Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

M’Cheyne Bible Reading Plan

The classic M'Cheyne plan--read the Old Testament, New Testament, and Psalms or Gospels every day.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
2 Samuẹli 10

Dafidi ṣẹ́gun Ammoni

10 (A)Ó sì ṣe lẹ́yìn èyí, ọba àwọn ará Ammoni sì kú, Hanuni ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Dafidi sì wí pé, “Èmi yóò ṣe oore fún Hanuni ọmọ Nahaṣi gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ sì ti ṣe oore fún mi.” Dafidi sì ránṣẹ́ láti tù Hanuni nínú láti ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wá, nítorí ti baba rẹ̀.

Àwọn ìránṣẹ́ Dafidi sì wá sí ilé àwọn ọmọ Ammoni. Àwọn olórí àwọn ọmọ Ammoni sì wí fún Hanuni olúwa wọn pé, “Ǹjẹ́ o rò pé Dafidi ń bu ọlá fún baba rẹ nígbà tí ó rán ènìyàn wá láti bá ọ kẹ́dùn? Kò ha ṣe pé Dafidi rán àwọn ìránṣẹ́ sí ọ láti wo ìlú àti láti yọ́ ọ wò àti láti gbà ọ́.” Hanuni sì mú àwọn ìránṣẹ́ Dafidi ó fá apá kan irùngbọ̀n wọn, ó sì gé ààbọ̀ kúrò ní agbádá wọn, títí ó fi dé ìdí wọn, ó sì rán wọn lọ.

Wọ́n sì sọ fún Dafidi, ó sì ránṣẹ́ lọ pàdé wọn, nítorí tí ojú ti àwọn ọkùnrin náà púpọ̀: ọba sì wí pé, “Ẹ dúró ní Jeriko títí irùngbọ̀n yín yóò fi hù, nígbà náà ni kí ẹ tó máa bọ̀.”

Àwọn ogun Siria àti Ammoni sá níwájú Israẹli

Àwọn ará Ammoni sì ri pé, wọ́n di ẹni ìríra níwájú Dafidi, àwọn ọmọ Ammoni sì ránṣẹ́, wọ́n sì fi owó bẹ́ ogún àwọn ará Siria ti Beti-Rehobu; àti Siria-Soba, ẹgbàáwàá ẹlẹ́ṣẹ̀ àti ti ọba Maaka, ẹgbẹ̀rún ọkùnrin àti ti Tobu ẹgbàafà ọkùnrin lọ́wẹ̀.

Dafidi sì gbọ́, ó sì rán Joabu, àti gbogbo ogún àwọn ọkùnrin alágbára. Àwọn ọmọ Ammoni sì jáde wá, wọ́n sì tẹ́ ogun ní ẹnu odi; ará Siria-Soba, àti ti Rehobu, àti Tobu, àti Maaka, wọ́n sì tẹ ogun ni pápá fún ara wọn.

Nígbà tí Joabu sì rí i pé ogun náà dojúkọ òun níwájú àti lẹ́yìn, ó sì yàn nínú gbogbo àwọn akíkanjú ọkùnrin ní Israẹli, ó sì tẹ́ ogun kọjú sí àwọn ará Siria. 10 Ó sì fi àwọn ènìyàn tí ó kù lé Abiṣai àbúrò rẹ̀ lọ́wọ́, kí ó lè tẹ ogun kọjú sí àwọn ọmọ Ammoni. 11 Ó sì wí pé, “Bí agbára àwọn ará Siria bá pọ̀ ju èmi lọ, ìwọ yóò sì wá ràn mí lọ́wọ́: ṣùgbọ́n bí ọwọ́ àwọn ọmọ Ammoni bá sì pọ̀jù ọ́ lọ, èmi ó sì wá ràn ọ́ lọ́wọ́. 12 Mú ọkàn lè, jẹ́ kí a ṣe onígboyà nítorí àwọn ènìyàn wa, àti nítorí àwọn ìlú Ọlọ́run wa; Olúwa yóò sì ṣe èyí tí ó dára lójú rẹ̀.”

13 Joabu àti àwọn ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ sì bá àwọn ará Siria pàdé ìjà: wọ́n sì sá níwájú rẹ̀. 14 Nígbà tí àwọn ọmọ Ammoni sì rí i pé àwọn ará Siria sá, àwọn pẹ̀lú sì sá níwájú Abiṣai, wọ́n sì wọ inú ìlú lọ. Joabu sì padà kúrò lẹ́yìn àwọn ọmọ Ammoni, ó sì wá sí Jerusalẹmu.

Ìṣẹ́gun lórí ogun Ammoni àti Siria ní Helami

15 Nígbà tí àwọn ará Siria sì rí i pé Àwọn ṣubú níwájú Israẹli: wọ́n sì kó ara wọn jọ 16 Hadadeseri sì ránṣẹ́, ó sì mú àwọn Siria tí ó wà ní òkè odò Eufurate jáde wá: wọ́n sì wá sí Helami; Sobaki olórí ogun Hadadeseri sì ṣe olórí wọn.

17 Nígbà tí a sọ fún Dafidi, ó sì kó gbogbo Israẹli jọ, wọ́n sì kọjá Jordani, wọ́n sì wá sí Helami, Àwọn ará Siria sì tẹ́ ogun kọjú sí Dafidi, wọ́n sì bá a jà. 18 Àwọn ará Siria sì sá níwájú Israẹli, Dafidi sì pa nínú àwọn ará Siria ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin àwọn oníkẹ̀kẹ́, àti ọ̀kẹ́ méjì ẹlẹ́ṣin, wọ́n sì kọlu Sobaki olórí ogun wọn, ó sì kú níbẹ̀. 19 Nígbà tí gbogbo àwọn ọba tí ó wà lábẹ́ Hadadeseri sì rí i pé wọ́n di bíbì ṣubú níwájú Israẹli, wọ́n sì bá Israẹli làjà, wọ́n sì ń sìn wọ́n.

Àwọn ará Siria sì bẹ̀rù láti máa ran àwọn ọmọ Ammoni lọ́wọ́ mọ́.

2 Kọrinti 3

(A)Àwa ha tún bẹ̀rẹ̀ láti máa yín ara wá bí? Tàbí àwa ha ń fẹ́ ìwé ìyìn sọ́dọ̀ yín, tàbí láti ọ̀dọ̀ yín gẹ́gẹ́ bí ẹlòmíràn tí ń ṣe? Ẹ̀yin fúnrayín ni ìwé ìyìn wa, tí a ti kọ sí yín ní ọkàn, ti gbogbo ènìyàn mọ̀, tí wọ́n sì ń kà. (B)Ẹ̀yin sì ń fihàn pé ìwé tí a gbà sílẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Kristi ni yín, kì í ṣe èyí tí a sì fi jẹ́lú kọ, bí kò sẹ Ẹ̀mí Ọlọ́run alààyè, kì í ṣe nínú wàláà òkúta bí kò ṣe nínú wàláà ọkàn ẹran.

Irú ìgbẹ́kẹ̀lé yìí ni àwa ní nípasẹ̀ Kristi sọ́dọ̀ Ọlọ́run: Kì í ṣe pé àwa tó fún ara wa láti ṣírò ohunkóhun bí ẹni pé láti ọ̀dọ̀ àwa tìkára wa; ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ní tító wà; Ẹni tí ó mú wa yẹ bí ìránṣẹ́ májẹ̀mú tuntun; kì í ṣe ní ti ìwé àkọsílẹ̀ ṣùgbọ́n ní ti ẹ̀mí, nítorí ìwé a máa pa ni, ṣùgbọ́n ẹ̀mí a máa sọ ní di ààyè.

Ògo tó wà nínú májẹ̀mú tuntun

(C)Ṣùgbọ́n bí iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ikú, tí a tí kọ tí a sì ti gbẹ́ sí ara òkúta bá jẹ́ ológo tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli kò lè tẹjúmọ́ wíwo ojú Mose nítorí ògo ojú rẹ̀ (ògo ti ń kọjá lọ); yóò ha ti rí tí iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti ẹ̀mí kì yóò kúkú jẹ́ ògo jù? Nítorí pé bi iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìdálẹ́bi bá jẹ́ ológo, mélòó mélòó ni iṣẹ́ ìránṣẹ́ òdodo yóò tayọ jù ú ní ògo. 10 Nítorí, èyí tí a tí ṣe lógo rí, kó lógo mọ́ báyìí, nítorí ògo tí ó tayọ. 11 Nítorí pé bí èyí ti ń kọjá lọ bá lógo, mélòó mélòó ni èyí tí ó dúró kí yóò ní ògo!

12 Ǹjẹ́ nítorí náà bí a tí ní irú ìrètí bí èyí, àwa ń fi ìgboyà púpọ̀ sọ̀rọ̀. 13 Kì í sì í ṣe bí Mose, ẹni tí ó fi ìbòjú bo ojú rẹ̀, ki àwọn ọmọ Israẹli má ba à lè tẹjúmọ́ wíwo òpin èyí tí ń kọjá lọ 14 Ṣùgbọ́n ojú inú wọn fọ́; nítorí pé títí fi di òní olónìí nípa kíka májẹ̀mú láéláé, ìbòjú kan náà ṣì wà láìká kúrò; nítorí pé nínú Kristi ni a tí lè mú ìbòjú náà kúrò. 15 Ṣùgbọ́n títí di òní olónìí, nígbàkúgbà ti a bá ń ka Mose, ìbòjú náà ń bẹ lọ́kàn wọn. 16 Ṣùgbọ́n nígbà ti òun bá yípadà sí Olúwa, a ó mú ìbòjú náà kúrò. 17 (D)Ǹjẹ́ Olúwa ni Ẹ̀mí náà: níbi tí Ẹ̀mí Olúwa bá sì wà, níbẹ̀ ni òmìnira gbé wà 18 Ṣùgbọ́n gbogbo wa ń wo ògo Olúwa láìsí ìbòjú bí ẹni pé nínú àwòjìji, a sì ń pa wa dà sí àwòrán kan náà láti ògo dé ògo, àní bí láti ọ̀dọ̀ Olúwa tí í ṣe Ẹ̀mí.

Esekiẹli 17

Ẹyẹ idì méjì àti àjàrà

17 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ ní wá wí pé: “Ọmọ ènìyàn pa àlọ́ kan, sì pa òwe kan fún ilé Israẹli. Sọ fún wọn pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Idì ńlá kan tó ní apá títóbi àti ìyẹ́ gígùn tó kún fún àwọ̀ oríṣìíríṣìí wa si Lebanoni, ó sì mu ẹ̀ka igi Kedari tó ga jùlọ, ó gé ọ̀mùnú orí ẹ̀ka yìí kúrò, ó mú un lọ sí ilẹ̀ oníṣòwò, ó sì gbìn ín sí ìlú àwọn oníṣòwò.

“ ‘Ó mú lára irúgbìn ilẹ̀ náà, ó gbìn ín sí ilẹ̀ ọlọ́ràá, lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi, ó gbìn ín bí igi wílóò. Ó dàgbà, ó sì di àjàrà tó kúrú ṣùgbọ́n to bolẹ̀. Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ kọjú sí i, gbòǹgbò rẹ̀ sì dúró lábẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó di àjàrà, ó sì mu ẹ̀ka àti ewé jáde.

“ ‘Ṣùgbọ́n ẹyẹ idì ńlá mìíràn tún wá, tó ní apá títóbi pẹ̀lú ìyẹ́ púpọ̀. Gbòǹgbò àjàrà náà sì ta lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti orí ilẹ̀ tí wọn gbìn ín sí, ó wá pẹ̀ka lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ kí ó le fún un ni omi. Orí ilẹ̀ tó dára lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi ni a gbìn ín sí, kí ó bá à le pẹ̀ka, kò sì so èso, ó sì wá di igi àjàrà tó lọ́lá púpọ̀.’

“Sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Olúwa Olódùmarè wí nìyí: Yóò wá gbilẹ̀ bí? A kò wá ní i wú gbòǹgbò rẹ̀, ki a si gé èso rẹ̀ kúrò kí ó bá à le rọ? Gbogbo ewé rẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ ni yóò rẹ̀. Kò sì nígbà agbára tàbí ènìyàn púpọ̀ láti fà gbòǹgbò rẹ̀ tu. 10 Bí a tilẹ̀ tún un gbìn, yóò wa gbilẹ̀ bí? Kò wá ní i rọ pátápátá nígbà ti afẹ́fẹ́ láti ìlà-oòrùn bá kọlù ú. Gbogbo ewé rẹ̀ yóò rẹ̀ lórí ilẹ̀ tó ti dàgbà?’ ”

11 Nígbà náà, ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mi wá pé: 12 “Sọ fún ọlọ̀tẹ̀ ilé yìí, ‘Ǹjẹ́ ẹ mọ ìtumọ̀ àwọn nǹkan wọ̀nyí?’ Sọ fún wọn: ‘ọba Babeli wá sí Jerusalẹmu, ó sì kó ọba àti àwọn ìjòyè ọmọ-aládé ibẹ̀ lọ sí Babeli lọ́dọ̀ rẹ̀. 13 Lẹ́yìn èyí, ó bá ọ̀kan nínú ọmọ ọba dá májẹ̀mú, ó mú un ìbúra, ó tún kó àwọn alágbára ilẹ̀ náà lọ. 14 Kí ìjọba ilẹ̀ náà le rẹ ilẹ̀, kí ó má lè gbé ara rẹ̀ sókè, kí ó lè dúró nípa pípa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́. 15 Ṣùgbọ́n ọba ṣọ̀tẹ̀ sí i nípa ríran àwọn ikọ̀ rẹ̀ lọ sí Ejibiti, kí wọn bá à lè fún un ni ẹṣin àti àwọn ọmọ-ogun púpọ̀. Yóò ha ṣe àṣeyọrí? Ṣe ẹni tó ṣe irú nǹkan yìí yóò sì bọ́ níbẹ̀? Yóò ha dalẹ̀ tán kí ó sì bọ́ níbẹ̀ bí?

16 “ ‘Bí mo ti wà láààyè ni Olúwa Olódùmarè wí, òun yóò kú ní Babeli, ní ilẹ̀ ọba tó fi sórí oyè, ìbúra ẹni tí ó kẹ́gàn àti májẹ̀mú ẹni tí ó dà. 17 Farao pẹ̀lú àwọn ọmọ-ogun àti àjọ ńlá rẹ̀ kò ní lè ṣe ìrànwọ́ fún un lójú ogun. Nígbà tí wọ́n bá pa bùdó ogun tì í, tí wọ́n sì mọ odi láti pa ọ̀pọ̀ ènìyàn, 18 Nítorí pé ó kẹ́gàn ìbúra nípa dída májẹ̀mú, àti pé ó juwọ́ sílẹ̀ nínú ṣíṣe ìlérí, kì yóò bọ níbẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn nǹkan tí ó ṣe yìí.

19 “ ‘Nítorí náà Olúwa Olódùmarè wí pé: Bí mo ti wà láààyè, Èmi yóò mú ẹ̀san ẹ̀jẹ́ mi tó kẹ́gàn àti májẹ̀mú mi tó dà wa sórí rẹ̀. 20 Èmi yóò ta àwọ̀n mi sórí rẹ̀, yóò sì bọ sínú okùn mi, Èmi yóò mú ọ lọ Babeli láti ṣe ìdájọ́ ìwà ọ̀dàlẹ̀ tó hù sí mi. 21 Gbogbo ìgbèkùn àti ọ̀wọ́ ọmọ-ogun rẹ̀ ni yóò kú pẹ̀lú idà, èmi yóò sì fọn àwọn ìyókù ká sínú afẹ́fẹ́ káàkiri. Nígbà náà ni yóò mọ̀ pé, “Èmi Olúwa ni ó ti sọ̀rọ̀.”

22 “ ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Èmi fúnra mi yóò mú ọ̀kan lára ẹ̀ka tí ó ga jùlọ lórí igi Kedari gíga, tí èmi yóò sì gbìn ín, èmi yóò sì gé ọ̀mùnú tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ láti òkè, èmi yóò sì gbìn ín sórí òkè tó ga tó sì lókìkí. 23 (A)Ní ibi gíga òkè Israẹli ni èmi yóò gbìn ín sí; yóò pẹ̀ka, yóò sì so èso, yóò wa di igi Kedari tí ó lọ́lá. Oríṣìíríṣìí ẹyẹ yóò sì fi òjìji abẹ ẹ̀ka rẹ ṣe ibùgbé; wọn yóò ṣe ibùgbé si abẹ́ òjìji ẹ̀ka rẹ̀ 24 Gbogbo igi inú oko yóò mọ̀ pé, Èmi Olúwa ni ó mú igi gíga walẹ̀, tí mo sì mú kúkúrú ga sókè, tí mo mu igi tútù gbẹ, tí mo sì mú igi gbígbẹ rúwé.

“ ‘Èmi Olúwa ni ó sọ bẹ́ẹ̀, Èmi yóò sì ṣe e.’ ”

Saamu 60-61

Fún adarí orin. Tí ohùn “Lílì ti Májẹ̀mú.” Miktamu ti Dafidi. Fún ìkọ́ni. Nígbà tí ó bá Aramu-Naharaimu àti Siria-Soba jà, àti nígbà tí Joabu yípadà tí ó sì pa ẹgbẹ̀rún méjìlá àwọn ará Edomu ní Àfonífojì Iyọ̀.

60 Ìwọ ti kọ̀ wá sílẹ̀,
    Ọlọ́run, ìwọ ti tú wa ká,
ìwọ ti bínú nísinsin yìí, tún ara rẹ yípadà sí wa.
Ìwọ ti mú ilẹ̀ wárìrì, ìwọ ti fọ́ ọ;
    mú fífọ́ rẹ̀ bọ̀ sípò, nítorí tí ó mì.
Ìwọ ti fi ìgbà ewu han àwọn ènìyàn rẹ;
    Ìwọ fún wa ní wáìnì tí ó máa ń ta wá gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n.
Àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, ní ìwọ fi ọ̀págun fún
    kí a lè fihàn nítorí òtítọ́. Sela.

(A)Fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbà wá, kí o sì ràn wá lọ́wọ́,
    kí a lè gba àwọn tí o fẹ́ là.
Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ láti ibi mímọ́ rẹ̀:
    “Ní ayọ̀, èmi ó pọ Ṣekemu jáde
    èmi ó sì wọ́n Àfonífojì Sukkoti.
Tèmi ni Gileadi, tèmi sì ni Manase;
    Efraimu ni àṣíborí mi,
    Juda sì ni ọ̀pá àṣẹ mi.
Moabu ní ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi,
    lórí Edomu ní mo bọ́ bàtà mi sí;
    lórí Filistia ni mo kígbe ayọ̀.”

Ta ni yóò mú mi wá sí ìlú olódi nì?
    Ta ni yóò tọ́ mí lọ sí Edomu?
10 Kì í ha ń ṣe ìwọ, Ọlọ́run, tí ó ti kọ̀ wá sílẹ̀
    tí o kò sì bá ogun wa jáde mọ́?
11 Fún wa ní ìrànlọ́wọ́ lórí àwọn ọ̀tá,
    nítorí asán ni ìrànlọ́wọ́ ènìyàn.
12 Nípa Ọlọ́run ni a óò ní ìṣẹ́gun,
    yóò sì tẹ àwọn ọ̀tá wa mọ́lẹ̀.

Fún adarí orin. Ohun èlò orin olókùn. Ti Dafidi.

61 Gbọ́ ẹkún mi, Ọlọ́run;
    Tẹ́tí sí àdúrà mi.

Láti òpin ayé wá ni èmi yóò pè ọ́,
    mo pè nígbà àyà mi ń ṣàárẹ̀;
    mú mi lọ sí ibi àpáta tí ó ga jù mí lọ.
Nítorí ìwọ ti jẹ́ ibi ààbò mi,
    ilé ìṣọ́ agbára àwọn ọ̀tá.

Mo ń lépa láti máa gbé nínú àgọ́ rẹ títí láé
    kí n sì rí ààbò níbi ìyẹ́ apá rẹ.
Nítorí ìwọ ti gbọ́ àwọn ẹ̀jẹ́ mi, Ọlọ́run;
    Ìwọ ti fún mi ní ogún àwọn tí ó bẹ̀rù orúkọ rẹ.

Jẹ́ kí ẹ̀mí ọba kí ó gùn,
    ọdún rẹ̀ fún ìrandíran.
Kí ó máa jẹ ọba níwájú Ọlọ́run títí láé;
    pèsè àánú àti òtítọ́ rẹ tí yóò máa ṣe ìtọ́jú rẹ.

Nígbà náà ni èmi ó máa kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ títí láé
    kí n san ẹ̀jẹ́ mi ní ojoojúmọ́.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.