Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

M’Cheyne Bible Reading Plan

The classic M'Cheyne plan--read the Old Testament, New Testament, and Psalms or Gospels every day.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
1 Samuẹli 9

Samuẹli fi òróró yan Saulu

Ará Benjamini kan wà, ẹni tí ó jẹ́ aláàánú ọlọ́rọ̀, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kiṣi, ọmọ Abieli, ọmọ Serori, ọmọ Bekorati, ọmọ Afiah ti Benjamini. Ó ní ọmọkùnrin kan tí à ń pè ní Saulu, ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó yanjú, tí ó jẹ́ arẹwà, tí kò sí ẹni tó ní ẹwà jù ú lọ láàrín gbogbo àwọn ọmọ Israẹli—láti èjìká rẹ̀ lọ sí òkè, ó ga ju gbogbo àwọn ènìyàn tókù lọ.

Nísinsin yìí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó jẹ́ ti Kiṣi baba Saulu sì sọnù. Nígbà náà, Kiṣi sọ fún Saulu ọmọ rẹ̀ pé, “Mú ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́ pẹ̀lú rẹ kí ẹ lọ láti wá àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà.” Bẹ́ẹ̀ ní ó kọjá láàrín àwọn ìlú olókè Efraimu, ó sì kọjá ní àyíká ilẹ̀ Ṣaliṣa, ṣùgbọ́n wọn kò rí wọn. Wọ́n sì kọjá lọ sí òpópó Ṣaalimu, ṣùgbọ́n àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kò sí níbẹ̀. Nígbà náà, ó kọjá ní agbègbè Benjamini, wọn kò sì rí wọn.

Nígbà tí wọ́n dé agbègbè Sufu, Saulu sọ fún ìránṣẹ́ tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Wá, jẹ́ kí á padà sẹ́yìn, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, baba mi yóò dá ìrònú rẹ̀ dúró nípa àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yóò sì bẹ̀rẹ̀ àníyàn nípa wa.”

Ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ náà fún un ní èsì pé, “Wò ó, ní inú ìlú yìí ọkùnrin ènìyàn Ọlọ́run kan wà; ó jẹ́ ẹni tí wọ́n ń bu ọlá fún, àti gbogbo ohun tí ó bá sọ ní ó máa ń jẹ́ òtítọ́. Jẹ́ kí á lọ síbẹ̀ nísinsin yìí, bóyá yóò sọ fún wá ọ̀nà tí a yóò gbà.”

Saulu sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀, “Tí àwa bá lọ, kín ni àwa lè fún ọkùnrin náà? Oúnjẹ inú àpò wa ti tán. A kò sì ní ẹ̀bùn láti mú lọ sọ́dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run. Kí ni a ní?”

Ìránṣẹ́ sì dá a lóhùn lẹ́ẹ̀kan sí i. “Wò ó,” ó wí pé, “Mo ní ìdámẹ́rin ṣékélì fàdákà lọ́wọ́. Èmi yóò fún ènìyàn Ọlọ́run náà kí ó lè fi ọ̀nà hàn wá.” (Tẹ́lẹ̀ ní Israẹli tí ọkùnrin kan bá lọ béèrè lọ́dọ̀ Ọlọ́run, yóò wí pé, “Wá, jẹ́ kí a lọ sí ọ̀dọ̀ wòlíì náà,” nítorí àwọn alásọtẹ́lẹ̀ ìsinsin yìí ni wọ́n ń pè ní wòlíì).

10 Saulu sọ fún ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀ pé ó dára “Jẹ́ kí a lọ” Wọ́n jáde lọ sí ìlú tí ènìyàn Ọlọ́run náà ń gbé.

11 Bí wọ́n ṣe ń lọ ní orí òkè sí ìlú náà, wọ́n pàdé àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin tí ó ń jáde í bọ̀ láti wá pọn omí. Wọ́n sì bi wọ́n, “Ṣé wòlíì náà wà níbí?”

12 “Ó wà,” wọ́n dáhùn. “Ó ń bẹ níwájú u yín, múra nísinsin yìí, ó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ wa lónìí ni, nítorí àwọn ènìyàn ní ẹbọ rírú ni ibi gíga. 13 Kété tí ẹ bá ti wọ ìlú, ẹ ó rí i kí ó tó lọ sí ibi gíga láti lọ jẹun. Àwọn ènìyàn kò sì ní bẹ̀rẹ̀ sí jẹun títí tí yóò fi dé. Torí ó gbọdọ̀ bùkún ẹbọ náà; lẹ́yìn náà, àwọn tí a pè yóò jẹun. Gòkè lọ nísinsin yìí: ó yẹ kí ẹ rí i ní àkókò yìí.”

14 Wọ́n gòkè lọ sí ìlú náà, bí wọ́n ti ń wọlé, níbẹ̀ ni Samuẹli, ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ wọn bí ó ti ń lọ ibi gíga náà.

15 Olúwa ti sọ létí Samuẹli ní ọjọ́ kan kí Saulu ó tó dé pé, 16 “Ní ìwòyí ọ̀la, èmi yóò ran ọmọkùnrin kan sí ọ láti ilẹ̀ Benjamini. Fi òróró yàn án gẹ́gẹ́ bí olórí lórí àwọn ọmọ Israẹli, yóò gba àwọn ènìyàn mi kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Filistini. Mo ti bojú wo àwọn ènìyàn mi, nítorí igbe wọn ti dé ọ̀dọ̀ mi.”

17 Nígbà tí Samuẹli fojúrí Saulu, Olúwa sọ fún un pé, “Èyí ni ọkùnrin tí mo sọ fún ọ nípa rẹ̀, yóò darí àwọn ènìyàn mi.”

18 Saulu sì súnmọ́ Samuẹli ní ẹnu-ọ̀nà ìlú, ó sì wí pé, “Sọ fún mi èmi ń bẹ̀ ọ́ níbo ni ilé wòlíì náà wà.”

19 Samuẹli dáhùn pé, “Èmi ni wòlíì náà. Ẹ máa gòkè lọ ṣáájú mi, ní ibi gíga, ẹ ó sì bá mi jẹun lónìí. Ní òwúrọ̀ ni èmi yóò tó jẹ́ kí ẹ lọ, gbogbo ohun tí ó wà ní ọkàn rẹ ní èmi yóò sọ fún ọ. 20 Fún ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó sọnù fún ọjọ́ mẹ́ta sẹ́yìn, má ṣe dààmú nípa wọ́n: a ti rí wọn. Sí ta ni gbogbo ìfẹ́ Israẹli wà? Bí kì í ṣe sí ìwọ àti sí gbogbo ilé baba à rẹ.”

21 Saulu dáhùn pé, “Ṣùgbọ́n èmi kì í há ṣe ẹ̀yà Benjamini? Kékeré nínú ẹ̀yà Israẹli: Ìdílé mi kò ha rẹ̀yìn jùlọ nínú gbogbo ẹ̀yà Benjamini? Èéṣì ti ṣe tí ìwọ sọ̀rọ̀ yìí sí mi?”

22 Nígbà náà ni Samuẹli mú Saulu pẹ̀lú ìránṣẹ́ rẹ̀ wọ inú gbọ̀ngán, ó sì mú wọn jókòó sí iwájú àwọn tí a pè—tí wọn tó ọgbọ̀n. 23 Samuẹli sọ fún alásè pé, “Mú ìpín ẹran tí mo fún ọ wá, èyí tí mo sọ fún ọ pé kí o yà sọ́tọ̀.”

24 Alásè náà sì gbé ẹsẹ̀ náà pẹ̀lú ohun tí ó wà lórí i rẹ̀, ó sì gbé e síwájú Saulu. Samuẹli wí pé, “Èyí ni ohun tí a fi pamọ́ fún ọ. Jẹ, nítorí a yà á sọ́tọ̀ fún ọ, fún ìdí yìí, láti ìgbà tí mo ti wí pé, ‘Mo ní àlejò tí a pè.’ ” Saulu sì jẹun pẹ̀lú Samuẹli ní ọjọ́ náà.

25 Lẹ́yìn ìgbà tí wọn ti sọ̀kalẹ̀ láti ibí gíga náà wá sí inú ìlú, Samuẹli sì bá Saulu sọ̀rọ̀ lórí òrùlé ilé e rẹ̀. 26 Wọ́n sì dìde ní àfẹ̀mọ́júmọ́, ó pe Saulu sórí òrùlé pé, “Múra, èmi yóò rán ọ lọ.” Nígbà tí Saulu múra tán òun àti Samuẹli jọ jáde lọ síta. 27 Bí wọ́n ti ń sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìpẹ̀kun ìlú náà, Samuẹli wí fún Saulu pé, “Sọ fún ìránṣẹ́ náà kí ó máa lọ ṣáájú u wa,” ìránṣẹ́ náà sì ṣe bẹ́ẹ̀, “ṣùgbọ́n kí ìwọ kí ó dúró díẹ̀, kí èmi kí ó lè sọ ọrọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run fún ọ.”

Romu 7

Àpèjúwe kan láti inú ìgbéyàwó

Ẹ̀yin kò ha mọ̀, ara: nítorí èmí bá àwọn tí ó mọ òfin sọ̀rọ̀ pé, òfin ní ipá lórí ènìyàn níwọ̀n ìgbà tí ó bá wà láààyè nìkan? (A)Fún àpẹẹrẹ, nípa òfin ní a de obìnrin mọ́ ọkọ rẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí ọkọ náà wà láààyè, ṣùgbọ́n bí ọkọ rẹ̀ bá kú, a tú u sílẹ̀ kúrò nínú òfin ìgbéyàwó náà. Nígbà náà, bí ó bá fẹ́ ọkùnrin mìíràn nígbà tí ọkọ rẹ̀ wà láààyè, panṣágà ní a ó pè é. Ṣùgbọ́n bí ọkọ rẹ̀ bá kú, ó bọ́ lọ́wọ́ òfin náà, kí yóò sì jẹ́ panṣágà bí ó bá ní ọkọ mìíràn.

(B)Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin ará mi, ẹ̀yin pẹ̀lú ti di òkú sí òfin nípa ara Kristi, kí ẹ̀yin kí ó lè ní ẹlòmíràn, àní ẹni náà tí a jí dìde kúrò nínú òkú, kí àwa kí ó lè so èso fún Ọlọ́run (C)Nítorí ìgbà tí a wa nípa ti ara, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ nípa ti òfin, ma ń ṣiṣẹ́ nínú wa, tí a sì ń so èso tí ó yẹ fún ikú. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, nípa kíkú ohun tó so wá pọ̀ tẹ́lẹ̀ rí, a ti tú wa sílẹ̀ kúrò nínú òfin, kí a lè sin ín ní ìlànà tuntun ti Ẹ̀mí, kì í ṣe ní ìlànà àtijọ́ tí ìwé òfin gùnlé.

Bíbá ẹ̀ṣẹ̀ wọ ìjàkadì

(D)Ǹjẹ́ àwa o ha ti wí, nígbà náà? Òfin ha ń ṣe ẹ̀ṣẹ̀ bí? Kí a má rí i! Ṣùgbọ́n èmi kì bá tí mọ ohun tí ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́, bí kò ṣe nípa òfin. Èmi kì bá tí mọ ojúkòkòrò, bí kò ṣe bí òfin ti wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò.” (E)Ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ sì ti ipa òfin rí ààyè ṣiṣẹ́ onírúurú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ nínú mi. Nítorí láìsí òfin, ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ ikú. Èmi sì ti wà láààyè láìsí òfin nígbà kan rí; ṣùgbọ́n nígbà tí òfin dé, ẹ̀ṣẹ̀ sọjí èmi sì kú. 10 (F)Mo ṣàkíyèsí pé òfin tí ó yẹ kí ó mú ìyè wá ni ó padà mú ikú wá. 11 Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ti ipa òfin rí ààyè láti tàn mí jẹ, ó sì ti ipa òfin ṣe ikú pa mi. 12 (G)Bẹ́ẹ̀ ni mímọ́ ni òfin, mímọ́ sì ni àṣẹ, àti òdodo, àti dídára.

13 Ǹjẹ́ ohun tí ó dára ha di ikú fún mi bí? Kí a má rí i! Ṣùgbọ́n kí ẹ̀ṣẹ̀, kí ó lè farahàn bí ẹ̀ṣẹ̀, ó ń ti ipa ohun tí ó dára ṣiṣẹ́ ikú nínú mi, kí ẹ̀ṣẹ̀ lè ti ipa òfin di búburú rékọjá.

14 (H)Nítorí àwa mọ̀ pé ohun ẹ̀mí ni òfin: ṣùgbọ́n ẹni ti ara ni èmi, tí a ti tà sábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀. 15 (I)Èmi pàápàá, kò mọ̀ ohun tí èmi ń ṣe. Nítorí pé, ohun tí mo fẹ́ ṣe gan an n kò ṣe é, ṣùgbọ́n ohun tí mo kórìíra ni mo ń ṣe. 16 Ṣùgbọ́n bí mo bá ṣe ohun tí èmi kò fẹ́, mo gbà pé òfin dára. 17 Ṣùgbọ́n bí ọ̀rọ̀ ṣe rí yìí kì í ṣe èmi ni ó ṣe é bí kò ṣe ẹ̀ṣẹ̀ tí ń gbé inú mi. 18 Èmi mọ̀ dájú pé kò sí ohun tí ó dára kan tí ń gbé inú mi, àní, nínú ara ẹ̀ṣẹ̀ mi. Èmi fẹ́ ṣe èyí tí ó dára, ṣùgbọ́n kò sé é ṣe. 19 Nítorí ohun tí èmi ṣe kì í ṣe ohun rere tí èmi fẹ́ láti ṣe; rárá, ṣùgbọ́n búburú tí èmi kò fẹ́, èyí nì ni èmi ń ṣe. 20 Nísinsin yìí, bí mo bá ń ṣe nǹkan tí n kò fẹ́ láti ṣe, kì í ṣe èmí fúnra mi ni ó ṣe é, bí kò ṣe ẹ̀ṣẹ̀ tí ń bẹ nínú ni ó ṣe é.

21 Nítorí náà, èmi kíyèsi pé òfin ní ń ṣiṣẹ́ nínú mi: nígbà tí èmi bá fẹ́ ṣe rere, búburú wà níbẹ̀ pẹ̀lú mi. 22 (J)Nínú ìjìnlẹ̀ ọkàn mi mo ní inú dídùn sí òfin Ọlọ́run; 23 (K)mo rí òfin mìíràn tó ń ṣiṣẹ́ nínú ẹ̀yà ara mi, èyí tí ń gbógun ti òfin tó tinú ọkàn mi wá, èyí tí ó sọ mi di ẹrú òfin ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ń ṣiṣẹ́ nínú ẹ̀yà ara mi. 24 (L)Èmi ẹni òsì! Ta ni yóò ha gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ara kíkú yìí? 25 Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nípasẹ̀ Jesu Kristi Olúwa wa!

Ǹjẹ́ nítorí náà, èmi fúnra mi jẹ́ ẹrú sí òfin Ọlọ́run, ṣùgbọ́n nínú ara ẹ̀ṣẹ̀ mo jẹ́ ẹrú fún òfin ẹ̀ṣẹ̀.

Jeremiah 46

Àṣọtẹ́lẹ̀ ní tí Ejibiti

46 (A)Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Jeremiah wòlíì wá nípa àwọn orílẹ̀-èdè:

Ní ti Ejibiti:

Èyí ni ọ̀rọ̀ nípa àwọn ọmọ-ogun Farao Neko ọba Ejibiti ẹni tí a borí rẹ̀ ní Karkemiṣi, ní odò Eufurate láti ọwọ́ Nebukadnessari ọba Babeli ní ọdún kẹrin Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda:

“Ẹ múra àpáta, èyí tí ó tóbi, àti èyí tí ó kéré,
    kí ẹ sì súnmọ́ ojú ìjà!
Ẹ di ẹṣin ní gàárì,
    kí ẹ sì gùn ún.
Ẹ dúró lẹ́sẹẹsẹ
    pẹ̀lú àṣíborí yín!
Ẹ dán ọ̀kọ̀ yín,
    kí ẹ sì wọ ẹ̀wù irin.
(B)Kí ni nǹkan tí mo tún rí?
    Wọ́n bẹ̀rù,
wọ́n sì ń padà sẹ́yìn,
    wọ́n ti ṣẹ́gun àwọn jagunjagun.
Wọ́n sá,
    wọn kò sì bojú wẹ̀yìn,
ìbẹ̀rù sì wà níbi gbogbo,”
    ni Olúwa wí.
“Ẹni tí ó yára kì yóò le sálọ,
    tàbí alágbára kò ní lè sá àsálà.
Ní àríwá ní ibi odò Eufurate
    wọn yóò kọsẹ̀, wọn yóò sì ṣubú.

“Ta ni èyí tí ó gòkè wá bí odò Ejibiti,
    tí omi rẹ̀ ń ru gẹ́gẹ́ bí odò wọ̀n-ọn-nì?
Ejibiti dìde bí odò náà,
    bí omi odò tí ń ru.
Ó sì wí pé, ‘Èmi yóò dìde, n ó sì bo gbogbo ilẹ̀ ayé.’
    Èmi yóò pa ìlú àti àwọn ènìyàn rẹ̀ run.
Ẹ gòkè wá ẹ̀yin ẹṣin,
    ẹ sì sáré kíkankíkan ẹ̀yin kẹ̀kẹ́.
Kí àwọn alágbára túbọ̀ tẹ̀síwájú,
    àwọn ará Kuṣi àti àwọn ará Puti tí ń di asà mú;
    àti àwọn ará Lidia tí ń fa ọrun.
10 Ṣùgbọ́n ọjọ́ náà jẹ́ ti Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun,
    ọjọ́ ìgbẹ̀san, ìgbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀.
Idà yóò sì jẹ́ títí yóò fi ní ìtẹ́lọ́rùn,
    títí yóò fi pa òǹgbẹ rẹ̀ rẹ́ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀.
Nítorí pé Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò rú ẹbọ
    ní ilẹ̀ gúúsù ní odò Eufurate.

11 “Gòkè lọ sí Gileadi, kí o sì mú ìkunra,
    ìwọ wúńdíá ọmọbìnrin Ejibiti.
Ṣùgbọ́n ní asán ni ìwọ ń lo oògùn,
    kì yóò sí ìwòsàn fún ọ.
12 Àwọn orílẹ̀-èdè yóò gbọ́ nípa ìtìjú rẹ,
    igbe rẹ yóò kún gbogbo ayé.
Jagunjagun yóò máa ṣubú lu ara wọn lórí rẹ,
    àwọn méjèèjì yóò sì jọ ṣubú papọ̀.”

13 Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó bá Jeremiah wòlíì nì sọ nípa wíwá Nebukadnessari ọba Babeli láti lọ dojú ìjà kọ Ejibiti:

14 “Kéde èyí ní Ejibiti, sì sọ ọ́ ní Migdoli,
    sọ ọ́ ní Memfisi àti Tafanesi:
‘Dúró sí ààyè rẹ kí o sì múra sílẹ̀,
    nítorí pé idà náà ń pa àwọn tí ó yí ọ ká.’
15 Èéṣe tí àwọn akọni rẹ fi ṣubú?
    Wọn kò ní le dìde dúró, nítorí Olúwa yóò tì wọ́n ṣubú.
16 Wọn yóò máa ṣubú léraléra
    wọn yóò máa ṣubú lu ara wọn.
Wọn yóò sọ wí pé, ‘Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a padà
    sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn wa àti ilẹ̀ ìbí wa,
    kúrò níbi idà àwọn aninilára.’
17 Níbẹ̀ ni wọn ó kígbe pé,
    ‘Ariwo lásán ni Farao ọba Ejibiti pa,
    ó ti sọ àǹfààní rẹ̀ nù.’

18 “Bí èmi ti wà láààyè,” ni ọba,
    ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé,
“nítòótọ́ gẹ́gẹ́ bí Tabori láàrín àwọn òkè àti
    gẹ́gẹ́ bi Karmeli lẹ́bàá Òkun bẹ́ẹ̀ ni òun yóò dé.
19 Ìwọ, ọmọbìnrin ti ń gbé Ejibiti
    pèsè ohun èlò ìrìnàjò fún ara rẹ
nítorí Memfisi yóò di ahoro
    a ó sì fi jóná, láìní olùgbé.

20 “Ẹgbọrọ abo màlúù tó lẹ́wà ní Ejibiti
    ṣùgbọ́n eṣinṣin ìparun dé,
    ó dé láti àríwá.
21 Àwọn jagunjagun rẹ̀
    dàbí àbọ́pa akọ màlúù.
Àwọn pẹ̀lú yóò yípadà,
    wọn ó sì jùmọ̀ sá,
wọn kò ní le dúró,
    Nítorí tí ọjọ́ ibi ń bọ̀ lórí wọn
    àsìkò láti jẹ wọ́n ní ìyà.
22 Ejibiti yóò pòṣé bí ejò tí ń sá
    bí ọmọ-ogun ṣe ń tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú agbára.
Wọn ó tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú àáké,
    gẹ́gẹ́ bí i ti agégi.
23 Wọn o gé igbó rẹ̀ lulẹ̀,”
    ni Olúwa wí,
“nítorí ti a kò le rídìí rẹ̀,
    nítorí pé wọ́n pọ̀ ju ẹlẹ́ǹgà lọ, wọ́n sì jẹ́ àìníye.
24 A ó dójútì ọmọbìnrin Ejibiti,
    a ó fà á lé ọwọ́ àwọn ènìyàn àríwá.”

25 Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí pé: “Èmi yóò rọ̀jò ìyà mi sórí Amoni òrìṣà Tebesi, sórí Farao, sórí Ejibiti àti àwọn òrìṣà rẹ̀ àti sórí àwọn ọba rẹ̀ àti sórí àwọn tó gbẹ́kẹ̀lé Farao. 26 Èmi ó sì fi wọ́n lé àwọn tó wá ẹ̀mí wọn lọ́wọ́, lé Nebukadnessari ọba Babeli, ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Ejibiti yóò sì di gbígbé bí i ti àtijọ́,” ni Olúwa wí.

27 “Má bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu ìránṣẹ́ mi,
    má fòyà, ìwọ Israẹli.
Dájúdájú èmi ó gbà ọ́ láti ọ̀nà jíjìn,
    àwọn ọmọ ọmọ rẹ ní ilẹ̀ ìgbèkùn.
Jakọbu yóò tún ní àlàáfíà àti ààbò,
    kò sì ṣí ẹni tí yóò dẹ́rùbà á.
28 Má bẹ̀rù, Jakọbu ìránṣẹ́ mi,
    nítorí pé mo wà pẹ̀lú rẹ,” bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí.
“Bí mo tilẹ̀ pa gbogbo orílẹ̀-èdè run,
    láàrín àwọn tí mo fọ́n yín ká sí.
Èmi kò ní run yín tán.
    Èmi yóò jẹ ọ́ ní ìyà lórí òdodo,
    èmi kí yóò jọ̀wọ́ rẹ lọ́wọ́ lọ láìjẹ ọ́ ní yà.”

Saamu 22

Fún adarí orin. Tí ohùn orin “àgbọ̀nrín òwúrọ̀.” Saamu ti Dafidi.

22 (A)Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀?
    Èéṣe tí o fi jìnnà láti gbà mí là,
    àní sí igbe ìkérora mi?
Ọlọ́run mi, ní ọ̀sán gangan ni mo kígbe, ṣùgbọ́n ìwọ kò dá mi ní ohùn:
    àti ní òru èmi kò dákẹ́.

Ṣùgbọ́n síbẹ̀ ẹni mímọ́ ni ìwọ;
    ẹni tí ó tẹ ìyìn Israẹli dó;
Àwọn baba ńlá wa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ;
    wọ́n ní ìgbẹ́kẹ̀lé, ìwọ sì gbà wọ́n.
Ìwọ ni wọ́n sun ẹkún sí, wọ́n sì ní ìgbàlà;
    ìwọ ni wọ́n gbẹ́kẹ̀lé, a kò sì dójútì wọ́n.

Ṣùgbọ́n kòkòrò ní mo jẹ́, kì í sì í ṣe ènìyàn;
    mo di ẹlẹ́gàn àwọn ènìyàn, ẹlẹ́yà àwọn ènìyàn
Gbogbo àwọn tí ó rí mí fi mí ṣe ẹlẹ́yà;
    wọ́n yọ ètè ẹ̀gàn wọn sí mi, wọ́n sì ń mi orí wọn pé.
“Ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé Olúwa;
    jẹ́ kí Olúwa gbà á là.
Jẹ́ kí ó gbà á là,
    nítorí pé, ó ní ayọ̀ nínú rẹ̀.”

Síbẹ̀ ìwọ ni ó ti mú mi wá láti inú;
    ìwọ ni ó mú mi wà láìléwu, nígbà tí mo rọ̀ mọ́ ọmú ìyá mi.
10 Ìwọ ni a fi mí lé lọ́wọ́ láti inú ìyá mi wá,
    nígbà tí ìyá mí sì ti bí mi, ìwọ ni Ọlọ́run mi.

11 Má ṣe jìnnà sí mi,
    nítorí pé ìyọnu súnmọ́ tòsí
    kò sì ṣí ẹnìkan tí yóò ṣe ìrànlọ́wọ́.

12 Ọ̀pọ̀ akọ màlúù yí mi ká;
    àwọn màlúù alágbára Baṣani rọ̀gbà yí mi ká.
13 Wọ́n ya ẹnu wọn sì mi bí i kìnnìún tí ń dọdẹ kiri,
    tí ń ké ramúramù.
14 A dà mí jáde gẹ́gẹ́ bí omi,
    gbogbo egungun mi ti yẹ̀ kúrò ní oríkèé rẹ̀.
Ọkàn mi sì dàbí i ìda;
    tí ó yọ́ láàrín inú mi.
15 Agbára mí ti gbẹ bí àpáàdì,
    ahọ́n mí sì tilẹ̀ mọ́ párí ẹ̀rẹ̀kẹ́ ẹ mi;
    ìwọ ti tẹ́ mi sínú eruku ikú.

16 Àwọn ajá yí mi ká;
    ìjọ àwọn ènìyàn ibi ti ká mi mọ́,
    Wọ́n gún mi lọ́wọ́, wọ́n sì gún mi lẹ́sẹ̀
17 Mo lè ka gbogbo àwọn egungun mi;
    àwọn tìkára wọn ń wò, wọ́n dójú lé mi.
18 Wọ́n pín aṣọ mi láàrín ara wọn
    àní lórí aṣọ mi ni wọ́n ṣẹ́ gègé.

19 Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, má ṣe jìnnà sí mi;
    Háà! Olùrànlọ́wọ́ ọ̀ mi, yára wá fún àtìlẹ́yìn mi!
20 Gba ọkàn mi sílẹ̀ lọ́wọ́ idà,
    àní ẹ̀mí mi lọ́wọ́ agbára àwọn ajá.
21 Gba ọkàn mi sílẹ̀ lọ́wọ́ kìnnìún;
    Kí o sì gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ìwo àgbáǹréré.

22 Èmi yóò kéde orúkọ rẹ láàrín arákùnrin àti arábìnrin mi;
    nínú ìjọ ni èmi yóò máa yìn ọ́.
23 Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù Olúwa, ẹ yìn ín!
    Gbogbo ẹ̀yin ìran Jakọbu, ẹ fi ògo fún un!
    Ẹ dìde fún un tẹ̀rù tẹ̀rù, ẹ̀yin irú-ọmọ Israẹli!
24 Nítorí pé òun kò ṣátá, bẹ́ẹ̀ ni kò sì kórìíra
    ìpọ́njú àwọn tí a ni lára;
kò sì fi ojú rẹ̀ pamọ́ fún mi
    ṣùgbọ́n ó gbọ́ nígbà tí mo ké pè é.

25 Láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìyìn mi yóò ti wá nínú àjọ ńlá;
    ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ni èmi yóò san níwájú àwọn tí o bẹ̀rù rẹ̀
26 tálákà yóò jẹ yóò sì yó;
    àwọn tí n wá Olúwa yóò yin
    jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ̀ wà láààyè títí ayérayé!

27 Gbogbo òpin ayé ni yóò rántí
    wọn yóò sì yípadà sí Olúwa,
àti gbogbo ìdílé orílẹ̀-èdè
    ni wọn yóò jọ́sìn níwájú rẹ̀,
28 Nítorí ìjọba ni ti Olúwa.
    Òun ni ó ń pàṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè.

29 Bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo àwọn olówó ayé wọn yóò ṣe àsè, wọn yóò sì sìn;
    gbogbo àwọn tí ó wọ inú ilẹ̀ lọ yóò kúnlẹ̀ ní iwájú rẹ̀
    àti ẹni tí kò lè pa ọkàn ara rẹ̀ mọ́ ni ààyè.
30 Irú-ọmọ rẹ̀ yóò sìn ín;
    a ó sọ fún àwọn ìran tí ń bọ̀ nípa Olúwa,
31 Wọn yóò polongo òdodo rẹ̀
    sí àwọn ọmọ tí a kò tí ì bí,
    wí pé, òun ni ó ṣe èyí.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.