Chronological
Má ṣe gbàgbé Olúwa
8 Ẹ kíyèsi i láti máa tẹ̀lé gbogbo àṣẹ tí mo fún un yín lónìí, kí ẹ bá à le yè, kí ẹ sì pọ̀ sí i wọ ilẹ̀ náà, kí ẹ sì le gba ilẹ̀ náà, tí Olúwa fì búra ṣèlérí fún àwọn baba ńlá a yín. 2 Ẹ rántí bí Olúwa Ọlọ́run yín ti tọ́ ọ yín ṣọ́nà ní gbogbo ọ̀nà ní aginjù fún ogójì ọdún wọ̀nyí láti tẹ orí yín ba àti láti dán an yín wò kí ó ba à le mọ bí ọkàn yín ti rí, bóyá ẹ ó pa òfin rẹ̀ mọ́ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. 3 (A)Ó rẹ̀ yín sílẹ̀ nípa fífi ebi pa yín, Ó sì fi manna bọ́ ọ yín, èyí tí ẹ kò mọ̀, tí àwọn baba yín kò mọ̀, kí ó ba à lè kọ́ ọ yín pé, ènìyàn kò ti ipa oúnjẹ nìkan wà láààyè, bí kò ṣe ohun gbogbo tí ó jáde láti ẹnu Olúwa wá. 4 Aṣọ yín kò gbó mọ́ ọn yín lọ́rùn bẹ́ẹ̀ ní ẹsẹ̀ yín kò sì wú, ní ogójì ọdún náà. 5 Ẹ mọ̀ ní ọkàn an yín pé, bí baba ti ń kọ́ ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa Ọlọ́run yín ń kọ́ ọ yín.
6 Nítorí èyí, ẹ gbọdọ̀ pa òfin Olúwa Ọlọ́run yín mọ́, nípa rínrìn ní ọ̀nà rẹ̀, àti bíbẹ̀rù rẹ̀. 7 Nítorí pé Olúwa Ọlọ́run yín ń mú un yín bọ̀ wá sí ilẹ̀ rere ilẹ̀ tí ó kún fún odò àti ibú omi, pẹ̀lú àwọn ìsun tí ń sàn jáde láti orí òkè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀. 8 Ilẹ̀ tí ó kún fún jéró àti ọkà barle, tí ó sì kún fún àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́, igi pomegiranate, òróró olifi àti oyin. 9 Ilẹ̀ tí oúnjẹ kò ti wọ́n, kò sí ohun tí ẹ̀yin yóò ṣe aláìní, ilẹ̀ tí irin ti pọ̀ bí òkúta, ẹ̀yin sì lè wa idẹ jáde láti inú òkè rẹ̀ wá.
10 Nígbà tí ẹ bá ti jẹ tí ẹ sì yó tán ẹ yin Olúwa Ọlọ́run yín fún pípèsè ilẹ̀ rere fún un yín. 11 (B)Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má gbàgbé Olúwa Ọlọ́run yín, nípa kíkùnà láti pa àṣẹ rẹ̀, àwọn òfin rẹ̀, àti àwọn ìlànà rẹ̀ tí mo ń fún un yín lónìí mọ́. 12 Kí ó má ba à jẹ́ pé, nígbà tí ẹ bá jẹun yó tán, tí ẹ bá kọ́ ilé tí ó dára tán, tí ẹ sí ń gbé inú rẹ̀, 13 nígbà tí àwọn agbo màlúù yín àti tí ewúrẹ́ ẹ yín bá pọ̀ sí i tán, tí fàdákà àti wúrà yín sì ń peléke sí i, tí ohun gbogbo tí ẹ ní sì ń pọ̀ sí i, 14 nígbà náà ni ọkàn yín yóò gbéga, tí ẹ̀yin yóò sì gbàgbé Olúwa Ọlọ́run yín, tí ó mú un yín jáde láti Ejibiti wá, nínú oko ẹrú. 15 Òun ni ó mú un yín la aginjù ẹlẹ́rù ńlá já, ilẹ̀ tí kò sí omi tí ó sì kún fún òǹgbẹ, pẹ̀lú àwọn ejò olóró ńláńlá àti àkéekèe. Ó mú omi jáde fún un yín láti inú àpáta. 16 Ó fún yín ní manna láti jẹ nínú aginjù, ohun tí àwọn baba yín kò mọ̀ rí, kí Òun bá à le tẹ orí yín ba kí ó sì lè dán an yín wò, kí ó bá à lè dára fún un yín. 17 Ẹ lè rò nínú ara yín pé, “Agbára mi àti iṣẹ́ ọwọ́ mi ni ó mú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wá fún mi.” 18 Ṣùgbọ́n ẹ rántí Olúwa Ọlọ́run yín tí ó fún un yín ní agbára àti lè ní àwọn ọrọ̀ wọ̀nyí, tí ó sì fi mú májẹ̀mú rẹ̀ ṣẹ tí ó ti búra fún àwọn baba ńlá a yín bí ó ti rí lónìí.
19 Bí ẹ bá wá gbàgbé Olúwa Ọlọ́run yín, tí ẹ sì tẹ̀lé àwọn òrìṣà mìíràn, tí ẹ sì sìn wọ́n, tí ẹ sì foríbalẹ̀ fún wọn, Mo kìlọ̀ fún un yín pé rírun ni ẹ̀yin yóò run. 20 Bí àwọn orílẹ̀-èdè tí Olúwa parun níwájú u yín, bákan náà ni ẹ ó parun, torí pé ẹ kò gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run yín lẹ́nu.
Kì í ṣe nítorí òdodo Israẹli
9 Gbọ́, ìwọ Israẹli. Báyìí, ẹ̀yin ti gbáradì láti la Jordani kọjá, láti lọ gba ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n tóbi, tí wọ́n sì lágbára jù yín lọ, tí wọ́n ní àwọn ìlú ńláńlá, tí odi wọn kan ọ̀run. 2 Àwọn ènìyàn náà lágbára wọ́n sì ga àní àwọn ọmọ Anaki ni wọ́n. Ẹ gbọ́ nípa wọn, ẹ sì gbọ́ tí àwọn ènìyàn ń sọ nípa wọn pé, “Ta ni ó le è dojú ìjà kọ àwọn ọmọ Anaki (òmíràn)?” 3 (C)Ṣùgbọ́n kí ó dá a yín lójú lónìí pé Olúwa Ọlọ́run yín ni ó ń ṣáájú u yín lọ gẹ́gẹ́ bí iná ajónirun. Yóò jó wọn run, yóò sì tẹ orí wọn ba níwájú yín. Ẹ̀yin yóò sì lé wọ́n jáde, ẹ̀yin yóò sì run wọ́n kíákíá, bí Olúwa ti ṣèlérí fún un yín.
4 Lẹ́yìn tí Olúwa Ọlọ́run yín bá ti lé wọn jáde níwájú u yín, ẹ má ṣe wí fún ara yín pé, “Torí òdodo mi ní Olúwa ṣe mú mi wá síbí láti gba ilẹ̀ náà.” Rárá, ṣùgbọ́n nítorí ìwà búburú àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí ni Olúwa yóò ṣe lé wọn jáde níwájú u yín. 5 Kì í ṣe nítorí òdodo yín, tàbí ìdúró ṣinṣin ni ẹ ó fi wọ ìlú wọn lọ láti gba ilẹ̀ wọn, ṣùgbọ́n nítorí ìwà búburú àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí ni Olúwa Ọlọ́run yín yóò fi lé wọn jáde kúrò níwájú u yín láti lè mú ohun tí ó búra fún àwọn baba ṣẹ: fún Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu. 6 Ṣùgbọ́n kí ó yé yín pé kì í ṣe nítorí òdodo yín ni Olúwa Ọlọ́run yín fi ń fún un yín ní ilẹ̀ rere náà, láti ní, nítorí pé ènìyàn ọlọ́rùn líle ni ẹ jẹ́.
Ère òrìṣà wúrà
7 Ẹ rántí, ẹ má sì ṣe gbàgbé bí ẹ̀yin ti mú Olúwa Ọlọ́run yín bínú ní aginjù. Láti ọjọ́ ti ẹ tí kúrò ní Ejibiti ni ẹ̀yin ti ń ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa títí tí ẹ̀yin fi dé ìhín yìí. 8 (D)Ní Horebu ẹ̀yin ti mú kí Olúwa bínú, títí dé bi pé ó fẹ́ run yín. 9 Nígbà tí mo gòkè lọ láti lọ gba wàláà òkúta, wàláà májẹ̀mú ti Olúwa ti bá a yín dá. Ogójì ọ̀sán àti òru ni mo fi wà lórí òkè náà, èmi kò fẹnu kan oúnjẹ bẹ́ẹ̀ ni ń kò mu omi. 10 Olúwa fún mi ní wàláà òkúta méjì tí a fi ìka Ọlọ́run kọ. Lórí wọn ni a kọ àwọn òfin tí Ọlọ́run sọ fún un yín lórí òkè láàrín iná, ní ọjọ́ ìpéjọpọ̀ sí.
11 Lópin ogójì ọ̀sán àti òru wọ̀nyí, Olúwa fún mi ní sílétì òkúta méjì, wàláà òkúta májẹ̀mú náà. 12 Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa sọ fún mi pé, “Sọ̀kalẹ̀ kúrò níhìn-ín kíákíá, torí pé àwọn ènìyàn rẹ tí o mú jáde láti Ejibiti ti hùwà ìbàjẹ́. Wọ́n ti yípadà kúrò, nínú ọ̀nà mi, wọ́n sì ti ṣe ère dídá fún ara wọn.”
13 Olúwa sì sọ fún mi pé, “Mo ti rí àwọn ènìyàn wọ̀nyí pé ènìyàn ọlọ́rùn líle gbá à ni wọ́n. 14 Fi mí sílẹ̀, jẹ́ kí n run wọ́n, kí n sì pa orúkọ wọn rẹ́ kúrò lábẹ́ ọ̀run. Èmi yóò sì sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè tí ó lágbára tí ó sì pọ̀jù wọ́n lọ.”
15 Báyìí ni mo yípadà, tí mó sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà wá, orí òkè tí o ń yọ iná. Àwọn wàláà májẹ̀mú méjèèjì sì wà lọ́wọ́ mi. 16 Ìgbà tí mo ṣàkíyèsí, mo rí i pé ẹ ti dẹ́ṣẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run yín. Ẹ ti ṣe ère òrìṣà ní ìrí ọ̀dọ́ màlúù, fún ara yín. Ẹ ti yípadà kánkán kúrò nínú ọ̀nà tí Olúwa ti pàṣẹ fún un yín. 17 Bẹ́ẹ̀ ni mó ju wàláà méjèèjì náà mọ́lẹ̀, mo sì fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́ lójú u yín.
18 Lẹ́yìn náà mo tún wólẹ̀ níwájú Olúwa fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru: Èmi kò jẹ oúnjẹ kankan bẹ́ẹ̀ ni èmi kò mu omi, nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ tí dá, tí ẹ sì ń ṣe búburú lójú Olúwa, tí ẹ sì ń mú u bínú. 19 Mo bẹ̀rù ìbínú àti ìrunú Olúwa, nítorí pé inú bí i sí i yín dé bi wí pé ó fẹ́ pa yín run. Ṣùgbọ́n Olúwa tún fetí sí mi lẹ́ẹ̀kan sí i. 20 Inú sì bí Olúwa sí Aaroni láti pa á run, nígbà náà ni mo tún gbàdúrà fún Aaroni náà. 21 Bẹ́ẹ̀ ni mo sì mú ohun tí ó mú un yín dẹ́ṣẹ̀, àní ère ẹgbọrọ màlúù tí ẹ ti ṣe, mo sì fi iná sun ún, bẹ́ẹ̀ ni mo gún un, mo sì lọ̀ ọ́ lúúlúú bí eruku lẹ́búlẹ́bú, mo sì da ẹ̀lọ̀ rẹ̀ sínú odò tí ń sàn nísàlẹ̀ òkè.
22 Ẹ̀yin tún mú Olúwa bínú ní Tabera, Massa àti ní Kibirotu-Hattaafa.
23 Nígbà tí Olúwa ran an yín jáde ní Kadeṣi-Barnea, Ó wí pé, “Ẹ gòkè lọ, kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà tí mo fi fún un yín.” Ṣùgbọ́n ẹ ṣọ̀tẹ̀ sí òfin Olúwa Ọlọ́run yín. Ẹ kò gbẹ́kẹ̀lé e, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọ́ tirẹ̀. 24 Láti ìgbà tí mo ti mọ̀ yín ni ẹ ti ń ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa.
25 Mo ti wólẹ̀ níwájú Olúwa fún ogójì ọ̀sán àti òru wọ̀nyí nítorí pé Olúwa sọ pé Òun yóò pa yín run. 26 Mo gbàdúrà sí Olúwa wí pé, “Olúwa Olódùmarè, má ṣe run àwọn ènìyàn rẹ, àní ogún rẹ tí o ti rà padà, nípa agbára rẹ tí o sì fi agbára ńlá mú wọn jáde láti Ejibiti wá. 27 Rántí àwọn ìránṣẹ́ rẹ Abrahamu, Isaaki, àti Jakọbu. Fojú fo orí kunkun àwọn ènìyàn yìí, pẹ̀lú ìwà búburú àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn. 28 Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, orílẹ̀-èdè tí ìwọ ti mú wa jáde wá yóò wí pé, ‘Torí pé Olúwa kò lè mú wọn lọ sí ilẹ̀ náà tí ó ti ṣèlérí fún wọn, àti pé ó ti kórìíra wọn, ni ó fi mú wọn jáde láti pa wọ́n ní aginjù.’ 29 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn rẹ ni wọ́n, ogún rẹ tí o ti fi ọwọ́ agbára rẹ àti nínà ọwọ́ rẹ mú jáde.”
Wàláà òfin bí i ti ìṣáájú
10 Nígbà náà ni Olúwa wí fún mi pé, “Gbé wàláà òkúta méjì bí i ti àkọ́kọ́ kí o sì gòkè tọ̀ mí wá. Kí o sì tún fi igi kan àpótí kan. 2 Èmi yóò sì kọ ọ̀rọ̀ tí ó wà lára wàláà àkọ́kọ́ tí ìwọ fọ́, sára wàláà wọ̀nyí. Ìwọ yóò sì fi wọ́n sínú àpótí náà.”
3 Mo sì kan àpótí náà pẹ̀lú igi kasia, mo sì gbẹ́ wàláà òkúta méjì náà jáde bí i ti ìṣáájú. Mo sì gòkè lọ pẹ̀lú wàláà méjèèjì lọ́wọ́ mí. 4 Olúwa tún ohun tí ó ti kọ tẹ́lẹ̀ kọ sórí wàláà wọ̀nyí. Àwọn òfin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí ó ti sọ fún un yín lórí òkè, láàrín iná, ní ọjọ́ ìpéjọpọ̀. Olúwa sì fi wọ́n fún mi. 5 Mo sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà, mo sì ki àwọn wàláà òkúta náà sínú àpótí tí mo ti kàn, bí Olúwa ti pàṣẹ fún mi, wọ́n sì wà níbẹ̀ di ìsinsin yìí.
6 (Àwọn ará Israẹli sì gbéra láti kànga àwọn ará Jaakani dé Mosera. Níbí ni Aaroni kú sí, tí a sì sin ín, Eleasari ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ bí i àlùfáà. 7 Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti rìn lọ sí Gudgoda, títí dé Jotbata, ilẹ̀ tí o kún fún odò tí ó ń sàn. 8 Ní ìgbà yìí ni Olúwa yan àwọn ẹ̀yà Lefi láti máa ru àpótí ẹ̀rí Olúwa, láti máa dúró níwájú Olúwa láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́, àti láti fi orúkọ Olúwa súre bí wọ́n ti ń ṣe títí di òní yìí. 9 Ìdí nìyí tí àwọn ẹ̀yà Lefi kò fi ní ìpín tàbí ogún kan láàrín àwọn arákùnrin wọn. Olúwa ni ogún wọn gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run ti sọ fún un yín.)
10 Mo tún dúró ní orí òkè náà fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, bí mo ti ṣe ní ìgbà àkọ́kọ́, Olúwa sì gbọ́ tèmi ní àkókò yìí bákan náà. Kì í ṣe ìfẹ́ rẹ̀ láti run yín. 11 Olúwa sọ fún mi pé, “Lọ darí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní ọ̀nà wọn, kí wọn bá à lè wọ ilẹ̀ náà, kí wọn sì gba ilẹ̀ tí mo ti búra fún àwọn baba wọn láti fún wọn.”
Ẹ bẹ̀rù Olúwa
12 Nísinsin yìí ìwọ Israẹli, kín ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run rẹ béèrè lọ́wọ́ rẹ? Bí kò ṣe kí ìwọ bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run rẹ àti láti máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀, láti fẹ́ràn rẹ̀, láti fi gbogbo ọkàn rẹ sin Olúwa Ọlọ́run rẹ ọkàn àti àyà rẹ, 13 àti láti máa kíyèsi àṣẹ àti ìlànà Olúwa tí mo ń fún ọ lónìí, fún ìre ara à rẹ.
14 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé Olúwa Ọlọ́run yín ni ó ni ọ̀run àní àwọn ọ̀run tó ga ju ayé àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀. 15 Síbẹ̀ Olúwa sì tún fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn fún àwọn baba ńlá a yín, Ó sì fẹ́ wọn Ó sì yan ẹ̀yin ọmọ wọn láti borí gbogbo orílẹ̀-èdè títí di òní. 16 Ẹ kọ ọkàn yín ní ilà, (Ẹ wẹ ọkàn ẹ̀ṣẹ̀ yín mọ́) kí ẹ má sì ṣe jẹ́ olórí kunkun mọ́ láti òní lọ. 17 (E)Torí pé Olúwa Ọlọ́run yín, ni Ọlọ́run àwọn ọlọ́run àti Olúwa àwọn olúwa. Ọlọ́run alágbára, tí ó tóbi tí ó sì lẹ́rù, tí kì í ṣe ojúsàájú kì í sì í gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀. 18 Ó máa ń gbẹjọ́ aláìní baba àti opó rò, Ó fẹ́ràn àjèjì, Òun fi aṣọ àti oúnjẹ fún wọn. 19 (F)Ẹ gbọdọ̀ fẹ́ràn àwọn àjèjì, torí pé ẹ̀yin pẹ̀lú ti jẹ́ àjèjì rí ní Ejibiti. 20 Ẹ bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run yín, ẹ sì máa sìn ín. Ẹ dìímú ṣinṣin, kí ẹ sì búra ní orúkọ rẹ̀. 21 Òun ni ìyìn in yín, Òun sì ni Ọlọ́run yín, tí ó ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu ńlá àti ohun ẹ̀rù, tí ẹ fojú ara yín rí. 22 (G)Àádọ́rin (70) péré ni àwọn baba ńlá a yín tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti, ṣùgbọ́n Olúwa Ọlọ́run yín ti mú un yín pọ̀ sí i ní iye bí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.