Historical
Orin ọpẹ́ Dafidi
16 Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run, wá sínú àgọ́ ti Dafidi ti pèsè fún un, wọ́n sì gbé ẹbọ sísun àti ọrẹ ìdàpọ̀ kalẹ̀ níwájú Ọlọ́run. 2 Lẹ́yìn tí Dafidi parí ẹbọ sísun àti ọrẹ ìdàpọ̀, ó bùkún àwọn ènìyàn ní orúkọ Olúwa. 3 Nígbà náà ó fún olúkúlùkù ọkùnrin àti obìnrin ọmọ Israẹli ní ìṣù àkàrà kan, àkàrà dídùn ti àkókò kan àti àkàrà dídùn ti èso àjàrà kan.
4 Ó yan díẹ̀ lára àwọn ará Lefi láti máa jọ́sìn níwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa, àti láti ṣe ìrántí àti dúpẹ́ àti láti yin Olúwa, Ọlọ́run Israẹli. 5 Asafu ni olóyè, àtẹ̀lé rẹ ni Sekariah, Jehieli, Ṣemiramotu, Asieli, Mattitiah, Eliabu, Benaiah, Obedi-Edomu àti Jeieli, àwọn ni yóò lu ohun èlò orin olókùn àti dùùrù haapu. Asafu ni yóò lu símbálì kíkan. 6 Àti Benaiah àti Jahasieli àwọn àlùfáà ni yóò fọn ìpè nígbà gbogbo níwájú àpótí ẹ̀rí májẹ̀mú ti Ọlọ́run.
7 Ní ọjọ́ náà Dafidi kọ́kọ́ fi lé Asafu àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ orin Dafidi ti ọpẹ́ sí Olúwa:
8 (A)Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, ẹ pe orúkọ rẹ̀,
ẹ fi iṣẹ́ rẹ̀ hàn nínú àwọn ènìyàn fún ohun tí ó ṣe
9 Ẹ kọrin sí i, ẹ kọrin ìyìn, sí i,
Ẹ sọ ti gbogbo iṣẹ́ ìyanu rẹ̀
10 Ìyìn nínú orúkọ rẹ̀ mímọ́;
jẹ kí ọkàn àwọn tí ó yin Olúwa kí ó yọ̀.
11 Ẹ wá Olúwa àti agbára rẹ̀;
E wá ojú rẹ̀ nígbà gbogbo.
12 Rántí àwọn ìyanu tí Ó ti ṣe,
iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ àti ìdájọ́ tí Ó ti sọ.
13 A! ẹ̀yin ìran ọmọ Israẹli ìránṣẹ́ rẹ̀,
àwọn ọmọ Jakọbu, ẹ̀yin tí ó ti yàn.
14 Òun ni Olúwa Ọlọ́run wa;
ìdájọ́ rẹ̀ wà ní gbogbo ayé.
15 Ó rántí májẹ̀mú rẹ̀ láéláé,
ọ̀rọ̀ tí ó pàṣẹ, fún ẹgbẹgbẹ̀rún ìran,
16 májẹ̀mú tí ó dá pẹ̀lú Abrahamu,
ìbúra tí ó ṣe pẹ̀lú fún Isaaki.
17 Ó ṣe ìdánilójú u rẹ̀ fún Jakọbu,
gẹ́gẹ́ bí àṣẹ sí Israẹli, gẹ́gẹ́ bi májẹ̀mú ayérayé:
18 “Sí ọ, ni Èmi yóò fún ní ilẹ̀ Kenaani.
Gẹ́gẹ́ bí ààyè tí ìwọ yóò jogún.”
19 Nígbà tí wọn kéré ní iye,
wọ́n kéré gidigidi, wọ́n sì jẹ́ àlejò níbẹ̀,
20 wọ́n rìn kiri láti orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè
láti ìjọba kan sí èkejì.
21 Kò gba ọkùnrin kankan láyè láti pọ́n wọn lójú;
nítorí tiwọn, ó bá àwọn ọba wí.
22 “Má ṣe fọwọ́ kan àwọn ẹni ààmì òróró mi;
Má ṣe pa àwọn wòlíì mi lára.”
23 (B)Kọrin sí Olúwa gbogbo ayé;
ẹ máa fi ìgbàlà rẹ̀ hàn láti ọjọ́ dé ọjọ́.
24 Kéde ògo à rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,
ohun ìyàlẹ́nu tí ó ṣe láàrín gbogbo ènìyàn.
25 Nítorí títóbi ni Olúwa òun sì ni ìyìn yẹ Jùlọ;
òun ni kí a bẹ̀rù ju gbogbo àwọn Ọlọ́run lọ.
26 Nítorí gbogbo àwọn ọlọ́run orílẹ̀-èdè jẹ́ àwọn òrìṣà,
ṣùgbọ́n Olúwa dá àwọn ọ̀run.
27 Dídán àti ọláńlá ni ó wà níwájú rẹ̀;
agbára àti ayọ̀ ni ó wà ní ibi ibùgbé rẹ̀.
28 Fi fún Olúwa, ẹ̀yin ìdílé àwọn orílẹ̀-èdè,
ẹ fi ògo àti ipá fún Olúwa.
29 Fún Olúwa ní ìyìn nítorí orúkọ rẹ̀;
gbé ọrẹ kí ẹ sì wá síwájú rẹ̀.
Sìn Olúwa nínú inú dídùn ìwà mímọ́ rẹ̀.
30 Wárìrì níwájú rẹ̀, gbogbo ayé!
Ayé sì fi ìdí múlẹ̀; a kò sì le è ṣí i.
31 Jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó yọ̀, jẹ́ kí ayé kí ó ṣe inú dídùn;
Jẹ́ kí wọn kí ó sọ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, pé “Olúwa jẹ ọba!”
32 Jẹ́ kí ọ̀run kí ó tún dún padà, àti gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀;
Jẹ́ kí àwọn pápá kí ó hó fún ayọ̀, àti gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀!
33 Nígbà náà ni igi igbó yóò kọrin,
Wọn yóò kọrin fún ayọ̀ níwájú Olúwa,
nítorí tí ó wá láti ṣèdájọ́ ayé.
34 (C)Fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó dára;
ìfẹ́ ẹ rẹ̀ dúró títí láé.
35 (D)Ké lóhùn rara, “Gbà wá, Ọlọ́run Olùgbàlà a wa;
kó wa jọ kí o sì gbà wá kúrò lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè,
kí àwa kí ó lè fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ,
kí àwa kí ó lè yọ̀ nínú ìyìn rẹ̀.”
36 Olùbùkún ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli,
láé àti láéláé.
Lẹ́yìn náà gbogbo àwọn ènìyàn wí pé “Àmín,” wọ́n sì “Yin Olúwa.”
37 Dafidi fi Asafu àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa láti jíṣẹ́ níbẹ̀ déédé, gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ṣe gbà. 38 Ó fi Obedi-Edomu àti méjì-dínláàdọ́rin (68) ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ láti ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lú wọn. Obedi-Edomu mọ Jedutuni, àti Hosa pẹ̀lú jẹ́ olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà.
39 Dafidi fi Sadoku àlùfáà àti àwọn àlùfáà ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ níwájú Àgọ́ Olúwa ní ibi gíga ní Gibeoni. 40 Láti gbé pẹpẹ ẹbọ sísun déédé, àárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí a kọ sínú òfin Olúwa, tí ó ti fún Israẹli. 41 Pẹ̀lú wọn ni Hemani àti Jedutuni àti ìyókù tí a mú àti yàn nípasẹ̀ orúkọ láti fi ọpẹ́ fún Olúwa Nítorí tí ìfẹ́ rẹ̀ dúró títí láéláé 42 Hemani àti Jedutuni ni wọ́n dúró fún fífọn ìpè àti Kimbali àti fún lílo ohun èlò yòókù fún orin Ọlọ́run. Àwọn ọmọ Jedutuni wà ní ipò dídúró ní ẹnu-ọ̀nà.
43 Nígbà náà gbogbo àwọn ènìyàn kúrò, olúkúlùkù sí ilé rẹ̀: Dafidi yípadà láti súre fún ìdílé rẹ̀.
Ìlérí Ọlọ́run sí Dafidi
17 (E)Lẹ́yìn ìgbà tí Dafidi ti fi ìdí kalẹ̀ sínú ààfin rẹ̀, ó sọ fún Natani wòlíì pé, “Èmi nìyí, tí ń gbé inú òpépé (igi) ààfin kedari nígbà tí àpótí ẹ̀rí Olúwa wà lábẹ́ àgọ́.”
2 Natani dá Dafidi lóhùn pé, “Ohunkóhun tí o bá ní lọ́kàn, ṣe é nítorí tí Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ.”
3 Ní àṣálẹ́ ọjọ́ náà, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ Natani wá, wí pé:
4 “Lọ sọ fún ìránṣẹ́ mi Dafidi, ‘Èyí ni ohun tí Ọlọ́run wí: Ìwọ kò gbọdọ̀ kọ́ ilé fún mi láti máa gbé. 5 Èmi kò tí ì gbé nínú ilé láti ọjọ́ tí mo ti mú Israẹli jáde wá láti Ejibiti títí di òní yìí. Èmi ń lọ láti àgọ́ dé àgọ́ àti láti ibùgbé dé ibùgbé. 6 Ni ibi gbogbo tí mo ti bá gbogbo Israẹli rìn dé, ǹjẹ́ mo wí nǹkan kan sí ọ̀kan nínú àwọn adarí Israẹli, tí èmí pàṣẹ fún láti máa jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn àwọn ènìyàn mi, wí pé, “Kí ní ṣe tí ẹ̀yin kò fi kọ́ ilé tí a fi igi kedari kọ́ fún mi?” ’
7 “Nígbà náà, sọ fún ìránṣẹ́ mi Dafidi pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi mú ọ kúrò ní pápá oko tútù wá, àní kúrò lẹ́yìn agbo àgùntàn, kí ìwọ kí ó lè máa ṣe olórí àwọn ènìyàn mi Israẹli. 8 Èmi ti wà pẹ̀lú rẹ ní, ibikíbi tí ìwọ bá lọ, èmí sì ti gé gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ kúrò níwájú rẹ. Nísinsin yìí Èmi yóò mú kí orúkọ rẹ kí ó dàbí orúkọ àwọn ènìyàn ńlá jùlọ tí ó wà ní ayé. 9 Èmi yóò sì pèsè ààyè kan fún àwọn ènìyàn mi Israẹli, kí wọn kí ó lè ní ilé tiwọn, kí a má sì ṣe dààmú wọn mọ́. Àwọn ènìyàn búburú kì yóò ni wọ́n lára mọ́, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀. 10 Bí wọ́n sì ti ṣe láti ìgbà tí mo ti yan àwọn aṣáájú lórí àwọn ènìyàn mi Israẹli. Èmi pẹ̀lú yóò ṣẹ́gun gbogbo àwọn ọ̀tá yín.
“ ‘Èmi sọ fún yín pé Olúwa yóò kọ́ ilé kan fún yín: 11 Nígbà ti ọjọ́ rẹ bá kọjá, tí ìwọ bá lọ láti lọ bá àwọn baba à rẹ, Èmi yóò gbé àwọn ọmọ rẹ sókè láti rọ́pò rẹ, ọ̀kan lára àwọn ọmọ tìrẹ, Èmi yóò sì fìdí ìjọba rẹ̀ kalẹ̀. 12 Òun ni ẹni tí yóò kọ́ ilé fún mi, èmi yóò sí fi ìdí ìtẹ́ rẹ̀ kalẹ̀ títí láé. 13 Èmi yóò jẹ́ baba rẹ̀, Òun yóò sì jẹ́ ọmọ mi. Èmi kì yóò mú ìfẹ́ mi kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ láéláé gẹ́gẹ́ bí mo ṣe mú un kúrò lọ́dọ̀ àwọn aṣáájú rẹ̀. 14 Èmi yóò gbé e ka orí ilé mi àti ìjọba mi títí láé; ìtẹ́ rẹ̀ ni a ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ títí láé.’ ”
15 Natani ròyìn fún Dafidi gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ ti ìfihàn yí.
Àdúrà Dafidi
16 Nígbà náà, ọba Dafidi wọlé lọ, ó sì jókòó níwájú Olúwa ó sì wí pé:
“Ta ni èmi, Olúwa Ọlọ́run, àti ki ni ìdílé mi, tí ìwọ mú mi dé ibí? 17 Pẹ̀lú bí ẹni pé èyí kò tó lójú rẹ, Ọlọ́run. Ìwọ ti sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ iwájú ilé ìránṣẹ́ rẹ. Ìwọ ti wò mí bí ẹni pé èmi ni ẹni gbígbéga jù láàrín àwọn ọkùnrin Olúwa Ọlọ́run.
18 “Kí ni ohun tí Dafidi tún lè sọ nítorí ọlá tí o bù fún ìránṣẹ́ rẹ? Nítorí tí ìwọ mọ ìránṣẹ́ rẹ, 19 Olúwa. Nítorí ti ìránṣẹ́ rẹ àti gẹ́gẹ́ bí àṣẹ rẹ, ìwọ ti ṣe ohun ńlá yìí àti láti fi gbogbo ìlérí ńlá yìí hàn.
20 “Kò sí ẹnìkan bí rẹ, kò sì sí Ọlọ́run kan àfi ìwọ, gẹ́gẹ́ bí à ti gbọ́ pẹ̀lú etí ara wa. 21 Pẹ̀lú ta ni ó dàbí àwọn ènìyàn rẹ Israẹli—orílẹ̀-èdè kan ní ayé, tí Ọlọ́run jáde lọ láti ra àwọn ènìyàn kan padà fún ara rẹ̀, àti láti lè ṣe orúkọ fún ara à rẹ, àti láti ṣe ohun ńlá àti ọwọ́ ìyanu nípa lílé àwọn orílẹ̀-èdè kúrò níwájú àwọn ènìyàn rẹ̀, ẹni tí ó gbàlà láti Ejibiti? 22 Ìwọ ṣe àwọn ènìyàn rẹ Israẹli ní tìrẹ láéláé ìwọ Olúwa sì ti di Ọlọ́run wọn.
23 “Nísinsin yìí, Olúwa, Jẹ́ kí ìlérí tí ìwọ ti ṣe fún ìránṣẹ́ rẹ àti ilé rẹ̀ di fífi ìdí múlẹ̀ títí láé. Ṣe gẹ́gẹ́ bí o ti ṣe ìlérí. 24 Kí ó lè di fífi ìdí múlẹ̀ àti kí orúkọ rẹ di gbígbéga títí láé. Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin yóò wí pé, ‘Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ni Ọlọ́run Israẹli.’ Ilé ìránṣẹ́ rẹ Dafidi sì ni a ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ níwájú rẹ.
25 “Ìwọ, Ọlọ́run mi, ti fihan ìránṣẹ́ rẹ pé, ìwọ yóò kọ́ ilé fún un. Bẹ́ẹ̀ ni ìránṣẹ́ rẹ ti ní ìgboyà láti gbàdúrà sí ọ. 26 Olúwa, ìwọ ni Ọlọ́run. Ìwọ ti fi ìlérí dídára yìí fún ìránṣẹ́ rẹ. 27 Nísinsin yìí ó ti tẹ́ ọ lọ́rùn láti bùkún ilé ìránṣẹ́ rẹ kí ó lè tẹ̀síwájú ní ojú rẹ; nítorí ìwọ, Olúwa, ti bùkún un, a ó sì bùkún un títí láéláé.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.