Revised Common Lectionary (Complementary)
Ẹlẹgbẹ́ mi ni àwọn tó mọ òfin Olúwa
73 Ọwọ́ rẹ ni ó dá mi tí ó sì mọ mí;
fún mi ní òye láti kọ́ àṣẹ rẹ.
74 Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ máa yọ̀ nígbà tí wọ́n bá rí mi,
nítorí èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.
75 Èmi mọ, Olúwa, nítorí òfin rẹ òdodo ni,
àti ní òtítọ́ ni ìwọ pọ́n mi lójú.
76 Kí ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà jẹ́ ìtùnú mi,
gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ sí ìránṣẹ́ rẹ.
77 Jẹ́ kí àánú rẹ kí ó tọ̀ mí wá, kí èmi kí ó lè yè,
nítorí òfin rẹ jẹ́ ìdùnnú mi.
78 Kí ojú kí ó ti àwọn agbéraga
nítorí wọn pa mí lára láìnídìí
ṣùgbọ́n èmi yóò máa ṣe àṣàrò nínú ẹ̀kọ́ rẹ.
79 Kí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ yí padà sí mi,
àwọn tí ó ní òye òfin rẹ.
80 Jẹ́ kí ọkàn mi wà láìlẹ́bi sí òfin rẹ,
kí ojú kí ó má ṣe tì mí.
10 Ta ni ẹni tí mo lè bá sọ̀rọ̀ àti
tí mo lè fún ní ìmọ̀ràn? Ta ni
yóò tẹ́tí sílẹ̀ sí mi? Etí wọn
ti di, nítorí náà wọn kò lè gbọ́.
Ọ̀rọ̀ Olúwa, jẹ́ ohun búburú sí wọn,
wọn kò sì ní inú dídùn nínú rẹ̀.
11 Èmi kún fún ìbínú
Olúwa, èmi kò sì le è pa á mọ́ra.
“Tú u sí orí àwọn ọmọ ńigboro, àti
sórí àwọn ọmọkùnrin tí wọn kó ra
wọn jọ pọ̀, àti ọkọ àti aya ni a ò
mú sínú rẹ̀, àti àwọn arúgbó
tí ó ní ọjọ́ kíkún lórí.
12 Ilé wọn o sì di ti ẹlòmíràn,
oko wọn àti àwọn aya wọn,
nígbà tí èmi bá na ọwọ́ mi
sí àwọn olùgbé ilẹ̀ náà,”
ni Olúwa wí.
13 “Láti orí ẹni tí ó kéré sí orí
ẹni tí ó tóbi ju, gbogbo wọn
ni ó sì ní ojúkòkòrò fún èrè,
àwọn wòlíì àti àlùfáà lápapọ̀
sì kún fún ẹ̀tàn.
14 Wọ́n sì ń wo ọgbẹ́ àwọn ènìyàn
mi bí ẹni pé kò tó nǹkan.
Wọ́n ń wí pé, ‘Àlàáfíà, Àlàáfíà,’
nígbà tí kò sì sí àlàáfíà.
15 Ojú ha a tì wọ́n nítorí ìwà
ìríra wọn bí? Rárá, wọn kò
ní ìtìjú mọ́, wọn kò tilẹ̀ ní oorun ìtìjú
Nítorí náà, wọn ó ṣubú láàrín
àwọn tó ṣubú, a ó sì ké wọn
lulẹ̀ nígbà tí mo bá bẹ̀ wọ́n wò,”
ni Olúwa wí.
16 Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“Ẹ dúró sí ìkóríta, kí ẹ sì wò,
ẹ béèrè fún ọ̀nà àtijọ́, ẹ béèrè
ẹ béèrè ọ̀nà dáradára nì, kí ẹ rìn nínú rẹ,
ẹ̀yin yóò sì rí ìsinmi fún ọkàn yín.
Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wí pé, ‘Àwa kì yóò rìn nínú rẹ̀.’
17 Èmi yan olùṣọ́ fún un yín,
mo sì wí pé:
‘Tẹ́tí sí dídún fèrè náà,’
ẹ̀yìn wí pé, ‘Àwa kì yóò tẹ́tí sílẹ̀.’
18 Nítorí náà, gbọ́ ẹ̀yin orílẹ̀-èdè
kíyèsi, kí ẹ sì jẹ́ ẹlẹ́rìí
ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí wọn.
19 Gbọ́, ìwọ ayé!
Mò ń mú ìparun bọ̀ sórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí,
èso ìrò inú wọn,
nítorí wọn kò fi etí sí ọ̀rọ̀ mi,
wọ́n sì ti kọ òfin mi sílẹ̀.
21 Ǹjẹ́ bí nǹkan wọ̀nyí tí parí tan, Paulu pinnu nínú ọkàn rẹ̀ pé, nígbà tí òun bá kọjá ní Makedonia àti Akaia, òun ó lọ sí Jerusalẹmu, ó wí pé, “Lẹ́yìn ìgbà tí mo bá dé ibẹ̀, èmi kò lè ṣàìmá dé Romu pẹ̀lú.” 22 Nígbà tí ó sì tí rán méjì nínú àwọn tí ń ṣe ìránṣẹ́ fún un lọ sí Makedonia, Timotiu àti Erastu, òun tìkára rẹ̀ dúró díẹ̀ ní ilẹ̀ Asia.
Ìrúkèrúdò ní Efesu
23 Ní àkókò náà ìrúkèrúdò díẹ̀ kan wà nítorí ọ̀nà náà. 24 Nítorí ọkùnrin kan tí a ń pè ní Demetriusi, alágbẹ̀dẹ fàdákà, tí o máa ń fi fàdákà ṣe ilé òrìṣà fún Artemisi, ó mú ère tí kò mọ níwọ̀n wá fún àwọn oníṣọ̀nà; 25 Nígbà tí ó pè wọ́n jọ, àti irú àwọn oníṣẹ́-ọnà bẹ́ẹ̀, ó wí pé, “Alàgbà, ẹ̀yin mọ̀ pé nípa iṣẹ́ ọnà yìí ni àwa fi ní ọrọ̀ wa. 26 Ẹ̀yin sì rí i, ẹ sì gbọ́ pé, kì í ṣe ni Efesu nìkan ṣoṣo ni, ṣùgbọ́n ó fẹ́rẹ jẹ́ gbogbo Asia ni Paulu yìí ń yí ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ́kàn padà, tí ó sì ń dárí wọn wí pé, ohun tí a fi ọwọ́ ṣe, kì í ṣe Ọlọ́run. 27 Kì í sì ṣe pé kìkì iṣẹ́ ọnà wa yìí ni ó wà nínú ewu dídí asán; ṣùgbọ́n tẹmpili Artemisi òrìṣà ńlá yóò di gígàn pẹ̀lú, àti gbogbo ọláńlá rẹ̀ yóò sì run, ẹni tí gbogbo Asia àti gbogbo ayé ń bọ.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.