Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

M’Cheyne Bible Reading Plan

The classic M'Cheyne plan--read the Old Testament, New Testament, and Psalms or Gospels every day.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Onidajọ 17

Ìbọ̀rìṣà Mika

17 Nígbà náà ni ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mika láti agbègbè òkè Efraimu sọ fún ìyá rẹ̀ pé, “Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà ṣékélì fàdákà èyí tí wọ́n jí mọ́ ọ lọ́wọ́, àti nípa èyí tí mo gbọ́ tí ìwọ ń ṣẹ́ èpè. Kíyèsi fàdákà náà wà ní ọ̀dọ̀ mi, èmi ni mo kó o.”

Nígbà náà ni ìyá rẹ̀ dáhùn pé, “Kí Olúwa bùkún ọ ọmọ mi!”

Nígbà tí ó da ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà ṣékélì fàdákà náà padà fún ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ dáhùn pé, “Èmi ti fi òtítọ́ inú ya sílífà náà sọ́tọ̀ sí Olúwa fún ọmọ mi láti fi dá ère dídá àti ère gbígbẹ́. Èmi yóò dá a padà fún ọ.”

Nítorí náà òun dá sílífà náà padà fún ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ sì mú igba (200) ṣékélì fàdákà, ó sì fún alágbẹ̀dẹ fàdákà ẹni tí ó fi wọ́n rọ ère fínfín àti ère dídà. Wọ́n sì kó wọn sí ilé Mika.

Ọkùnrin náà, Mika sì ní ojúbọ kan. Òun sì ra ẹ̀wù efodu kan, ó sì ṣe àwọn ère kan, ó sì fi ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin ṣe àlùfáà rẹ̀. Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àwọn ọmọ Israẹli kò ní ọba; olúkúlùkù ṣe bí ó ti rò pé ó tọ́ ní ojú ara rẹ́.

Ọ̀dọ́mọkùnrin kan sì ti Bẹtilẹhẹmu ti Juda wá, tí í ṣe ìdílé Juda, ẹni tí í ṣe ẹ̀yà Lefi, òun sì ṣe àtìpó níbẹ̀, Ọkùnrin náà sì ti ìlú Bẹtilẹhẹmu ti Juda lọ, láti ṣe àtìpó ní ibikíbi tí ó bá rí. Ní ojú ọ̀nà àjò rẹ̀, ó dé ilẹ̀ Mika nínú àwọn ilẹ̀ òkè Efraimu.

Mika bi í pé, “Níbo ni ó ti ń bọ̀?”

Ó dáhùn pé, “Ọmọ Lefi ni mí láti Bẹtilẹhẹmu Juda, mo sì ń wá ibi tí èmi yóò máa gbé.”

10 Mika sì sọ fún un wí pé, “Dúró lọ́dọ̀ mi kí ìwọ sì jẹ́ baba mi àti àlùfáà fún mi, èmi ó sì máa fún ọ ní ṣékélì mẹ́wàá fàdákà ní ọdọọdún, pẹ̀lú aṣọ àti oúnjẹ rẹ̀.” 11 Ọmọ Lefi náà sì gbà láti máa bá a gbé, ọ̀dọ́mọkùnrin náà sì dàbí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀. 12 Nígbà náà ni Mika ya ará Lefi náà sí mímọ́, ọ̀dọ́mọkùnrin náà sì di àlùfáà rẹ̀, ó sì ń gbé ilé rẹ̀. 13 Mika sì wí pé, “Báyìí, èmi mọ̀ pé Olúwa yóò ṣe mi ní oore nítorí pé mo ní ọmọ Lefi ní àlùfáà mi.”

Ìṣe àwọn Aposteli 21

Sí Jerusalẹmu

21 Lẹ́yìn tí àwa ti kúrò lọ́dọ̀ wọn, tí a sì ṣíkọ̀, àwa bá ọ̀nà wa lọ tààrà sí Kosi. Ní ọjọ́ kejì a sì lọ sí Rodu, àti gba ibẹ̀ lọ sí Patara: A rí ọkọ̀ ojú omi kan tí ń rékọjá lọ sí Fonisia, a wọ inú ọkọ̀ náà, a sì ṣíkọ̀. Nígbà tí àwa sì ń wo Saipurọsi lókèèrè, a sì fi í sí ọwọ́ òsì, a fi orí ọ́kọ̀ le Siria, a sì gúnlẹ̀ ni Tire; nítorí níbẹ̀ ni ọkọ̀ yóò tí já ẹrù sílẹ̀. Nígbà tí a sì ti rí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn níbẹ̀, a dúró ní ọ̀dọ̀ wọn níbẹ̀ fún ọjọ́ méje: àwọn ẹni tí ó ti ipá Ẹ̀mí wí fún Paulu pé, kí ó má ṣe lọ sí Jerusalẹmu. Nígbà tí a sì tí lo ọjọ́ wọ̀nyí tan, àwa jáde, a sì mu ọ̀nà wá pọ̀n; gbogbo wọn sì sìn wá, pẹ̀lú àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé títí àwa fi jáde sí ẹ̀yìn ìlú, nígbà tí àwa sì gúnlẹ̀ ní èbúté, a sì gbàdúrà. Nígbà tí a sì ti dágbére fún ara wa, a bọ́ sí ọkọ̀; bẹ́ẹ̀ ni àwọn sì padà lọ sí ilé wọn.

Nígbà tí a sì ti parí àjò wa láti Tire, àwa dé Pitolemai; nígbà ti a sì kí àwọn ará, a sì bá wọn gbé ní ọjọ́ kan. Ní ọjọ́ kejì a lọ kúrò, a sì wá sí Kesarea; nígbà tí á sì wọ ilé Filipi efangelisti tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn méje; àwa sì wọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀. Ọkùnrin yìí sì ní ọmọbìnrin mẹ́rin, wúńdíá, tí wọ́n máa ń sọtẹ́lẹ̀.

10 Bí a sì tí wà níbẹ̀ lọ́jọ́ púpọ̀, wòlíì kan tí Judea sọ̀kalẹ̀ wá, tí a ń pè ní Agabu. 11 Nígbà tí ó sì dé ọ̀dọ̀ wa, ó mú àmùrè Paulu, ó sì de ara rẹ̀ ní ọwọ́ àti ẹsẹ̀, ó sì wí pé, “Báyìí ni Ẹ̀mí Mímọ́ wí: ‘Báyìí ni àwọn Júù tí ó wà ní Jerusalẹmu yóò de ọkùnrin tí ó ní àmùrè yìí, wọn ó sì fi í lé àwọn aláìkọlà lọ́wọ́.’ ”

12 Nígbà tí a sì tí gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, àti àwa, àti àwọn ará ibẹ̀ náà bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó má ṣe gòkè lọ sí Jerusalẹmu. 13 Nígbà náà ni Paulu dáhùn wí pé, “Èwo ni ẹ̀yin ń ṣe yìí, tí ẹ̀yin ń sọkún, tí ẹ sì ń mú àárẹ̀ bá ọkàn mi; nítorí èmí tí múra tan, kì í ṣe fún dídè nìkan, ṣùgbọ́n láti kú pẹ̀lú ni Jerusalẹmu, nítorí orúkọ Jesu Olúwa.” 14 Nígbà tí a kò lè pa á ní ọkàn dà, a dákẹ́ wí pé, “Ìfẹ́ tí Olúwa ni kí ó ṣe!”

15 Lẹ́yìn ọjọ́ wọ̀nyí, a palẹ̀mọ́, a sì gòkè lọ sí Jerusalẹmu. 16 Nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn láti Kesarea bá wa lọ, wọ́n sì mú wa lọ sí ilé Munasoni ọmọ-ẹ̀yìn àtijọ́ kan ara Saipurọsi, lọ́dọ̀ ẹni tí àwa yóò dé sí.

Dídé Paulu sí Jerusalẹmu

17 Nígbà tí a sì dé Jerusalẹmu, àwọn arákùnrin sì fi ayọ̀ gbà wá, 18 Ní ọjọ́ kejì, a bá Paulu lọ sọ́dọ̀ Jakọbu; gbogbo àwọn alàgbà sì wà níbẹ̀. 19 Nígbà tí ó sì kí wọn tan, ó ròyìn lẹ́sẹẹsẹ ohun gbogbo tí Ọlọ́run ṣe láàrín àwọn aláìkọlà nípa iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀.

20 Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, wọ́n yin Ọlọ́run lógo, wọ́n sì wí fún un pé, “Arákùnrin, ìwọ rí iye ẹgbẹẹgbẹ̀rún nínú àwọn Júù tí ó gbàgbọ́, gbogbo wọn ni ó sì ní ìtara fún òfin. 21 Wọ́n sì ti ròyìn rẹ̀ fún wọn pé, ìwọ ń kọ́ gbogbo àwọn Júù tí ó wà láàrín àwọn aláìkọlà pé, kí wọn kọ Mose sílẹ̀, ó ń wí fún wọn pé kí wọn má ṣe kọ àwọn ọmọ wọn ní ilà mọ́, kí wọn má sì ṣe rìn gẹ́gẹ́ bí àṣà wọn. 22 Ǹjẹ́ èwo ni ṣíṣe? Ìjọ kò lè ṣàìmá péjọpọ̀: dájúdájú wọn yóò gbọ́ pé, ìwọ dé. 23 Ǹjẹ́ èyí tí àwa ó wí fún ọ yìí ni kí o ṣe: Àwa ni ọkùnrin mẹ́rin tí wọ́n wà lábẹ́ ẹ̀jẹ́; 24 Àwọn ni kí ìwọ mú, kí o sì ṣe ìwẹ̀nùmọ́ pẹ̀lú wọn, kí ó sì san owó láti fá irun orí wọn: gbogbo ènìyàn yóò sì mọ̀ pé, kò sì òtítọ́ kan nínú ohun tí wọ́n gbọ́ sí ọ; àti pé, ìwọ tìkára rẹ ń rìn déédé, ìwọ sì ń pa òfin Mose mọ́. 25 Ṣùgbọ́n ní ti àwọn aláìkọlà tí ó gbàgbọ́, àwa tí kọ̀wé, a sì ti pinnu rẹ̀ pé, kí wọn pa ara wọn mọ́ kúrò nínú ohun tí a fi rú ẹbọ sí òrìṣà, àti ẹ̀jẹ̀ àti ohun ìlọ́lọ́rùnpa, àti àgbèrè.”

26 Nígbà náà ni Paulu mú àwọn ọkùnrin náà; ní ọjọ́ kejì ó ṣe ìwẹ̀nùmọ́ pẹ̀lú wọn, ó sì wọ inú tẹmpili lọ, láti sọ ìgbà tí ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ náà yóò pé tí a ó sì fi ọrẹ lélẹ̀ fún olúkúlùkù wọn.

A mú Paulu

27 Nígbà tí ọjọ́ méje sì fẹ́rẹ̀ pé, tí àwọn Júù tí ó ti Asia wá rí i ni tẹmpili, wọ́n rú gbogbo àwọn ènìyàn sókè, wọ́n nawọ́ mú un. 28 Wọ́n ń kígbe wí pé, “Ẹ̀yin ènìyàn Israẹli, ẹ gbà wá: Èyí ni ọkùnrin náà tí ń kọ́ gbogbo ènìyàn níbi gbogbo lòdì sí àwọn ènìyàn, àti sí òfin, àti sí ibí yìí: àti pẹ̀lú ó sì mú àwọn ará Giriki wá sínú tẹmpili, ó sì tí ba ibi mímọ́ yìí jẹ́.” 29 Nítorí wọ́n tí rí Tirofimu ará Efesu pẹ̀lú rẹ̀ ní ìlú, ẹni tí wọ́n ṣe bí Paulu mú wá sínú tẹmpili.

30 Gbogbo ìlú sì wà ní ìrúkèrúdò, àwọn ènìyàn sì súré jọ: wọ́n sì mú Paulu, wọ́n sì wọ́ ọ jáde kúrò nínú tẹmpili: lójúkan náà, a sì ti ìlẹ̀kùn. 31 Bí wọn sì ti ń wá ọ̀nà láti pa á, ìròyìn dé ọ̀dọ̀ olórí ẹgbẹ́ ọmọ-ogun pé, gbogbo Jerusalẹmu ti dàrú. 32 Lójúkan náà, ó sì ti mú àwọn ọmọ-ogun àti àwọn balógun ọ̀rún, ó sì súré sọ̀kalẹ̀ tọ̀ wọ́n lọ; nígbà tí wọ́n sì rí í olórí ogun àti àwọn ọmọ-ogun dẹ́kun lílù Paulu.

33 Nígbà náà ni olórí ogun súnmọ́ wọn, ó sì mú un, ó pàṣẹ pé kí a fi ẹ̀wọ̀n méjì dè é; ó sì béèrè ẹni tí ó jẹ́, àti ohun tí ó ṣe. 34 Àwọn kan ń kígbe ohun kan, àwọn mìíràn ń kígbe ohun mìíràn nínú àwùjọ; nígbà tí kò sì lè mọ̀ ìdí pàtàkì fún ìrúkèrúdò náà, ó pàṣẹ kí wọ́n mú un lọ sínú àgọ́ àwọn ológun. 35 Nígbà tí ó sì dé orí àtẹ̀gùn, gbígbé ni a gbé e sókè lọ́wọ́ àwọn ọmọ-ogun nítorí ìwà ipá àwọn ènìyàn. 36 Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn rọ́ tẹ̀lé e, wọ́n ń kígbe pé, “Mú un kúrò!”

Ọ̀rọ̀ Paulu níwájú àwọn ènìyàn

37 Bí wọ́n sì tí fẹ́rẹ̀ mú Paulu wọ inú àgọ́ àwọn ológun lọ, ó wí fún olórí ogun pé, “Èmi ha lè bá ọ sọ̀rọ̀ bí?”

Ó sì dáhùn wí pé, “Ìwọ mọ èdè Giriki bí? 38 Ìwọ ha kọ ní ara Ejibiti náà, tí ó ṣọ̀tẹ̀ ṣáájú ọjọ́ wọ̀nyí, ti ó sì ti mú ẹgbàajì ọkùnrin nínú àwọn tí í ṣe apànìyàn lẹ́yìn lọ sí ijù?”

39 Ṣùgbọ́n Paulu sì wí pé, “Júù ní èmi jẹ́, ará Tarsu ìlú Kilikia, tí kì í ṣe ìlú yẹpẹrẹ kan, èmi síbẹ̀ ọ, fún mi ní ààyè láti bá àwọn ènìyàn wọ̀nyí sọ̀rọ̀!”

40 Nígbà tí ó sì tí fún un ní ààyè, Paulu dúró lórí àtẹ̀gùn, ó sì juwọ́ sí àwọn ènìyàn. Nígbà tí wọ́n sì dákẹ́ rọ́rọ́, ó bá wọn sọ̀rọ̀ ní èdè Heberu, wí pé:

Jeremiah 30-31

Ìmúpadà sípò Israẹli

30 Ọ̀rọ̀ tí ó tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá, wí pé: “Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí, pé: ‘Ìwọ kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ti bá ọ sọ sínú ìwé kan. Ọjọ́ ń bọ̀ nígbà tí ń ó mú àwọn ènìyàn mi, àwọn ọmọ Israẹli àti Juda kúrò nínú ìgbèkùn, tí n ó sì dá wọn padà sí orí ilẹ̀ tí mo fi fún àwọn baba ńlá wọn láti ní,’ ni Olúwa Ọlọ́run wí.”

Ìwọ̀nyí ni àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run sí Israẹli àti Juda: “Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“ ‘Igbe ẹ̀rù àti ìwárìrì ni a gbọ́
    láìṣe igbe àlàáfíà.
Béèrè kí o sì rí:
    Ǹjẹ́ ọkùnrin le dá ọmọ bí?
Èéṣe tí mo fi ń rí àwọn alágbára ọkùnrin
    tí wọ́n fi ọwọ́ wọn mú inú wọn bí obìnrin tó ń rọbí,
    tí ojú gbogbo wọ́n sì fàro fún ìrora?
Ọjọ́ náà yóò ha ti burú tó!
    Kò sí ọjọ́ tí yóò dàbí rẹ̀,
Ọjọ́ náà yóò jẹ́ àkókò ìdààmú fún Jakọbu
    ṣùgbọ́n yóò rí ìgbàlà kúrò nínú ìdààmú náà.

“ ‘Ní ọjọ́ náà,’ Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé;
    ‘Èmi yóò gbé àjàgà kúrò lọ́rùn wọn,
Èmi yóò sì tú ìdè wọn sọnù.
    Àwọn àjèjì kì yóò sì mú ọ sìn wọ́n mọ́
Dípò bẹ́ẹ̀ wọn yóò máa sin Olúwa Ọlọ́run wọn
    àti Dafidi gẹ́gẹ́ bí ọba wọn,
    ẹni tí èmi yóò gbé dìde fún wọn.

10 “ ‘Nítorí náà, má ṣe bẹ̀rù, Ìwọ Jakọbu ìránṣẹ́ mi,
    má sì ṣe jẹ́ kí ẹ̀rù bà ọ́, Ìwọ Israẹli,’
    ni Olúwa wí.
    ‘Èmi yóò gbà ọ́ kúrò láti ọ̀nà jíjìn wá,
àní àwọn ìran rẹ láti ilẹ̀ àtìpó wọn.
    Jakọbu yóò sì tún ní àlàáfíà àti ààbò rẹ̀ padà,
    kò sì ṣí ẹni tí yóò ṣẹ̀rù bà á mọ́.
11 Èmi wà pẹ̀lú rẹ, n ó sì gbà ọ́,’
    ni Olúwa wí.
‘Bí mo tilẹ̀ pa gbogbo orílẹ̀-èdè run,
    nínú èyí tí mo ti fọ́n ọn yín ká,
síbẹ̀ èmi kì yóò pa yín run pátápátá.
    Èmi yóò bá yín wí pẹ̀lú ìdájọ́ òdodo nìkan;
    Èmi kò ní fi yín sílẹ̀ láìjìyà.’

12 “Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“ ‘Ọgbẹ́ yín kò gbóògùn,
    bẹ́ẹ̀ ni egbò yín kọjá ìwòsàn.
13 Kò sí ẹnìkan tí yóò bẹ̀bẹ̀ fún àìṣedéédéé yín,
    kò sí ètùtù fún ọgbẹ́ yín,
    a kò sì mú yín láradá.
14 Gbogbo àwọn olùfẹ́ rẹ ti gbàgbé rẹ,
    wọn kò sì náání rẹ mọ́ pẹ̀lú.
Mo ti nà ọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá rẹ yóò ti nà ọ,
    mo sì bá a ọ wí gẹ́gẹ́ bí ìkà,
nítorí tí ẹ̀bi rẹ pọ̀ púpọ̀,
    ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kò sì lóǹkà.
15 Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń kígbe nítorí ọgbẹ́ yín,
    ìrora yín èyí tí kò ní oògùn?
Nítorí ọ̀pọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ yín àti ẹ̀bi yín tó ga
    ni mo fi ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí sí i yín.

16 “ ‘Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ṣe yín ní ibi ni ibi yóò bá,
    àní gbogbo àwọn ọ̀tá yín ni a ó sọ di àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì;
    gbogbo àwọn tí wọ́n bà yín jẹ́ ni a ó bàjẹ́.
17 Ṣùgbọ́n èmi yóò fi ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìlera fún yín,
    èmi yóò sì wo ọ̀gbẹ́ yín sàn,’
    ni Olúwa wí,
    ‘nítorí tí a pè yín ní alárìnkiri
    Sioni tí gbogbo ènìyàn dágunlá sí.’

18 “Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“ ‘Èmi yóò dá gbogbo ìre àgọ́ Jakọbu padà,
    èmi yóò sì ṣe àánú fún olùgbé àgọ́ rẹ̀;
ìlú náà yóò sì di títúnṣe
    tí ààfin ìlú náà yóò sì wà ní ipò rẹ̀.
19 Láti ẹnu wọn ni orin ọpẹ́ àti
    ìyìn yóò sì ti máa jáde.
Èmi yóò sọ wọ́n di púpọ̀,
    wọn kì yóò sì dínkù ní iye,
Èmi yóò fi ọlá fún wọn,
    wọn kò sì ní di ẹni àbùkù.
20 Ọmọ ọmọ wọn yóò wà bí i ti ìgbàanì
    níwájú mi ni wọn yóò sì tẹ àwùjọ wọn dúró sí.
Gbogbo ẹni tó bá ni wọ́n lára,
    ni èmi yóò fì ìyà jẹ.
21 Ọ̀kan nínú wọn ni yóò jẹ́ olórí wọn,
    ọba wọn yóò dìde láti àárín wọn.
Èmi yóò mú un wá sí ọ̀dọ̀ mi, òun yóò sì súnmọ́ mi,
    nítorí ta ni ẹni náà tí yóò fi ara rẹ̀ jì láti súnmọ́ mi?’
    ni Olúwa wí.
22 ‘Nítorí náà, ẹ̀yin yóò jẹ́ ènìyàn mi,
    èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run yín.’ ”

23 Wò ó, ìbínú Ọlọ́run yóò tú jáde,
    ìjì líle yóò sì sọ̀kalẹ̀ sórí àwọn ènìyàn búburú.
24 Ìbínú ńlá Ọlọ́run kò ní dẹ̀yìn lẹ́yìn
    àwọn ìkà títí yóò fi mú
    èrò ọkàn rẹ̀ ṣẹ.
Ní àìpẹ́ ọjọ́,
    òye rẹ̀ yóò yé e yín.

31 “Nígbà náà, Èmi yóò jẹ́ Ọlọ́run fún gbogbo ìdílé ìran Israẹli, àwọn náà yóò sì jẹ́ ènìyàn mi,” ni Olúwa wí.

Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“Àwọn ènìyàn tí ó sá àsálà lọ́wọ́ idà
    yóò rí ojúrere Olúwa ní aṣálẹ̀,
    Èmi yóò sì fi ìsinmi fún Israẹli.”

Olúwa ti fi ara rẹ̀ hàn wá ní ìgbà kan rí, ó wí pé:

“Èmi ti nífẹ̀ẹ́ yín pẹ̀lú ìfẹ́ àìlópin;
    mo ti fi ìfẹ́ ńlá fà yín,
Èmi yóò tún gbé e yín sókè,
    àní a ó tún gbé e yín ró ìwọ wúńdíá ilẹ̀ Israẹli.
Àní ẹ ó tún tún ohun èlò orin yín gbé,
    ẹ ó sì jáde síta pẹ̀lú ijó àti ayọ̀.
Ẹ ó tún gbin ọgbà àjàrà
    ní orí òkè Samaria;
àwọn àgbẹ̀ yóò sì máa
    gbádùn èso oko wọn.
Ọjọ́ kan máa wà tí àwọn olùṣọ́ yóò kígbe jáde
    lórí òkè Efraimu wí pé,
‘Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a gòkè lọ sí Sioni,
    ní ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run wa.’ ”

Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa sọ wí pé:

“Ẹ fi ayọ̀ kọrin sí Jakọbu;
    ẹ hó sí olórí àwọn orílẹ̀-èdè gbogbo.
Jẹ́ kí wọ́n gbọ́ ìyìn rẹ kí o sì wí pé,
    Olúwa, gba àwọn ènìyàn rẹ là;
    àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Israẹli.’
Wò ó, Èmi yóò mú wọn wá láti ilẹ̀ àríwá;
    èmi yóò kó gbogbo wọn jọ láti òpin ayé.
Lára wọn ni yóò jẹ́ afọ́jú àti arọ,
    aboyún àti obìnrin tí ń rọbí,
    ọ̀pọ̀ ènìyàn yóò wá.
Wọn yóò wá pẹ̀lú ẹkún,
    wọn yóò gbàdúrà bí Èmi yóò ṣe mú wọn padà.
Èmi yóò jẹ́ atọ́nà fún wọn ní ẹ̀bá odò omi;
    ní ọ̀nà tí ó tẹ́jú tí wọn kì yóò le ṣubú,
nítorí èmi ni baba Israẹli,
    Efraimu sì ni àkọ́bí ọkùnrin mi.

10 “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin orílẹ̀-èdè
    ẹ kéde rẹ̀ ní erékùṣù jíjìn;
‘Ẹni tí ó bá tú Israẹli ká yóò kójọ,
    yóò sì ṣọ́ agbo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùntàn.’
11 Nítorí Olúwa ti tú Jakọbu sílẹ̀, o sì rà á padà
    ní ọwọ́ àwọn tí ó lágbára jù ú lọ
12 Wọn yóò wá, wọn ó sì hó ìhó ayọ̀ lórí òkè Sioni;
    wọn yóò yọ ayọ̀ níbi oore Olúwa.
Àlìkámà ni, ọtí wáìnì tuntun àti òróró
    ọ̀dọ́-àgùntàn àti ọ̀dọ́ ọ̀wọ́ ẹran.
Wọn ó dàbí ọgbà àjàrà tí a bomirin,
    ìkorò kò ní bá wọn mọ́.
13 Àwọn wúńdíá yóò jó, wọn ó sì kún fún ayọ̀,
    bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ọkùnrin àti obìnrin.
Èmi yóò sọ ọ̀fọ̀ wọn di ayọ̀,
    dípò ìkorò èmi yóò tù wọ́n nínú.
    Èmi ó sì fún wọn ní ayọ̀.
14 Èmi ó tẹ́ àwọn àlùfáà lọ́rùn pẹ̀lú ọ̀pọ̀;
    àwọn ènìyàn mi yóò sì kún fún oore mi,”
    ni Olúwa wí.

15 (A)Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“A gbọ́ ohùn kan ní Rama
    tí ń ṣọ̀fọ̀ pẹ̀lú ẹkún kíkorò.
Rakeli ń sọkún àwọn ọmọ rẹ̀;
    kò gbà kí wọ́n tu òun nínú,
    nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ kò sí mọ́.”

16 Báyìí ni Olúwa wí:

“Dá ohùn rẹ dúró nínú ẹkún
    àti ojú rẹ nínú omijé;
nítorí a ó fi èrè sí iṣẹ́ rẹ,”
    ni Olúwa wí.
    “Wọn ó sì padà wá láti ilẹ̀ ọ̀tá.
17 Nítorí ìrètí wà fún ọjọ́ iwájú rẹ,”
    ni Olúwa wí.
    “Àwọn ọmọ rẹ yóò padà wá sí ilẹ̀ wọn.

18 “Nítòótọ́, èmi ti gbọ́ ìpohùnréré Efraimu wí pé,
    ‘Ìwọ ti bá mi wí gẹ́gẹ́ bí ọmọ màlúù tí a kò kọ́
èmi sì ti gbọ́ ìbáwí.
    Rà mí padà, èmi yóò sì yípadà,
    nítorí ìwọ ni Olúwa Ọlọ́run mi.
19 Lẹ́yìn tí èmi ti yípadà,
    mo ronúpìwàdà,
lẹ́yìn tí èmi ti wá mọ̀,
    èmi lu àyà mi.
Ojú tì mí, mo sì dààmú;
    nítorí èmi gba èrè ẹ̀gàn ìgbà èwe mi.’
20 Efraimu kì í ha í ṣe ọmọkùnrin mi dáradára
    tí inú mi dùn sí bí?
Bí èmi ti ń sọ̀rọ̀ sí i tó,
    síbẹ̀, èmi rántí rẹ̀.
Nítorí náà, ọkàn mi ṣe ohun kan fún un,
    èmi káàánú gidigidi fún un,”
    ni Olúwa wí.

21 “Gbé ààmì ojú ọ̀nà dìde,
    ṣe atọ́nà ààmì,
kíyèsi òpópó ọ̀nà geere
    ojú ọ̀nà tí ó ń gbà.
Yípadà ìwọ wúńdíá Israẹli,
    padà sí àwọn ìlú rẹ.
22 Ìwọ yóò ti ṣìnà pẹ́ tó,
    ìwọ aláìṣòótọ́ ọmọbìnrin;
Olúwa yóò dá ohun tuntun lórí ilẹ̀,
    ọmọbìnrin kan yóò yí ọkùnrin kan ká.”

23 Báyìí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Israẹli wí: “Nígbà tí èmi bá kó wọn dé láti ìgbèkùn; àwọn ènìyàn tí ó wà ní ilẹ̀ Juda àti ní àwọn ìlú rẹ̀ yóò tún lo àwọn ọ̀rọ̀ yìí lẹ́ẹ̀kan sí i; wí pé, ‘Kí Olúwa kí ó bùkún fún ọ, ìwọ ibùgbé òdodo, ìwọ òkè ìwà mímọ́.’ 24 Àwọn ènìyàn yóò gbé papọ̀ ní Juda àti ní gbogbo àwọn ìlú rẹ̀; bákan náà ni àgbẹ̀ àti àwọn tí ń tẹ̀lé agbo ẹran wọn ká. 25 Èmi yóò sọ aláàárẹ̀ di ọ̀tun, èmi yóò sì tẹ́ gbogbo ọkàn tí ń káàánú lọ́rùn.”

26 Lórí èyí ni mo jí, mo sì wò yíká, oorun mi sì dùn mọ́ mi.

27 “Wò ó, ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “nígbà tí èmi yóò gbin ilé Israẹli àti ilé Juda pẹ̀lú irúgbìn ọmọ ènìyàn àti ẹranko. 28 Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ń ṣọ́ wọn, láti fàtu, àti láti wó lulẹ̀, àti láti gba ìṣàkóso, láti bàjẹ́ àti láti mú ibi wá, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣọ́ wọn láti kọ́ àti láti gbìn,” ni Olúwa wí. 29 “Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àwọn ènìyàn kò ní sọ mọ́ pé:

“ ‘Àwọn baba ti jẹ èso àjàrà àìpọ́n
    àti pé eyín kan àwọn ọmọdé.’

30 Ṣùgbọ́n olúkúlùkù ni yóò kú fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ èso kíkan ni eyín yóò kan.

31 (B)(C) “Ìgbà kan ń bọ̀,” ni Olúwa wí,
    “tí Èmi yóò bá ilé Israẹli
àti ilé Juda dá májẹ̀mú tuntun.
32 Kò ní dàbí májẹ̀mú
    tí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá,
nígbà tí mo fà wọ́n lọ́wọ́,
    tí mo mú wọn jáde ní Ejibiti
nítorí wọ́n da májẹ̀mú mi.
    Lóòótọ́ ọkọ ni èmi jẹ́ fún wọn,”
    ni Olúwa wí.
33 “Èyí ni májẹ̀mú tí èmi yóò bá ilé Israẹli dá
    lẹ́yìn ìgbà náà,” ni Olúwa wí pé:
“Èmi yóò fi òfin mi sí ọkàn wọn,
    èmi ó sì kọ ọ́ sí àyà wọn.
Èmi ó jẹ́ Olúwa wọn;
    àwọn ó sì jẹ́ ènìyàn mi.
34 Kò ní sí pé ọkùnrin kan ń kọ́ àwọn ará ilé rẹ̀
    tàbí ọkùnrin ń kọ́ arákùnrin rẹ̀ pé, ‘Ẹ mọ Olúwa,’
nítorí gbogbo wọn ni yóò mọ̀ mí
    láti ẹni kékeré wọn títí dé ẹni ńlá,”
    ni Olúwa wí.
“Nítorí èmi ó dárí àìṣedéédéé wọn jì,
    èmi kò sì ní rántí ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́.”

35 Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

ẹni tí ó mú oòrùn
    tan ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀sán,
tí ó mú òṣùpá àti ìràwọ̀
    ràn ní òru;
tí ó rú omi Òkun sókè
    tó bẹ́ẹ̀ tí Ìjì rẹ̀ fi ń hó
    Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.
36 “Àyàfi tí ìlànà yìí bá kúrò níwájú mi,”
    ni Olúwa wí.
“Ǹjẹ́ àwọn ọmọ Israẹli yóò dẹ́kun
    láti jẹ́ orílẹ̀-èdè níwájú mi láéláé.”

37 Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“Àyàfi tí a bá lé àwọn ọ̀run lókè
    tí ìpìlẹ̀ ayé sì di àwárí ní ìsàlẹ̀,
ni èmi yóò kọ àwọn Israẹli
    nítorí ohun gbogbo tí wọ́n ti ṣe,”
    ni Olúwa wí.

38 “Ọjọ́ náà ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “tí wọn yóò tún ìlú yìí kọ́ fún mi láti ilé ìṣọ́ Hananeli dé igun ẹnu ibodè. 39 Okùn ìwọ̀n yóò sì nà jáde láti ibi gígùn lọ sí òkè Garebu yóò sì lọ sí Goa. 40 Gbogbo Àfonífojì níbi tí wọ́n ń da òkú àti eérú sí, àti gbogbo Àfonífojì Kidironi ní ìhà ìlà-oòrùn títí dé igun ẹnu ibodè ẹṣin yóò jẹ́ mímọ́ sí Olúwa. A kì yóò fa ìlú náà tu tàbí kí a wó o palẹ̀.”

Marku 16

Àjíǹde

16 (A)(B) Nígbà tí ọjọ́ ìsinmi sì kọjá, Maria Magdalene, Maria ìyá Jakọbu, àti Salome mú òróró olóòórùn dídùn wá kí wọn bá à le fi kun Jesu lára. Ní kùtùkùtù ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀, wọ́n wá sí ibi ibojì nígbà tí oòrùn bẹ̀rẹ̀ sí yọ, wọn sì ń bi ara wọn léèrè pé, “Ta ni yóò yí òkúta náà kúrò ní ẹnu ibojì fún wa?”

Ṣùgbọ́n nígbà tí wọn sì wò ó, wọ́n rí i pé a ti yí òkúta tí ó tóbi gidigidi náà kúrò. Nígbà tí wọ́n sì wo inú ibojì náà, wọ́n rí ọ̀dọ́mọkùnrin kàn tí ó wọ aṣọ funfun, ó jókòó ní apá ọ̀tún, ẹnu sì yà wọn.

Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má bẹ̀rù: Ẹ̀yin ń wá Jesu tí Nasareti, tí a kàn mọ́ àgbélébùú. Ó jíǹde! Kò sí níhìn-ín yìí mọ́, Ẹ wo ibi tí wọ́n gbé tẹ́ ẹ sí. (C)Ṣùgbọ́n ẹ lọ sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ títí kan Peteru wí pé, ‘Òun ti ń lọ síwájú yín sí Galili. Ibẹ̀ ni ẹ̀yin yóò ti rí i, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ fún yín.’ ”

Wọ́n sáré jáde lọ kánkán, kúrò ní ibi ibojì náà, nítorí tí wọ́n wárìrì; ẹ̀rù sì bà wọn gidigidi; wọn kò wí ohunkóhun fún ẹnikẹ́ni, nítorí ẹ̀rù bá wọ́n.

[Àwọn àkọsílẹ̀ àtijọ́ àti àwọn ẹlẹ́rìí àtijọ́ kò ní ẹsẹ 9-20.]

Nígbà tí Jesu jíǹde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ní ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀, ó kọ́ fi ara hàn fun Maria Magdalene, ni ara ẹni tí ó ti lé ẹ̀mí Èṣù méje jáde. 10 Òun sì lọ sọ fún àwọn tí ó ti ń bá a gbé, bí wọn ti ń gbààwẹ̀, tí wọ́n sì ń sọkún. 11 Àti àwọn, nígbà tí wọ́n sì gbọ́ pé Jesu wa láààyè, àti pé, òun ti rí i, wọn kò gbàgbọ́.

12 Lẹ́yìn èyí, ó sì fi ara hàn fún àwọn méjì ní ọ̀nà mìíràn, bí wọ́n ti ń rìn ní ọ̀nà, tí wọ́n sì ń lọ sí ìgbèríko. 13 Nígbà tí wọ́n sì mọ ẹni tí i ṣe, wọ́n sì lọ ròyìn fún àwọn ìyókù, síbẹ̀, àwọn ìyókù kò gbà wọ́n gbọ́.

14 Lẹ́yìn náà, Jesu fi ara rẹ̀ hàn fún àwọn mọ́kànlá níbi tí wọ́n ti ń jẹun papọ̀; Ó sì bá wọn wí fún àìgbàgbọ́ àti ọkàn líle wọn, nítorí wọn kò gba ẹ̀rí àwọn tí ó ti rí i lẹ́yìn àjíǹde rẹ̀ gbọ́.

15 Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ sí gbogbo ayé, kí ẹ sì máa wàásù ìhìnrere mi fún gbogbo ẹ̀dá. 16 Ẹni tí ó bá gbàgbọ́, tí a sì tẹ̀bọmi yóò là. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá kọ̀ tí kò gbàgbọ́ yóò jẹ̀bi. 17 Ààmì wọ̀nyí yóò sì máa bá àwọn tí ó gbàgbọ́ lọ. Ní orúkọ mi ni wọ́n yóò máa lé ẹ̀mí èṣù jáde. Wọn yóò máa fi èdè tuntun sọ̀rọ̀. 18 Wọn yóò sì gbé ejò lọ́wọ́, bí wọ́n bá sì jẹ májèlé kò nípa wọ́n lára rárá. Wọ́n yóò gbé ọwọ́ lé àwọn aláìsàn, ara wọn yóò sì dá.”

19 Nígbà tí Jesu Olúwa sì ti bá wọn sọ̀rọ̀ báyìí tan, á gbé e lọ sí ọ̀run, ó sì jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọ́run. 20 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì jáde lọ. Wọ́n ń wàásù káàkiri. Ọlọ́run sì wà pẹ̀lú wọn, ó sì ń fi ìdí ọ̀rọ̀ rẹ̀ múlẹ̀ nípa àwọn ààmì tí ó tẹ̀lé e.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.