Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
99 Olúwa jẹ ọba;
jẹ́ kí ayé kí ó wárìrì
Ó jókòó lórí ìtẹ́ kérúbù
jẹ́ kí ayé kí ó wárìrì.
2 Olúwa tóbi ní Sioni;
Ó sì ga jù gbogbo orílẹ̀-èdè lọ.
3 Kí wọ́n sì yin orúkọ rẹ̀ tí ó tóbi
tí ó ni ẹ̀rù, Mímọ́ ni òun.
4 Ọba ní agbára, ó sì fẹ́ òdodo,
ìwọ fi ìdí àìṣègbè múlẹ̀;
ìwọ ṣe ohun tí ó tọ́ àti ohun tí ó yẹ nínú Jakọbu.
5 Gbígbéga ni Olúwa Ọlọ́run wa
ẹ foríbalẹ̀ níbi ẹsẹ̀ rẹ̀; ó jẹ́ mímọ́.
6 Mose àti Aaroni wà nínú àwọn àlùfáà rẹ̀
Samuẹli wà nínú àwọn tí ó ń ké pe orúkọ rẹ̀
wọ́n ké pe Olúwa, ó sì dá wọn lóhùn.
7 Ó sọ̀rọ̀ sí wọn nínú ọ̀wọ́n àwọsánmọ̀,
wọ́n pa ẹ̀rí rẹ̀ mọ́ àti ìlànà tí ó fún wọn.
8 Olúwa Ọlọ́run wa, ó dá wọn lóhùn;
ó jẹ́ Ọlọ́run tí ó ń dáríjì àwọn ọmọ Israẹli
ìwọ tí ó ń fi ìyà àìṣedéédéé wọn jẹ wọ́n
9 Gbígbéga ni Olúwa Ọlọ́run wa
kí a sìn ín ní òkè mímọ́ rẹ̀
nítorí Olúwa Ọlọ́run wa jẹ́ mímọ́.
41 Ní ọjọ́ kejì gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli kùn sí Mose àti Aaroni pé, “Ẹ ti pa àwọn ènìyàn Olúwa.”
42 Ṣùgbọ́n nígbà tí gbogbo ìjọ ènìyàn péjọ lòdì sí Mose àti Aaroni, níwájú àgọ́ ìpàdé, lójijì ni ìkùùkuu bolẹ̀, ògo Olúwa sì fi ara hàn. 43 Nígbà náà ni Mose àti Aaroni lọ síwájú àgọ́ ìpàdé, 44 Olúwa sì sọ fún Mose pé, 45 “Yàgò kúrò láàrín ìjọ ènìyàn yìí, kí ń ba le run wọ́n ní ìṣẹ́jú kan.” Wọ́n sì dojúbolẹ̀.
46 Mose sì sọ fún Aaroni pé, “Mú àwo tùràrí, kí o fi iná sí i lórí pẹpẹ, fi tùràrí sínú rẹ̀, kí o sì tètè mu lọ sí àárín ìjọ ènìyàn láti ṣe ètùtù fún wọn nítorí pé ìbínú Olúwa ti jáde, àjàkálẹ̀-ààrùn sì ti bẹ̀rẹ̀.” 47 Aaroni ṣe bí Mose ti wí, ó sáré lọ sí àárín àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n àjàkálẹ̀-ààrùn ti bẹ̀rẹ̀ láàrín wọn, ṣùgbọ́n Aaroni fín tùràrí, ó sì ṣe ètùtù fún wọn. 48 Ó dúró láàrín àwọn alààyè àti òkú, àjàkálẹ̀-ààrùn náà sì dúró. 49 Ṣùgbọ́n àjàkálẹ̀-ààrùn ti pa ẹgbàá-méje ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (14,700) ènìyàn ní àfikún sí àwọn tí ó kú níbi ìṣẹ̀lẹ̀ Kora. 50 Aaroni padà tọ Mose lọ ní ẹnu-ọ̀nà Àgọ́ Ìpàdé nítorí pé àjàkálẹ̀-ààrùn náà ti dúró.
7 Ṣùgbọ́n òpin ohun gbogbo kù sí dẹ̀dẹ̀; nítorí náà kí ẹ̀yin wà ní àìrékọjá, kí ẹ sì máa ṣọ́ra nínú àdúrà. 8 Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ẹ ní ìfẹ́ tí ó gbóná láàrín ara yín: nítorí ìfẹ́ ni ń bo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀. 9 Ẹ máa ṣe ara yín ni àlejò láìsí ìkùnsínú. 10 Bí olúkúlùkù ti rí ẹ̀bùn gbà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ máa ṣe ìpín fún ni rẹ̀ láàrín ara yín, bí ìríjú rere tí onírúurú oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run. 11 Bí ẹnikẹ́ni ba ń sọ̀rọ̀, kí o máa sọ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, bí ẹnikẹ́ni bá ń ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́, kí ó ṣe é bí agbára tí Ọlọ́run fi fún un, kí a lè máa yin Ọlọ́run lógo ní ohun gbogbo nípa Jesu Kristi, ẹni tí ògo àti ìjọba wà fún láé àti láéláé. Àmín.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.