Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu. Orin.
68 Kí Ọlọ́run kí ó dìde, kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ kí ó fọ́nká;
kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ kí ó sá níwájú rẹ̀.
2 Bí ìjì ti ń fẹ́ èéfín lọ,
kí ó fẹ́ wọn lọ;
bí ìda ti í yọ́ níwájú iná,
kí olùṣe búburú ṣègbé níwájú Ọlọ́run.
3 Ṣùgbọ́n kí inú olódodo kí ó dùn
kí ó sì kún fún ayọ̀ níwájú Ọlọ́run;
kí inú wọn kí ó dùn, kí ó sì kún fún ayọ̀.
4 Ẹ kọrin sí Ọlọ́run,
ẹ kọrin ìyìn sí i,
ẹ la ọ̀nà fún ẹni tí ń rékọjá ní aginjù.
Olúwa ni orúkọ rẹ̀, kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú rẹ̀.
5 Baba àwọn aláìní baba àti onídàájọ́ àwọn opó ni Ọlọ́run ní ibùgbé
rẹ̀ mímọ́
6 Ọlọ́run gbé aláìlera
kalẹ̀ nínú ìdílé,
ó darí àwọn ẹlẹ́wọ̀n pẹ̀lú orin,
ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́tẹ̀ ní ń gbé nínú ilẹ̀ gbígbẹ.
7 Nígbà tí ìwọ bá jáde lónìí níwájú àwọn ènìyàn rẹ, Ọlọ́run,
tí ń kọjá lọ láàrín aginjù, Sela.
8 Ilẹ̀ mì títí,
àwọn ọ̀run ń rọ òjò jáde,
níwájú Ọlọ́run,
ẹni Sinai,
níwájú Ọlọ́run, Ọlọ́run Israẹli.
9 Ìwọ fún wa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ òjò, Ọlọ́run;
ìwọ tu ilẹ̀ ìní rẹ̀ lára nígbà tí ó rẹ̀ ẹ́ tan.
10 Àwọn ènìyàn rẹ tẹ̀dó síbẹ̀
nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìní rẹ, Ọlọ́run, ìwọ pèsè fún àwọn aláìní.
19 Olùbùkún ni Olúwa,
Ọlọ́run Olùgbàlà wa,
ẹni tí ó ń fi ojoojúmọ́ gba ẹrù wa rù. Sela.
20 Ọlọ́run wa jẹ́ Ọlọ́run tó ń gbàlà
àti sí Olúwa Olódùmarè ni ó ń gbà wá lọ́wọ́ ikú.
9 Wọ́n já ọmọ aláìní baba kúrò ní ẹnu ọmú,
wọ́n sì gbà ọmọ tálákà nítorí gbèsè.
10 Wọ́n rìn kiri ní ìhòhò láìní aṣọ;
àwọn tí ebi ń pa rẹrù ìdì ọkà,
11 Àwọn ẹni tí ń fún òróró nínú àgbàlá wọn,
tí wọ́n sì ń tẹ ìfúntí àjàrà, síbẹ̀ òǹgbẹ sì ń gbẹ wọn.
12 Àwọn ènìyàn ń kérora láti ìlú wá,
ọkàn àwọn ẹni tí ó gbọgbẹ́ kígbe sókè fún ìrànlọ́wọ́
síbẹ̀ Ọlọ́run kò kíyèsi àṣìṣe náà.
13 “Àwọn ni ó wà nínú àwọn tí ó ṣọ̀tẹ̀ sí ìmọ́lẹ̀;
Wọn kò mọ̀ ipa ọ̀nà rẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dúró nípa ọ̀nà rẹ̀.
14 Apànìyàn a dìde ní àfẹ̀mọ́júmọ́,
a sì pa tálákà àti aláìní,
àti ní òru a di olè.
15 Ojú alágbèrè pẹ̀lú dúró kí ilẹ̀ ṣú díẹ̀;
‘Ó ní, ojú ẹnìkan kì yóò rí mi,’
ó sì fi ìbòjú bojú rẹ̀.
16 Ní òkùnkùn wọn á rúnlẹ̀ wọlé,
tí wọ́n ti fi ojú sọ fún ara wọn ní ọ̀sán,
wọn kò mọ̀ ìmọ́lẹ̀.
17 Nítorí pé bí òru dúdú ní òwúrọ̀ fún gbogbo wọn;
nítorí tí wọn sì mọ̀ ìbẹ̀rù òkùnkùn.
18 “Ó yára lọ bí ẹni lójú omi;
ìpín wọn ní ilé ayé ni a ó parun;
òun kò rìn lọ mọ́ ní ọ̀nà ọgbà àjàrà.
19 Gẹ́gẹ́ bi ọ̀dá àti òru ní í mú omi òjò-dídì yọ́,
bẹ́ẹ̀ ní isà òkú í run àwọn tó dẹ́ṣẹ̀.
20 Inú ìbímọ yóò gbàgbé rẹ̀, kòkòrò
ní yóò máa fi adùn jẹun lára rẹ̀,
a kì yóò rántí ènìyàn búburú
mọ́; Bẹ́ẹ̀ ní a ó sì ṣẹ ìwà búburú bí ẹní ṣẹ́ igi;
21 Ẹni tí o hù ìwà búburú sí àgàn tí
kò ṣe rere sí opó.
22 Ọlọ́run fi ipá agbára rẹ̀ fa alágbára,
bí wọ́n tilẹ̀ fìdímúlẹ̀, kò sí ìrètí ìyè fún wọn.
23 Ọlọ́run sì fi àìléwu fún un,
àti nínú èyí ni a ó sì tì i lẹ́yìn,
ojú rẹ̀ sì wà ní ipa ọ̀nà wọn.
24 A gbé wọn lékè nígbà díẹ̀, wọ́n kọjá lọ;
a sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀; A sì mú wọn kúrò ní ọ̀nà bí àwọn ẹlòmíràn,
a sì ké wọn kúrò bí orí síírí ọkà bàbà.
25 “Ǹjẹ́, bí kò bá rí bẹ́ẹ̀ nísinsin yìí, ta ni yóò mú mi ní èké,
tí yóò sì sọ ọ̀rọ̀ mi di aláìníláárí?”
Paulu tako Peteru
11 (A)Ṣùgbọ́n nígbà tí Peteru wá sí Antioku, mo takò ó lójú ara rẹ̀, nítorí tí ó jẹ̀bi, mo sì bá a wí. 12 Nítorí pé kí àwọn kan tí ó ti ọ̀dọ̀ Jakọbu wá tó dé, ó ti ń ba àwọn aláìkọlà jẹun; Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé, ó fàsẹ́yìn, ó sì ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn aláìkọlà nítorí ó bẹ̀rù àwọn ti ó kọlà. 13 Àwọn Júù tí ó kù pawọ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ láti jùmọ̀ ṣe àgàbàgebè, tó bẹ́ẹ̀ tí wọn sì fi àgàbàgebè wọn si Barnaba lọ́nà.
14 Nígbà tí mo rí i pé wọn kò rìn déédé gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ ìhìnrere, mo wí fún Peteru níwájú gbogbo wọn pé, “Bí ìwọ, tí ì ṣe Júù ba ń rìn gẹ́gẹ́ bí ìwà àwọn kèfèrí, èéṣe tí ìwọ fi ń fi agbára mu àwọn keferi láti máa rìn bí àwọn Júù?
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.