Historical
Mordekai rọ Esteri láti ràn àwọn Júù lọ́wọ́
4 Nígbà tí Mordekai gbọ́ gbogbo nǹkan tí ó ṣẹlẹ̀, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó wọ aṣọ ọ̀fọ̀, ó sì fi eérú kun ara, ó jáde lọ sí inú ìlú ó kígbe sókè ó sì sọkún kíkorò. 2 Ṣùgbọ́n ó lọ sí ẹnu-ọ̀nà ọba nìkan, nítorí kò sí ẹnìkan tí ó wọ aṣọ ọ̀fọ̀ tì a gbà láààyè láti wọ ibẹ̀. 3 Ní gbogbo ìgbèríko tí àṣẹ ikú ọba dé, ọ̀fọ̀ ńlá dé bá àwọn Júù, pẹ̀lú àwẹ̀, ẹkún àti ìpohùnréré ẹkún. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wà nínú aṣọ ọ̀fọ̀ tí wọ́n fi eérú kúnra.
4 Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́bìnrin àti àwọn ìwẹ̀fà Esteri wá, wọ́n sọ nípa Mordekai fún un, ayaba sì wà nínú ìbànújẹ́ ńlá. Ó fi aṣọ ránṣẹ́ sí i kí ó wọ̀ ọ́ dípò aṣọ ọ̀fọ̀ tí ó wọ̀, ṣùgbọ́n òun kò gbà wọ́n. 5 Nígbà náà ni Esteri pe Hataki, ọ̀kan nínú àwọn ìwẹ̀fà ọba tí a yàn láti máa jíṣẹ́ fún un, ó pàṣẹ fún un pé kí ó béèrè ohun tí ó ń dààmú Mordekai àti ohun tí ó ṣe é.
6 Bẹ́ẹ̀ ni Hataki jáde lọ bá Mordekai ní ìta gbangba ìlú níwájú ẹnu-ọ̀nà ọba. 7 Mordekai sọ ohun gbogbo tí ó ṣẹlẹ̀ fún un, papọ̀ pẹ̀lú iye owó tí Hamani ti ṣe ìpinnu láti san sínú àpò ìṣúra ọba fún ìparun àwọn Júù. 8 Ó sì tún fún un ní ọ̀kan lára ìwé tí ó gbé jáde fún ìparun wọn, èyí tí a tẹ̀ jáde ní Susa, láti fihan Esteri kí ó sì ṣe àlàyé e rẹ̀ fún un, ó sì sọ fún un pé kí ó bẹ̀ ẹ́ kí ó lọ síwájú ọba láti bẹ̀bẹ̀ fún àánú, kí ó bẹ̀bẹ̀ nítorí àwọn ènìyàn rẹ̀.
9 Hataki padà ó sì lọ ṣàlàyé fún Esteri ohun tí Mordekai sọ. 10 Nígbà náà ni Esteri pàṣẹ fún Hataki pé kí ó sọ fún Mordekai, 11 “Gbogbo àwọn ìjòyè ọba àti àwọn ènìyàn agbègbè ìjọba rẹ̀ mọ̀ wí pé: fún ẹnikẹ́ni ọkùnrin tàbí obìnrin kan tàbí tí ó bá bá ọba sọ̀rọ̀ láìjẹ́ pé a ránṣẹ́ pè é (ọba ti gbé òfin kan kalẹ̀ pé) kíkú ni yóò kú. Ohun kan tí ó le yẹ èyí ni pé, kí ọba na ọ̀pá wúrà rẹ̀ sí i kí ó sì dá ẹ̀mí rẹ sí. Ṣùgbọ́n, ọgbọ̀n ọjọ́ ti kọjá tí a ti pè mí láti lọ sí ọ̀dọ̀ ọba.”
12 Nígbà tí a sọ ọ̀rọ̀ Esteri fún Mordekai, 13 Nígbà náà ni Mordekai sọ kí a dá Esteri lóhùn pé; “Má ṣe rò nínú ara rẹ pé nítorí pé ìwọ wà ní ilé ọba ìwọ nìkan là láàrín gbogbo àwọn Júù. 14 Nítorí bí ìwọ bá dákẹ́ ní àkókò yìí, ìrànlọ́wọ́ àti ìtúsílẹ̀ fún àwọn Júù yóò dìde láti ibòmíràn, ṣùgbọ́n ìwọ àti àwọn ìdílé baba à rẹ yóò ṣègbé. Ta ni ó mọ̀ wí pé nítorí irú àkókò yìí ni o ṣe wà ní ipò ayaba?”
15 Nígbà náà ni Esteri rán iṣẹ́ yìí sí Mordekai: 16 “Lọ, kí o kó gbogbo àwọn Júù tí ó wà ní Susa jọ, kí ẹ sì gbààwẹ̀ fún mi. Ẹ má ṣe jẹun tàbí omi fún ọjọ́ mẹ́ta, ní òru àti ní ọ̀sán. Èmi àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin mi náà yóò gbààwẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà ti ṣe. Nígbà tí ẹ bá ṣe èyí, èmi yóò tọ ọba lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lòdì sí òfin. Bí mo bá sì ṣègbé, mo ṣègbé.”
17 Bẹ́ẹ̀ ni Mordekai lọ, ó sì sọ gbogbo ohun tí Esteri pàṣẹ fún un.
Ẹ̀bẹ̀ Esteri sí ọba
5 Ní ọjọ́ kẹta Esteri wọ aṣọ ayaba rẹ̀ ó sì dúró sí inú àgbàlá ààfin, ní iwájú gbọ̀ngàn ọba, ọba Jókòó lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀ nínú gbọ̀ngàn, ó kọjú sí ẹnu-ọ̀nà ìta. 2 Nígbà tí ó rí ayaba Esteri tí ó dúró nínú àgbàlá, inú rẹ̀ yọ́ sí i, ọba sì na ọ̀pá aládé wúrà ọwọ́ rẹ̀ sí i. Bẹ́ẹ̀ ni Esteri ṣe súnmọ́ ọn ó sì fi ọwọ́ kan orí ọ̀pá náà.
3 (A)Nígbà náà ni ọba béèrè pé, “Kí ni ó dé, ayaba Esteri? Kí ni o fẹ́? Bí ó tilẹ̀ ṣe títí dé ìdajì ọba mi, àní, a ó fi fún ọ.”
4 Esteri sì dáhùn pé, “Bí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn, jẹ́ kí ọba, pẹ̀lú Hamani, wá lónìí sí ibi àsè tí èmi ti pèsè fún un.”
5 Ọba sì wí pé, “ẹ mú Hamani wá kíákíá, nítorí kí a lè ṣe ohun tí Esteri béèrè fún un.”
Bẹ́ẹ̀ ni ọba àti Hamani lọ sí ibi àsè tí Esteri ti pèsè. 6 Bí wọ́n ṣe ń mu wáìnì, ọba tún béèrè lọ́wọ́ Esteri, “Báyìí pé: kí ni ẹ̀bẹ̀ rẹ? A ó sì fi fún ọ. Kí ni ìwọ ń béèrè fún? Àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ ìdajì ìjọba mi, a ó fi fún ọ.”
7 Esteri sì dáhùn, “Ẹ̀bẹ̀ mi àti ìbéèrè mi ni èyí: 8 Bí ọba bá fi ojúrere rẹ̀ fún mi, tí ó bá sì tẹ́ ọba lọ́rùn láti gba ẹ̀bẹ̀ mi àti láti mú ìbéèrè mi ṣẹ, jẹ́ kí ọba àti Hamani wá ní ọ̀la sí ibi àsè tí èmi yóò pèsè fún wọn. Nígbà náà ni èmi yóò dáhùn ìbéèrè ọba.”
Ìrunú Hamani sí Mordekai
9 Hamani jáde lọ ní ọjọ́ náà pẹ̀lú ayọ̀ àti inú dídùn. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó rí Mordekai ní ẹnu-ọ̀nà ọba, ó wòye pé kò dìde tàbí kí ó bẹ̀rù ní iwájú òun, inú bí i gidigidi sí Mordekai. 10 Ṣùgbọ́n, Hamani kó ara rẹ̀ ní ìjánu, ó lọ sí ilé.
Ó pe àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ jọ àti Sereṣi ìyàwó rẹ̀ 11 Hamani gbéraga sí wọn nípa títóbi ọ̀rọ̀ rẹ̀, púpọ̀ àwọn ọmọ rẹ̀, àti gbogbo ọ̀nà tí ọba ti bu ọlá fún un àti bí ó ṣe gbé e ga ju àwọn ọlọ́lá àti àwọn ìjòyè tókù lọ. 12 Hamani tún fi kún un pé, “Kì í ṣe èyí nìkan. Èmi nìkan ni ayaba Esteri pè láti sin ọba wá sí ibi àsè tí ó sè. Bákan náà, ó sì tún ti pè mí pẹ̀lú ọba ní ọ̀la. 13 Ṣùgbọ́n gbogbo èyí kò ì tí ì tẹ́ mi lọ́rùn níwọ̀n ìgbà tí mo bá sì ń rí Mordekai ará a Júù náà tí ó ń jókòó ní ẹnu-ọ̀nà ọba.”
14 Ìyàwó rẹ̀ Sereṣi àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ wí fún un pé, “Ri igi kan, kí ó ga tó ìwọ̀n ẹ̀ṣẹ̀ bàtà márùn-ún le láàdọ́rin, kí o sì sọ fún ọba ní òwúrọ̀ ọ̀la kí ó gbé Mordekai rọ̀ sórí i rẹ̀. Nígbà náà ni ìwọ yóò bá ọba lọ sí ibi àsè pẹ̀lú ayọ̀.” Èrò yí dùn mọ́ Hamani nínú, ó sì ri igi náà.
Ọba bu ọlá fún Mordekai
6 Ní òru ọjọ́ náà ọba kò le è sùn; nítorí náà, ó pàṣẹ kí wọn mú ìwé ìrántí wá, àkọsílẹ̀ ìjọba rẹ̀, wọ́n mú un wá wọ́n sì kà á sí létí. 2 Wọ́n rí àkọsílẹ̀ níbẹ̀ pé Mordekai tí sọ àṣírí Bigitana àti Tereṣi, àwọn ìjòyè ọba méjì tí wọ́n ń ṣọ́ ẹnu-ọ̀nà, tí wọ́n ń gbèrò láti pa ọba Ahaswerusi.
3 Ọba béèrè pé, “Kí ni ọlá àti iyì tí Mordekai ti gbà fún èyí?”
Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì dáhùn pé, “Kò tí ì sí ohun tí a ṣe fún un.”
4 Ọba wí pé, “Ta ni ó wà nínú àgbàlá?” Nísinsin yìí, Hamani ṣẹ̀ṣẹ̀ wọ àgbàlá ìta ààfin ni láti sọ fún ọba nípa síso Mordekai lórí igi tí ó ti rì fún un.
5 Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì dáhùn pé, “Hamani ni ó wà níbẹ̀ ó dúró sí inú àgbàlá.”
Ọba pàṣẹ pé, “Ẹ mú un wọlé wá.”
6 Nígbà tí Hamani wọlé, ọba béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni kí a ṣe fún ọkùnrin tí inú ọba dùn sí láti bu ọlá fún?”
Nísinsin yìí Hamani sì ro èyí fúnrarẹ̀ pé, “Ta ni ó wà níbẹ̀ tí ọba fẹ́ dá lọ́lá ju èmi lọ?” 7 Nítorí náà Hamani dá ọba lóhùn pé, “Fún ọkùnrin tí inú ọba dùn sí láti dá lọ́lá, 8 jẹ́ kí wọn kí ó mú aṣọ ọba èyí tí ọba ń wọ̀ àti ẹṣin tí ọba máa ń gùn, pẹ̀lú ọ̀kan lára adé ọba kí a fi dé e ní orí. 9 Jẹ́ kí a fi aṣọ àti ẹṣin lé ọ̀kan lára àwọn ìjòyè ọba tí ó ga jùlọ lọ́wọ́, kí wọn wọ aṣọ náà fún ọkùnrin tí inú ọba dùn sí láti dá lọ́lá, kí wọn sì sìn ín gun ẹṣin jákèjádò gbogbo ìgboro ìlú, kí wọn máa kéde níwájú rẹ̀ pé, ‘Èyí ni a ṣe fún ọkùnrin náà ẹni tí inú ọba dùn sí láti dá lọ́lá!’ ”
10 Ọba pàṣẹ fún Hamani pé, “Lọ lẹ́sẹ̀kan náà. Mú aṣọ náà àti ẹṣin kí o sì ṣe gẹ́gẹ́ bí o ṣe sọ fún Mordekai ará a Júù, ẹni tí ó jókòó sí ẹnu-ọ̀nà ọba. Má ṣe fi ohunkóhun sílẹ̀ nínú ohun tí o ti yàn.”
11 Bẹ́ẹ̀ ni Hamani ṣe mú aṣọ àti ẹṣin náà. Ó fi wọ Mordekai, Mordekai sì wà lórí ẹṣin jákèjádò gbogbo ìgboro ìlú, ó sì ń kéde níwájú rẹ̀ pé, “Èyí ni a ó ṣe fún ọkùnrin náà ẹni tí inú ọba dùn sí láti dá lọ́lá!”
12 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí Mordekai padà sí ẹnu-ọ̀nà ọba. Ṣùgbọ́n Hamani sáré lọ ilé, ó sì bo orí rẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́, 13 Hamani sì sọ ohun gbogbo tí ó ṣẹlẹ̀ sí i fún Sereṣi ìyàwó rẹ̀ àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.
Àwọn olùbádámọ̀ràn rẹ̀ àti ìyàwó o rẹ̀ sọ fún un pé, “Níwọ́n ìgbà tí Mordekai ti jẹ́ ẹ̀yà Júù, níwájú ẹni tí ìṣubú rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀, ìwọ kò lè rí ẹ̀yìn in rẹ̀—dájúdájú ìwọ yóò parun!” 14 Bí wọ́n ṣe ń bá a sọ̀rọ̀, àwọn ìwẹ̀fà ọba wọlé, wọ́n sì kán Hamani lójú láti lọ sí ibi àsè tí Esteri ti pèsè.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.