M’Cheyne Bible Reading Plan
Amnoni àti Tamari
13 Ó sì ṣe, lẹ́yìn èyí, Absalomu ọmọ Dafidi ní àbúrò obìnrin kan tí ó ṣe arẹwà, orúkọ rẹ̀ a sì máa jẹ́ Tamari; Amnoni ọmọ Dafidi sì fẹ́ràn rẹ̀.
2 Amnoni sì banújẹ́ títí ó fi ṣe àìsàn nítorí Tamari àbúrò rẹ̀ obìnrin; nítorí pé wúńdíá ni; ó sì ṣe ohun tí ó ṣòro lójú Amnoni láti bá a dàpọ̀.
3 Ṣùgbọ́n Amnoni ní ọ̀rẹ́ kan, orúkọ rẹ̀ a sì máa jẹ́ Jonadabu, ọmọ Ṣimea ẹ̀gbọ́n Dafidi: Jonadabu sì jẹ́ alárékérekè ènìyàn gidigidi. 4 Ó sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ ọmọ ọba ń fi ń rù lójoojúmọ́ báyìí? Ǹjẹ́ o kò ní sọ fún mi?”
Amnoni sì wí fún un pé, “Èmi fẹ́ Tamari àbúrò Absalomu arákùnrin mi.”
5 Jonadabu sì wí fún un pé, “Dùbúlẹ̀ ní ibùsùn rẹ kí ìwọ sì díbọ́n pé, ìwọ kò sàn: baba rẹ yóò sì wá wò ọ́, ìwọ ó sì wí fún un pé, ‘Jọ̀wọ́ jẹ́ kí Tamari àbúrò mi wá kí ó sì fún mi ní oúnjẹ kí ó sì ṣe oúnjẹ náà níwájú mi kí èmi ó rí i, èmi ó sì jẹ ẹ́ ní ọwọ́ rẹ̀.’ ”
6 Amnoni sì dùbúlẹ̀, ó sì díbọ́n pé òun ṣàìsàn: ọba sì wá wò ó, Amnoni sì wí fún ọba pé, “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí Tamari àbúrò mi ó wá, kí ó sì dín àkàrà méjì lójú mi, èmi ó sì jẹ ní ọwọ́ rẹ̀.”
7 Dafidi sì ránṣẹ́ sí Tamari ní ilé pé, “Lọ sí ilé Amnoni ẹ̀gbọ́n rẹ, kí ó sì se oúnjẹ fún un.” 8 Tamari sì lọ sí ilé Amnoni ẹ̀gbọ́n rẹ̀, òun sì ń bẹ ní ìdùbúlẹ̀. Tamari sì mú ìyẹ̀fun, ó sì pò ó, ó sì fi ṣe àkàrà lójú rẹ̀, ó sì dín àkàrà náà. 9 Òun sì mú àwo náà, ó sì dà á sínú àwo mìíràn níwájú rẹ̀; ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti jẹ.
Amnoni sì wí pé, “Jẹ́ kí gbogbo ọkùnrin jáde kúrò lọ́dọ̀ mi!” Wọ́n sì jáde olúkúlùkù ọkùnrin kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. 10 Amnoni sì wí fún Tamari pé, “Mú oúnjẹ náà wá sí yàrá, èmi ó sì jẹ ẹ́ lọ́wọ́ rẹ.” Tamari sì mú àkàrà tí ó ṣe, ó sì mú un tọ Amnoni ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ní yàrá. 11 Nígbà tí ó sì súnmọ́ ọn láti fi oúnjẹ fún un, òun sì dìímú, ó sì wí fún un pé, “Wá dùbúlẹ̀ tì mí, àbúrò mi.”
12 Òun sì dá a lóhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́ ẹ̀gbọ́n mi, má ṣe tẹ́ mi; nítorí pé kò tọ kí a ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ní Israẹli, ìwọ má ṣe hùwà òmùgọ̀ yìí. 13 Àti èmi, níbo ni èmi ó gbé ìtìjú mi wọ̀? Ìwọ ó sì dàbí ọ̀kan nínú àwọn aṣiwèrè ní Israẹli. Ǹjẹ́ nítorí náà, èmi bẹ̀ ọ́, sọ fún ọba; nítorí pé òun kì yóò kọ̀ láti fi mí fún ọ.” 14 Ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti gbọ́ ohùn rẹ̀; ó sì fi agbára mú un, ó sì ṣẹ́gun rẹ̀, ó sì bá a dàpọ̀.
15 Amnoni sì kórìíra rẹ̀ gidigidi, ìríra náà sì wá ju ìfẹ́ tí òun ti ní sí i rí lọ. Amnoni sì wí fún un pé, “Dìde, kí o sì máa lọ!”
16 Òun sì wí fún un pé, “Kó ha ní ìdí bí! Lílé tí ìwọ ń lé mi yìí burú ju èyí tí ìwọ ti ṣe sí mi lọ.”
Ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ gbọ́ tirẹ̀. 17 Òun sì pe ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ tí í ṣe ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Jọ̀wọ́, ti obìnrin yìí sóde fún mi, kí o sì ti ìlẹ̀kùn mọ́ ọn.” 18 Òun sì ní aṣọ aláràbarà kan lára rẹ̀: nítorí irú aṣọ àwọ̀lékè bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọbìnrin ọba tí í ṣe wúńdíá máa ń wọ̀. Ìránṣẹ́ rẹ̀ sì mú un jáde, ó sì ti ìlẹ̀kùn mọ́ ọn. 19 Tamari sì bu eérú sí orí rẹ̀, ó sì fa aṣọ aláràbarà tí ń bẹ lára rẹ̀ ya, ó sì ká ọwọ́ rẹ̀ lé orí, ó sì ń kígbe bí ó ti ń lọ.
Absalomu kọlu Amnoni
20 Absalomu ẹ̀gbọ́n rẹ̀ sì bí i léèrè pé, “Amnoni ẹ̀gbọ́n rẹ bá ọ sùn bí? Ǹjẹ́ àbúrò mi, dákẹ́; ẹ̀gbọ́n rẹ ní í ṣe; má fi nǹkan yìí sí ọkàn rẹ.” Tamari sì jókòó ní ìbànújẹ́ ní ilé Absalomu ẹ̀gbọ́n rẹ̀.
21 Ṣùgbọ́n nígbà tí Dafidi ọba gbọ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí, inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi. 22 Absalomu kò sì bá Amnoni sọ nǹkan rere, tàbí búburú: nítorí pé Absalomu kórìíra Amnoni nítorí èyí tí ó ṣe, àní tí ó fi agbára mú Tamari àbúrò rẹ̀.
23 Ó sì ṣe, lẹ́yìn ọdún méjì, Absalomu sì ní olùrẹ́run àgùntàn ní Baali-Hasori, èyí tí ó gbé Efraimu: Absalomu sì pe gbogbo àwọn ọmọ ọba. 24 Absalomu sì tọ ọba wá, ó sì wí pé, “Wò ó, jọ̀wọ́, ìránṣẹ́ rẹ ní olùrẹ́run àgùntàn, èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ọba, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bá ìránṣẹ́ rẹ lọ.”
25 Ọba sì wí fún Absalomu pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ, ọmọ mi, mo bẹ̀ ọ́, má ṣe jẹ́ kí gbogbo wa lọ, kí a má bá à mú ọ náwó púpọ̀.” Ó sì rọ̀ ọ́ gidigidi, ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ lọ, òun sì súre fún un.
26 Absalomu sì wí pé, “Bí kò bá le rí bẹ́ẹ̀, èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí Amnoni ẹ̀gbọ́n mi bá wa lọ.”
Ọba sì wí pé, “Ìdí rẹ̀ tí yóò fi bá ọ lọ.” 27 Absalomu sì rọ̀ ọ́, òun sì jẹ́ kí Amnoni àti gbogbo àwọn ọmọ ọba bá a lọ.
28 Absalomu sì fi àṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Kí ẹ̀yin máa kíyèsi àkókò tí ọtí-wáinì yóò mú ọkàn Amnoni dùn, èmi ó sì wí fún yín pé, ‘Kọlu Amnoni,’ kí ẹ sì pa á. Ẹ má bẹ̀rù. Ṣé èmi ni ó fi àṣẹ fún yin? Ẹ ṣe gírí, kí ẹ ṣe bí alágbára ọmọ.” 29 Àwọn ìránṣẹ́ Absalomu sì ṣe sí Amnoni gẹ́gẹ́ bí Absalomu ti pàṣẹ. Gbogbo àwọn ọmọ ọba sì dìde, olúkúlùkù gun ìbáaka rẹ̀, wọ́n sì sá.
30 Nígbà tí wọ́n ń bẹ lọ́nà, ìròyìn sì dé ọ̀dọ̀ Dafidi pé, “Absalomu pa gbogbo àwọn ọmọ ọba, ọ̀kan kò sì kù nínú wọn.” 31 Ọba sì dìde, ó sì fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì dùbúlẹ̀ ni ilẹ̀; gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n dúró tì í sì fà aṣọ wọn ya.
32 Jonadabu ọmọ Ṣimea arákùnrin Dafidi sì dáhùn ó sì wí pé, “Kí olúwa mi ọba má ṣe rò pé wọ́n ti pa gbogbo àwọn ọ̀dọ́mọdékùnrin àwọn ọmọ ọba; nítorí pé Amnoni nìkan ṣoṣo ni ó kú: nítorí láti ẹnu Absalomu wá ni a ti pinnu rẹ̀ láti ọjọ́ tí ó ti fi agbára mú Tamari àbúrò rẹ̀. 33 Ǹjẹ́ kí olúwa mi ọba má ṣe fi nǹkan yìí sí ọkàn pé gbogbo àwọn ọmọ ọba ni o kú: nítorí Amnoni nìkan ṣoṣo ni ó kú.”
Absalomu sálọ sí Geṣuri
34 Absalomu sì sá.
Ọ̀dọ́mọkùnrin náà ti ń ṣọ́nà sì gbé ojú rẹ̀ sókè, o si rí i pé, “ọ̀pọ̀ ènìyàn ń bọ́ lọ́nà lẹ́yìn rẹ̀ láti ìhà òkè wá.”
35 Jonadabu sì wí fún ọba pé, “Wò ó, àwọn ọmọ ọba ń bọ́; gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó rí.”
36 Nígbà tí ó sì parí ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ, sì wò ó àwọn ọmọ ọba dé, wọ́n sì gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì sọkún: ọba àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú sì sọkún ńláńlá.
37 Absalomu sì sá, ó sì tọ Talmai lọ, ọmọ Ammihudu, ọba Geṣuri. Dafidi sì ń káàánú nítorí ọmọ rẹ̀ lójoojúmọ́.
38 Absalomu sì sá, ó sì lọ sí Geṣuri ó sì gbé ibẹ̀ lọ́dún mẹ́ta. 39 Ọkàn Dafidi ọba sì fà gidigidi sí Absalomu: nítorí tí ó tí gba ìpẹ̀ ní ti Amnoni: ó sá à ti kú.
6 Gẹ́gẹ́ bí alábáṣiṣẹ́pọ̀ nínú Ọlọ́run, ǹjẹ́, àwa ń rọ̀ yín kí ẹ má ṣe gba oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run lásán. 2 (A)Nítorí o wí pé,
“Ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà mi, èmi tí gbọ́ ohùn rẹ,
àti ọjọ́ ìgbàlà, èmi sì ti ràn ọ́ lọ́wọ́.”
Èmi wí fún ọ, nísinsin yìí ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà, nísinsin yìí ni ọjọ́ ìgbàlà.
Àwọn wàhálà Paulu
3 Àwa kò sì gbé ohun ìkọ̀sẹ̀ kankan si ọ̀nà ẹnikẹ́ni, ki iṣẹ́ ìránṣẹ́ wa má ṣe di ìṣọ̀rọ̀-òdì-sí. 4 (B)Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, ni ọnà gbogbo, àwa ń fi ara wa hàn bí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ sùúrù, nínú ìpọ́njú, nínú àìní, nínú wàhálà, 5 (C)nípa nínà, nínú túbú, nínú ìrúkèrúdò, nínú iṣẹ́ àṣekára, nínú àìsàn, nínú ìgbààwẹ̀. 6 Nínú ìwà mímọ́, nínú ìmọ̀, nínú ìpamọ́ra, nínú ìṣeun, nínú Ẹ̀mí Mímọ́, nínú ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn. 7 (D)Nínú ọ̀rọ̀ òtítọ́, nínú agbára Ọlọ́run, nínú ìhámọ́ra òdodo ní apá ọ̀tún àti ní apá òsì. 8 Nípa ọlá àti ẹ̀gàn, nípa ìyìn búburú àti ìhìnrere: bí ẹlẹ́tàn, ṣùgbọ́n a jásí olóòtítọ́, 9 (E)bí ẹni tí a kò mọ̀, ṣùgbọ́n a mọ̀ wá dájúdájú; bí ẹni tí ń kú lọ, ṣùgbọ́n a ṣì wà láààyè; bí ẹni tí a nà, ṣùgbọ́n a kò sì pa wá, 10 (F)bí ẹni tí ó kún fún ìbànújẹ́, ṣùgbọ́n àwa ń yọ̀ nígbà gbogbo; bí tálákà, ṣùgbọ́n àwa ń sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ dí ọlọ́rọ̀; bí ẹni tí kò ní nǹkan, ṣùgbọ́n àwa ni ohun gbogbo.
11 (G)Ẹ̀yin ará Kọrinti, a ti bá yín sọ òtítọ́ ọ̀rọ̀, a ṣí ọkàn wa páyà sí yín. 12 Àwa kò fa ìfẹ́ wa sẹ́hìn fún yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin fa ìfẹ́ yín sẹ́hìn kúrò lọ́dọ̀ wa. 13 Ní sísán padà, ní ọ̀nà tí ó dára, èmi ń sọ bí ẹni pé fún àwọn ọmọdé, ẹ̀yin náà ẹ ṣí ọkàn yín páyà pẹ̀lú.
Má ṣe dàpọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́
14 Ẹ má ṣe fi àìdọ́gba dàpọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́: nítorí ìdàpọ̀ kín ni òdodo ní pẹ̀lú àìṣòdodo? Ìdàpọ̀ kín ni ìmọ́lẹ̀ sì ní pẹ̀lú òkùnkùn? 15 Ìrẹ́pọ̀ kín ni Kristi ní pẹ̀lú Beliali? Tàbí ìpín wó ni ẹni tí ó gbàgbọ́ ní pẹ̀lú aláìgbàgbọ́? 16 (H)Ìrẹ́pọ̀ kín ni tẹmpili Ọlọ́run ní pẹ̀lú òrìṣà? Nítorí ẹ̀yin ní tẹmpili Ọlọ́run alààyè; gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti wí pé:
“Èmi á gbé inú wọn,
èmi o sì máa rìn láàrín wọn,
èmi ó sì jẹ́ Ọlọ́run wọn,
wọn yóò sì jẹ́ ènìyàn mi.”
17 (I)Nítorí náà,
“Ẹ jáde kúrò láàrín wọn,
kí ẹ sì yá ara yín si ọ̀tọ̀,
ni Olúwa wí.
Ki ẹ má ṣe fi ọwọ́ kan ohun àìmọ́;
Èmi ó sì gbà yín.”
18 Àti,
(J)“Èmi o sì jẹ́ Baba fún yín,
Ẹ̀yin ó sì jẹ́ ọmọkùnrin mi àti ọmọbìnrin mi!
ní Olúwa Olódùmarè wí.”
Ìwà ọlọ́tẹ̀ tí Israẹli hù
20 Ní ọjọ́ kẹwàá, oṣù karùn-ún ọdún keje, ní díẹ̀ nínú àwọn àgbàgbà Israẹli wá wádìí lọ́wọ́ Olúwa, wọn jókòó níwájú mi.
2 Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: 3 “Ọmọ ènìyàn, sọ fún àwọn àgbàgbà Israẹli, kì ó sì wí fún wọn pé, ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Ṣe ki ẹ lè wádìí lọ́dọ̀ mi ni ẹ ṣe wá? Bí mo ti wà láààyè, ní Olúwa Olódùmarè wí, Èmi kì yóò gbà kí ẹ wádìí lọ́dọ̀ mi.’
4 “Ìwọ fẹ́ dájọ́ wọn bí? Ìwọ fẹ́ dájọ́ wọn bí ọmọ ènìyàn? Nítorí náà fi gbogbo ìwà ìríra baba wọn kò wọ́n lójú, 5 kí ó sì sọ fún wọn pé: ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Ní ọjọ́ tí mo yàn Israẹli, mo gbé ọwọ́ mi sókè nínú ìbúra sí àwọn ọmọ ilé Jakọbu, mo sì fi ara mi hàn wọn ní Ejibiti, mo gbé ọwọ́ mi sókè nínú ẹ̀jẹ́ wí pé, “Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.” 6 Ní ọjọ́ náà mo lọ búra fún wọn pé, èmi yóò mú wọn jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti lọ sí ilẹ̀ ti mo ti wá sílẹ̀ fún wọn, ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin, ilẹ̀ tí ó lẹ́wà jùlọ láàrín àwọn ilẹ̀ yòókù. 7 Mo sì wí fún wọn pé, “Kí olúkúlùkù nínú yín gbé ìríra ojú rẹ̀ kúrò, kí ẹ sì má bá sọ ara yín di àìmọ́ pẹ̀lú àwọn òrìṣà Ejibiti, èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.”
8 “ ‘Ṣùgbọ́n wọn ṣọ̀tẹ̀ sí mi wọn kò sì gbọ́rọ̀, wọn kò gbé àwòrán ìríra tí wọ́n dojúkọ kúrò níwájú wọn bẹ́ẹ̀ ni wọn kò si kọ̀ àwọn òrìṣà Ejibiti sílẹ̀, torí náà mo sọ pé èmi yóò tú ìbínú gbígbóná mi lé wọn lórí, èmi yóò sì jẹ́ kí ìbínú mi sẹ̀ lórí wọn ní ilẹ̀ Ejibiti. 9 Ṣùgbọ́n nítorí orúkọ mi, mo ṣe ohun tí kò ní jẹ́ kí orúkọ mi bàjẹ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn ń gbé láàrín wọn, lójú àwọn ẹni tí mo ti fi ara hàn fún ara Israẹli nípa mímú wọn jáde ní ilẹ̀ Ejibiti. 10 Nítorí náà, mo mú wọn jáde ní ilẹ̀ Ejibiti mo sì mú wọn wá sínú aginjù. 11 Mo sì fún wọn ni òfin mi, mo sì fi àwọn òfin mi hàn wọ́n; nítorí pé ẹni tó bá ṣe wọ́n yóò yè nípa wọn. 12 Bẹ́ẹ̀ ni mo fún wọn ní ọjọ́ ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ààmì láàrín àwọn àti èmi, kí wọn lè mọ̀ pé èmi ni Olúwa tó sọ wọn di mímọ́.
13 “ ‘Síbẹ̀; ilé Israẹli ṣọ̀tẹ̀ sí mí nínú aginjù. Wọn kò tẹ̀lé àṣẹ mi, wọn sì kọ àwọn òfin mi sílẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni tó bá pa á mọ́ yóò yè nínú rẹ̀. Wọn sì sọ ọjọ́ ìsinmi mi di aláìmọ́ lọ́pọ̀lọpọ̀. Nítorí náà, mo sọ pé èmi yóò tú ìbínú gbígbóná mi sórí wọn, èmi yóò sì pa wọ́n run nínú aginjù. 14 Ṣùgbọ́n nítorí orúkọ mi, mo ṣe ohun tí kò ní mú kí orúkọ mi bàjẹ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè tí mo kó wọn jáde. 15 Nítorí náà, mo tún gbọ́wọ́ mi sókè ní ìbúra fún wọn nínú aginjù pé, èmi kì yóò mú wọn dé ilẹ̀ tí mo fi fún wọn—ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin, ilẹ̀ tí ó lẹ́wà jùlọ láàrín àwọn ilẹ̀ yòókù. 16 Nítorí pé, wọn kọ òfin mi sílẹ̀, wọn kò sì tẹ̀lé àṣẹ mi, wọn sọ ọjọ́ ìsinmi mi dí aláìmọ́. Nítorí pé tọkàntọkàn ni wọn ń tẹ̀lé òrìṣà wọn. 17 Síbẹ̀síbẹ̀ mo wò wọ́n pẹ̀lú àánú, ń kò sì pa wọ́n run tàbí kí òpin dé bá wọn nínú aginjù. 18 Ṣùgbọ́n mo sọ fún àwọn ọmọ wọn nínú aginjù pé, “Ẹ má ṣe rìn ní ìlànà àwọn baba yín, ẹ má ṣe pa òfin wọn mọ́, ẹ má ṣe bá ara yín jẹ́ pẹ̀lú òrìṣà wọn. 19 Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, ẹ tẹ̀lé àṣẹ mi, kí ó sì pa òfin mi mọ́. 20 Ẹ ya ọjọ́ ìsinmi mi sí mímọ́ kí ó lè jẹ́ ààmì láàrín wa: ki ẹ lè mọ̀ pé èmi ní Olúwa Ọlọ́run yín.”
21 “ ‘Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ náà ṣọ̀tẹ̀ sí mi. Wọn kò tẹ̀lé àṣẹ mi, wọn kò sì pa òfin mi mọ́ bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni tó bá tẹ̀lé àwọn òfin yìí, yóò yè nínú rẹ̀, wọ́n sì tún sọ ọjọ́ ìsinmi mi di aláìmọ́. Nítorí náà, mo sọ pé èmi yóò tú ìbínú mi lórí wọn, Èmi yóò sì mú kí ìbínú gbígbóná mi wá sórí wọn ni aginjù. 22 Síbẹ̀síbẹ̀ mo dáwọ́ dúró, nítorí orúkọ mi, mo sì ṣe ohun tí kò ní ba orúkọ mi jẹ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè ti mo kó wọn jáde lójú wọn. 23 Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lú ọwọ́ ti mo gbé sókè sí wọn, mo búra fún wọn nínú aginjù pé èmi yóò tú wọn ka sì àárín àwọn orílẹ̀-èdè, èmi yóò sì fọ́n wọn káàkiri ilẹ̀ gbogbo, 24 nítorí pé wọn kò pa òfin mi mọ́, wọn sì tún kọ àṣẹ mi sílẹ̀, wọn tún sọ ọjọ́ ìsinmi mi di aláìmọ́. Ojú wọn sì wà ní ara òrìṣà baba wọn. 25 Èmi náà sì fi wọn fún ìlànà tí kò dára àti òfin tí wọn kò le e yè nípa rẹ̀; 26 Mo jẹ́ kí ó sọ wọn di aláìmọ́ nípa ẹ̀bùn nípa fífi àkọ́bí ọmọ wọn rú ẹbọ sísun, àkọ́bí wọn la iná kọjá, kí èmi sọ wọ́n di ahoro, kí wọn le mọ̀ pé èmi ni Olúwa.’
27 “Nítorí náà, Ọmọ ènìyàn, sọ fún ilé Israẹli kí ó sì wí fún wọn pé, ‘Èyí ní ohun ti Olúwa Olódùmarè wí: Nínú èyí tí baba yín ti sọ̀rọ̀-òdì sí mi, nípa kíkọ̀ mí sílẹ̀. 28 Nítorí nígbà tí mo mú wọn dé ilẹ̀ náà, tí mo gbé ọwọ́ mi sókè láti fi í fún wọn, Nígbà náà ni wọ́n rí olúkúlùkù òkè gíga, àti gbogbo igi bíbò, wọ́n sì rú ẹbọ wọn níbẹ̀, wọ́n sì gbé ìmúnibínú ọrẹ wọ́n kalẹ̀ níbẹ̀; níbẹ̀ pẹ̀lú ni wọ́n ṣe òórùn dídùn wọn, wọ́n sì ta ohun ọrẹ mímu sílẹ̀ níbẹ̀, 29 Nígbà náà ni mo wí fún wọn pé: Kí ní ibi gíga tí ẹ̀yin lọ yìí?’ ” (Orúkọ rẹ̀ ni a sì ń pè ní Bama di òní yìí.)
Ìdájọ́ Àti Ìmúpadàbọ̀sípò
30 “Nítorí náà sọ fún ilé Israẹli pé: ‘Èyí ní ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Ṣé o fẹ́ ba ara rẹ jẹ́ bi àwọn baba rẹ ṣe ṣe, tiwọn ń ṣe àgbèrè nípa títẹ̀lé àwọn àwòrán ìríra? 31 Nígbà tí ẹ̀yin bá san ọrẹ yìí, ìrúbọ ọmọkùnrin ọmọ yín, tí ẹ mú ọmọ yin la iná kọjá, ẹ̀yin ń tẹ̀síwájú láti ba ara yín jẹ́ pẹ̀lú àwọn òrìṣà yín títí di òní yìí, ẹ̀yin yóò ha jẹ wádìí lọ́dọ̀ mi, ìwọ ilé Israẹli? Bí mo ti wà láààyè, ní Olúwa Olódùmarè wí, Èmi ki yóò jẹ́ kí ẹ wádìí lọ́dọ̀ mi.
32 “ ‘Ẹ̀yin wí pé, “Àwa fẹ́ dàbí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, bí àwọn ènìyàn ayé, tó ń bọ igi àti òkúta.” Ṣùgbọ́n ohun ti ẹ ni lọ́kàn kò ní ṣẹ rárá. 33 Bí mo ti wà láààyè, ní Olúwa Olódùmarè wí, Èmi yóò jẹ ọba lórí yín pẹ̀lú ọwọ́ agbára tí èmi yóò nà jáde pẹ̀lú ìtújáde ìbínú gbígbóná mi. 34 Èmi yóò si mú yín jáde kúrò láàrín àwọn ènìyàn, èmi yóò sì ṣà yín jọ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè tí a fọ́n yín sí pẹ̀lú ọwọ́ agbára àti apá nínà tí èmi yóò nà jáde àti pẹ̀lú ìtújáde ìbínú gbígbóná ni. 35 Èmi yóò si mú yín wá sí aginjù àwọn orílẹ̀-èdè, níbẹ̀ ni ojúkójú ni èmi yóò ṣe ìdájọ́ lé e yín lórí. 36 Bí mo ṣe ṣe ìdájọ́ àwọn baba yín nínú aginjù nílẹ̀ Ejibiti, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣe ìdájọ́ yín ní Olúwa Olódùmarè wí. 37 Èmi yóò kíyèsi i yín bí mo ti mú un yín kọjá lábẹ́ ọ̀pá, èmi yóò sì mú yín wá sí abẹ́ ìdè májẹ̀mú 38 Èmi yóò si ṣa àwọn ọlọ̀tẹ̀ kúrò láàrín yín, àti àwọn o lù re òfin kọjá, èmi yóò mu wọn jáde kúrò ni ilẹ̀ tiwọn gbé ṣe àtìpó, wọn ki yóò si wọ ilẹ̀ Israẹli: Nígbà náà ní ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, èmi ní Olúwa.
39 “ ‘Ní tí ẹ̀yin, ilé Israẹli, èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Kí olúkúlùkù yín lọ máa sìn òrìṣà rẹ̀, ṣùgbọ́n lẹ́yìn èyí, ẹ̀yin yóò gbọ́ tèmi, ẹ̀yin kò sí ní i bá orúkọ mímọ́ mi jẹ́ pẹ̀lú ọrẹ àti àwọn òrìṣà yín mọ́. 40 Nítorí lórí òkè mímọ́ mi, lórí òkè gíga Israẹli, ni Olúwa Olódùmarè wí, níbẹ̀ ni ilẹ̀ náà ní gbogbo ilé Israẹli yóò sìn mí; èmi yóò sì tẹ́wọ́ gba wọ́n níbẹ̀. Níbẹ̀ èmi yóò béèrè ọrẹ àti ẹ̀bùn nínú àkọ́so yín pẹ̀lú gbogbo ẹbọ mímọ́ yín 41 Èmi yóò tẹ́wọ́ gbà yín gẹ́gẹ́ bí tùràrí olóòórùn dídùn nígbà tí mo ba mú yín jáde láàrín àwọn orílẹ̀-èdè tí a fọ́n yín ká sí, èmi yóò sì fi ìwà mímọ́ mi hàn láàrín yín lójú àwọn orílẹ̀-èdè. 42 Nígbà náà ni ẹ o mọ̀ pé èmi ní Olúwa, nígbà tí mo bá mú yín wa sí ilẹ̀ Israẹli; sí ilẹ̀ tí mo gbọ́wọ́ mí sókè nínú ẹ̀jẹ́ láti fún àwọn baba yín. 43 (A)Níbẹ̀ ni ẹ ó wa rántí ìwà àti gbogbo ìṣesí yín, èyí tí ẹ̀yin fi sọ ara yín di aláìmọ́, ẹ̀yin yóò sì kórìíra ara yín fún gbogbo ibi tí ẹ̀yin ti ṣe. 44 Nígbà náà ní ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa, nígbà tí mo bá hùwà sí yín nítorí orúkọ mi ni, tí ń kò hùwà sí yín gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ibi àti ìwà ìríra yín. Ẹ̀yin Ilé Israẹli, ni Olúwa Olódùmarè wí.’ ”
Sọtẹ́lẹ̀ lòdì sí ìhà gúúsù
45 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá: 46 “Ọmọ ènìyàn, dojúkọ ìhà gúúsù; wàásù lòdì sí gúúsù kí ìwọ sì sọtẹ́lẹ̀ sí igbó ilẹ̀ gúúsù. 47 Sọ fún igbó ìhà gúúsù pé: ‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa. Èyí ní ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Kíyèsi í, èmi yóò dá iná kan nínú rẹ̀, yóò sì jó olúkúlùkù igi tútù nínú rẹ̀, àti olúkúlùkù igi gbígbẹ, Jíjò ọwọ́ iná náà ní kí yóò ṣé é pa, àti gbogbo ojú láti gúúsù dé àríwá ni a ó sun nínú rẹ̀. 48 Gbogbo ènìyàn yóò sì mọ̀ pé Èmi Olúwa ni ó dá a, a kì yóò sì le è pa á.’ ”
49 Nígbà náà ni mo wí pé, “Háà! Olúwa Olódùmarè! Wọn ń wí fún mi pé, ‘Kì í wa ṣe pé òwe lo ń pa bí?’ ”
Fún adarí orin. Orin. Saamu.
66 Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọ́run, ẹ̀yin ilẹ̀ gbogbo!
2 Ẹ kọrin ọlá orúkọ rẹ̀;
Ẹ kọrin ìyìnsí i,
3 Ẹ wí fún Ọlọ́run “pé,
ìwọ ti ní ẹ̀rù tó nínú iṣẹ́ rẹ!
Nípa ọ̀pọ̀ agbára rẹ ni àwọn ọ̀tá
rẹ yóò fi sìn ọ́.
4 Gbogbo ayé ń wólẹ̀ fún ọ;
wọn ń kọrin ìyìn sí ọ,
wọ́n ń kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ.” Sela.
5 Ẹ wá wo ohun tí Ọlọ́run ṣe,
Iṣẹ́ rẹ̀ ti ní ẹ̀rù tó sí àwọn ọmọ ènìyàn!
6 Ó yí Òkun padà sí ilẹ̀ gbígbẹ,
wọ́n fi ẹsẹ̀ rin inú omi kọjá,
níbẹ̀ ni àwa yọ̀ nínú rẹ̀.
7 Ó ń jẹ ọba títí láé nípa agbára rẹ̀,
ojú rẹ̀ ń wo orílẹ̀-èdè
kí àwọn ọlọ̀tẹ̀ má ṣe gbé ara wọn ga. Sela.
8 Ẹ yin Ọlọ́run wa, ẹ̀yin ènìyàn,
jẹ́ kí a mú ni gbọ́ ohùn ìyìn rẹ̀;
9 Ó ti dá ààbò bo ẹ̀mí wa,
kò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ wa kí ó yẹ̀
10 Nítorí ìwọ, Ọlọ́run, dán wa wò;
ìwọ dán wa bí a tí ń dán fàdákà wò.
11 Ìwọ mú wa wá sínú ẹ̀wọ̀n
o sì di ẹrù lé ẹ̀yìn wa
12 Ìwọ mú àwọn ènìyàn gún wá ní orí
àwa la iná àti omi kọjá
ṣùgbọ́n ìwọ mú wa dé ibi ọ̀pọ̀.
13 Èmi ó wá sí tẹmpili rẹ pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun,
kí n sì mú ẹ̀jẹ́ mi ṣẹ sí ọ
14 Ẹ̀jẹ́ tí ètè mi jẹ́, tí ẹnu mi sì sọ
nígbà tí mo wà nínú ìṣòro.
15 Èmi ó rú ẹbọ sísun ọlọ́ràá sí ọ,
àti ẹbọ ọ̀rá àgbò;
èmi ó rú akọ màlúù àti ewúrẹ́. Sela.
16 Ẹ wá gbọ́ gbogbo ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run;
ẹ jẹ́ kí n sọ ohun tí ó ṣe fún mi.
17 Mo fi ẹnu mi kígbe sókè sí i:
Ìyìn rẹ̀ wà ní ẹnu mi.
18 Bí èmi bá gba ẹ̀ṣẹ̀ ní àyà mi,
Olúwa kì yóò gbọ́ ohùn mi;
19 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run gbọ́ nítòótọ́
ó ti gbọ́ ohùn mi nínú àdúrà.
20 Ìyìn ni fún Ọlọ́run
ẹni tí kò kọ àdúrà mi
tàbí mú ìfẹ́ rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi!
Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Saamu. Orin.
67 Kí Ọlọ́run kí ó ṣàánú fún wa kí ó sì bùkún fún wa,
kí ó sì jẹ́ kí ojú rẹ̀ tàn yí wa ká,
2 kí ọ̀nà rẹ le di mí mọ̀ ní ayé,
ìgbàlà rẹ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.
3 Kí àwọn ènìyàn kí ó yìn ọ́, Ọlọ́run;
kí gbogbo ènìyàn kí ó yìn ọ́!
4 Kí orílẹ̀-èdè kí ó yọ̀, kí ó sì kọrin fún ayọ̀,
nítorí ìwọ fi òdodo darí àwọn ènìyàn,
ìwọ sì jẹ ọba àwọn orílẹ̀-èdè ní ayé.
5 Kí àwọn ènìyàn kí ó yìn ọ́, Ọlọ́run;
kí gbogbo ènìyàn kí ó yìn ọ́. Sela.
6 Nígbà náà ní ilẹ̀ yóò mú ìkórè rẹ̀ wá, Ọlọ́run,
Ọlọ́run wa, yóò bùkún fún wa.
7 Ọlọ́run yóò bùkún fún wa,
àti gbogbo òpin ilẹ̀ ayé yóò sì máa bẹ̀rù rẹ̀.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.