Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 85:8-13

Èmi ó gbọ́ ohun tí Olúwa Ọlọ́run yóò wí;
    ó ṣèlérí àlàáfíà fún àwọn ènìyàn rẹ̀, àní ẹni mímọ́ rẹ̀:
Ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí wọn padà sí àìmoye.
Nítòótọ́ ìgbàlà rẹ̀ súnmọ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
    pé kí ògo rẹ̀ kí ó lè gbé ní ilẹ̀ wa.

10 Ìfẹ́ àti òtítọ́ parapọ̀;
    òdodo àti àlàáfíà fẹnu ko ara wọn.
11 Òtítọ́ ń sun jáde láti ilẹ̀ wá
    òdodo sì bojú wolẹ̀ láti ọ̀run.
12 Olúwa yóò fi ohun dídára fún ni nítòótọ́,
    ilẹ̀ wa yóò sì mú ìkórè rẹ̀ jáde.
13 Òdodo síwájú rẹ lọ
    o sì pèsè ọ̀nà fún ìgbésẹ̀ rẹ̀.

Amosi 3:1-12

Ẹ̀rí jíjẹ́ nípa àwọn ọmọ Israẹli

Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run ti sọ nípa rẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn Israẹli nípa àwọn ìdílé tí mo mú jáde láti Ejibiti:

“Ìwọ nìkan ni ẹni tí mo yàn
    nínú gbogbo àwọn ìran ayé yìí;
nígbà náà èmi ó jẹ ọ́ ní yà
    fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.”

Ẹni méjì ha à le rìn pọ̀
    láìjẹ́ pé wọ́n ti pinnu láti ṣe bẹ?
Ǹjẹ́ Kìnnìún yóò ha bú ramúramù nínú igbó,
    bí kò bá ní ohun ọdẹ?
Ọmọ kìnnìún yóò ha ké jáde nínú ìhó rẹ̀
    bí kò bá rí ohun kan mú?
Ǹjẹ́ ẹyẹ ṣubú sínú okùn ọdẹ lórí ilẹ̀
    nígbà tí a kò dẹ okùn ọdẹ fún un?
Okùn ọdẹ ha lè hù jáde lórí ilẹ̀
    nígbà tí kò sí ohun tí yóò mú?
Nígbà tí ìpè bá dún ní ìlú,
    àwọn ènìyàn kò ha bẹ̀rù?
Tí ewu bá wa lórí ìlú
    kò ha ṣe Olúwa ni ó fà á?

(A)Nítòótọ́ Olúwa Olódùmarè kò ṣe ohun kan
    láìfi èrò rẹ̀ hàn
    fun àwọn wòlíì ìránṣẹ́ rẹ̀.

Kìnnìún ti bú ramúramù
    ta ni kì yóò bẹ̀rù?
Olúwa Olódùmarè ti sọ̀rọ̀
    ta ni le ṣe àìsọ àsọtẹ́lẹ̀?

Ẹ kéde ní ààfin Aṣdodu
    àti ní ààfin ní ilẹ̀ Ejibiti.
“Ẹ kó ara yín jọ sí orí òkè ńlá Samaria;
    Kí ẹ sì wo ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ńlá láàrín rẹ̀
    àti ìnilára láàrín àwọn ènìyàn rẹ.”

10 “Wọn kò mọ bí wọ́n ṣe ń ṣe rere,” ni Olúwa wí,
    “àwọn ẹni tí ó gba àwọn ìwà ipá àti olè sí ààfin rẹ̀.”

11 Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí:

“Àwọn ọ̀tá yóò pa ilẹ̀ náà run;
    yóò wó ibi gíga yín palẹ̀
    a ó sì ba ààfin rẹ̀ jẹ́.”

12 Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“Bí olusọ-àgùntan ti ń gbà itan méjì
    kúrò ní ẹnu kìnnìún tàbí ẹ̀là etí kan
    bẹ́ẹ̀ ni a ó mú àwọn ọmọ Israẹli,
tí ń gbé Samaria kúrò
    ní igun ibùsùn wọn
    ní orí àga ìrọ̀gbọ̀kú wọn ní Damasku.”

Kolose 4:2-18

Àwọn ìlànà fún ìjọ

Ẹ fi ara yín jì fún àdúrà gbígbà, kí ẹ ṣọ́ra kí ẹ sì máa dúpẹ́; Ẹ máa gbàdúrà fún wa pẹ̀lú, kí Ọlọ́run lè ṣí ìlẹ̀kùn fún wa fún ọ̀rọ̀ náà, láti máa sọ ohun ìjìnlẹ̀ Kristi, nítorí èyí tí mo ṣe wà nínú ìdè pẹ̀lú: Ẹ gbàdúrà pé kí èmi le è máa kéde rẹ̀ kedere gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ fún mi. (A)Ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ti bí ẹ ti ń ṣe pẹ̀lú àwọn tí ń bẹ lóde, kí ẹ sì máa ṣe ṣí àǹfààní tí ẹ bá nílò. Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yín kí ó dàpọ̀ mọ́ oore-ọ̀fẹ́ nígbà gbogbo, èyí tí a fi iyọ̀ dùn, kí ẹ̀yin kí ó le mọ́ bí ẹ̀yin ó tí máa dá olúkúlùkù ènìyàn lóhùn.

Àwọn ìkíni ìkẹyìn

(B)Gbogbo bí nǹkan ti rí fún mi ní Tikiku yóò jẹ́ kí ẹ mọ̀. Òun jẹ́ arákùnrin olùfẹ́ àti olóòtítọ́ ìránṣẹ́ àti ẹlẹgbẹ́ nínú Olúwa: Ẹni tí èmí ń rán sí yín nítorí èyí kan náà, kí ẹ̀yin lè mọ́ bí a ti wà, kí òun kí ó lè tu ọkàn yín nínú; (C)Òun sì ń bọ̀ pẹ̀lú Onesimu, arákùnrin olóòtítọ́ àti olùfẹ́, ẹni tí í ṣe ọ̀kan nínú yín. Àwọn ní yóò sọ ohun gbogbo tí à ń ṣe níhìn-ín-yìí fún un yín.

10 (D)Aristarku, ẹlẹgbẹ́ mí nínú túbú kí i yín, àti Marku, ọmọ arábìnrin Barnaba (Nípasẹ̀ ẹni tí ẹ̀yin ti gba àṣẹ; bí ó bá sì wá sí ọ̀dọ̀ yín, ẹ gbà á).

11 Àti Jesu, ẹni tí à ń pè ní Justu, ẹni tí ń ṣe ti àwọn onílà. Àwọn wọ̀nyí nìkan ni olùbáṣiṣẹ́ mí fún ìjọba Ọlọ́run, àwọn ẹni tí ó tí jásí ìtùnú fún mi.

12 Epafira, ẹni tí ń ṣe ọ̀kan nínú yín àti ìránṣẹ́ Kristi Jesu kí i yín. Òun fi ìwàyáàjà gbàdúrà nígbà gbogbo fún un yín, kí ẹ̀yin kí ó lè dúró ní pípé nínú ohun gbogbo nínú ìfẹ́ Ọlọ́run. 13 Nítorí mo jẹ́rìí rẹ̀ pé ó ń ṣiṣẹ́ kárakára fún yín, àti fún àwọn tí ó wà ní Laodikea, àti àwọn tí ó wà ní Hirapoli.

14 (E)Luku, arákùnrin wa ọ̀wọ́n, oníṣègùn, àti Dema ki í yín.

15 Ẹ kí àwọn ará tí ó wà ní Laodikea, àti Nimpa, àti ìjọ tí ó wà ní ilé rẹ̀.

16 Nígbà tí a bá sì ka ìwé yìí ní àárín yín tan, kí ẹ mú kí a kà á pẹ̀lú nínú ìjọ Laodikea; ẹ̀yin pẹ̀lú sì ka èyí tí ó ti Laodikea wá.

17 Kí ẹ sì wí fún Arkippu pe, “Kíyèsi iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ìwọ ti gbà nínú Olúwa kí o sì ṣe é ní kíkún.”

18 (F)Ìkíni láti ọwọ́ èmi Paulu. Ẹ máa rántí ìdè mi. Kí oore-ọ̀fẹ́ kí ó wà pẹ̀lú yín.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.