Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Jeremiah 34-36

Ìkìlọ̀ fún Sedekiah

34 (A)Nígbà tí Nebukadnessari ọba Babeli àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ìjọba àti àwọn ènìyàn ní ilẹ̀ ọba tí ó jẹ ọba lé lórí ń bá Jerusalẹmu jà, àti gbogbo àwọn ìlú tí ó yíká, ọ̀rọ̀ yìí tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa pé: “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli ọmọ-ogun wí: Lọ sí ọ̀dọ̀ Sedekiah ọba Juda kí o sì sọ fún un pé, ‘Èyí ni ohun tí Ọlọ́run wí: Èmi fẹ́ fa ìlú yìí lé ọba Babeli lọ́wọ́, yóò sì jó palẹ̀. Ìwọ kò ní sá àsálà, ṣùgbọ́n à ó mú ọ, bẹ́ẹ̀ ni a ó sì fà ọ́ lé e lọ́wọ́. Ìwọ yóò rí ọba Babeli pẹ̀lú ojú ara rẹ; yóò sì bá ọ sọ̀rọ̀ lójúkojú; ìwọ yóò sì lọ sí Babeli.

“ ‘Síbẹ̀, gbọ́ ìlérí Olúwa, ìwọ Sedekiah ọba Juda. Èyí ni ohun tí Ọlọ́run wí nípa rẹ; ìwọ kì yóò ti ipa idà kú; Ìwọ yóò kú ní àlàáfíà. Bí àwọn ènìyàn sì ti ń ṣe iná ìsìnkú ní ọlá fún àwọn baba rẹ, ọba tí ó jẹ ṣáájú rẹ, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò ṣe iná ní ọlá rẹ, wọn ó sì pohùnréré pé, “Yé, olúwa!” Èmi fúnra mi ni ó ṣèlérí yìí ni Olúwa wí.’ ”

Nígbà náà ni Jeremiah wòlíì sọ gbogbo nǹkan yìí fún Sedekiah ọba Juda ní Jerusalẹmu. Nígbà tí ogun ọba Babeli ń bá Jerusalẹmu jà, àti gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó kù ní Juda, Lakiṣi, Aseka; àwọn nìkan ni ìlú olódi tí ó kù ní Juda.

Òmìnira fún àwọn ẹrú

Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jeremiah wá lẹ́yìn ìgbà tí ọba Sedekiah ti dá májẹ̀mú pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn ní Jerusalẹmu láti polongo ìtúsílẹ̀ fún àwọn ẹrú. Kí oníkálùkù lè jẹ́ kí ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin tí í ṣe Heberu lọ lọ́fẹ̀ẹ́, kí ẹnikẹ́ni kí ó má mú ará Juda arákùnrin rẹ̀ sìn. 10 Nítorí náà, gbogbo àwọn aláṣẹ àti àwọn ènìyàn tí wọ́n fi ọwọ́ sí májẹ̀mú náà láti dá ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin sílẹ̀ kí wọ́n sì má ṣe fi wọ́n sínú ìgbèkùn mọ́. Wọ́n sì gbà, wọ́n sì jẹ́ kí wọn lọ lọ́fẹ̀ẹ́ 11 Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, wọ́n yí ọkàn wọn padà; wọ́n sì mú àwọn ẹrú tí wọ́n ti dá sílẹ̀ padà láti tún máa sìn wọ́n.

12 Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wá wí pé: 13 “Èyí ni ohun tí Ọlọ́run Israẹli wí pé: Mo dá májẹ̀mú kan pẹ̀lú àwọn baba ńlá yín nígbà tí mo mú wọn kúrò ní Ejibiti; kúrò ní oko ẹrú. Mo wí pé, 14 ‘Ní ọdún keje, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín gbọdọ̀ tú àwọn Heberu tí wọ́n ti ta ara wọn fún un yín sílẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti sìn yín fún ọdún mẹ́fà. Ẹ gbọdọ̀ jẹ́ kí wọn kí ó lọ’; ṣùgbọ́n àwọn baba yín kò gbọ́; bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fetí sí mi. 15 Láìpẹ́ yìí ẹ ti ronúpìwàdà, ẹ sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú mi, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín sì ṣe ìtúsílẹ̀ fún àwọn ènìyàn. Ẹ sì tún bá mi dá májẹ̀mú ní àwọn ilé tí a ti ń pe orúkọ mi. 16 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin yípadà, ẹ sì sọ orúkọ mi di èérí, olúkúlùkù sì mú kí àwọn ẹni rẹ tí ó ti sọ di òmìnira bí ọkàn wọn ti fẹ́ padà; ẹ̀yin sì tún fi wọ́n ṣe ẹrú.

17 “Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí: Ẹ̀yin kò fetí sí mi nípa ọ̀rọ̀ òmìnira láàrín ẹ̀gbọ́n sí àbúrò, láàrín ẹnìkan sí èkejì rẹ̀. Wò ó, èmi yóò kéde òmìnira fún un yín ni Olúwa wí. Sí idà, sí àjàkálẹ̀-ààrùn, àti sí ìyàn, èmi ó sì fi yín fún ìwọ̀sí ní gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé. 18 Èmi ó ṣe àwọn ọkùnrin náà tí ó da májẹ̀mú mi, tí kò tẹ̀lé májẹ̀mú tí wọ́n ti dá níwájú mi bí ẹgbọrọ màlúù tí wọ́n gé sí méjì, tí ó sì kọjá láàrín ìpín méjì náà. 19 Àwọn ìjòyè Juda àti àwọn ti Jerusalẹmu, àwọn aláṣẹ àti àwọn àlùfáà àti gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà tí ó kọjá láàrín àwọn ìpín méjèèjì ẹgbọrọ màlúù náà. 20 Èmi ó fi wọ́n lé ọwọ́ àwọn ọ̀tá wọn, àti lé àwọn tí ń wá ẹ̀mí wọn lọ́wọ́. Òkú wọn yóò jẹ́ oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti fún àwọn ẹranko igbó.

21 “Sedekiah ọba àti àwọn ìjòyè rẹ̀ ní Juda ni èmí yóò fi lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́, àti àwọn tí ń wá ẹ̀mí wọn àti lé ọwọ́ ogun Babeli tí ó ti lọ kúrò lọ́dọ̀ yín. 22 Wò ó èmi ó pàṣẹ ni Olúwa wí, èmi ó sì mú wọn padà sí ìlú yìí, wọn ó sì bá a jà, wọn ó sì kó o, wọn ó fi iná jó o. Èmi ó sì sọ ìlú Juda dí ahoro.”

Àwọn Rekabu

35 Ọ̀rọ̀ tí ó tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa ní ọjọ́ Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda wí pé: “Lọ sí ilé àwọn ọmọ Rekabu, kí o sì bá wọn sọ̀rọ̀, kí o sì mú wọn wá sí ilé Olúwa, sí ọ̀kan nínú iyàrá wọ̀n-ọn-nì, kí o sì fún wọn ní ọtí wáìnì mu.”

Nígbà náà ni mo mu Jaaṣaniah ọmọ Jeremiah, ọmọ Habasiniah àti àwọn arákùnrin rẹ̀; àti gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀, àti gbogbo ilé àwọn ọmọ Rekabu. Mo sì mú wọn wá sí ilé Olúwa sínú iyàrá Hanani ọmọ Igdaliah, ènìyàn Ọlọ́run, tí ó wà lẹ́bàá yàrá àwọn ìjòyè, tí ó wà ní òkè yàrá Maaseiah, ọmọ Ṣallumu olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà. Mo sì gbé ìkòkò tí ó kún fún ọtí wáìnì pẹ̀lú ago ka iwájú àwọn ọmọ Rekabu. Mo sì wí fún wọn pé, “Mu ọtí wáìnì.”

Ṣùgbọ́n wọ́n wí pé, “Àwa kì yóò mu ọtí wáìnì nítorí Jonadabu ọmọ Rekabu, baba wa pàṣẹ fún wa pé: ‘Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ mu ọtí wáìnì ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín láéláé Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ kọ́ ilé tàbí kí ẹ fúnrúgbìn, tàbí kí ẹ gbin ọgbà àjàrà. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ní ọ̀kankan nínú àwọn ohun wọ̀nyí, ṣùgbọ́n ní gbogbo ọjọ́ yín ni ẹ̀yin ó máa gbé inú àgọ́; kí ẹ̀yin kí ó lè wá ní ọjọ́ púpọ̀ ní ilẹ̀ náà; níbi tí ẹ̀yin ti ń ṣe àtìpó.’ Báyìí ni àwa gba ohùn Jehonadabu ọmọ Rekabu baba wa gbọ́ nínú gbogbo èyí tí ó pàṣẹ fún wa, kí a má mu ọtí wáìnì ní gbogbo ọjọ́ ayé wa; àwa, àwọn aya wa, àwọn ọmọkùnrin wa, àti àwọn ọmọbìnrin wa. Àti kí a má kọ́ ilé láti gbé; bẹ́ẹ̀ ni àwa kò ní ọgbà àjàrà tàbí oko, tàbí ohun ọ̀gbìn. 10 Ṣùgbọ́n àwa ń gbé inú àgọ́, a sì gbọ́rọ̀, a sì ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí Jonadabu baba wa pàṣẹ fún wa. 11 Ó sì ṣe, nígbà tí Nebukadnessari ọba Babeli gòkè wá sí ilẹ̀ náà; àwa wí pé, ‘Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a lọ sí Jerusalẹmu, nítorí ìbẹ̀rù ogun àwọn ara Siria.’ Bẹ́ẹ̀ ni àwa sì ń gbé Jerusalẹmu.”

12 Nígbà yìí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wá wí pé: 13 “Báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí pé, lọ, kí o sì sọ fún àwọn ọkùnrin Juda, àti àwọn olùgbé Jerusalẹmu pé, ‘Ẹ̀yin kì yóò ha gba ẹ̀kọ́ láti fetí sí ọ̀rọ̀ mi,’ ni Olúwa wí. 14 ‘Ọ̀rọ̀ Jehonadabu ọmọ Rekabu tí ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé wọn kò gbọdọ̀ mu ọtí wáìnì, ni a mú ṣẹ, wọn kò sì mu ọtí wáìnì títí di òní yìí, nítorí tí wọ́n gba òfin baba wọn. Èmi sì ti ń sọ̀rọ̀ fún un yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fetí sí mi. 15 Èmi rán gbogbo àwọn ìránṣẹ́ àti àwọn wòlíì mí sí yín pẹ̀lú wí pé, “Ẹ yípadà nísinsin yìí kúrò ní ọ̀nà búburú yín, kí ẹ sì tún ìṣe yín ṣe sí rere. Kí ẹ ma sì ṣe bọ òrìṣà tàbí sìn wọ́n; ẹ̀yin ó sì máa gbé ní ilẹ̀ náà tí mo fi fún un yín àti fún àwọn baba ńlá yín.” Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fetí sí mi. 16 Nítòótọ́, àwọn ọmọ Jehonadabu ọmọ Rekabu pa òfin baba wọn mọ́ tí ó pàṣẹ fún wọn, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn wọ̀nyí kò pa òfin mi mọ́.’

17 “Nítorí náà, báyìí ni, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Fetísílẹ̀! Èmi ó mú gbogbo ohun búburú tí èmi ti sọ wá sórí Juda, àti sórí gbogbo olùgbé Jerusalẹmu nítorí èmi ti bá wọn sọ̀rọ̀: Ṣùgbọ́n wọn kò sì dáhùn.’ ”

18 Nígbà náà ni Jeremiah wí fún ìdílé Rekabu pé, “Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí pé: ‘Nítorí tí ẹ̀yin gba òfin Jehonadabu baba yín, tí ẹ sì pa gbogbo rẹ̀ mọ́, tí ẹ sì ṣe gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó pàṣẹ fún un yín.’ 19 Nítorí náà, báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí, pé: ‘Jonadabu ọmọ Rekabu kì yóò fẹ́ ọkùnrin kan kù láti sìn mí.’ ”

Jehoiakimu jó ìwé kíká Jeremiah

36 Ní ọdún kẹrin Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda, ọ̀rọ̀ yìí tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wí pé: “Mú ìwé kíká fún ará rẹ, kí o sì kọ sínú rẹ̀ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ nípa Israẹli àti ti Juda, àti sí gbogbo orílẹ̀-èdè láti ìgbà tí mo ti sọ fún ọ láti ọjọ́ Josiah títí di òní. Ó lè jẹ́ wí pé ilé Juda yóò gbọ́ gbogbo ibi tí mo ti pinnu láti ṣe fún wọn; kí wọn kí ó sì yípadà, olúkúlùkù wọn kúrò ní ọ̀nà búburú rẹ̀. Kí èmi kí ó lè dárí àìṣedéédéé àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n.”

Nígbà náà ni Jeremiah pe Baruku ọmọ Neriah, ó sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run bá a sọ fún, Baruku sì kọ láti ẹnu Jeremiah, gbogbo ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó ti sọ fún un sórí ìwé kíká náà. Nígbà náà ni Jeremiah wí fún Baruku pé, “A sé mi mọ́! Èmi kò lè lọ sí ilé Olúwa. Nítorí náà, ìwọ lọ sí ilé Olúwa ní ọjọ́ àwẹ̀, kí o sì kà nínú ìwé kíká náà ọ̀rọ̀ Olúwa tí ìwọ ti ẹnu mi kọ; ìwọ ó sì kà á ní etí gbogbo Juda, tí wọ́n jáde wá láti ìlú wọn. Ó lè jẹ́ pé, ẹ̀bẹ̀ wọn yóò wá sí iwájú Olúwa, wọ́n ó sì yípadà kúrò ní ọ̀nà búburú wọn; nítorí pé títóbi ni ìbínú àti ìrunú tí Olúwa ti sọ sí àwọn ènìyàn yìí.”

Baruku ọmọ Neriah sì ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí wòlíì Jeremiah sọ fún, láti ka ọ̀rọ̀ Olúwa láti inú ìwé ní ilé Olúwa. Ní oṣù kẹsànán ọdún karùn-ún Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda ni wọ́n kéde àwẹ̀ níwájú Olúwa fún gbogbo ènìyàn Jerusalẹmu àti fún gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wá láti ìlú Juda. 10 Láti inú yàrá Gemariah ọmọ Ṣafani akọ̀wé, ní àgbàlá òkè níbi ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà ilé Olúwa tuntun. Baruku sì ka ọ̀rọ̀ Jeremiah láti inú ìwé ní ilé Olúwa sí etí gbogbo ènìyàn.

11 Nígbà tí Mikaiah ọmọ Gemariah ọmọ Ṣafani gbọ́ gbogbo àkọsílẹ̀ ọ̀rọ̀ Olúwa láti inú ìwé náà; 12 Ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé ọba sínú yàrá akọ̀wé; níbi tí gbogbo àwọn ìjòyè gbé jókòó sí: Eliṣama akọ̀wé, Delaiah ọmọ Ṣemaiah, Elnatani ọmọ Akbori, Gemariah ọmọ Ṣafani àti Sedekiah ọmọ Hananiah àti gbogbo àwọn ìjòyè. 13 Lẹ́yìn tí Mikaiah sọ gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀n-ọn-nì tí o ti gbọ́ fún wọn, nígbà tí Baruku kà láti inú ìwé kíkà náà ní etí àwọn ènìyàn. 14 Gbogbo àwọn ìjòyè sì rán Jehudu ọmọ Netaniah ọmọ Ṣelemiah ọmọ Kuṣi sí Baruku wí pé, mú ìwé kíká náà ní ọwọ́ rẹ láti inú èyí tí ìwọ kà ní etí àwọn ènìyàn; kí o si wá. Nígbà náà ni Baruku ọmọ Neriah wá sí ọ̀dọ̀ wọn pẹ̀lú ìwé kíká ní ọwọ́ rẹ̀. 15 Wọ́n sì wí fún pé, “Jókòó, jọ̀wọ́ kà á sí etí wa!”

Nígbà náà ni Baruku sì kà á ní etí wọn. 16 Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ náà tan; wọ́n ń wo ara wọn lójú pẹ̀lú ẹ̀rù. Wọ́n sì wí fún Baruku pé, “Àwa gbọdọ̀ jábọ̀ gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún ọba.” 17 Wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ Baruku pé, “Sọ fún wa báwo ni o ṣe kọ gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí? Ṣé Jeremiah ló sọ wọ́n?”

18 Baruku sì dá wọn lóhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, láti ẹnu rẹ̀ ni, ó sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ báyìí fún mi, èmi sì fi tàdáwà kọ wọ́n sínú ìwé náà.”

19 Nígbà náà ni àwọn ìjòyè sọ fún Baruku wí pé, “Lọ fi ara rẹ pamọ́ àti Jeremiah, má sì ṣe jẹ́ kí ẹnìkan mọ ibi tí ẹ̀yin wà.”

20 Lẹ́yìn tí wọ́n fi ìwé kíká náà pamọ́ sí iyàrá Eliṣama akọ̀wé, wọ́n sì wọlé tọ ọba lọ nínú àgbàlá, wọ́n sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà ní etí ọba. 21 Ọba sì rán Jehudu láti lọ mú ìwé kíká náà wá, Jehudu sì mu jáde láti inú iyàrá Eliṣama akọ̀wé. Ó sì ka ìwé náà ní etí ọba àti ní etí gbogbo àwọn ìjòyè tí ó dúró ti ọba. 22 Ó sì jẹ́ ìgbà òtútù nínú oṣù kẹsànán, ọba sì jókòó ní ẹ̀bá iná ààrò, iná náà sì ń jó ní iwájú rẹ̀. 23 Nígbà tí Jehudu ka ojú ìwé mẹ́ta sí mẹ́rin nínú ìwé náà, ọba fi ọ̀bẹ gé ìwé, ó sì sọ sínú iná tí ó wà nínú ìdáná, títí tí gbogbo ìwé kíká náà fi jóná tán. 24 Síbẹ̀, ọba àti gbogbo àwọn ẹ̀mẹwàá rẹ̀ tí wọ́n gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí kò bẹ̀rù; wọn kò sì fa aṣọ wọn yá. 25 Elnatani, Delaiah àti Gemariah sì bẹ ọba kí ó má ṣe fi ìwé kíká náà jóná, ṣùgbọ́n ọba kọ̀ láti gbọ́ tiwọn. 26 Dípò èyí ọba pàṣẹ fún Jerahmeeli ọmọ Hameleki, Seraiah ọmọ Asrieli àti Ṣelemiah ọmọ Abdeeli láti mú Baruku akọ̀wé àti Jeremiah wòlíì ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi wọ́n pamọ́.

27 Lẹ́yìn tí ọba fi ìwé kíká náà tí ọ̀rọ̀ tí Baruku kọ láti ẹnu Jeremiah jóná tán, ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jeremiah wá: 28 “Wí pé, tún mú ìwé kíká mìíràn kí o sì kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú ìwé kíká èkínní tí Jehoiakimu ọba Juda fi jóná. 29 Kí o sì wí fún Jehoiakimu ọba Juda pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí: Ìwọ ti fi ìwé kíká náà jóná, o sì wí pé, “Èéṣe tí ìwọ fi kọ̀wé sínú rẹ̀, pé lóòtítọ́ ni ọba Babeli yóò wá, yóò sì pa ilẹ̀ run, àti ènìyàn, àti ẹranko kúrò nínú rẹ̀.” 30 Nítorí náà, báyìí ni Olúwa wí ní ti Jehoiakimu ọba Juda pé: Òun kì yóò ní ẹni tí yóò jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi, à ó sì sọ òkú rẹ̀ nù fún ooru ní ọ̀sán àti fún òtútù ní òru. 31 Èmi ó sì jẹ òun àti irú-ọmọ rẹ̀, ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ìyà nítorí àìṣedéédéé wọn; èmi ó sì mú gbogbo ibi tí èmi ti sọ sí wọn wá sórí wọn, àti sórí àwọn olùgbé Jerusalẹmu àti àwọn ènìyàn Juda, nítorí tí wọn kò fetísí mi.’ ”

32 Nígbà náà ni Jeremiah mú ìwé kíká mìíràn fún Baruku akọ̀wé ọmọ Neriah, ẹni tí ó kọ̀wé sínú rẹ̀ láti ẹnu Jeremiah gbogbo ọ̀rọ̀ inú ìwé tí Jehoiakimu ọba Juda ti sun níná. A sì fi onírúurú ọ̀rọ̀ bí irú èyí kún pẹ̀lú.

Heberu 2

Ìkìlọ̀ láti ṣe ìgbọ́ràn

Nítorí náà, ó yẹ kí àwa máa fi iyè sí àwọn nǹkan wọ̀n-ọn-nì gidigidi tí àwa ti gbọ́, kí a má ba à gbá wa lọ kúrò nínú wọn nígbà kan. Nítorí bí ọ̀rọ̀ tí a tí ẹnu àwọn angẹli sọ bá sì dúró ṣinṣin, àti tí olúkúlùkù ẹ̀ṣẹ̀ sí òfin àti àìgbọ́ràn gba ìjìyà tí ó tọ́ sí i, kín ni ohun náà tí ó mú wa lérò pé a lè bọ́ kúrò nínú ìjìyà bí a kò bá náání ìgbàlà ńlá yìí? Ìgbàlà tí Olúwa fúnrarẹ̀ kọ́kọ́ kéde, èyí tí a sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ fún wa láti ọwọ́ àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà lẹ́nu rẹ̀. Ọlọ́run jẹ́rìí sí i nípa àwọn iṣẹ́ ààmì àti ìyanu àti oríṣìíríṣìí iṣẹ́ agbára àti nípa ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ tí a pín gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀.

Jesu bí arákùnrin rẹ̀

Nítorí pé, kì í ṣe abẹ́ ìṣàkóso àwọn angẹli ni ó fi ayé tí ń bọ̀, tí àwa ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ sí. (A)Ṣùgbọ́n ibìkan wà tí ẹnìkan tí jẹ́rìí pé:

“Kí ni ènìyàn tí ìwọ fi ń ṣe ìrántí rẹ̀,
    tàbí ọmọ ènìyàn, tí ìwọ fi ń bẹ̀ ẹ́ wò?
Ìwọ dá a ní onírẹ̀lẹ̀ díẹ̀ ju àwọn angẹli lọ;
    ìwọ fi ògo àti ọlá de e ni adé,
    ìwọ sì fi í jẹ olórí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ:
    Ìwọ fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.”

Ní ti fífi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n àwa kò ì tí ì rí ohun kan tí ó kù tí kò sí ní abẹ́ àkóso rẹ̀. Síbẹ̀ nísinsin yìí àwa kò ì tí ì rí pé ó fi ohun gbogbo sábẹ́ ìṣàkóso rẹ̀ Ṣùgbọ́n àwa rí Jesu ẹni tí a rẹ̀ sílẹ̀ díẹ̀ ju àwọn angẹli lọ fún àkókò díẹ̀, àní Jesu, ẹni tí a fi ògo àti ọlá dé ní adé nítorí ìjìyà wa; kí ó lè tọ́ ikú wò fún olúkúlùkù ènìyàn nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.

10 Nítorí pé ó yẹ fún Ọlọ́run, nítorí nípasẹ̀ ẹni tí ohun gbogbo ṣẹ̀ wà, láti mú àwọn ọmọ púpọ̀ wá sínú ògo, láti ṣe balógun ìgbàlà wọn ni àṣepé nípa ìjìyà. 11 Nítorí àti ẹni tí ń sọ ni di mímọ́ àti àwọn tí a ń sọ di mímọ́, láti ọ̀dọ̀ ẹnìkan ṣoṣo ni gbogbo wọn ti wá: Nítorí èyí ni kò ṣe tijú láti pè wọ́n ni arákùnrin. 12 (B)Àti wí pé,

“Èmi ó sọ̀rọ̀ orúkọ rẹ̀ fún àwọn ará mi,
    ni àárín ìjọ ni èmi yóò kọrin ìyìn rẹ̀.”

13 (C)Àti pẹ̀lú,

“Èmi yóò gbẹ́kẹ̀ mi lé e.”

Àti pẹ̀lú,

“Kíyèsi í, èmi rèé, èmi àti àwọn ọmọ tí Ọlọ́run fi fún mi.”

14 Ǹjẹ́ ni ìwọ̀n bí àwọn ọmọ tí ṣe alábápín ará àti ẹ̀jẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni òun pẹ̀lú sì ṣe alábápín nínú ohun kan náà; kí ó lè ti ipa ikú rẹ̀ pa ẹni tí ó ní agbára ikú run, èyí ni èṣù. 15 Kí o sì lè gba gbogbo àwọn tí ó tìtorí ìbẹ̀rù ikú wà lábẹ́ ìdè lọ́jọ́ ayé wọn gbogbo kúrò lọ́wọ́ ìbẹ̀rù. 16 (D)Nítorí pé, nítòótọ́, kì í ṣe àwọn angẹli ni ó ṣe ìrànlọ́wọ́ fún, ṣùgbọ́n àwọn irú-ọmọ Abrahamu ni ó ṣe ìrànlọ́wọ́ fún. 17 Nítorí náà, ó yẹ pé nínú ohun gbogbo kí ó dàbí àwọn ará rẹ̀, kí ó lè jẹ́ aláàánú àti olóòtítọ́ alábojútó Àlùfáà nínú ohun tí i ṣe ti Ọlọ́run, kí o lè ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn. 18 Nítorí níwọ̀n bí òun tìkára rẹ̀ ti jìyà tí a sì ti dán an wò, òun ní agbára láti ran àwọn tí a ń dánwò lọ́wọ́.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.