Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Read the New Testament in 24 Weeks

A reading plan that walks through the entire New Testament in 24 weeks of daily readings.
Duration: 168 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Ìfihàn 21-22

Jerusalẹmu tuntun

21 (A)Mo sì rí ọ̀run tuntun kan àti ayé tuntun kan: nítorí pé ọ̀run ti ìṣáájú àti ayé ìṣáájú ti kọjá lọ; Òkun kò sì ṣí mọ́. (B)Mo sì rí ìlú mímọ́, Jerusalẹmu tuntun ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, tí a ti múra sílẹ̀ bí ìyàwó tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ fún ọkọ rẹ̀. (C)Mo sì gbọ́ ohùn ńlá kan láti orí ìtẹ́ náà wá, ń wí pé, “Kíyèsi i, àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú àwọn ènìyàn, òun ó sì máa bá wọn gbé, wọn ó sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀, àti Ọlọ́run tìkára rẹ̀ yóò wà pẹ̀lú wọn, yóò sì máa jẹ́ Ọlọ́run wọn. (D)Ọlọ́run yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ni ojú wọn; kì yóò sì ṣí ikú mọ́, tàbí ọ̀fọ̀, tàbí ẹkún, bẹ́ẹ̀ ni kí yóò sí ìrora mọ́: nítorí pé ohun àtijọ́ tí kọjá lọ.”

(E)Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà, sì wí pé, “Kíyèsi i, mo sọ ohun gbogbo di ọ̀tun!” Ó sì wí fún mi pé, “Kọ̀wé rẹ̀: Nítorí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí òdodo àti òtítọ́ ni wọ́n.”

(F)Ó sì wí fún mi pé, “Ó parí. Èmi ni Alfa àti Omega, ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti òpin. Èmi ó sì fi omi fún ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ láti inú orísun omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́. (G)Ẹni tí ó ba ṣẹ́gun ni yóò jogún nǹkan wọ̀nyí; èmi ó sì máa jẹ́ Ọlọ́run rẹ̀, òun ó sì máa jẹ ọmọ mi. (H)Ṣùgbọ́n àwọn ojo, àti aláìgbàgbọ́, àti ẹni ìríra, àti apànìyàn, àti àgbèrè, àti oṣó, àti abọ̀rìṣà, àti àwọn èké gbogbo, ni yóò ni ipa tiwọn nínú adágún tí ń fi iná àti sulfuru jó: èyí tí i ṣe ikú kejì.”

Ọ̀kan nínú àwọn angẹli méje, tí wọ́n ni ago méje, tí ó kún fún ìyọnu méje ìkẹyìn sì wá, ó sì ba mi sọ̀rọ̀ wí pé, “Wá níhìn-ín, èmi ó fi ìyàwó, aya Ọ̀dọ́-àgùntàn hàn ọ́.” 10 (I)Ó sì mu mi lọ nínú Ẹ̀mí si òkè ńlá kan tí o sì ga, ó sì fi ìlú náà hàn mi, Jerusalẹmu mímọ́, tí ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, 11 Tí ó ní ògo Ọlọ́run: ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ sì dàbí òkúta iyebíye gidigidi, àní bí òkúta Jasperi, ó mọ́ bí Kirisitali; 12 (J)Ó sì ní odi ńlá àti gíga, ó sì ni ẹnu ibodè méjìlá, àti ní àwọn ẹnu ibodè náà angẹli méjìlá àti orúkọ tí a kọ sára wọn tí i ṣe orúkọ àwọn ẹ̀yà méjìlá tí àwọn ọmọ Israẹli; 13 Ní ìhà ìlà-oòrùn ẹnu ibodè mẹ́ta; ní ìhà àríwá ẹnu ibodè mẹ́ta; ní ìhà gúúsù ẹnu ibodè mẹ́ta; àti ní ìhà ìwọ̀-oòrùn ẹnu ibodè mẹ́ta. 14 Odi ìlú náà sì ni ìpìlẹ̀ méjìlá, àti lórí wọn orúkọ àwọn Aposteli méjìlá tí Ọ̀dọ́-Àgùntàn.

15 (K)Ẹni tí o sì ń bá mi sọ̀rọ̀ ní ọ̀pá-ìwọ̀n wúrà kan láti fi wọn ìlú náà àti àwọn ẹnu ibodè rẹ̀, àti odi rẹ̀. 16 Ìlú náà sì wà ní ibú mẹ́rin lọ́gbọọgba, gígùn rẹ̀ àti ìbú rẹ̀ sì dọ́gba: ó sì fi ọ̀pá-ìwọ̀n náà wọn ìlú náà wò, ó jẹ ẹgbàafà ibùsọ̀ gígùn rẹ̀ àti ìbú rẹ̀, àti gíga rẹ̀ sì dọ́gba. 17 Ó sì wọn odi rẹ̀ ó jẹ́ ogóje ìgbọ̀nwọ́ lé mẹ́rin (144), gẹ́gẹ́ bí òṣùwọ̀n ènìyàn, bẹ́ẹ̀ ni tí angẹli náà. 18 A sì fi jasperi mọ odi ìlú náà. Ìlú náà sì jẹ́ kìkì wúrà, ó dàbí dígí tí o mọ́ kedere. 19 (L)A fi onírúurú òkúta iyebíye ṣe ìpìlẹ̀ ògiri ìlú náà lọ́ṣọ̀ọ́. Ìpìlẹ̀ èkínní jẹ́ jasperi; èkejì, safiru; ẹ̀kẹta, kalkedoni ẹ̀kẹrin, emeradi, 20 ẹ̀karùnún, sardoniki; ẹ̀kẹfà, kaneliani; èkeje, krisoliti; ẹ̀kẹjọ, bereli; ẹ̀kẹsànán, topasi; ẹ̀kẹwàá, krisoprasu; ẹ̀kọkànlá, jakiniti; èkejìlá, ametisiti. 21 Ẹnu ibodè méjèèjìlá jẹ́ pearli méjìlá: olúkúlùkù ẹnu ibodè jẹ́ peali kan; ọ̀nà ìgboro ìlú náà sì jẹ́ kìkì wúrà, ó dàbí dígí dídán.

22 Èmi kò sì ri tẹmpili nínú rẹ̀: nítorí pé Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè ni tẹmpili rẹ̀, àti Ọ̀dọ́-àgùntàn. 23 (M)Ìlú náà kò sì ní oòrùn, tàbí òṣùpá, láti máa tan ìmọ́lẹ̀ sí i: nítorí pé ògo Ọlọ́run ni ó ń tàn ìmọ́lẹ̀ sí i, Ọ̀dọ́-àgùntàn sì ni fìtílà rẹ̀. 24 Àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì máa rìn nípa ìmọ́lẹ̀ rẹ̀: àwọn ọba ayé sì ń mú ògo wọn wá sínú rẹ̀. 25 (N)A kì yóò sì ṣé àwọn ẹnu ibodè rẹ̀ rárá ní ọ̀sán: nítorí ki yóò si òru níbẹ̀. 26 Wọ́n ó sì máa mú ògo àti ọlá àwọn orílẹ̀-èdè wá sínú rẹ̀. 27 (O)Ohun aláìmọ́ kan ki yóò sì wọ inú rẹ̀ rárá, tàbí ohun tí ń ṣiṣẹ́ ìríra àti èké; bí kò ṣe àwọn tí a kọ sínú ìwé ìyè Ọ̀dọ́-àgùntàn.

Omi iyè

22 Ó sì fi odò omi ìyè kan hàn mi, tí ó mọ́ bí Kirisitali, tí ń tí ibi ìtẹ́ Ọlọ́run àti tí Ọ̀dọ́-Àgùntàn jáde wá, (P)Ní àárín ìgboro rẹ̀, àti níhà èkínní kejì odò náà, ni igi ìyè gbé wà, tí o máa ń so onírúurú èso méjìlá, a sì máa so èso rẹ̀ ni oṣooṣù ewé igi náà sí wà fún mímú àwọn orílẹ̀-èdè láradà. (Q)Ègún kì yóò sì ṣí mọ: ìtẹ́ Ọlọ́run àti tí Ọ̀dọ́-àgùntàn ni yóò sì máa wà níbẹ̀; àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò sì máa sìn ín: (R)Wọ́n ó si máa rí ojú rẹ̀; orúkọ rẹ̀ yóò si máa wà ni iwájú orí wọn. Òru kì yóò sí mọ́; wọn kò sì ní wa ìmọ́lẹ̀ fìtílà, tàbí ìmọ́lẹ̀ oòrùn; nítorí pé Olúwa Ọlọ́run ni yóò tan ìmọ́lẹ̀ fún wọn: wọn ó sì máa jẹ ọba láé àti láéláé.

Ó sì wí fún mi pé, “Òdodo àti òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: Olúwa Ọlọ́run ẹ̀mí àwọn wòlíì ni ó sì ran angẹli rẹ̀ láti fi ohun tí ó ní láti ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ yìí hàn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.”

“Kíyèsi i, èmi ń bọ̀ kánkán! Ìbùkún ni fún ẹni tí ń pa ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé yìí mọ́!”

Èmi, Johanu, ni ẹni tí ó gbọ́ tí ó sì ri nǹkan wọ̀nyí. Nígbà tí mo sì gbọ́ tí mo sì rí, mo wólẹ̀ láti foríbalẹ̀ níwájú ẹsẹ̀ angẹli náà, tí o fi nǹkan wọ̀nyí hàn mi, Nígbà náà ni ó wí fún mi pé, “Wó ò, má ṣe bẹ́ẹ̀: ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ ni èmi, àti ti àwọn arákùnrin rẹ̀ wòlíì, àti ti àwọn tí ń pa ọ̀rọ̀ inú ìwé yìí mọ́: foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run!”

10 Ó sì wí fún mi pé, “má ṣe fi èdìdì di ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ tí inú ìwé yìí: nítorí ìgbà kù sí dẹ̀dẹ̀. 11 (S)Ẹni tí ń ṣe aláìṣòótọ́, kí ó máa ṣe aláìṣòótọ́ nì só: àti ẹni tí ń ṣe ẹlẹ́gbin, kí ó máa ṣe ẹ̀gbin nì só: àti ẹni tí ń ṣe olódodo, kí ó máa ṣe òdodo nì só: Àti ẹni tí ń ṣe mímọ́, kí ó máa ṣe mímọ́ nì só.”

12 (T)“Kíyèsi i, èmi ń bọ̀ kánkán; èrè mí sì ń bẹ pẹ̀lú mi, láti sán fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ yóò tí rí. 13 (U)Èmi ni Alfa àti Omega, ẹni ìṣáájú àti ẹni ìkẹyìn, ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti òpin.

14 “Ìbùkún ni fún àwọn ti ń fọ aṣọ wọn, kí wọ́n lè ni ẹ̀tọ́ láti wá sí ibi igi ìyè náà, àti kí wọ́n lè gbà àwọn ẹnu ibodè wọ inú ìlú náà. 15 Nítorí ni òde ni àwọn ajá gbé wà, àti àwọn oṣó, àti àwọn àgbèrè, àti àwọn apànìyàn, àti àwọn abọ̀rìṣà, àti olúkúlùkù ẹni tí ó fẹ́ràn èké tí ó sì ń hùwà èké.

16 “Èmi, Jesu, ni ó rán angẹli mi láti jẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí fún yin ní tí àwọn ìjọ. Èmi ni gbòǹgbò àti irú-ọmọ Dafidi, àti ìràwọ̀ òwúrọ̀ tí ń tàn.”

17 (V)Ẹ̀mí àti ìyàwó wí pé, “Máa bọ!” Àti ẹni tí ó ń gbọ́ kí ó wí pé, “Máa bọ̀!” Àti ẹni tí òǹgbẹ ń gbẹ kí ó wá, àti ẹni tí o bá sì fẹ́, kí ó gba omi ìyè náà lọ́fẹ̀ẹ́.

18 Èmi kìlọ̀ fún olúkúlùkù ẹni tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé yìí pé, bí ẹnikẹ́ni ba fi kún wọn, Ọlọ́run yóò fi kún àwọn ìyọnu tí a kọ sínú ìwé yìí fún un. 19 Bí ẹnikẹ́ni bá sì mú kúrò nínú ọ̀rọ̀ ìwé ìsọtẹ́lẹ̀ yìí, Ọlọ́run yóò sì mú ipa tirẹ̀ kúrò nínú ìwé ìyè, àti kúrò nínú ìlú mímọ́ náà, àti kúrò nínú àwọn ohun tí a kọ sínú ìwé yìí.

20 Ẹni tí ó jẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí wí pé, “Nítòótọ́ èmi ń bọ̀ kánkán.”

Àmín, Máa bọ̀, Jesu Olúwa!

21 (W)Oore-ọ̀fẹ́ Jesu Olúwa kí ó wà pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́. Àmín.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.