Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
118 (A)Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó dára;
àánú rẹ̀ dúró láéláé.
2 Jẹ́ kí Israẹli wí pé:
“Àánú rẹ̀ dúró láéláé”.
19 Ṣí ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà òdodo fún mi:
èmi yóò bá ibẹ̀ wọlé, èmi yóò sì fi ọpẹ́ fún Olúwa.
20 Èyí ni ìlẹ̀kùn Olúwa
ibẹ̀ ni àwọn olódodo yóò bá wọlé.
21 Èmi yóò fi ọpẹ́ fún ọ, nítorí ó dá mi lóhùn;
ìwọ sì di ìgbàlà mi.
22 (A)Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀,
ni ó di pàtàkì igun ilé;
23 Olúwa ti ṣe èyí,
ó ṣe ìyanu ní ojú wa.
24 Èyí ni ọjọ́ tí Olúwa dá:
ẹ jẹ́ kí ayọ̀ kí inú wa sì máa dùn nínú rẹ̀.
25 (B)Olúwa, gbà wá;
Olúwa, fún wa ní àlàáfíà.
26 Ìbùkún ni ẹni tí ń bọ̀ wá ní orúkọ Olúwa.
Àwa ti fi ìbùkún fún ọ láti ilé Olúwa wá.
27 Olúwa ni Ọlọ́run,
ó ti mú ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tàn sí wa lára
pẹ̀lú ẹ̀ka igi ní ọwọ́, ó dára pọ̀ mọ́
ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń wọ́ nínú ayọ̀
ẹ fi okùn di ẹbọ náà mọ́ ìwo pẹpẹ.
28 Ìwọ ni Ọlọ́run mi, èmi yóò máa fi ọpẹ́ fún ọ;
ìwọ ni Ọlọ́run mi, èmi yóò gbé ọ ga.
29 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó ṣeun;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
Fífi ayọ̀ wọlé
21 (A)Bí wọ́n ti súnmọ́ Jerusalẹmu, tí wọ́n dé itòsí ìlú Betfage ní orí òkè Olifi, Jesu sì rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì, 2 Ó wí fún wọn pé, “Ẹ lọ sí ìletò tó wà ni tòsí yín, ẹ̀yin yóò rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan ti wọ́n so pẹ̀lú ọmọ rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ẹ tú wọn, kí ẹ sì mú wọn wá fún mi. 3 Bí ẹnikẹ́ni bá sì béèrè ìdí tí ẹ fi ń ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ sá à wí pé, Olúwa fẹ́ lo wọn, òun yóò sì rán wọn lọ.”
4 Èyí ṣẹlẹ̀ láti mú àsọtẹ́lẹ̀ wòlíì ṣẹ pé:
5 (B)“Ẹ sọ fún ọmọbìnrin Sioni pé,
‘Wò ó, ọba rẹ ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ,
ní ìrẹ̀lẹ̀, ó ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,
àti lórí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.’ ”
6 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà sí lọ, wọ́n ṣe bí Jesu ti sọ fún wọn 7 Wọ́n sì mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà pẹ̀lú ọmọ rẹ̀, wọ́n tẹ́ aṣọ lé e, Jesu si jókòó lórí rẹ̀. 8 (C)Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì tẹ́ aṣọ wọn sí ojú ọ̀nà níwájú rẹ̀, ẹlòmíràn ṣẹ́ ẹ̀ka igi wẹ́wẹ́ wọ́n sì tẹ́ wọn sí ojú ọ̀nà. 9 (D)Ọ̀pọ̀ ènìyàn ń lọ níwájú rẹ̀ àti lẹ́yìn rẹ̀ pẹ̀lú ń kígbe pé,
“Hosana fún ọmọ Dafidi!”
“Olùbùkún ni fún ẹni tí ó ń bọ̀ ní orúkọ Olúwa!”
“Hosana ní ibi gíga jùlọ!”
10 Bí Jesu sì ti ń wọ Jerusalẹmu, gbogbo ìlú mì tìtì, àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí í bi ara wọn pé, “Ta nìyìí?”
11 (E)Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì dáhùn pé, “Èyí ni Jesu, wòlíì náà láti Nasareti ti Galili.”
4 Olúwa Olódùmarè ti fún mi ni ahọ́n tí a fi iṣẹ́ rán,
láti mọ àwọn ọ̀rọ̀ tí ó lè gbé àwọn aláàárẹ̀ ró.
O jí mi láràárọ̀,
o jí etí mi láti gbọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí à ń kọ́.
5 Olúwa Olódùmarè ti ṣí mi ní etí,
bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ṣọ̀tẹ̀ rí;
Èmi kò sì padà sẹ́yìn.
6 Mo ṣí ẹ̀yìn mi sílẹ̀ fún àwọn tí ó ń nà mí,
àti ẹ̀rẹ̀kẹ́ mi fún àwọn tí ń fa irùngbọ̀n mi;
Èmi kò fi ojú mi pamọ́
kúrò lọ́wọ́ ẹlẹ́yà àti ìyọṣùtì sí.
7 Nítorí Olúwa Olódùmarè ràn mí lọ́wọ́;
A kì yóò dójútì mí.
Nítorí náà ni mo ṣe gbé ojú mi ró bí òkúta akọ
èmi sì mọ pé, ojú kò ní tì mí.
8 Ẹni tí ó dá mi láre wà nítòsí.
Ta ni ẹni náà tí yóò fẹ̀sùn kàn mí?
Jẹ́ kí a kojú ara wa!
Ta ni olùfisùn mi?
Jẹ́ kí ó kò mí lójú!
9 Olúwa Olódùmarè ni ó ń ràn mí lọ́wọ́.
Ta ni ẹni náà tí yóò dá mi lẹ́bi?
Gbogbo wọn yóò gbó bí aṣọ;
kòkòrò ni yóò sì jẹ wọn run.
9 Ṣàánú fún mi, ìwọ Olúwa, nítorí mo wà nínú ìpọ́njú;
ojú mi fi ìbìnújẹ́ sùn,
ọkàn àti ara mi pẹ̀lú.
10 Èmi fi ìbànújẹ́ lo ọjọ́ mi
àti àwọn ọdún mi pẹ̀lú ìmí ẹ̀dùn;
agbára mi ti kùnà nítorí òsì mi,
egungun mi sì ti rún dànù.
11 Èmi di ẹni ẹ̀gàn láàrín àwọn ọ̀tá mi gbogbo,
pẹ̀lúpẹ̀lú láàrín àwọn aládùúgbò mi,
mo sì di ẹ̀rù fún àwọn ojúlùmọ̀ mi;
àwọn tí ó rí mi ní òde ń yẹra fún mi.
12 Èmi ti di ẹni ìgbàgbé kúrò ní ọkàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ti kú;
Èmi sì dàbí ohun èlò tí ó ti fọ́.
13 (A)Nítorí mo gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpayà tí ó yí mi ká;
tí wọn gbìmọ̀ pọ̀ sí mi,
wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí mi
láti gba ẹ̀mí mi.
14 Ṣùgbọ́n èmí gbẹ́kẹ̀lé ọ, ìwọ Olúwa
Mo sọ wí pé, “Ìwọ ní Ọlọ́run mi.”
15 Ìgbà mi ń bẹ ní ọwọ́ rẹ;
gbà mí kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá mi
àti àwọn onínúnibíni.
16 Jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí ìránṣẹ́ rẹ lára;
Gbà mí nínú ìfẹ́ rẹ tí ó dúró ṣinṣin.
5 (A)Nínú ìbáṣepọ̀ yin pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, ẹ ni irú ìlépa ọkàn náà bí ti Kristi Jesu.
6 Ẹni tí, bí o tilẹ̀ jẹ́ ìrísí Ọlọ́run,
kò kà á sí ohun tí ìbá fi ìwọra gbámú láti bá Ọlọ́run dọ́gba.
7 Ṣùgbọ́n ó bọ́ ògo rẹ̀ sílẹ̀,
ó sì mú àwọ̀ ìránṣẹ́,
a sì ṣe é ni àwòrán ènìyàn.
8 Ó sì wà ní àwòrán ènìyàn,
ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀,
o sì tẹríba títí de ojú ikú,
àní ikú lórí àgbélébùú.
9 (B)Nítorí náà, Ọlọ́run
ti gbé e ga sí ipele tí ó ga jùlọ,
ó sì ti fi orúkọ kan ti ó borí gbogbo orúkọ fún un
10 Pé ni orúkọ Jesu ni kí gbogbo eékún máa wólẹ̀,
ní ọ̀run, àti ní orí ilẹ̀ ayé àti ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé,
11 Àti pé kí gbogbo ahọ́n jẹ́wọ́ pé, Jesu Kristi ni Olúwa,
fún ògo Ọlọ́run Baba.
Judasi gbà láti fi Jesu hàn
14 (A)Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn aposteli méjìlá ti à ń pè ní Judasi Iskariotu lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà. 15 (B)Òun sì béèrè pé, “Kí ni ẹ̀yin yóò san fún mi bí mo bá fi Jesu lé yín lọ́wọ́?” Wọ́n sì fún un ní ọgbọ́n owó fàdákà. Ó sì gbà á. 16 Láti ìgbà náà lọ ni Judasi ti bẹ̀rẹ̀ sí i wá ọ̀nà láti fà á lé wọn lọ́wọ́.
Oúnjẹ alẹ́ ìkẹyìn
17 (C)Ní ọjọ́ kìn-ín-ní àjọ àìwúkàrà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tọ Jesu wá pé, “Níbo ni ìwọ fẹ́ kí a pèsè sílẹ̀ láti jẹ àsè ìrékọjá?”
18 (D)Jesu sì dáhùn pé, “Ẹ wọ ìlú lọ, ẹ̀yin yóò rí ọkùnrin kan, ẹ wí fún un pé, ‘Olùkọ́ wa wí pé: Àkókò mi ti dé. Èmi yóò sì jẹ àsè ìrékọjá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi ní ilé rẹ.’ ” 19 (E)Nítorí náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà ṣe gẹ́gẹ́ bí Jesu ti sọ fún wọn. Wọ́n sì tọ́jú oúnjẹ àsè ti ìrékọjá níbẹ̀.
20 (F)Ní àṣálẹ́ ọjọ́ kan náà, bí Jesu ti jókòó pẹ̀lú àwọn méjìlá, 21 nígbà tí wọ́n sì ń jẹun, ó wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ọ̀kan nínú yín yóò fi mí hàn.”
22 Ìbànújẹ́ sì bo ọkàn wọn nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bi í pé, “Olúwa, èmi ni bí?”
23 Jesu dáhùn pé, “Ẹni ti ó bá mi tọwọ́ bọ inú àwo, ni yóò fi mi hàn. 24 Ọmọ Ènìyàn ń lọ bí a ti kọ̀wé nípa rẹ̀: ṣùgbọ́n ègbé ni fún ọkùnrin náà lọ́wọ́ ẹni tí a ó ti fi Ọmọ ènìyàn hàn! Ìbá kúkú sàn fún ẹni náà, bí a kò bá bí.”
25 Judasi, ẹni tí ó fi í hàn pẹ̀lú béèrè pé, “Rabbi, èmi ni bí?”
Jesu sì dá a lóhùn pé, “Ìwọ wí i.”
26 (G)Bí wọ́n ti ń jẹun, Jesu sì mú ìwọ̀n àkàrà kékeré kan, lẹ́yìn tí ó ti gbàdúrà sí i, ó bù ú, Ó fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Ó wí pé, “Gbà, jẹ; nítorí èyí ni ara mi.”
27 Bákan náà, ó sì mú ago wáìnì, ó dúpẹ́ fún un, ó sì gbé e fún wọn. Ó wí pé, “Kí gbogbo yín mu nínú rẹ̀. 28 Nítorí èyí ni ẹ̀jẹ̀ mi tí májẹ̀mú tuntun, tí a ta sílẹ̀ fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn. 29 Sì kíyèsi àwọn ọ̀rọ̀ mi. Èmi kì yóò tún mu nínú ọtí wáìnì yìí mọ́ títí di ọjọ́ náà tí èmi yóò mu ún ní tuntun pẹ̀lú yín ní ìjọba Baba mi.”
30 (H)Wọ́n sì kọ orin kan, lẹ́yìn náà wọ́n lọ sórí òkè Olifi.
Jesu sọ pé Peteru yóò sẹ́ òun
31 (I)Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Gbogbo yín ni yóò kọsẹ̀ lára mi ní òru òní. Nítorí a ti kọ ọ́ pé:
“ ‘Èmi yóò kọlu olùṣọ́-àgùntàn
a ó sì tú agbo àgùntàn náà ká kiri.’
32 (J)Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí mo bá jí dìde, èmi yóò ṣáájú yín lọ sí Galili.”
33 Peteru sì dá a lóhùn pé, “Bí gbogbo ènìyàn tilẹ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀, èmi kì yóò ṣe bẹ́ẹ̀.”
34 Jesu wí fún un pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún ọ pé, ní òru yìí, kí àkùkọ kí ó tó kọ, ìwọ yóò sẹ́ mi nígbà mẹ́ta.”
35 Peteru wí fún un pé, “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ láti kú pẹ̀lú, èmi kò jẹ́ sẹ́ ọ.” Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wí.
Jesu ní Getsemane
36 (K)Nígbà náà ni Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sí ibi kan ti à ń pè ní ọgbà Getsemane, ó wí fún wọn pé, “Ẹ jókòó níhìn-ín nígbà tí mo bá lọ gbàdúrà lọ́hùn ún ni.” 37 Ó sì mú Peteru àti àwọn ọmọ Sebede méjèèjì Jakọbu àti Johanu pẹ̀lú rẹ̀, ìrora àti ìbànújẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí gba ọkàn rẹ̀. 38 (L)Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé, “Ọkàn mi gbọgbẹ́ pẹ̀lú ìbànújẹ́ títí dé ojú ikú, ẹ dúró níhìn-ín yìí, kí ẹ máa ṣọ́nà pẹ̀lú mi.”
39 (M)Òun lọ sí iwájú díẹ̀ sí i, ó sì dojúbolẹ̀, ó sì gbàdúrà pé, “Baba mi, bí ó bá ṣe é ṣe, jẹ́ kí a mú ago yìí ré mi lórí kọjá, ṣùgbọ́n ìfẹ́ tìrẹ ni mo fẹ́ kí ó ṣẹ, kì í ṣe ìfẹ́ tèmi.”
40 Bí ó ti padà sọ́dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, ó bá wọn, wọ́n ń sùn. Ó kígbe pé, “Peteru, ẹ̀yin kò tilẹ̀ lè bá mi ṣọ́nà fún wákàtí kan? 41 Ẹ máa ṣọ́ra, kí ẹ sì máa gbàdúrà kí ẹ̀yin má ba à bọ́ sínú ìdẹwò. Nítorí Ẹ̀mí ń fẹ́ nítòótọ́, ṣùgbọ́n ó ṣe àìlera fún ara.”
42 (N)Ó tún fi wọ́n sílẹ̀ nígbà kejì, ó sí gbàdúrà pé, “Baba mi, bí ago yìí kò bá lè ré mi lórí kọjá bí kò ṣe pé mo bá mu ún, ìfẹ́ tìrẹ ni kí a ṣe.”
43 Nígbà tí ó tún padà dé sọ́dọ̀ wọn, Ó rí i pé wọn ń sùn, nítorí ojú wọn kún fún oorun. 44 Nítorí náà, ó fi wọn sílẹ̀ ó tún padà lọ láti gbàdúrà nígbà kẹta, ó ń wí ohun kan náà.
45 (O)Nígbà náà ni ó tọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá, ó wí pé, “Àbí ẹ̀yin sì ń sùn síbẹ̀, ti ẹ sì ń sinmi? Wò ó wákàtí náà tí dé ti a ó fi Ọmọ ènìyàn lé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́. 46 Ẹ dìde! Ẹ jẹ́ kí a máa lọ! Ẹ wò ó, ẹni tí yóò fi mi hàn ń bọ̀ wá!”
A mú Jesu
47 (P)Bí ó ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Judasi, ọ̀kan nínú àwọn méjìlá dé pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ènìyàn pẹ̀lú idà àti kùmọ̀ lọ́wọ́ wọn, wọ́n ti ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà àti àgbàgbà Júù wá. 48 Ẹni tí ó sì fi í hàn ti fi ààmì fún wọn, pé, “Ẹnikẹ́ni tí mo bá fi ẹnu kò ní ẹnu, òun náà ni; ẹ mú un.” 49 Nísinsin yìí, Judasi wá tààrà sọ́dọ̀ Jesu, ó wí pé, “Àlàáfíà, Rabbi” ó fi ẹnu kò ó ní ẹnu.
50 (Q)Jesu wí pé, “Ọ̀rẹ́, kí ni nǹkan tí ìwọ bá wá.”
Àwọn ìyókù sì sún síwájú wọ́n sì mú Jesu. 51 Sì wò ó, ọ̀kan nínú àwọn tí ó wà pẹ̀lú Jesu na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fa idà yọ, ó sì sá ọ̀kan tí i ṣe ọmọ ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, ó sì gé e ní etí sọnù.
52 (R)Jesu wí fún un pé, “Fi idà rẹ bọ àkọ̀ nítorí àwọn tí ó ń fi idà pa ni a ó fi idà pa. 53 Ìwọ kò mọ̀ pé èmi lè béèrè lọ́wọ́ Baba mi kí ó fún mi ju légíónì (6,000) angẹli méjìlá? Òun yóò sì fi wọ́n ránṣẹ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. 54 Ṣùgbọ́n bí mo bá ṣe eléyìí ọ̀nà wo ni a ó fi mú Ìwé Mímọ́ ṣẹ, èyí tí ó ti sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nísinsin yìí?”
55 (S)Nígbà náà ni Jesu wí fún ìjọ ènìyàn náà pé, “Ǹjẹ́ èmi ni ẹ kà sí ọ̀daràn ti ẹ múra pẹ̀lú idà àti kùmọ̀ kí ẹ tó lé mú mi? Ẹ rántí pé mo ti wà pẹ̀lú yín, tí mo ń kọ́ yín lójoojúmọ́ nínú tẹmpili, ẹ̀yin kò sì mú mi nígbà náà. 56 Ṣùgbọ́n gbogbo wọ̀nyí ń ṣẹlẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí a tì ẹnu àwọn wòlíì sọ, tí a kọ sínú Ìwé Mímọ́ lè ṣẹ.” Nígbà yìí gan an ni gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì sálọ.
Níwájú Sahẹndiri
57 (T)Àwọn tí ó mú Jesu fà á lọ sí ilé Kaiafa, olórí àlùfáà, níbi ti àwọn olùkọ́ òfin àti gbogbo àwọn àgbàgbà Júù péjọ sí. 58 Ṣùgbọ́n Peteru ń tẹ̀lé e lókèèrè. Òun sì wá sí àgbàlá olórí àlùfáà. Ó wọlé, ó sì jókòó pẹ̀lú àwọn olùṣọ́. Ó ń dúró láti ri ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí Jesu.
59 Nígbà náà ni àwọn olórí àlùfáà àti gbogbo ìgbìmọ̀ Júù ní ilé ẹjọ́ tí ó ga jùlọ ti Júù péjọ síbẹ̀, wọ́n wá àwọn ẹlẹ́rìí tí yóò purọ́ mọ́ Jesu, kí a ba à lè rí ẹjọ́ rò mọ́ ọn lẹ́sẹ̀, eléyìí tí yóò yọrí si ìdájọ́ ikú fún un. 60 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹlẹ́rìí èké dìde, ṣùgbọ́n wọn kò rí ohun kan.
Níkẹyìn, àwọn ẹlẹ́rìí méjì dìde. 61 (U)Wọn wí pé, “Ọkùnrin yìí sọ pé, ‘Èmi lágbára láti wó tẹmpili Ọlọ́run lulẹ̀, èmi yóò sì tún un mọ ní ọjọ́ mẹ́ta.’ ”
62 Nígbà náà ni olórí àlùfáà sì dìde, ó wí fún Jesu pé, “Ẹ̀rí yìí ńkọ́? Ìwọ sọ bẹ́ẹ̀ tàbí ìwọ kò sọ bẹ́ẹ̀?” 63 (V)Ṣùgbọ́n Jesu dákẹ́ rọ́rọ́.
Nígbà náà ni olórí àlùfáà wí fún un pé, “Mo fi ọ́ bú ní orúkọ Ọlọ́run alààyè: Kí ó sọ fún wa, bí ìwọ bá í ṣe Kristi Ọmọ Ọlọ́run.”
64 (W)Jesu sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, ìwọ wí.” Ṣùgbọ́n mo wí fún gbogbo yín. “Ẹ̀yin yóò rí Ọmọ Ènìyàn ti yóò jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún alágbára, tí yóò sì máa bọ̀ wá láti inú ìkùùkuu.”
65 (X)Nígbà náà ni olórí àlùfáà fa aṣọ òun tìkára rẹ̀ ya. Ó sì kígbe pé, “Ọ̀rọ̀-òdì! Kí ni a tún ń wá ẹlẹ́rìí fún? Gbogbo yín ti gbọ́ ọ̀rọ̀-òdì rẹ̀. Kí ni ìdájọ́ yín?” 66 Ki ni ẹ ti rò èyí sí.
Gbogbo wọn sì kígbe lọ́hùn kan pé, “Ó jẹ̀bi ikú!”
67 Wọ́n tu itọ́ sí i ní ojú. Wọ́n kàn án lẹ́ṣẹ̀ẹ́. Àwọn ẹlòmíràn sì gbá a lójú. 68 Wọ́n wí pé, “Sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún wa! Ìwọ Kristi, Ta ni ẹni tí ó ń lù Ọ́?”
Peteru sẹ́ Jesu
69 Lákòókò yìí, bí Peteru ti ń jókòó ní àgbàlá, ọmọbìnrin kan sì tọ̀ ọ́ wá, ó ní, “Ìwọ wà pẹ̀lú Jesu ti Galili.”
70 Ṣùgbọ́n Peteru sẹ̀ ní ojú gbogbo wọn pé “Èmi kò tilẹ̀ mọ ohun tí ẹ ń sọ nípa rẹ̀.”
71 Lẹ́yìn èyí, ní ìta ní ẹnu-ọ̀nà, ọmọbìnrin mìíràn tún rí i, ó sì wí fún àwọn tí ó dúró yíká pé, “Ọkùnrin yìí wà pẹ̀lú Jesu ti Nasareti.”
72 Peteru sì tún sẹ́ lẹ́ẹ̀kejì pẹ̀lú ìbúra pé, “Èmi kò tilẹ̀ mọ ọkùnrin náà rárá.”
73 Nígbà tí ó pẹ́ díẹ̀, àwọn ọkùnrin tí ó ń dúró níbi ìran yìí tọ̀ ọ́ wá, wọ́n wí fún Peteru pé, “Lóòótọ́, ìwọ jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn, àwa mọ̀ ọ́n. Èyí sì dá wa lójú nípa ààmì ohùn rẹ̀ tí ó ń ti ẹnu rẹ jáde.”
74 Peteru sì tún bẹ̀rẹ̀ sí í búra ó sì fi ara rẹ̀ ré wí pé, “Mo ní èmi kò mọ ọkùnrin yìí rárá.”
Lójúkan náà àkùkọ sì kọ. 75 (Y)Nígbà náà ni Peteru rántí nǹkan tí Jesu ti sọ pé, “Kí àkùkọ tó ó kọ, ìwọ yóò sẹ́ mi nígbà mẹ́ta.” Òun sì bọ́ sí òde, ó sọkún kíkorò.
Judasi lọ pokùnso
27 (Z)Ní òwúrọ̀, gbogbo àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà Júù tún padà láti gbìmọ̀ bí wọn yóò ti ṣe pa Jesu. 2 Lẹ́yìn èyí, wọ́n fi ẹ̀wọ̀n dè é, wọ́n sì jọ̀wọ́ rẹ̀ fún Pilatu tí i ṣe gómìnà.
3 (AA)(AB) Nígbà tí Judasi, ẹni tí ó fi í hàn, rí i wí pé a ti dá a lẹ́bi ikú, ó yí ọkàn rẹ̀ padà, ó sì káàánú nípa ohun tí ó ṣe. Ó sì mú ọgbọ̀n owó fàdákà tí ó gba náà wá fún àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà Júù. 4 Ó wí pé, “Mo ti ṣẹ̀ nítorí tí mo ti ta ẹ̀jẹ̀ aláìlẹ́ṣẹ̀ sílẹ̀.”
Wọ́n dá a lóhùn pẹ̀lú ìbínú pé, “Èyí kò kàn wá! Wàhálà tìrẹ ni!”
5 Nígbà náà ni Judasi da owó náà sílẹ̀ nínú tẹmpili. Ó jáde, ó sì lọ pokùnso.
6 (AC)Àwọn olórí àlùfáà sì mú owó náà. Wọ́n wí pé, “Àwa kò lè fi owó yìí sínú owó ìkójọpọ̀. Ní ìwọ̀n ìgbà tí ó lòdì sí òfin wa nítorí pé owó ẹ̀jẹ̀ ni.” 7 Wọ́n sì gbìmọ̀, wọ́n sì fi ra ilẹ̀ amọ̀kòkò, láti máa sin òkú àwọn àjèjì nínú rẹ̀. 8 Ìdí nìyìí tí à ń pe ibi ìsìnkú náà ní “Ilẹ̀ Ẹ̀jẹ̀” títí di òní. 9 (AD)Èyí sì jẹ́ ìmúṣẹ èyí tí a ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu wòlíì Jeremiah wí pé, “Wọ́n sì mú ọgbọ̀n owó fàdákà tí àwọn ènìyàn Israẹli díye lé e. 10 Wọ́n sì fi ra ilẹ̀ kan lọ́wọ́ àwọn amọ̀kòkò gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ.”
Jesu níwájú Pilatu
11 (AE)Nígbà náà ni Jesu dúró níwájú baálẹ̀ láti gba ìdájọ́. Baálẹ̀ sì béèrè pé, “Ṣe ìwọ ni ọba àwọn Júù?”
Jesu dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, nítorí tí ìwọ wí i.”
12 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà Júù fi gbogbo ẹ̀sùn wọn kàn án, Jesu kò dáhùn kan. 13 Nígbà náà ni Pilatu, béèrè lọ́wọ́ Jesu pé, “Àbí ìwọ kò gbọ́ ẹ̀rí tí wọn ń wí nípa rẹ ni?” 14 (AF)Jesu kò sì tún dáhùn kan. Èyí sì ya baálẹ̀ lẹ́nu.
15 Ó jẹ́ àṣà gómìnà láti dá ọ̀kan nínú àwọn ẹlẹ́wọ̀n Júù sílẹ̀ lọ́dọọdún, ní àsìkò àjọ̀dún ìrékọjá. Ẹnikẹ́ni tí àwọn ènìyàn bá ti fẹ́ ni. 16 Ní àsìkò náà ọ̀daràn paraku kan wà nínú ẹ̀wọ̀n tí à ń pè Jesu Baraba. 17 Bí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti péjọ síwájú ilé Pilatu lówúrọ̀ ọjọ́ náà, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ta ni ẹ̀yin ń fẹ́ kí n dá sílẹ̀ fún yín, Baraba tàbí Jesu, ẹni tí ń jẹ́ Kristi?” 18 Òun ti mọ̀ pé nítorí ìlara ni wọn fi fà á lé òun lọ́wọ́.
19 (AG)Bí Pilatu sì ti ṣe jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́ rẹ̀, ìyàwó rẹ̀ ránṣẹ́ sí i pé, “Má ṣe ní ohun kankan ṣe pẹ̀lú ọkùnrin aláìṣẹ̀ náà. Nítorí mo jìyà ohun púpọ̀ lójú àlá mi lónìí nítorí rẹ̀.”
20 Ṣùgbọ́n àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà Júù rọ àwọn ènìyàn, láti béèrè kí a dá Baraba sílẹ̀, kí a sì béèrè ikú fún Jesu.
21 (AH)Nígbà tí Pilatu sì tún béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èwo nínú àwọn méjèèjì yìí ni ẹ̀ ń fẹ́ kí n dá sílẹ̀ fún yín?”
Àwọn ènìyàn sì kígbe padà pé, “Baraba!”
22 Pilatu béèrè pé, “Kí ni kí èmi ṣe sí Jesu ẹni ti a ń pè ní Kristi?”
Gbogbo wọn sì tún kígbe pé, “Kàn án mọ́ àgbélébùú!”
23 Pilatu sì béèrè pé, “Nítorí kí ni? Kí ló ṣe tí ó burú?”
Wọ́n kígbe sókè pé, “Kàn án mọ́ àgbélébùú! Kàn án mọ́ àgbélébùú!”
24 (AI)Nígbà tí Pilatu sì rí i pé òun kò tún rí nǹkan kan ṣe mọ́, àti wí pé rògbòdìyàn ti ń bẹ̀rẹ̀, ó béèrè omi, ó sì wẹ ọwọ́ rẹ̀ níwájú ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó wí pé, “Ọrùn mí mọ́ nípa ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin yìí. Ẹ̀yin fúnrayín, ẹ bojútó o!”
25 (AJ)Gbogbo àgbájọ náà sì ké pé, “Kí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wà lórí wa, àti ní orí àwọn ọmọ wa!”
26 Nígbà náà ni Pilatu dá Baraba sílẹ̀ fún wọn. Lẹ́yìn tí òun ti na Jesu tán, ó fi í lé wọn lọ́wọ́ láti mú un lọ kàn mọ́ àgbélébùú.
Àwọn ọmọ-ogun na Jesu
27 (AK)Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ogun gómìnà mú Jesu lọ sí gbọ̀ngàn ìdájọ́ wọ́n sì kó gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ-ogun tì í 28 Wọ́n tú Jesu sì ìhòhò, wọ́n sì wọ̀ ọ́ ní aṣọ òdòdó, 29 Wọ́n sì hun adé ẹ̀gún. Wọ́n sì fi dé e lórí. Wọ́n sì fi ọ̀pá sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀pá ọba. Wọ́n sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n fi í ṣe ẹlẹ́yà pé, “Kábíyèsí, ọba àwọn Júù!” 30 Wọ́n sì tu itọ́ sí i lójú àti ara, wọ́n gba ọ̀pá wọ́n sì nà án lórí. 31 Nígbà tí wọ́n fi ṣẹ̀sín tán, wọ́n bọ́ aṣọ ara rẹ̀. Wọ́n tún fi aṣọ tirẹ̀ wọ̀ ọ́. Wọ́n sì mú un jáde láti kàn án mọ́ àgbélébùú.
A kan Jesu mọ́ àgbélébùú
32 (AL)Bí wọ́n sì ti ń jáde, wọ́n rí ọkùnrin kan ará Kirene tí à ń pè ní Simoni. Wọ́n sì mú ọkùnrin náà ní túláàsì láti ru àgbélébùú Jesu. 33 (AM)Wọ́n sì jáde lọ sí àdúgbò kan tí à ń pè ní Gọlgọta, (èyí tí í ṣe Ibi Agbárí.) 34 Níbẹ̀ ni wọn ti fún un ni ọtí wáìnì tí ó ní egbòogi nínú láti mu. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó tọ́ ọ wò, ó kọ̀ láti mu ún. 35 (AN)Lẹ́yìn tí wọ́n sì ti kàn án mọ́ àgbélébùú, wọ́n dìbò láti pín aṣọ rẹ̀ láàrín ara wọn. 36 Nígbà náà ni wọ́n jókòó yí i ká. Wọ́n ń ṣọ́ ọ níbẹ̀. 37 Ní òkè orí rẹ̀, wọ́n kọ ohun kan tí ó kà báyìí pé:
“èyí ni jesu, ọba àwọn júù”
síbẹ̀. 38 Wọ́n kan àwọn olè méjì pẹ̀lú rẹ̀ ní òwúrọ̀ náà. Ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún, àti èkejì ní ọwọ́ òsì rẹ̀. 39 (AO)Àwọn tí ń kọjá lọ sì ń bú u. Wọ́n sì ń mi orí wọn pé: 40 (AP)“Ìwọ tí yóò wó tẹmpili, ìwọ tí yóò sì tún un mọ ní ọjọ́ kẹta. Bí ó bá jẹ́ pé Ọmọ Ọlọ́run ni ìwọ, sọ̀kalẹ̀ láti orí igi àgbélébùú, kí ó sì gba ara rẹ là!”
41 Bákan náà àwọn olórí àlùfáà pẹ̀lú àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn àgbàgbà Júù sì fi í ṣe ẹlẹ́yà. 42 Wọ́n kẹ́gàn rẹ̀ pé, “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là, kò sí lè gba ara rẹ̀. Ìwọ ọba àwọn Israẹli? Sọ̀kalẹ̀ láti orí àgbélébùú nísinsin yìí, àwa yóò sì gbà ọ́ gbọ́. 43 Ó gba Ọlọ́run gbọ́, jẹ́ kí Ọlọ́run gbà á là ní ìsinsin yìí tí òun bá fẹ́ ẹ. Ǹjẹ́ òun kò wí pé, èmi ni Ọmọ Ọlọ́run?” 44 Bákan náà, àwọn olè tí a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀ fi í ṣe ẹlẹ́yà.
Ikú Jesu
45 (AQ)Láti wákàtí kẹfà ni òkùnkùn fi ṣú bo gbogbo ilẹ̀ títí dé wákàtí kẹsànán ọjọ́ 46 (AR)Níwọ̀n wákàtí kẹsànán ní Jesu sì kígbe ní ohùn rara wí pé, “Eli, Eli, Lama Sabakitani” (ní èdè Heberu). Ìtumọ̀ èyí tí í ṣe, “Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀?”
47 Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò yé díẹ̀ nínú àwọn ẹni tí ń wòran, nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, Wọ́n wí pé ọkùnrin yìí ń pe Elijah.
48 (AS)Lẹ́sẹ̀kan náà, ọ̀kan nínú wọn sáré, ó mú kànìnkànìn, ó tẹ̀ ẹ́ bọ inú ọtí kíkan. Ó fi lé orí ọ̀pá, ó gbé e sókè láti fi fún un mu. 49 Ṣùgbọ́n àwọn ìyókù wí pé, “Ẹ fi í sílẹ̀. Ẹ jẹ́ kí a wò ó bóyá Elijah yóò sọ̀kalẹ̀ láti gbà á là.”
50 Nígbà tí Jesu sì kígbe ní ohùn rara lẹ́ẹ̀kan sí i, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀, ó sì kú.
51 (AT)Lójúkan náà aṣọ ìkélé tẹmpili fàya, láti òkè dé ìsàlẹ̀. Ilẹ̀ sì mì tìtì. Àwọn àpáta sì sán. 52 Àwọn isà òkú sì ṣí sílẹ̀. Ọ̀pọ̀ òkú àwọn ẹni mímọ́ tí ó ti sùn sì tún jíǹde. 53 Wọ́n jáde wá láti isà òkú lẹ́yìn àjíǹde Jesu, wọ́n sì lọ sí ìlú mímọ́. Níbẹ̀ ni wọ́n ti fi ara han ọ̀pọ̀ ènìyàn.
54 (AU)Nígbà tí balógun ọ̀run àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ tí wọ́n ń sọ Jesu rí bí ilẹ̀ ṣe mì tìtì àti ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ẹ̀rù bà wọn gidigidi, wọ́n wí pé, “Lóòótọ́ ọmọ Ọlọ́run ní í ṣe!”
55 Ọ̀pọ̀ obìnrin tí ó wá láti Galili pẹ̀lú Jesu láti tọ́jú rẹ̀ wọn ń wò ó láti òkèèrè. 56 (AV)Nínú àwọn obìnrin ti ó wà níbẹ̀ ni Maria Magdalene, àti Maria ìyá Jakọbu àti Josẹfu, àti ìyá àwọn ọmọ Sebede méjèèjì wà níbẹ̀ pẹ̀lú.
A tẹ́ Jesu sínú ibojì
57 (AW)Nígbà tí alẹ́ sì lẹ́, ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan láti Arimatea, tí à ń pè ní Josẹfu, ọ̀kan nínú àwọn tí ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn Jesu, 58 lọ sọ́dọ̀ Pilatu, ó sì tọrọ òkú Jesu. Pilatu sì pàṣẹ kí a gbé é fún un. 59 Josẹfu sì gbé òkú náà. Ó fi aṣọ funfun mímọ́ dì í. 60 Ó sì tẹ́ ẹ sínú ibojì òkúta tí ó gbẹ́ nínú àpáta fúnrarẹ̀. Ó sì yí òkúta ńlá dí ẹnu-ọ̀nà ibojì náà, ó sì lọ. 61 Maria Magdalene àti Maria kejì wà níbẹ̀, wọn jókòó òdìkejì ibojì náà.
Àwọn olùṣọ́ ní ibojì
62 Lọ́jọ́ kejì tí ó tẹ̀lé ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisi lọ sọ́dọ̀ Pilatu. 63 (AX)Wọ́n sọ fún un pé, “Alàgbà àwa rántí pé ẹlẹ́tàn nnì wí nígbà tí ó wà láyé pé, ‘Lẹ́yìn ọjọ́ kẹta èmi yóò tún jí dìde.’ 64 Nítorí náà, pàṣẹ kí a ti ibojì rẹ̀ gbọningbọnin títí ọjọ́ kẹta, kí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ má ṣe wá jí gbé lọ, wọn a sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún gbogbo ènìyàn pé, ‘Òun ti jíǹde,’ Bí èyí bá ní láti ṣẹlẹ̀, yóò burú fún wa púpọ̀ ju ti àkọ́kọ́ lọ.”
65 Pilatu sì pàṣẹ pé, “Ẹ lo àwọn olùṣọ́ yín kí wọn dáàbò bo ibojì náà bí ẹ bá ti fẹ́.” 66 (AY)Nítorí náà wọ́n lọ. Wọ́n sì ṣé òkúta ibojì náà dáradára. Wọ́n sì fi àwọn olùṣọ́ sí ibẹ̀ láti dáàbò bò ó.
Jesu níwájú Pilatu
11 (A)Nígbà náà ni Jesu dúró níwájú baálẹ̀ láti gba ìdájọ́. Baálẹ̀ sì béèrè pé, “Ṣe ìwọ ni ọba àwọn Júù?”
Jesu dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, nítorí tí ìwọ wí i.”
12 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà Júù fi gbogbo ẹ̀sùn wọn kàn án, Jesu kò dáhùn kan. 13 Nígbà náà ni Pilatu, béèrè lọ́wọ́ Jesu pé, “Àbí ìwọ kò gbọ́ ẹ̀rí tí wọn ń wí nípa rẹ ni?” 14 (B)Jesu kò sì tún dáhùn kan. Èyí sì ya baálẹ̀ lẹ́nu.
15 Ó jẹ́ àṣà gómìnà láti dá ọ̀kan nínú àwọn ẹlẹ́wọ̀n Júù sílẹ̀ lọ́dọọdún, ní àsìkò àjọ̀dún ìrékọjá. Ẹnikẹ́ni tí àwọn ènìyàn bá ti fẹ́ ni. 16 Ní àsìkò náà ọ̀daràn paraku kan wà nínú ẹ̀wọ̀n tí à ń pè Jesu Baraba. 17 Bí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti péjọ síwájú ilé Pilatu lówúrọ̀ ọjọ́ náà, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ta ni ẹ̀yin ń fẹ́ kí n dá sílẹ̀ fún yín, Baraba tàbí Jesu, ẹni tí ń jẹ́ Kristi?” 18 Òun ti mọ̀ pé nítorí ìlara ni wọn fi fà á lé òun lọ́wọ́.
19 (C)Bí Pilatu sì ti ṣe jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́ rẹ̀, ìyàwó rẹ̀ ránṣẹ́ sí i pé, “Má ṣe ní ohun kankan ṣe pẹ̀lú ọkùnrin aláìṣẹ̀ náà. Nítorí mo jìyà ohun púpọ̀ lójú àlá mi lónìí nítorí rẹ̀.”
20 Ṣùgbọ́n àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà Júù rọ àwọn ènìyàn, láti béèrè kí a dá Baraba sílẹ̀, kí a sì béèrè ikú fún Jesu.
21 (D)Nígbà tí Pilatu sì tún béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èwo nínú àwọn méjèèjì yìí ni ẹ̀ ń fẹ́ kí n dá sílẹ̀ fún yín?”
Àwọn ènìyàn sì kígbe padà pé, “Baraba!”
22 Pilatu béèrè pé, “Kí ni kí èmi ṣe sí Jesu ẹni ti a ń pè ní Kristi?”
Gbogbo wọn sì tún kígbe pé, “Kàn án mọ́ àgbélébùú!”
23 Pilatu sì béèrè pé, “Nítorí kí ni? Kí ló ṣe tí ó burú?”
Wọ́n kígbe sókè pé, “Kàn án mọ́ àgbélébùú! Kàn án mọ́ àgbélébùú!”
24 (E)Nígbà tí Pilatu sì rí i pé òun kò tún rí nǹkan kan ṣe mọ́, àti wí pé rògbòdìyàn ti ń bẹ̀rẹ̀, ó béèrè omi, ó sì wẹ ọwọ́ rẹ̀ níwájú ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó wí pé, “Ọrùn mí mọ́ nípa ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin yìí. Ẹ̀yin fúnrayín, ẹ bojútó o!”
25 (F)Gbogbo àgbájọ náà sì ké pé, “Kí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wà lórí wa, àti ní orí àwọn ọmọ wa!”
26 Nígbà náà ni Pilatu dá Baraba sílẹ̀ fún wọn. Lẹ́yìn tí òun ti na Jesu tán, ó fi í lé wọn lọ́wọ́ láti mú un lọ kàn mọ́ àgbélébùú.
Àwọn ọmọ-ogun na Jesu
27 (G)Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ogun gómìnà mú Jesu lọ sí gbọ̀ngàn ìdájọ́ wọ́n sì kó gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ-ogun tì í 28 Wọ́n tú Jesu sì ìhòhò, wọ́n sì wọ̀ ọ́ ní aṣọ òdòdó, 29 Wọ́n sì hun adé ẹ̀gún. Wọ́n sì fi dé e lórí. Wọ́n sì fi ọ̀pá sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀pá ọba. Wọ́n sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n fi í ṣe ẹlẹ́yà pé, “Kábíyèsí, ọba àwọn Júù!” 30 Wọ́n sì tu itọ́ sí i lójú àti ara, wọ́n gba ọ̀pá wọ́n sì nà án lórí. 31 Nígbà tí wọ́n fi ṣẹ̀sín tán, wọ́n bọ́ aṣọ ara rẹ̀. Wọ́n tún fi aṣọ tirẹ̀ wọ̀ ọ́. Wọ́n sì mú un jáde láti kàn án mọ́ àgbélébùú.
A kan Jesu mọ́ àgbélébùú
32 (H)Bí wọ́n sì ti ń jáde, wọ́n rí ọkùnrin kan ará Kirene tí à ń pè ní Simoni. Wọ́n sì mú ọkùnrin náà ní túláàsì láti ru àgbélébùú Jesu. 33 (I)Wọ́n sì jáde lọ sí àdúgbò kan tí à ń pè ní Gọlgọta, (èyí tí í ṣe Ibi Agbárí.) 34 Níbẹ̀ ni wọn ti fún un ni ọtí wáìnì tí ó ní egbòogi nínú láti mu. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó tọ́ ọ wò, ó kọ̀ láti mu ún. 35 (J)Lẹ́yìn tí wọ́n sì ti kàn án mọ́ àgbélébùú, wọ́n dìbò láti pín aṣọ rẹ̀ láàrín ara wọn. 36 Nígbà náà ni wọ́n jókòó yí i ká. Wọ́n ń ṣọ́ ọ níbẹ̀. 37 Ní òkè orí rẹ̀, wọ́n kọ ohun kan tí ó kà báyìí pé:
“èyí ni jesu, ọba àwọn júù”
síbẹ̀. 38 Wọ́n kan àwọn olè méjì pẹ̀lú rẹ̀ ní òwúrọ̀ náà. Ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún, àti èkejì ní ọwọ́ òsì rẹ̀. 39 (K)Àwọn tí ń kọjá lọ sì ń bú u. Wọ́n sì ń mi orí wọn pé: 40 (L)“Ìwọ tí yóò wó tẹmpili, ìwọ tí yóò sì tún un mọ ní ọjọ́ kẹta. Bí ó bá jẹ́ pé Ọmọ Ọlọ́run ni ìwọ, sọ̀kalẹ̀ láti orí igi àgbélébùú, kí ó sì gba ara rẹ là!”
41 Bákan náà àwọn olórí àlùfáà pẹ̀lú àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn àgbàgbà Júù sì fi í ṣe ẹlẹ́yà. 42 Wọ́n kẹ́gàn rẹ̀ pé, “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là, kò sí lè gba ara rẹ̀. Ìwọ ọba àwọn Israẹli? Sọ̀kalẹ̀ láti orí àgbélébùú nísinsin yìí, àwa yóò sì gbà ọ́ gbọ́. 43 Ó gba Ọlọ́run gbọ́, jẹ́ kí Ọlọ́run gbà á là ní ìsinsin yìí tí òun bá fẹ́ ẹ. Ǹjẹ́ òun kò wí pé, èmi ni Ọmọ Ọlọ́run?” 44 Bákan náà, àwọn olè tí a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀ fi í ṣe ẹlẹ́yà.
Ikú Jesu
45 (M)Láti wákàtí kẹfà ni òkùnkùn fi ṣú bo gbogbo ilẹ̀ títí dé wákàtí kẹsànán ọjọ́ 46 (N)Níwọ̀n wákàtí kẹsànán ní Jesu sì kígbe ní ohùn rara wí pé, “Eli, Eli, Lama Sabakitani” (ní èdè Heberu). Ìtumọ̀ èyí tí í ṣe, “Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀?”
47 Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò yé díẹ̀ nínú àwọn ẹni tí ń wòran, nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, Wọ́n wí pé ọkùnrin yìí ń pe Elijah.
48 (O)Lẹ́sẹ̀kan náà, ọ̀kan nínú wọn sáré, ó mú kànìnkànìn, ó tẹ̀ ẹ́ bọ inú ọtí kíkan. Ó fi lé orí ọ̀pá, ó gbé e sókè láti fi fún un mu. 49 Ṣùgbọ́n àwọn ìyókù wí pé, “Ẹ fi í sílẹ̀. Ẹ jẹ́ kí a wò ó bóyá Elijah yóò sọ̀kalẹ̀ láti gbà á là.”
50 Nígbà tí Jesu sì kígbe ní ohùn rara lẹ́ẹ̀kan sí i, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀, ó sì kú.
51 (P)Lójúkan náà aṣọ ìkélé tẹmpili fàya, láti òkè dé ìsàlẹ̀. Ilẹ̀ sì mì tìtì. Àwọn àpáta sì sán. 52 Àwọn isà òkú sì ṣí sílẹ̀. Ọ̀pọ̀ òkú àwọn ẹni mímọ́ tí ó ti sùn sì tún jíǹde. 53 Wọ́n jáde wá láti isà òkú lẹ́yìn àjíǹde Jesu, wọ́n sì lọ sí ìlú mímọ́. Níbẹ̀ ni wọ́n ti fi ara han ọ̀pọ̀ ènìyàn.
54 (Q)Nígbà tí balógun ọ̀run àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ tí wọ́n ń sọ Jesu rí bí ilẹ̀ ṣe mì tìtì àti ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ẹ̀rù bà wọn gidigidi, wọ́n wí pé, “Lóòótọ́ ọmọ Ọlọ́run ní í ṣe!”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.