Historical
Kirusi ran àwọn tí a kó nígbèkùn lọ́wọ́ láti padà
1 (A)Ní ọdún kìn-ín-ní Kirusi, ọba Persia, kí a lè mú ọ̀rọ̀ Olúwa tí Jeremiah sọ ṣẹ, Olúwa ru ọkàn Kirusi ọba Persia sókè láti ṣe ìkéde jákèjádò gbogbo agbègbè ìjọba rẹ̀, kí ó sì ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ pé:
2 “Èyí ni ohun tí Kirusi ọba Persia wí pé:
“ ‘Olúwa, Ọlọ́run ọ̀run, ti fún mi ní gbogbo ìjọba ayé. Ó sì ti yàn mí láti kọ́ tẹmpili Olúwa fún un ní Jerusalẹmu tí ó wà ní Juda. 3 Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ láàrín yín—kí Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀, kí ó sì gòkè lọ sí Jerusalẹmu tí ó wà ní Juda, láti kọ́ tẹmpili Olúwa Ọlọ́run Israẹli, Ọlọ́run tí ó wà ní Jerusalẹmu. 4 Kí àwọn ènìyàn ní ibikíbi tí ẹni náà bá ń gbé kí ó fi fàdákà àti wúrà pẹ̀lú ohun tí ó dára àti ẹran ọ̀sìn, pẹ̀lú ọrẹ àtinúwá ràn án lọ́wọ́ fún tẹmpili Ọlọ́run ní Jerusalẹmu.’ ”
5 Nígbà náà àwọn olórí ìdílé Juda àti Benjamini àti àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi—olúkúlùkù ẹni tí Ọlọ́run ti fọwọ́ tọ́ ọkàn rẹ̀—múra láti gòkè lọ láti kọ ilé Olúwa ní Jerusalẹmu. 6 Gbogbo àwọn aládùúgbò wọn ràn wọ́n lọ́wọ́ pẹ̀lú ohun èlò ti fàdákà àti wúrà, pẹ̀lú onírúurú ohun ìní àti ẹran ọ̀sìn àti pẹ̀lú àwọn ẹ̀bùn iyebíye, ní àfikún si gbogbo àwọn ọrẹ àtinúwá.
7 Ní àfikún, ọba Kirusi mú àwọn ohun èlò tí ó jẹ́ ti ilé Olúwa jáde wá, tí Nebukadnessari ti kó lọ láti Jerusalẹmu tí ó sì ti kó sí ilé òrìṣà rẹ̀. 8 Kirusi ọba Persia pàṣẹ fún Mitredati olùṣọ́ ilé ìṣúra láti kó wọn jáde, ó sì kà wọ́n fún Ṣeṣbassari ìjòyè Juda.
9 Èyí ni iye wọn:
Ọgbọ̀n àwo wúrà | 30 |
Ẹgbẹ̀rún àwo fàdákà | 1,000 |
Àwo ìrúbọ fàdákà mọ́kàn-dínlọ́gbọ̀n | 29 |
10 Ọgbọ̀n àdému wúrà | 30 |
Irínwó ó-lé-mẹ́wàá oríṣìí àdému fàdákà mìíràn | 410 |
Ẹgbẹ̀rún kan àwọn ohun èlò mìíràn | 1,000 |
11 Gbogbo ohun èlò wúrà àti ti fàdákà ní àpapọ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún ó-lé-irínwó (5,400).
Ṣeṣbassari kó gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí wá pẹ̀lú àwọn ìgbèkùn tí ó gòkè wá láti Babeli sí Jerusalẹmu.
Àwọn ìgbèkùn tí o padà
2 (B)Lákòókò náà, wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn agbègbè Juda tí ó gòkè wá láti ìgbèkùn láàrín àwọn tí a kó lọ, ẹni tí Nebukadnessari ọba Babeli ti fi agbára mú ní ìgbèkùn lọ sí Babeli (wọ́n padà sí Jerusalẹmu àti Juda, olúkúlùkù sí ìlú rẹ̀. 2 Àwọn wọ̀nyí bá Serubbabeli, Jeṣua, Nehemiah, Seraiah, Reelaiah, Mordekai, Bilṣani, Mispari, Bigfai, Rehumu àti Baanah wá):
Iye àwọn ọkùnrin àwọn ènìyàn Israẹli:
3 Àwọn ọmọ
Paroṣi jẹ́ ẹgbàá ó-lé-méjìléláàádọ́sàn-án (2,172)
4 Ṣefatia jẹ́ òjì-dín-nírínwó ó-lé-méjìlá (372)
5 Arah jẹ́ ẹgbẹ̀rin ó-dínmẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (775)
6 Pahati-Moabu (láti ipasẹ̀ àwọn ọmọ Jeṣua àti Joabu) jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì àti ẹgbẹ̀rìn-lé-méjìlá (2,812)
7 Elamu jẹ́ àádọ́ta-lé-lẹ́gbẹ̀fà ó-lé-mẹ́rin (1,254)
8 Sattu jẹ́ ọ̀tà-dínlẹ́gbẹ̀rún ó-lé-márùn-ún (945)
9 Sakkai jẹ́ òjì-dínlẹ́gbẹ̀rin (760)
10 Bani jẹ́ òjìlélẹ́gbẹ̀ta ó-lé-méjì (642)
11 Bebai jẹ́ ẹgbẹ̀ta ó-lé-mẹ́tàlélógún (623)
12 Asgadi jẹ́ ẹgbẹ̀fà ó-lé-méjìlélógún (1,222)
13 Adonikami jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó-lé-mẹ́fà (666)
14 Bigfai jẹ́ ẹgbàá ó-lé-mẹ́rìn-dínlọ́gọ́ta (2,056)
15 Adini jẹ́ aádọ́ta-lé-ní-irínwó ó-lé-mẹ́rin (454)
16 Ateri (nípasẹ̀ Hesekiah) jẹ́ méjì-dínlọ́gọ́rin (78)
17 Besai jẹ́ ọrùn-dínnírínwó ó-lé-mẹ́ta (323)
18 Jora jẹ́ méjìléláàdọ́fà (112)
19 Haṣumu jẹ́ igba ó-lé-mẹ́tàlélógún (223)
20 Gibbari jẹ́ márùn-dínlọ́gọ́rùn (95)
21 Àwọn ọmọ
Bẹtilẹhẹmu jẹ́ mẹ́tàlélọ́gọ́fà (123)
22 Netofa jẹ́ mẹ́rìndínlọ́gọ́tà (56)
23 Anatoti jẹ́ méjì-dínláàdóje (128)
24 Asmafeti jẹ́ méjìlélógójì (42)
25 Kiriati-Jearimu, Kefira àti Beeroti jẹ́ ọ̀tà-dínlẹ́gbẹ̀rin ó-lé-mẹ́ta (743)
26 Rama àti Geba jẹ́ ẹgbẹ̀ta ó-lé-mọ́kànlélógún (621)
27 Mikmasi jẹ́ méjìlélọ́gọ́fà (122)
28 Beteli àti Ai jẹ́ igba ó-lé-mẹ́tàlélógún (223)
29 Nebo jẹ́ méjìléláàdọ́ta (52)
30 Magbiṣi jẹ́ mẹ́rìn-dínlọ́gọ́jọ (156)
31 Elamu mìíràn jẹ́ ẹgbẹ̀fà ó-lé-mẹ́rìnléláàdọ́ta (1,254)
32 Harimu jẹ́ ọ̀rìn-dínnírínwó (320)
33 Lodi, Hadidi àti Ono jẹ́ ọ̀rìn-dínlẹ́gbẹ̀rin ó-lé-márùn-ún (725)
34 Jeriko jẹ́ ọ̀tà-dínnírínwó ó-lé-márùn-ún (345)
35 Senaa jẹ́ egbèjì-dínlógún ó-lé-ọgbọ̀n (3,630)
36 Àwọn àlùfáà:
Àwọn ọmọ
Jedaiah (láti ipasẹ̀ ìdílé Jeṣua) jẹ́ ogún-dínlẹ́gbẹ̀rin ó-dínméje (973)
37 Immeri jẹ́ àádọ́ta-lé-lẹ́gbẹ̀rún ó-lé-méjì (1,052)
38 Paṣuri jẹ́ ẹgbẹ̀fà ó-lé-mẹ́tà-dínláàdọ́ta (1,247)
39 Harimu jẹ́ ẹgbẹ̀rún ó-lé-mẹ́tà-dínlógún (1,017)
40 Àwọn ọmọ Lefi:
Àwọn ọmọ
Jeṣua àti Kadmieli (ti ìdílé Hodafiah) jẹ́ mẹ́rìnléláàdọ́rin (74)
41 Àwọn akọrin:
Àwọn ọmọ
Asafu jẹ́ méjì-dínláádóje (128)
42 Àwọn aṣọ́bodè:
Àwọn ará
Ṣallumu, Ateri, Talmoni,
Akkubu, Hatita àti Ṣobai jẹ́ mọ́kàn-dínlógóje (139)
43 Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili:
Àwọn ọmọ
Ṣiha, Hasufa, Tabboati,
44 Kerosi, Ṣiaha, Padoni,
45 Lebana, Hagaba, Akkubu,
46 Hagabu, Ṣalmai, Hanani,
47 Giddeli, Gahari, Reaiah,
48 Resini, Nekoda, Gassamu,
49 Ussa, Pasea, Besai,
50 Asna, Mehuni, Nefisimu,
51 Bakbu, Hakufa, Harhuri.
52 Basluti, Mehida, Harṣa,
53 Barkosi, Sisera, Tema,
54 Nesia àti Hatifa.
55 Àwọn ọmọ àwọn ìránṣẹ́ Solomoni:
Àwọn ọmọ
Sotai, Sofereti, Peruda,
56 Jaala, Darkoni, Giddeli,
57 Ṣefatia, àwọn ọmọ Hattili,
Pokereti ti Haṣebaimu àti àwọn ọmọ Ami.
58 Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili àti àwọn ọmọ àwọn ìránṣẹ́ Solomoni jẹ́ irínwó-ó-dínmẹ́jọ (392)
59 Àwọn wọ̀nyí gòkè wá láti àwọn ìlú ti Teli-Mela, Teli-Harṣa, Kerubu, Addoni àti Immeri, ṣùgbọ́n wọn kò lè sọ pẹ̀lú ìdánilójú pé ìdílé àwọn wá láti ara ìran ẹ̀yà Israẹli:
60 Àwọn ọmọ
Delaiah, Tobiah àti Nekoda jẹ́ àádọ́ta-lé-lẹ́gbẹ̀ta ó-lé-méjì (652)
61 Àti nínú àwọn ọmọ àwọn àlùfáà:
Àwọn ọmọ:
Hobaiah, Hakosi àti Barsillai (ọkùnrin tí ó fẹ́ ọmọbìnrin Barsillai ará Gileadi a sì ń fi orúkọ náà pè é).
62 Àwọn wọ̀nyí wá ìwé ìrántí ìdílé wọn, ṣùgbọ́n wọn kò rí i, bẹ́ẹ̀ ni a kò kà wọ́n kún ara àlùfáà nítorí, a kà wọ́n sí aláìmọ́. 63 Baálẹ̀ pa á láṣẹ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ jẹ nínú oúnjẹ mímọ́ jùlọ títí tí àlùfáà kan yóò fi ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lú Urimu àti Tumimu.
64 Gbogbo ìjọ ènìyàn náà jẹ́ ẹgbàá-mọ́kànlélógún ó-lé-òjìdínnírínwó (42,360). 65 Yàtọ̀ sí ẹgbẹ̀rìn-dínlẹ́gbàárin-ó-dín mẹ́tàlélọ́gọ́ta (7,337) ìránṣẹ́ ọkùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin; wọ́n ní igba (200) akọrin ọkùnrin àti obìnrin. 66 Wọ́n ní ọ̀tà-dínlẹ́gbẹ̀rin ó-dínmẹ́rin ẹṣin (736); ìbáaka òjìlélúgba ó-lé-márùn-ún (245) 67 Ràkunmí jẹ́ irínwó ó-lé-márùn-dínlógójì; (435) àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹgbẹ̀rìnlélọ́gbọ̀n ó-dínọgọ́rin (6,720).
68 Ní ìgbà tí wọ́n dé ilé Olúwa ní Jerusalẹmu, díẹ̀ nínú àwọn olórí àwọn ìdílé fi ọrẹ àtinúwá sílẹ̀ fún ṣíṣe àtúnkọ́ ilé Ọlọ́run ní ààyè rẹ̀. 69 Gẹ́gẹ́ bí agbára wọn, wọ́n fún ilé ìṣúra fún iṣẹ́ yìí ní ọ̀kẹ́ mẹ́ta (61,000) ìwọ̀n dariki wúrà, ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n fàdákà (5,000) àti ọgọ́rùn-ún (100) ẹ̀wù àlùfáà.
70 Àwọn àlùfáà, àwọn ará Lefi, àwọn akọrin, àwọn aṣọ́bodè àti àwọn ìránṣẹ́ ilé Olúwa ṣe àtìpó sínú àwọn ìlú wọn, pẹ̀lú àwọn ènìyàn mìíràn, àti ìyókù àwọn ọmọ Israẹli ṣe àtìpó sínú ìlú u wọn.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.