú opó rẹ̀wẹ̀sì,
17 Tàbí tí mo bá nìkan bu òkèlè mi jẹ,
tí aláìní baba kò jẹ nínú rẹ̀;
18 nítorí pé láti ìgbà èwe mi wá ni a ti tọ́ ọ dàgbà pẹ̀lú mi bí ẹni pé baba,
èmi sì ń ṣe ìtọ́jú opó láti inú ìyá mi wá:
19 Bí èmi bá rí olùpọ́njú láìní aṣọ,
tàbí tálákà kan láìní ìbora;
20 Bí ọkàn rẹ̀ kò bá súre fún mi,
tàbí bí ara rẹ̀ kò sì gbóná nípasẹ̀ irun àgùntàn mi;
21 Bí mo bá sì gbé ọwọ́ mi sókè sí aláìní baba,
nítorí pé mo rí ìrànlọ́wọ́ mi ní ẹnu ibodè,
22 Ǹjẹ́, ní apá mi kí o wọ́n kúrò ní ihò èjìká rẹ̀,
kí apá mi kí ó sì ṣẹ́ láti egungun rẹ̀ wá.
23 Nítorí pé ìparun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ni ẹ̀rù ńlá fún mi,
àti nítorí ọláńlá rẹ̀ èmi kò le è dúró.
Òkú obìnrin kan àti obìnrin aláìsàn kan
40 (A)Ó sì ṣe, nígbà tí Jesu padà lọ, àwọn ènìyàn tẹ́wọ́gbà á; nítorí tí gbogbo wọn ti ń retí rẹ̀. 41 Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan tí a ń pè ní Jairu, ọ̀kan nínú àwọn olórí Sinagọgu wá; ó sì wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ Jesu, ó bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó wá sí ilé òun: 42 Nítorí ó ní ọmọbìnrin kan ṣoṣo, ọmọ ìwọ̀n ọdún méjìlá, ti ó ń kú lọ.
Bí ó sì ti ń lọ àwọn ènìyàn ko fun ni ààyè. 43 Obìnrin kan tí ó sì ní ìsun ẹ̀jẹ̀ láti ìgbà ọdún méjìlá, tí ó ná ohun gbogbo tí ó ní fún àwọn oníṣègùn, tí kò sì sí ẹnìkan tí ó lè mú un láradá, 44 Ó wá sí ẹ̀yìn rẹ̀, ó fi ọwọ́ tọ́ ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀; lọ́gán ni ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì ti gbẹ.
45 (B)Jesu sì wí pé, “Ta ni ó fi ọwọ́ kàn mí?”
Nígbà tí gbogbo wọn sẹ́ Peteru àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sọ pé, “Olùkọ́, àwọn ènìyàn ko ní ààyè, wọ́n sì ń kọlù ọ́, ìwọ sì wí pé, Ta ni ó fi ọwọ́ kàn mi?”
46 (C)Jesu sì wí pé, “Ẹnìkan fi ọwọ́ kàn mí: nítorí tí èmí mọ̀ pé, àṣẹ jáde lára mi.”
47 Nígbà tí obìnrin náà sì mọ̀ pé òun kò fi ara sin, ó wárìrì, ó wá, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì sọ fún un lójú àwọn ènìyàn gbogbo nítorí ohun tí ó ṣe, tí òun fi fi ọwọ́ kàn án, àti bí a ti mú òun láradá lójúkan náà. 48 (D)Ó sì wí fún un pé, “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradá; máa lọ ní Àlàáfíà!”
49 Bí ó sì ti ń sọ̀rọ̀ lẹ́nu, ẹnìkan ti ilé olórí Sinagọgu wá, ó wí fún un pé, “Ọmọbìnrin rẹ kú; má yọ olùkọ́ni lẹ́nu mọ́.”
50 Ṣùgbọ́n nígbà tí Jesu gbọ́, ó dá a lóhùn, pé, “Má bẹ̀rù: sá gbàgbọ́ nìkan, a ó sì mú un láradá.”
51 Ṣùgbọ́n nígbà tí Jesu sì wọ ilé, kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni wọlé, bí kò ṣe Peteru, àti Jakọbu, àti Johanu, àti baba àti ìyá ọmọbìnrin náà. 52 Gbogbo wọn sì sọkún, wọ́n pohùnréré ẹkún rẹ̀: ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má sọkún mọ́; kò kú, sísùn ni ó sùn.”
53 Wọ́n sì fi í ṣẹ̀fẹ̀, wọ́n sá mọ̀ pé ó kú. 54 Nígbà tí ó sì sé gbogbo wọn mọ́ òde, ó mú un lọ́wọ́, ó sì wí pé, “Ọmọbìnrin, dìde!” 55 Ẹ̀mí rẹ̀ sì padà bọ̀, ó sì dìde lọ́gán: ó ní kí wọn fún un ní oúnjẹ. 56 (E)Ẹnu sì ya àwọn òbí rẹ̀: ṣùgbọ́n ó kìlọ̀ fún wọn pé, kí wọn má ṣe wí fún ẹnìkan ohun tí a ṣe.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.