Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Historical

Read the books of the Bible as they were written historically, according to the estimated date of their writing.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Esteri 1-3

A rọ ayaba Faṣti lóyè

Èyí ni ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ìgbà Ahaswerusi, tí ó jẹ ọba lórí ẹ̀tàdínláàdóje ìletò bẹ̀rẹ̀ láti India títí ó fi dé Etiopia. Ní àkókò ìgbà náà ọba Ahaswerusi ń ṣe ìjọba ní orí ìtẹ́ ẹ rẹ̀ ní ilé ìṣọ́ ti Susa, Ní ọdún kẹta ìjọba rẹ̀, ó ṣe àsè fún gbogbo àwọn ọlọ́lá àti ìjòyè. Àwọn olórí ológun láti Persia àti Media, àwọn ọmọ-aládé, àti àwọn ọlọ́lá ìletò wà níbẹ̀ pẹ̀lú.

Ó ṣe àfihàn púpọ̀ ọrọ̀ ìjọba rẹ̀ àti dídán àti ògo ọláńlá rẹ̀ fún ọgọ́sàn-án ọjọ́ gbáko. Nígbà tí ọjọ́ wọ̀nyí kọjá, ọba ṣe àsè fún ọjọ́ méje, nínú ọgbà tí ó wà nínú àgbàlá ààfin ọba, gbogbo ènìyàn láti orí ẹni tí ó kéré dé orí ẹni tí ó lọ́lá jùlọ, tí wọ́n wà ní ilé ìṣọ́ ti Susa. Ọgbà náà ní aṣọ fèrèsé funfun àti aláwọ̀ òféfèé. Àwọn okùn tí a fi aṣọ aláwọ̀ funfun àti aláwọ̀ elése àlùkò rán ni a fi ta á mọ́ òrùka fàdákà lára àwọn òpó mábù. Àwọn ibùsùn tí a fi wúrà àti fàdákà ṣe wà níbi pèpéle òkúta tí a fi ń tẹ́lẹ̀ ilé tí ó jẹ́ mábù, píálì àti òkúta olówó iyebíye mìíràn. Kọ́ọ̀bù wúrà onídìí-odó ni a fi ń bu wáìnì fún wọn mu, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì yàtọ̀ sí èkejì, wáìnì ọba pọ̀ púpọ̀, gẹ́gẹ́ bí ọba ṣe lawọ́ sí. Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ọba a fi ààyè gba àlejò kọ̀ọ̀kan láti mu tó bí ó bá ti fẹ́, nítorí ọba ti pàṣẹ fún gbogbo àwọn ti ń bu wáìnì láti bù fún ẹnìkọ̀ọ̀kan bí wọ́n bá ṣe béèrè fún mọ.

Ayaba Faṣti náà ṣe àsè fún àwọn obìnrin ní ààfin ọba Ahaswerusi.

10 Ní ọjọ́ keje, nígbà tí wáìnì mú inú ọba dùn, ó pàṣẹ fún Mehumani, Bista, Harbona, Bigta àti Abagta, Setari àti Karkasi, àwọn ìwẹ̀fà méje tí ń jíṣẹ́ fún Ahaswerusi. 11 Kí wọn mú ayaba Faṣti wá síwájú rẹ̀, ti òun ti adé ọba rẹ̀, kí ó lè wá fi ẹwà rẹ̀ hàn àwọn ènìyàn àti àwọn ọlọ́lá, nítorí tí ó rẹwà. 12 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ jẹ́ iṣẹ́ ọba, ayaba Faṣti kọ̀ láti wá. Nígbà náà ni ọba bínú gidigidi, ìbínú náà sì pọ̀ jọjọ.

13 Gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀ ní ìgbà gbogbo, ọba máa ń béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ àwọn tí ó ní ìmọ̀ òfin àti ìdájọ́, ó sọ ọ́ fún àwọn amòye tí wọ́n mòye àkókò, 14 àwọn tí wọ́n súnmọ́ ọba àwọn wọ̀nyí ni Karṣina, Ṣetari, Admata, Tarṣiṣi, Meresi, Marsena àti Memukani, àwọn ọlọ́lá méje ti Persia àti Media tí wọ́n ṣe pàtàkì sí ọba, wọ́n sì tún wà ní ibi gíga ní ìjọba.

15 Ó béèrè pé, “Kí ni a lè ṣe sí ayaba Faṣti gẹ́gẹ́ bí òfin? Nítorí kò tẹríba fún àṣẹ ọba Ahaswerusi tí àwọn ìwẹ̀fà ọba sọ fún un.”

16 Memukani sì dáhùn níwájú ọba àti àwọn ọlọ́lá pé, “Ayaba Faṣti ti ṣe búburú, kì í ṣe sí ọba nìkan ṣùgbọ́n sí gbogbo àwọn ọlọ́lá àti àwọn ènìyàn tí ó wà ní gbogbo agbègbè ilẹ̀ ọba Ahaswerusi. 17 Nítorí ìwà ayaba yìí yóò tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn obìnrin, tó bẹ́ẹ̀ tí ọkọ wọn yóò di gígàn lójú u wọn, wọn yóò sì sọ pé, ọba Ahaswerusi pàṣẹ pé kí á mú ayaba Faṣti wá síwájú òun, ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti wá. 18 Ní ọjọ́ yìí gan an ni àwọn ọlọ́lá obìnrin Persia àti ti Media tí wọ́n ti gbọ́ nípa ìwà ayaba wọn yóò ṣe bẹ́ẹ̀ sí gbogbo àwọn ìjòyè ọba bákan náà. Àfojúdi àti àìnírẹ́pọ̀ tí kò lópin yóò wà.

19 “Nítorí náà, bí ó bá tọ́ lójú ọba, jẹ́ kí ó gbé àṣẹ ọba jáde, kí ó sì jẹ́ kí ó wà ní àkọsílẹ̀ pẹ̀lú òfin Persia àti Media, èyí tí kò le é parẹ́, pé kí Faṣti kí ó má ṣe wá síwájú ọba Ahaswerusi. Kí ọba sì fi oyè ayaba rẹ̀ fún ẹlòmíràn tí ó sàn jù ú lọ. 20 Nígbà náà tí a bá kéde òfin tí ọba ṣe ká gbogbo ilẹ̀ ìjọba rẹ̀, gbogbo àwọn obìnrin ni yóò bọ̀wọ̀ fún ọkọ wọn, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó kéré títí dé ọ̀dọ̀ ẹni ńlá.”

21 Ìmọ̀ràn yìí sì tẹ́ ọba àti àwọn ìjòyè rẹ̀ lọ́rùn, nítorí náà ọba ṣe gẹ́gẹ́ bí Memukani ṣé sọ. 22 Ó kọ̀wé ránṣẹ́ sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ọba rẹ̀, ó kọ̀wé sí ìgbèríko kọ̀ọ̀kan ní ìlànà bí wọ́n ṣe ń kọ̀wé, ó kọ̀wé sí àwọn ènìyàn kọ̀ọ̀kan ní èdè wọn, Ó tẹnumọ́ ní èdè oníkálùkù pé kí olúkúlùkù ọkùnrin máa ṣàkóso ilé rẹ̀.

Esteri di ayaba

Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Ahaswerusi ọba sì dáwọ́ ìbínú un rẹ̀ dúró, ó rántí i Faṣti àti ohun tí ó ti ṣe àti àṣẹ tí ó pa nípa tirẹ̀. Nígbà naà ni ìránṣẹ́ ọba tí ó wà ní ọ̀dọ̀ ọ rẹ̀ wí pé, “Jẹ́ kí a wá ọmọbìnrin arẹwà tí kò ì ti mọ ọkùnrin rí fún ọba. Àti pé kí ọba kí ó yan àwọn aláṣẹ ní gbogbo agbègbè ilẹ̀ ọba láti kó gbogbo àwọn arẹwà ọmọbìnrin wọ̀nyí jọ sí ilé àwọn obìnrin ní ilé ìṣọ́ Susa. Kí a kó wọn fún ìtọ́jú Hegai, ìwẹ̀fà ọba, ẹni tí ó ṣe olùtọ́jú àwọn obìnrin; kí a ṣe ìtọ́jú u wọn dáradára. Nígbà naà kí ọmọbìnrin tí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn kí ó jẹ́ ayaba dípò Faṣti.” Ìmọ̀ràn yìí tẹ́ ọba lọ́rùn, ó sì tẹ̀lé e.

Ó sì ṣe ní ìgbà náà ará a Júù kan wà ní ilé ìṣọ́ ti Susa, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mordekai ọmọ Jairi, ọmọ Ṣimei, ọmọ Kiṣi, ẹ̀yà Benjamini, Ẹni tí Nebukadnessari ọba Babeli ti gbé lọ sí ìgbèkùn láti Jerusalẹmu, lára àwọn tí wọ́n kó ní ìgbèkùn pẹ̀lú ọba Jekoniah ọba Juda. Mordekai ní arákùnrin kan ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Hadassa, ẹni tí ó tọ́ dàgbà nítorí tí kò ní baba bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní ìyá. Obìnrin yìí, ẹni tí a tún mọ̀ sí Esteri, ó dára ó sì lẹ́wà, Mordekai mú u gẹ́gẹ́ bí ọmọ rẹ̀ nígbà tí baba àti ìyá rẹ̀ ti kú.

Nígbà tí a ti kéde òfin àti àṣẹ ọba, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọbìnrin ni a kó wá sí ilé ti ìṣọ́ Susa, sí abẹ́ ìtọ́jú Hegai. A sì mú Esteri náà wá sí ààfin ọba pẹ̀lú, a fà á lé Hegai lọ́wọ́, ẹni tí ó jẹ́ alábojútó ilé àwọn obìnrin. Ọmọbìnrin náà sì wù ú, ó sì rí ojúrere rẹ̀, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ó pèsè àwọn ohun tí ó dára àti oúnjẹ pàtàkì fún un. Ó sì yan àwọn ìránṣẹ́bìnrin wúńdíá méje láti ààfin ọba òun àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin náà lọ sí ibi tí ó dára jù nínú ilé àwọn obìnrin.

10 Esteri kò tí ì sọ nípa àwọn ènìyàn àti ìdílé e rẹ̀, nítorí Mordekai ti pàṣẹ fún un pé kí ó má ṣe sọ ọ́. 11 Ní ojoojúmọ́ ni Mordekai máa ń rìn ní iwájú ilé àwọn obìnrin láti wo bí Esteri ṣe wà ní àlàáfíà àti ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí i.

12 Kí àkókò tó tó fún obìnrin kọ̀ọ̀kan láti lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Ahaswerusi, ó ní láti lo ohun èlò tí ń mú ara lẹ́wà tí a yàn fún àwọn obìnrin fún oṣù méjìlá, yóò lo òróró òjìá fún oṣù mẹ́fà, yóò sì lo ohun èlò olóòórùn dídùn tùràrí àti ìpara fún oṣù mẹ́fà pẹ̀lú. 13 Báyìí ni yóò ṣe lọ síwájú ọba: ohunkóhun tí ó bá béèrè ni wọ́n fi fún un láti inú ilé àwọn obìnrin lọ sí ààfin ọba. 14 Ní alẹ́ ni yóò lọ síbẹ̀, tí ó bá sì di òwúrọ̀ yóò padà sí ilé kejì nínú ilé àwọn obìnrin ní abẹ́ ìtọ́jú Ṣaaṣigasi ìwẹ̀fà ọba ẹni tí ó máa ń ṣe ìtọ́jú àwọn àlè. Òun kò ní lọ sí ọ̀dọ̀ ọba mọ́ àyàfi tí inú ọba bá dùn sí i, tí ó sì ránṣẹ́ pé ó ní orúkọ obìnrin.

15 Nígbà tí ó kan Esteri (ọmọbìnrin tí Mordekai gbà ṣe ọmọ, ọmọbìnrin arákùnrin rẹ̀ tí ó ń jẹ́ Abihaili) láti lọ sí ọ̀dọ̀ ọba, wọn kò béèrè fún ohunkóhun ju èyí tí Hegai, ìwẹ̀fà ọba ẹni tí ó jẹ́ olùtọ́jú ilé àwọn obìnrin sọ pé kí ó ṣe lọ. Esteri sì rí ojúrere lọ́dọ̀ gbogbo àwọn tí ó rí i. 16 A mú Esteri lọ síwájú ọba Ahaswerusi ní ibùgbé ọba ní oṣù kẹwàá, tí ó jẹ́ oṣù Tebeti, ní ọdún keje ìjọba rẹ̀.

17 Esteri sì wu ọba ju àwọn obìnrin tókù lọ, Ó sì rí ojúrere àti oore-ọ̀fẹ́ gbà ju ti àwọn wúńdíá tókù lọ. Nítorí náà ó fi adé ọba dé e ní orí ó sì fi ṣe ayaba dípò Faṣti. 18 Ọba sì ṣe àsè ńlá, àsè Esteri, fún gbogbo àwọn ọlọ́lá àti àwọn ìjòyè e rẹ̀. Ó sì kéde ìsinmi jákèjádò ìgbèríko ó sì pín ẹ̀bùn fún wọn pẹ̀lú bí ọba ṣe lawọ́ tó.

Mordekai Tú Àṣírí Ìṣọ̀tẹ̀

19 Nígbà tí àwọn wúńdíá tún péjọ ní ìgbà kejì, Mordekai jókòó sí ẹnu-ọ̀nà ọba. 20 Ṣùgbọ́n Esteri pa àṣírí ìdílé e rẹ̀ àti ibi tí ó ti wá mọ́ gẹ́gẹ́ bí Mordekai ṣe sọ fún un pé kí ó ṣe, nítorí tí ó ń tẹ̀lé àṣẹ tí Mordekai fún un gẹ́gẹ́ bí ó ṣe máa ń ṣe nígbà tí ó wà ní ọ̀dọ̀ Mordekai.

21 Ní àsìkò tí Mordekai jókòó sí ẹnu-ọ̀nà ọba, Bigitana àti Tereṣi, àwọn ìjòyè ọba méjì tí wọ́n máa ń ṣọ́ ẹnu-ọ̀nà, wọ́n bínú, wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa ọba Ahaswerusi. 22 Ṣùgbọ́n Mordekai sì mọ̀ nípa ọ̀tẹ̀ náà, ó sọ̀ fún ayaba Esteri, Esteri sì sọ fún ọba, wọ́n sì fi ọlá fún Mordekai. 23 Nígbà tí wọ́n sì wádìí ọ̀rọ̀ náà tí ó sì jásí òtítọ́, a sì so àwọn ìjòyè méjèèjì náà kọ́. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni a kọ sínú ìwé ìtàn ní iwájú ọba.

Ọ̀tẹ̀ Hamani láti pa àwọn Júù run

Lẹ́yìn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí, ọba Ahaswerusi dá Hamani ọmọ Hammedata, ará Agagi lọ́lá, ọba gbé e ga, ó si fún un ní àga ọlá tí ó ju ti gbogbo àwọn ọlọ́lá tókù lọ. Gbogbo àwọn ìjòyè ọba tí ó wà ní ẹnu-ọ̀nà ọba wọn kúnlẹ̀ wọ́n sì fi ọlá fun Hamani, nítorí ọba ti pàṣẹ èyí nípa tirẹ̀. Ṣùgbọ́n Mordekai kò ní kúnlẹ̀ tàbí bu ọlá fún un.

Nígbà náà ni àwọn ìjòyè ọba tí ó wà ní ẹnu-ọ̀nà béèrè lọ́wọ́ Mordekai pé, “Èéṣe tí ìwọ kò ṣe pa àṣẹ ọba mọ́.” Ní ojoojúmọ́ ni wọ́n máa n sọ fún un ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, wọ́n sọ fún Hamani nípa rẹ̀ láti wò ó bóyá ó lè gba irú ìwà tí Mordekai ń hù yìí, nítorí tí ó ti sọ fún wọn pé Júù ni òun.

Nígbà tí Hamani rí i pé Mordekai kò ní kúnlẹ̀ tàbí bu ọlá fún òun, ó bínú. Síbẹ̀ kò mọ irú ènìyàn tí Mordekai jẹ́, ó kẹ́gàn láti pa Mordekai nìkan. Dípò bẹ́ẹ̀ Hamani ń wá láti pa gbogbo ènìyàn Mordekai run, àwọn Júù jákèjádò gbogbo ìjọba Ahaswerusi.

Ní ọdún kejìlá ọba Ahaswerusi, ní oṣù kìn-ín-ní, èyí ni oṣù Nisani, wọ́n da puri (èyí tí í ṣe, ìbò) ní iwájú Hamani láti yan ọjọ́ kan àti oṣù, ìbò náà sì wáyé ní oṣù kejìlá, oṣù Addari.

Nígbà náà ni Hamani sọ fún ọba Ahaswerusi pé, “Àwọn ènìyàn kan wà tí wọ́n fọ́nká tí wọ́n sì túká ní ara àwọn ènìyàn ní gbogbo àgbáyé ìjọba rẹ̀ tí ìṣe wọn yàtọ̀ sí ti gbogbo àwọn tókù tí wọn kò sì pa òfin ọba mọ́; èyí kì í ṣe ìfẹ́ ọba láti gbà fún wọn bẹ́ẹ̀. Tí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn, kí a gbé òfin kan jáde tí yóò pa wọ́n run, èmi yóò sì fi ẹgbàárùn-ún tálẹ́ǹtì fàdákà sínú ìṣúra ọba fún àwọn ọkùnrin tí wọn o ṣe iṣẹ́ náà.”

10 Nítorí náà ọba sì bọ́ òrùka dídán (èdìdì) tí ó wà ní ìka rẹ̀ ó sì fi fún Hamani ọmọ Hammedata, ará Agagi, ọ̀tá àwọn Júù. 11 Ọba sọ fún Hamani pé, “pa owó náà mọ́, kí o sì ṣe ohun tí ó wù ọ́ fún àwọn ènìyàn náà.”

12 Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹtàlá oṣù kìn-ín-ní àkọ́kọ́, wọ́n pe àwọn akọ̀wé ọba jọ. Wọ́n kọ ọ́ ní ìlànà bí ìgbèríko kọ̀ọ̀kan ṣe ń kọ̀wé, ó kọ̀wé sí àwọn ènìyàn kọ̀ọ̀kan ní èdè wọn gbogbo èyí tí Hamani ti pàṣẹ sí àwọn akọ̀wé ọba, sí baálẹ̀ ìgbèríko kọ̀ọ̀kan àti àwọn ọlọ́lá àwọn onírúurú ènìyàn. A kọ èyí ní orúkọ ọba Ahaswerusi fúnrarẹ̀ ó sì fi òrùka ọba ṣe èdìdì i rẹ̀. 13 A sì fi ìwé náà ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn ìgbèríko ọba pẹ̀lú àṣẹ láti parun, láti pa gbogbo àwọn Júù èwe àti àgbà, obìnrin àti àwọn ọmọ wẹ́wẹ́—ní ọjọ́ kan kí wọn sì parẹ́, ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kejìlá, oṣù Addari kí a sì kó àwọn ohun ìní wọn. 14 Kí ẹ mú àdàkọ ìwé náà kí a tẹ̀ ẹ́ jáde bí òfin ní gbogbo ìgbèríko kí ó sì di mí mọ̀ fún àwọn ènìyàn ìlú nítorí kí wọ́n le múra fún ọjọ́ náà.

15 Àwọn ìránṣẹ́ náà sì jáde, wọ́n tẹ̀síwájú nípa àṣẹ ọba, ìkéde náà sì jáde ní ilé ìṣọ́ ti Susa. Ọba àti Hamani jókòó wọ́n ń mu, ṣùgbọ́n ìlú Susa wà nínú ìdààmú.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.