Revised Common Lectionary (Complementary)
Saamu ti Dafidi.
23 Olúwa ni Olùṣọ́ èmi àgùntàn rẹ̀, èmi kì yóò ṣe aláìní.
2 (A)Ó mú mi dùbúlẹ̀ sí ibi pápá oko tútù
Ó mú mi lọ sí ibi omi dídákẹ́ rọ́rọ́;
3 Ó mú ọkàn mi padà bọ̀ sípò
Ó mú mi lọ sí ọ̀nà òdodo
nítorí orúkọ rẹ̀.
4 Bí mo tilẹ̀ ń rìn
Láàrín àfonífojì òjìji ikú,
èmi kì yóò bẹ̀rù ibi kan;
nítorí ìwọ wà pẹ̀lú mi;
ọ̀gọ rẹ àti ọ̀pá à rẹ
wọ́n ń tù mí nínú.
5 Ìwọ tẹ́ tábìlì oúnjẹ sílẹ̀ níwájú mi
ní ojú àwọn ọ̀tá à mi;
ìwọ ta òróró sí mi ní orí;
ago mí sì kún àkúnwọ́sílẹ̀.
6 Nítòótọ́, ìre àti àánú ni yóò máa tọ̀ mí lẹ́yìn
ní ọjọ́ ayé è mi gbogbo,
èmi yóò sì máa gbé inú ilé Olúwa
títí láéláé.
Ọ̀rọ̀ Jeremiah
12 Olúwa, olódodo ni ọ́ nígbàkúgbà,
nígbà tí mo mú ẹjọ́ kan tọ̀ ọ́ wá.
Síbẹ̀ èmi yóò bá ọ sọ̀rọ̀ nípa òdodo rẹ.
Èéṣe tí ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú fi ń ṣe déédé?
Èéṣe tí gbogbo àwọn aláìṣòdodo sì ń gbé ní ìrọ̀rùn?
2 Ó ti gbìn wọ́n, wọ́n sì ti fi egbò múlẹ̀,
wọ́n dàgbà wọ́n sì so èso.
Gbogbo ìgbà ni ó wà ní ètè wọn,
o jìnnà sí ọkàn wọn.
3 Síbẹ̀ o mọ̀ mí ní Olúwa,
o ti rí mi o sì ti dán èrò mi nípa rẹ wò.
Wọ, wọ́n lọ bí àgùntàn tí a fẹ́ pa.
Yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ọjọ́ pípa.
4 Yóò ti pẹ́ tó tí ọ̀gbẹlẹ̀ yóò fi wà,
tí gbogbo ewéko igbó sì ń rọ?
Nítorí àwọn ènìyàn búburú ni ó ń gbé ibẹ̀.
Àwọn ẹranko àti àwọn ẹyẹ ti ṣègbé,
pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ènìyàn ń sọ pé,
“Kò lè rí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wa.”
Ìdáhùn Ọlọ́run
5 Bí ìwọ bá ń bá ẹlẹ́ṣẹ̀ sáré,
tí àárẹ̀ sì mú ọ,
báwo ni ìwọ yóò ṣe bá ẹṣin díje?
Bí ìwọ bá kọsẹ̀ ní ilẹ̀ àlàáfíà,
bí ìwọ bá ní ìgbẹ́kẹ̀lé,
kí ni ìwọ ó ṣe nínú ẹkùn odò Jordani?
6 Àwọn arákùnrin rẹ àti àwọn
ìdílé—
ti dà ọ́, kódà wọ́n ti kẹ̀yìn sí ọ
Wọ́n ti hó lé ọ lórí;
Má ṣe gbà wọ́n gbọ́
bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń sọ̀rọ̀ rẹ dáradára.
7 Èmi yóò kọ ilé mi sílẹ̀,
èmi yóò fi ìní mi sílẹ̀.
Èmi yóò fi ẹni tí mo fẹ́
lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́.
8 Ogún mi ti rí sí mi
bí i kìnnìún nínú igbó.
Ó ń bú ramúramù mọ́ mi;
nítorí náà mo kórìíra rẹ̀.
9 Ogún mi kò ha ti rí sí mi
bí ẹyẹ kannakánná
tí àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ dòyì ka, tí wọ́n sì kọjú ìjà sí i?
Ẹ lọ, kí ẹ sì kó gbogbo ẹranko igbó jọ,
ẹ mú wọn wá jẹ.
10 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùṣọ́-àgùntàn ni yóò sì ba ọgbà àjàrà mi jẹ́,
tí wọn yóò sì tẹ oko mi mọ́lẹ̀;
Wọ́n ó sọ oko dídára mi di
ibi tí a ń da ìdọ̀tí sí.
11 A ó sọ ọ́ di aṣálẹ̀ ilẹ̀
tí kò wúlò níwájú mi,
gbogbo ilẹ̀ ni yóò di ahoro
nítorí kò sí ẹnìkankan tí yóò náání.
12 Gbogbo ibi gíga tí ó wà nínú aṣálẹ̀
ni àwọn apanirun ti gorí,
nítorí idà Olúwa yóò pa
láti ìkangun kìn-ín-ní dé ìkangun èkejì ilẹ̀ náà;
kò sí àlàáfíà fún gbogbo alààyè.
13 Àlìkámà ni wọn yóò gbìn, ṣùgbọ́n ẹ̀gún ni wọn yóò ká,
wọn yóò fi ara wọn ṣe wàhálà, ṣùgbọ́n òfo ni èrè wọn.
Kí ojú kí ó tì yín nítorí èrè yín,
nítorí ìbínú gbígbóná Olúwa.
Afọ́jú alágbe gba ìwòsàn
35 (A)Bí ó ti súnmọ́ Jeriko, afọ́jú kan jókòó lẹ́bàá ọ̀nà ó ń ṣagbe: 36 Nígbà tí ó gbọ́ tí ọ̀pọ̀ ń kọjá lọ, ó béèrè pé, kín ni ìtumọ̀ èyí. 37 Wọ́n sì wí fún un pé, “Jesu ti Nasareti ni ó ń kọjá lọ.”
38 Ó sì kígbe pé, “Jesu, ìwọ ọmọ Dafidi, ṣàánú fún mi!”
39 Àwọn tí ń lọ níwájú bá a wí, pé, kí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́: ṣùgbọ́n òun sì kígbe sókè sí í pé, “Ìwọ Ọmọ Dafidi, ṣàánú fún mi!”
40 Jesu sì dúró, ó ní, kí á mú un tọ òun wá nígbà tí ó sì súnmọ́ ọn, ó bi í, 41 Wí pé, “Kí ni ìwọ ń fẹ́ kí èmi ṣe fún ọ?”
Ó sì wí pé, “Olúwa jẹ́ kí èmi ríran.”
42 (B)Jesu sì wí fún un pé, “Ríran; ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradá.” 43 Lójúkan náà ó sì ríran, ó sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó sì ń yin Ọlọ́run lógo àti gbogbo ènìyàn nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n fi ìyìn fún Ọlọ́run.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.