Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 104:24-34

24 Iṣẹ́ rẹ ti pọ̀ tó, Olúwa!
    Nínú ọgbọ́n ni ìwọ ṣe gbogbo wọn:
    ayé kún fún àwọn ìṣẹ̀dá á rẹ.
25 Bẹ́ẹ̀ ni Òkun yìí tí ó tóbi, tí ó sì ni ìbú,
    tí ó kún fún àwọn ẹ̀dá alààyè ní ìsàlẹ̀ láìníye
    ohun alààyè tí tóbi àti kékeré.
26 Níbẹ̀ ni ọkọ̀ ń lọ síwá sẹ́yìn,
    àti Lefitani, tí ìwọ dá láti ṣe àríyá nínú rẹ̀.

27 Àwọn wọ̀nyí ń wò ọ́
    láti fún wọn ní oúnjẹ wọn lákòókò rẹ̀.
28 Nígbà tí ìwọ bá fi fún wọn,
    wọn yóò kó jọ;
nígbà tí ìwọ bá la ọwọ́ rẹ̀,
    a tẹ́ wọn lọ́rùn pẹ̀lú ohun rere.
29 Nígbà tí ìwọ bá pa ojú rẹ mọ́
    ara kò rọ̀ wọ́n
nígbà tí ìwọ bá mú ẹ̀mí wọn lọ,
    wọn ó kú, wọn ó sì padà sí erùpẹ̀.
30 Nígbà tí ìwọ rán ẹ̀mí rẹ,
    ni a dá wọn,
    ìwọ sì tún ojú ayé ṣe.

31 Jẹ́ kí ògo Olúwa wà pẹ́ títí láé;
    kí inú Olúwa kí ó dùn ní ti iṣẹ́ rẹ̀
32 Ẹni tí ó wo ayé, tí ó sì wárìrì,
    ẹni tí ó fọwọ́ tọ́ àwọn òkè, tí wọ́n yọ èéfín.

33 Ní gbogbo ayé mi ní n ó kọrin sí Olúwa:
    èmi ó kọrin ìyìn sí Olúwa
níwọ̀n ìgbà tí mo wà láààyè.
34 Jẹ́ kí ẹ̀kọ́ mi kí ó tẹ́ ọ lọ́rùn
    bí mo ti ń yọ̀ nínú Olúwa.

Saamu 104:35

35 Ṣùgbọ́n kí ẹlẹ́ṣẹ̀ kúrò láyé
    kí ènìyàn búburú má sì sí mọ́.

Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi.

Yin Olúwa.

Numeri 11:24-30

24 Mose sì jáde, ó sọ ohun tí Olúwa wí fún àwọn ènìyàn. Ó mú àwọn àádọ́rin (70) àgbàgbà Israẹli dúró yí àgọ́ ká. 25 Nígbà náà ni Olúwa sọ̀kalẹ̀ nínú ìkùùkuu ó sì bá wọn sọ̀rọ̀, ó sì mú lára Ẹ̀mí tó wà lára Mose sí ara àwọn àádọ́rin (70) àgbàgbà náà, Ó sì ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí Ẹ̀mí náà bà lé wọn, wọ́n sọtẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n lẹ́yìn èyí wọn kò sọtẹ́lẹ̀ mọ́.

26 Àwọn ọkùnrin méjì, tí orúkọ wọn ń jẹ́ Eldadi àti Medadi kò kúrò nínú àgọ́. Orúkọ wọn wà lára àádọ́rin (70) àgbàgbà yìí ṣùgbọ́n wọn kò jáde nínú àgọ́ síbẹ̀ Ẹ̀mí náà bà lé wọn, wọ́n sì sọtẹ́lẹ̀ nínú àgọ́. 27 Ọmọkùnrin kan sì sáré lọ sọ fún Mose pé, “Eldadi àti Medadi ń sọtẹ́lẹ̀ nínú àgọ́.”

28 Joṣua ọmọ Nuni tí í ṣe ìránṣẹ́ Mose, láti kékeré tó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ dáhùn pé, “Mose olúwa mi, dá wọn lẹ́kun!”

29 Mose sì wí fún un pé, “Àbí ìwọ ń jowú nítorí mi? Ìbá ti wù mí tó, kí gbogbo àwọn ènìyàn Olúwa jẹ́ wòlíì, kí Olúwa sì fi Ẹ̀mí rẹ̀ sí wọn lára!” 30 Mose àti àwọn àgbàgbà Israẹli yìí sì padà sínú àgọ́.

Johanu 7:37-39

37 (A)Lọ́jọ́ tó kẹ́yìn, tí í ṣe ọjọ́ ńlá àjọ, Jesu dúró, ó sì kígbe wí pé, “Bí òǹgbẹ bá ń gbẹ ẹnikẹ́ni, kí ó tọ̀ mí wá, kí ó sì mu. 38 (B)Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà mí gbọ́ gẹ́gẹ́ bí ìwé mímọ́ ti wí, láti inú rẹ̀ ni odò omi ìyè yóò ti máa sàn jáde wá.” 39 (C)(Ṣùgbọ́n ó sọ èyí ní ti ẹ̀mí, tí àwọn tí ó gbà á gbọ́ ń bọ̀ wá gbà: nítorí a kò tí ì fi ẹ̀mí mímọ́ fún ni; nítorí tí a kò tí ì ṣe Jesu lógo.)

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.