Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 40:6-17

(A)Ẹbọ àti ẹran ẹbọ ni ìwọ kò fẹ́,
    ìwọ ti ṣí mi ní etí.
Ọrẹ ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀
    ni ìwọ kò béèrè.
Nígbà náà ni mo wí pé,
    “Èmi nìyí;
nínú ìwé kíká ni
    a kọ ọ nípa tèmi wí pé.
Mo ní inú dídùn
    láti ṣe ìfẹ́ ẹ̀ rẹ,
ìwọ Ọlọ́run mi;
    Òfin rẹ̀ ń bẹ ní àyà mi.”

Èmi ti sọ ìròyìn ayọ̀ ti ìgbàlà
    láàrín àwùjọ ńlá;
wò ó,
    èmi kò pa ètè mi mọ́,
gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti mọ̀,
    ìwọ Olúwa.
10 Èmi kò fi ìrànlọ́wọ́ ìgbàlà sin ní àyà mi;
    èmí ti sọ̀rọ̀ nípa òtítọ́ àti ìgbàlà rẹ.
Èmi kò sì pa ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ mọ́
    kúrò láàrín àwọn ìjọ ńlá.

11 Ìwọ má ṣe,
    fa àánú rẹ tí ó rọ́nú
sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ mi; Olúwa
    jẹ́ kí ìṣeun ìfẹ́ rẹ
àti òtítọ́ rẹ
    kí ó máa pa mi mọ́
títí ayérayé.
12 Nítorí pé àìníye ibi
    ni ó yí mi káàkiri,
ẹ̀ṣẹ̀ mi sì dì mọ́ mi,
    títí tí èmi kò fi ríran mọ́;
wọ́n pọ̀ ju irun orí mi lọ,
    àti wí pé àyà mí ti kùnà.

13 (B)Jẹ́ kí ó wù ọ́,
    ìwọ Olúwa,
láti gbà mí là;
    Olúwa,
yára láti ràn mí lọ́wọ́.

14 Gbogbo àwọn wọ̀n-ọn-nì
    ni kí ojú kí ó tì
kí wọn kí ó sì dààmú
    àwọn tí ń wá ọkàn mi
láti parun:
    jẹ́ kí a lé wọn padà sẹ́yìn
kí a sì dójútì wọ́n,
    àwọn tí ń wá ìpalára mi.
15 Jẹ́ kí àwọn tí ó wí fún mi pé, “Háà! Háà!”
    ó di ẹni à fi ọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nítorí ìtìjú wọn.
16 Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ń wá ọ
    kí ó máa yọ̀
kí inú wọn sì máa dùn sí ọ;
    kí gbogbo àwọn tí ó sì fẹ́ ìgbàlà rẹ
kí o máa wí nígbà gbogbo pé,
    “Gbígbéga ni Olúwa!”

17 Bí ó ṣe ti èmi ni,
    tálákà àti aláìní ni èmi,
ṣùgbọ́n Olúwa ń ṣe ìrántí mi.
    Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi
àti ìgbàlà mi;
    Má ṣe jẹ́ kí ó pẹ́,
    ìwọ Ọlọ́run mi.

Isaiah 48:12-21

Israẹli dòmìnira

12 (A)“Tẹ́tí sí mi, ìwọ Jakọbu
    Israẹli ẹni tí mo pè:
Èmi ni ẹni náà;
    Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìgbẹ̀yìn.
13 Ọwọ́ mi pàápàá ni ó fi àwọn ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,
    àti ọwọ́ ọ̀tún mi ni ó tẹ àwọn ọ̀run;
nígbà tí mo pè wọ́n,
    gbogbo wọn dìde sókè papọ̀.

14 “Gbogbo yín, ẹ péjọ kí ẹ sì gbọ́:
    Ta nínú wọn ni ó ti sọ nǹkan wọ̀nyí.
Olúwa ti fẹ́ ẹ,
    yóò sì ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ní Babiloni,
    apá rẹ̀ ni yóò sì wà ní ará àwọn ará Kaldea.
15 Èmi, àní Èmi ló ti sọ̀rọ̀;
    bẹ́ẹ̀ ni, mo ti pè é.
Èmi yóò mú un wá,
    òun yóò sì ṣe àṣeyọrí nínú ìrìnàjò rẹ̀.

16 “Ẹ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi kí ẹ sì dẹtí sí èyí:

“Láti ìgbà ìkéde àkọ́kọ́ èmi kò sọ̀rọ̀ ní ìkọ̀kọ̀;
    ní àsìkò tí ó sì ṣẹlẹ̀, Èmi wà níbẹ̀.”

Àti ní àkókò yìí, Olúwa Olódùmarè ni ó ti rán mi,
    pẹ̀lú ẹ̀mí rẹ̀.

17 Èyí ni ohun tí Olúwa
    Olùdáǹdè rẹ, Ẹni Mímọ́ Israẹli:
“Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,
    tí ó kọ́ ọ ní ohun tí ó dára fún ọ,
    tí ó tọ́ ọ ṣọ́nà tí ó yẹ kí o máa rìn.
18 Bí ó bá ṣe pé ìwọ bá ti tẹ́tí sílẹ̀ sí àṣẹ mi,
    àlàáfíà rẹ kì bá ti dàbí ì ti odò,
    àti òdodo rẹ bí ìgbì Òkun.
19 Àwọn ọmọ rẹ ìbá ti dàbí iyanrìn,
    àwọn ọmọ yín bí i hóró ọkà tí a kò lè kà tán;
orúkọ wọn ni a kì yóò ké kúrò
    tàbí kí a pa wọ́n run níwájú mi.”

20 Fi Babeli sílẹ̀,
    sá fún àwọn ará Babeli,
ṣe ìfilọ̀ èyí pẹ̀lú ariwo ayọ̀
    kí o sì kéde rẹ̀.
Rán an jáde lọ sí òpin ilẹ̀ ayé;
    wí pé, “Olúwa ti dá ìránṣẹ́ rẹ̀ Jakọbu nídè.”
21 Òrùngbẹ kò gbẹ wọ́n nígbà tí ó kó wọn
    kọjá nínú aginjù;
ó jẹ́ kí omi ó sàn fún wọn láti inú àpáta;
    ó fọ́ àpáta
    omi sì tú jáde.

Matiu 9:14-17

Ìbéèrè nípa àwẹ̀ lọ́wọ́ Jesu

14 (A)Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu tọ̀ ọ́ wá láti béèrè wí pé, “Èéṣe tí àwa àti àwọn Farisi fi ń gbààwẹ̀, ṣùgbọ́n tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ kò gbààwẹ̀?”

15 Jesu sì dáhùn pé, “Àwọn ọmọ ilé ìyàwó ha le máa ṣọ̀fọ̀, nígbà tí ọkọ ìyàwó ń bẹ lọ́dọ̀ wọn? Ṣùgbọ́n ọjọ́ ń bọ̀ nígbà tí a ó gba ọkọ ìyàwó lọ́wọ́ wọn; nígbà náà ni wọn yóò gbààwẹ̀.

16 “Kò sí ẹni tí ń fi ìrépé aṣọ tuntun lẹ ògbólógbòó ẹ̀wù; nítorí èyí tí a fi lẹ̀ ẹ́ yóò ya ní ojú lílẹ̀, aṣọ náà yóò sì ya púpọ̀ sì i ju ti ìṣáájú lọ. 17 Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí fi ọtí tuntun sínú ògbólógbòó ìgò-awọ; bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìgò-awọ yóò bẹ́, ọtí á sì tú jáde, ìgò-awọ á sì ṣègbé. Ṣùgbọ́n ọtí tuntun ni wọn í fi sínú ìgò-awọ tuntun àwọn méjèèjì a sì ṣe déédé.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.