Add parallel Print Page Options

17 Ó sì mú wá sórí wọn ọba àwọn ará Babeli tí wọ́n bá àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọn jà pẹ̀lú idà ní ilẹ̀ ibi mímọ́, kò sì ní ìyọ́nú sí àgbà ọkùnrin tàbí ọ̀dọ́mọdébìnrin, wúńdíá, tàbí arúgbó. Ọlọ́run sì fi gbogbo wọn lé Nebukadnessari lọ́wọ́. 18 Ó sì mú gbogbo ohun èlò láti ilé Ọlọ́run lọ sí Babeli, ńlá àti kékeré àti ìṣúra ilé Olúwa àti ìṣúra ọba àti ìjòyè rẹ̀. 19 Wọ́n sì fi iná sun ilé Ọlọ́run, wọ́n sì wó gbogbo ògiri ilé Jerusalẹmu, wọ́n sì jó gbogbo ààfin wọn, wọ́n sì ba gbogbo ohun èlò ibẹ̀ jẹ́.

20 Ó sì kó èyí tí ó kù lọ sí Babeli àwọn tí ó rí ibi sá kúrò lẹ́nu idà wọ́n sì di ìránṣẹ́ fún un àti àwọn ọmọ rẹ̀ títí tí ìjọba Persia fi gba agbára. 21 Ilẹ̀ náà sì gbádùn ìsinmi rẹ̀, ní gbogbo ìgbà ìdahoro, òun sì ń sinmi títí àádọ́rin ọdún (70) fi pé ní ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ Olúwa tí a sọ láti ẹnu Jeremiah.

Read full chapter