Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

New Testament in a Year

Read the New Testament from start to finish, from Matthew to Revelation.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Luku 5:17-39

Jesu wo arọ sàn

17 (A)(B) Ní ọjọ́ kan, bí ó sì ti ń kọ́ni, àwọn Farisi àti àwọn amòfin jókòó pẹ̀lú rẹ̀, àwọn tí ó ti àwọn ìletò Galili gbogbo, àti Judea, àti Jerusalẹmu wá: agbára Olúwa sì ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀ láti mú wọn láradá. 18 Sá à sì kíyèsi i, àwọn Ọkùnrin kan gbé ẹnìkan tí ó ní ààrùn ẹ̀gbà wà lórí àkéte: wọ́n ń wá ọ̀nà àti gbé e wọlé, àti láti tẹ́ ẹ síwájú Jesu. 19 Nígbà tí wọn kò sì rí ọ̀nà tí wọn ìbá fi gbé e wọlé nítorí ìjọ ènìyàn, wọ́n gbé e gun òkè àjà ilé lọ, wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ sí àárín èrò ti òun ti àkéte rẹ̀ níwájú Jesu.

20 (C)Nígbà tí ó sì rí ìgbàgbọ́ wọn, ó wí pé, “Ọkùnrin yìí, a darí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”

21 (D)Àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisi bẹ̀rẹ̀ sí í gbèrò wí pé, “Ta ni eléyìí tí ń sọ ọ̀rọ̀-òdì? Ta ni ó lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni bí kò ṣe Ọlọ́run nìkan ṣoṣo.”

22 Jesu sì mọ èrò inú wọn, ó dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ẹ fi ń ro nǹkan wọ̀nyí nínú ọkàn yín? 23 Èwo ni ó yá jù: láti wí pé, ‘A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́,’ tàbí láti wí pé, ‘Dìde kí ìwọ sì máa rìn’? 24 Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin lè mọ̀ pé ọmọ ènìyàn ní agbára ní ayé láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni.” Ó wí fún ẹlẹ́gbà náà pé, “Mo wí fún ọ, dìde, sì gbé àkéte rẹ, kí o sì máa lọ sí ilé!” 25 Ó sì dìde lọ́gán níwájú wọn, ó gbé ohun tí ó dùbúlẹ̀ lé, ó sì lọ sí ilé rẹ̀, ó yin Ọlọ́run lógo. 26 Ẹnu sì ya gbogbo wọn, wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo, ẹ̀rù sì bà wọ́n, wọ́n ń wí pé, “Àwa rí ohun ìyanu lónìí.”

Ìpè Lefi

27 (E)Lẹ́hìn èyí, Jesu jáde lọ, ó sì rí agbowó òde kan tí à ń pè ní Lefi ó jókòó sí ibi tí ó ti ń gba owó òde, Jesu sì wí fún un pé “Tẹ̀lé mi,” 28 Lefi sì fi ohun gbogbo sílẹ̀ ó sì ń tẹ̀lé e.

29 Lefi sì ṣe àsè ńlá kan fún Jesu ní ilé rẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn agbowó òde àti àwọn mìíràn sì ń jẹun pẹ̀lú wọn. 30 (F)Ṣùgbọ́n àwọn Farisi, àwọn olùkọ́ òfin tí ó jẹ́ ara wọn fi ẹ̀sùn kan àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pe “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń jẹun tí ẹ sì ń mú pẹ̀lú àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.”

31 Jesu dáhùn ó wí fún wọn pé, “Ẹni tí ara rẹ̀ le kò nílò oníṣègùn, bí kò ṣe ẹni tí ara rẹ̀ kò dá. 32 (G)Èmí kò wá láti pe àwọn olódodo bí kò ṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sí ìrònúpìwàdà.”

A béèrè nípa àwẹ̀ lọ́wọ́ Jesu

33 (H)(I) Wọ́n wí fún pé “Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu a máa gbààwẹ̀, wọn a sì máa gbàdúrà, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú sì ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àwọn Farisi ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ a máa jẹ, wọn a sì máa mu pẹ̀lú.”

34 Jesu sì dáhùn ó wí fún wọn pé, “Ǹjẹ́ ó ṣe é ṣe kí àwọn àlejò ọkọ ìyàwó máa gbààwẹ̀ nígbà tí ọkọ ìyàwó wà pẹ̀lú wọn bí? 35 Ṣùgbọ́n àkókò ń bọ̀ nígbà tí a ó gba ọkọ ìyàwó kúrò lọ́dọ̀ wọn, ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí ni wọn yóò gbààwẹ̀.”

36 Ó sì pa òwe yìí fún wọn wí pé: “Kò sí ẹni tó lè ya aṣọ tuntun kí ó sì rán mọ́, èyí tó ti gbó. Tí ó ba ṣe èyí, yóò ba aṣọ tuntun jẹ́, èyí tí ó tuntun náà kì yóò sì dọ́gba pẹ̀lú èyí tí ó ti gbó. 37 Àti wí pé, kò sí ẹni tí ó lè dá ọtí wáìnì tuntun sínú ògbólógbòó ìgò-awọ, tí ó bá ṣe èyí, wáìnì tuntun yóò fa awọ náà ya, wáìnì náà yóò dànù, awọ náà a sì bàjẹ́. 38 Nítorí náà, ó tọ́ kí á da wáìnì tuntun sínú awọ tuntun. 39 Kò sì ẹni tí yóò fẹ́ láti mu wáìnì tuntun lẹ́yìn tí ó bá ti mu ògbólógbòó tán, nítorí yóò wí pé, ‘Èyí tí ó jẹ́ ògbólógbòó dára jù.’ ”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.