Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Chronological

Read the Bible in the chronological order in which its stories and events occurred.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Numeri 28-30

Ọrẹ ojoojúmọ́

28 Olúwa sọ fún Mose pé, “Fún àwọn ọmọ Israẹli ní òfin yìí kí o sì wí fún wọn pé: ‘Ẹ rí i wí pé ẹ gbé e wá sí iwájú mi ní àkókò tí a ti yàn, oúnjẹ ọrẹ ẹbọ mi tí a fi iná ṣe sí mi, gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn sí mi.’ (A)Sọ fún wọn, ‘Èyí ní ọrẹ ẹbọ tí a fi iná sun tí ẹ gbọdọ̀ mú wá fún Olúwa: akọ ọ̀dọ́-àgùntàn méjì ọlọ́dún kan aláìlábàwọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun ní ojoojúmọ́. Pèsè ọ̀dọ́-àgùntàn kan ní òwúrọ̀ àti òmíràn ní àfẹ̀mọ́júmọ́. Pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ tí ó jẹ́ ìdámẹ́wàá efa ìyẹ̀fun dáradára tí a pò mọ́ ìdámẹ́rin hínì òróró tí a yọ lára Olifi. Èyí ni ẹbọ sísun gbogbo ìgbà tí a fi lélẹ̀ ní òkè Sinai gẹ́gẹ́ bí olóòórùn dídùn ẹbọ tí a fi iná sun fún Olúwa pẹ̀lú iná. Àfikún ọrẹ ohun mímu rẹ gbọdọ̀ jẹ́ ìdámẹ́rin ti hínì dídé omi mímu tí ó kan pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀dọ́-àgùntàn. Da ẹbọ mímu náà síta sí Olúwa ní ibi mímọ́. Pèsè ọ̀dọ́-àgùntàn kejì ní àfẹ̀mọ́júmọ́, pẹ̀lú oríṣìí ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu èyí tí ó pèsè ní òwúrọ̀, èyí ni ẹbọ tí a fi iná ṣe, olóòórùn dídùn sí Olúwa.

Ẹbọ ọjọ́ ìsinmi

“ ‘Ní ọjọ́ ìsinmi, pèsè akọ ọ̀dọ́-àgùntàn méjì ọlọ́dún kan tí kò lábùkù, pẹ̀lú ẹbọ ohun mímu àti ẹbọ ohun jíjẹ tí i ṣe ìdá méjì nínú ìdámẹ́wàá òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun tí a fi òróró pò. 10 Èyí ni ẹbọ sísun fún gbogbo ọjọ́ ìsinmi kọ̀ọ̀kan, ní àfikún pẹ̀lú ẹbọ sísun àti ẹbọ ohun mímu.

Ẹbọ oṣooṣù

11 “ ‘Àti ní ọjọ́ tí o bẹ̀rẹ̀ oṣù kọ̀ọ̀kan, kí ẹ̀yin kí ó gbé ẹbọ sísun fún Olúwa pẹ̀lú ọ̀dọ́ akọ màlúù méjì, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn méje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, kí gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ aláìlábùkù. 12 Pẹ̀lú akọ màlúù kọ̀ọ̀kan ni kí wọn ó rú ẹbọ ohun jíjẹ ẹbọ ìdámẹ́ta nínú mẹ́wàá ìyẹ̀fun tí a pòpọ̀ pẹ̀lú òróró; pẹ̀lú àgbò, ni kí wọn ó rú ẹbọ ohun jíjẹ tí í ṣe ìdá méjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun tí a pòpọ̀ mọ́ òróró; 13 pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀dọ́-àgùntàn, ni kí ẹ rú ẹbọ ìyẹ̀fun ìyẹ̀fun kíkúnná tí a pò mọ́ òróró. Èyí ni ẹbọ sísun, òórùn dídùn, àti ẹbọ tí a ṣe fún Olúwa pẹ̀lú iná. 14 Kí ẹbọ ohun mímu wọn jẹ́ ààbọ̀ òṣùwọ̀n hínì ti ọtí wáìnì, fún akọ màlúù kan, àti ìdámẹ́wàá òṣùwọ̀n hínì fún àgbò kan àti ìdámẹ́rin òṣùwọ̀n hínì fún ọ̀dọ́-àgùntàn kan. Èyí ni ẹbọ sísun tí wọn ó máa rú ní oṣù kọ̀ọ̀kan nínú ọdún. 15 Yàtọ̀ sí ẹbọ sísun pẹ̀lú ẹbọ ohun mímu, ẹ gbọdọ̀ fi akọ ewúrẹ́ kọ̀ọ̀kan fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.

Àjọ ìrékọjá

16 (B)“ ‘Ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ín-ní ni ìrékọjá Olúwa gbọdọ̀ wáyé. 17 (C)Ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù yìí ẹ gbọdọ̀ ṣiṣẹ́ àjọ̀dún fún ọjọ́ méje kí ó jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà. 18 Ní ọjọ́ kìn-ín-ní kí àpéjọ mímọ́ kí ó wà; ẹ́yin kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ agbára kankan. 19 Ẹ rú ẹbọ sísun sí Olúwa, ẹ rú u pẹ̀lú ọ̀dọ́ màlúù méjì akọ, ẹbọ sísun pẹ̀lú iná àgbò kan àti ọ̀dọ́-àgùntàn méje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan kí wọn kí ó jẹ́ aláìlábùkù. 20 Pẹ̀lú akọ màlúù kọ̀ọ̀kan ni kí ẹ pèsè ẹbọ ohun mímu pẹ̀lú ìdámẹ́ta nínú mẹ́wàá ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò; pẹ̀lú àgbò, ìdá méjì nínú mẹ́wàá; 21 pẹ̀lú ọ̀dọ́-àgùntàn kọ̀ọ̀kan ìdákan nínú mẹ́wàá. 22 Pẹ̀lú òbúkọ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣètùtù fún un yín. 23 Ṣe eléyìí ní àfikún sí ẹbọ sísun àràárọ̀. 24 Báyìí ní kí ẹ̀yin rúbọ ní ọjọọjọ́, jálẹ̀ ní ọjọ́ méjèèje, oúnjẹ ẹbọ tí a fi iná ṣe, tí olóòórùn dídùn sí Olúwa; ó rú u pẹ̀lú ẹbọ sísun ìgbà gbogbo, àti ẹbọ ohun mímu. 25 Ní ọjọ́ keje kí ẹ̀yin kí ó ní àpéjọ mímọ́, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan.

Àjọ ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀

26 (D)“ ‘Ní ọjọ́ àkọ́so pẹ̀lú, nígbà tí ẹ̀yin bá mú ẹbọ ohun jíjẹ tuntun wá fún Olúwa lẹ́yìn àsìkò àjọ̀dún, kí ẹ̀yin kí ó ní àpéjọ mímọ́, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan. 27 Kí ẹ mú ẹbọ sísun ẹgbọrọ màlúù méjì, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn méje ọlọ́dún kan gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn fún Olúwa. 28 Pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan akọ màlúù ní kí ẹ rú ẹbọ ohun mímu ìdámẹ́ta pẹ̀lú òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò pẹ̀lú àgbò kan. 29 Àti pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀dọ́-àgùntàn méje, kí ó jẹ́ ìdákan nínú mẹ́wàá. 30 Ẹ fi òbúkọ kan ṣe ètùtù fún ara yín. 31 Kí ẹ̀yin kí ó rú wọn pẹ̀lú ẹbọ sísun ìgbà gbogbo, àti ẹbọ ohun mímu yín àti ẹbọ ohun jíjẹ yín. Kí ẹ sì ri dájú pé àwọn ẹranko náà jẹ́ aláìlábùkù.

Àsè ìpè

29 (E)“ ‘Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù keje, kí ẹ ní àpéjọ mímọ́, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan. Ọjọ́ ìfùnpè ni ó jẹ́ fún yín. Gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn sí Olúwa, ẹ pèsè ẹgbọrọ akọ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan aláìlábùkù, kí ẹ fi ẹbọ sísun. Pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ wọn, ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò, ìdámẹ́ta nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n fún akọ màlúù kan, àti ìdá méjì nínú mẹ́wàá, òṣùwọ̀n fún àgbò kan, àti ìdámẹ́wàá òṣùwọ̀n fún ọ̀dọ́-àgùntàn kan, àti fún ọ̀dọ́-àgùntàn méje. Àti òbúkọ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣètùtù fún yín. Pẹ̀lú ẹbọ sísun oṣù àti ẹbọ ohun jíjẹ rẹ̀ àti ẹbọ sísun ìgbà gbogbo àti ẹbọ mímu wọn gẹ́gẹ́ bí ìlànà wọn. Fún òórùn dídùn, ẹbọ tí a fi iná ṣe sí Olúwa.

Ọjọ́ ẹbọ ètùtù

(F)“ ‘Ní ọjọ́ kẹwàá nínú oṣù keje, kí ẹ ṣe àpéjọ mímọ́. Kí ẹ̀yin kí ó sẹ́ ara yín, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan. Kí ẹ̀yin kí ó rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí Olúwa, ẹgbọrọ akọ màlúù kan, àgbò kan, àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn méje ọlọ́dún kan, kí wọn kí ó sì jẹ́ aláìlábùkù fún yín. Pẹ̀lú akọ màlúù, pèsè ọrẹ ìdámẹ́wàá mẹ́ta, òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun tí a fi òróró pò àti ìdámẹ́wàá méjì òṣùwọ̀n fún àgbò kan, 10 àti fún ọ̀dọ́-àgùntàn kọ̀ọ̀kan, ìdámẹ́wàá òṣùwọ̀n. 11 Pẹ̀lú akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, pẹ̀lú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún ètùtù àti ẹbọ sísun gbogbo ìgbà àti ẹbọ jíjẹ rẹ̀ àti ẹbọ mímu wọn.

Àpèjẹ Àgọ́

12 (G)“ ‘Ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù keje, kí ẹ̀yin kí ó ní àpéjọ mímọ́, ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan. Kí ẹ̀yin kí ó sì ṣe àjọyọ̀ fún Olúwa fún ọjọ́ méje. 13 Kí ẹ sì rú ẹbọ sísun kan, ẹbọ tí a fi iná ṣe, tí ó ní òórùn dídùn sí Olúwa, ẹbọ tí ẹgbọrọ akọ màlúù mẹ́tàlá, àgbò méjì àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́rìnlá tí ó jẹ́ ọdún kan, tí gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ aláìlábùkù. 14 Àti ẹbọ ohun jíjẹ wọn, ìyẹ̀fun tí a fi òróró pò, ìdámẹ́wàá mẹ́ta òṣùwọ̀n fún akọ màlúù kan, bẹ́ẹ̀ ni fún akọ màlúù mẹ́tẹ̀ẹ̀tàlá, ìdámẹ́wàá méjì òṣùwọ̀n fún àgbò kan, bẹ́ẹ̀ ni fún àgbò méjèèjì, 15 àti fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀dọ́-àgùntàn kan. Bẹ́ẹ̀ ni fún ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́rẹ̀ẹ̀rìnlá. 16 Àti akọ ewúrẹ́ kan gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu rẹ̀.

17 “ ‘Àti ní ọjọ́ kejì ni kí ẹ̀yin kí ó fi ẹgbọrọ akọ màlúù méjìlá, àgbò méjì àti ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́rìnlá ọlọ́dún kan aláìlábùkù rú ẹbọ. 18 Pẹ̀lú fún akọ màlúù, fún àgbò, àti fún ọ̀dọ́-àgùntàn kí ẹ pe ẹbọ ohun jíjẹ, àti ẹbọ ohun mímu, kí ó jẹ́ bí iye wọn, gẹ́gẹ́ bí ìlànà. 19 Àti òbúkọ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà pẹ̀lú ẹbọ jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu.

20 “ ‘Ní ọjọ́ kẹta, pèsè akọ màlúù mọ́kànlá, àgbò méjì, akọ àgùntàn mẹ́rìnlá ti ọdún kan tí kò ní àbùkù. 21 Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò, àti akọ àgùntàn, pèsè ọrẹ ohun jíjẹ àti ohun mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn. 22 Pẹ̀lú akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àti ẹbọ sísun ìgbà gbogbo pẹ̀lú ẹbọ jíjẹ àti ẹbọ mímu.

23 “ ‘Ní ọjọ́ kẹrin, pèsè akọ màlúù mẹ́wàá, àgbò méjì, àti ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́rìnlá ti ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbùkù. 24 Àti akọ màlúù, àgbò àti àgùntàn, pèsè ẹbọ jíjẹ àti ẹbọ mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn, gẹ́gẹ́ bí ìlànà. 25 Àti akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà, pẹ̀lú ẹbọ jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu.

26 “ ‘Àti ní ọjọ́ karùn-ún, pèsè akọ màlúù mẹ́sàn-án, àgbò méjì àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́rìnlá ti ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, tí gbogbo rẹ̀ kò ní àbùkù. 27 Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò àti ọ̀dọ́-àgùntàn, pèsè ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn sí ìlànà. 28 Àti akọ ewúrẹ́ kan gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ẹbọ sísun ìgbà gbogbo pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu.

29 “ ‘Ní ọjọ́ kẹfà, pèsè akọ màlúù mẹ́jọ, àgbò ọlọ́dún kan tí gbogbo rẹ̀ kò ní àbùkù. 30 Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò, àti ọ̀dọ́-àgùntàn, pèsè ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn. 31 Pẹ̀lú akọ ewúrẹ́ kan gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu.

32 “ ‘Àti ní ọjọ́ keje, pèsè akọ màlúù méje, àgbò méjì, àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́rìnlá ti ọlọ́dún kan, tí gbogbo rẹ̀ kò sì ní àbùkù. 33 Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò, àti ọ̀dọ́-àgùntàn, pèsè ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu fún wọn gẹ́gẹ́ bí iye wọn. 34 Pẹ̀lú akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà, pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu.

35 (H)“ ‘Àti ní ọjọ́ kẹjọ kí ẹ̀yin kó ní àpéjọ, kí ẹ má sì ṣe iṣẹ́ kankan. 36 Kí ẹ̀yin ṣe ìgbékalẹ̀ ẹbọ tí a fi iná ṣe tí ó ní òórùn dídùn sí Olúwa, ẹbọ sísun ti akọ màlúù kan, àgbò ọlọ́dún kan àti ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan méje, gbogbo rẹ̀ tí kò ní àbùkù. 37 Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò, àti ọ̀dọ́-àgùntàn, pèsè fún wọn ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn. 38 Àti akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà àti ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu.

39 “ ‘Pẹ̀lú ẹ̀jẹ́ yín, àti ẹbọ àtinúwá yín, kí ẹ̀yin kí o pèsè fún Olúwa ní àjọ̀dún tí a yàn yín, ẹbọ sísun, ẹbọ ohun jíjẹ, ẹbọ ohun mímu àti ẹbọ ìkẹ́gbẹ́ yín.’ ”

40 Mose sì sọ fún àwọn ọmọ Israẹli gbogbo ohun tí Olúwa ti pàṣẹ fún un.

Ẹ̀jẹ́

30 Mose sì sọ fún olórí àwọn ẹ̀yà ọmọ Israẹli pé: “Èyí ni ohun tí Olúwa pàṣẹ: (I)(J)Nígbà tí ọkùnrin kan bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ sí Olúwa tàbí búra láti fi de ara rẹ̀ ní ìdè kí òun má bà ba ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ kí ó ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sọ.

“Nígbà tí ọmọbìnrin kan bá sì wà ní ilé baba rẹ̀ tó bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa tàbí búra láti fi de ara rẹ̀ tí baba rẹ̀ bá sì gbọ́ ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tàbí ìdè rẹ̀ tí kò sì sọ nǹkan kan sí i, kí gbogbo ẹ̀jẹ́ rẹ̀ kí ó dúró àti gbogbo ìdè tí ó fi de ara rẹ̀ yóò sì dúró. Ṣùgbọ́n tí baba rẹ̀ bá kọ̀ fun un ní ọjọ́ tí ó gbọ́, kò sí ọ̀kan nínú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tàbí nínú ìdè tí ó fi de ara rẹ̀ tí yóò dúró; Olúwa yóò sì tú u sílẹ̀ nítorí baba rẹ̀ kọ̀ fún un.

“Tí ó bá sì ní ọkọ lẹ́yìn ìgbà tí ó jẹ́ ẹ̀jẹ́ tàbí lẹ́yìn ìgbà tí ó sọ ọ̀rọ̀ kan láti ẹnu rẹ̀ jáde nínú èyí tí ó fi de ara rẹ̀ ní ìdè, Tí ọkọ rẹ̀ sì gbọ́ nípa èyí ṣùgbọ́n tí kò sọ nǹkan kan, nígbà náà ni ẹ̀jẹ́ tàbí ìdè tí ó fi de ara rẹ̀ tó dúró. Ṣùgbọ́n tí ọkọ rẹ̀ bá kọ̀ nígbà tí ó gbọ́, ǹjẹ́ òun yóò mú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tí ó jẹ́ àti ohun tí ó ti ti ẹnu rẹ̀ jáde, èyí tí ó fi de ara rẹ̀ dasán, Olúwa yóò sì dáríjì í.

“Ṣùgbọ́n ẹ̀jẹ́ kí ẹ̀jẹ́ tàbí ìdè kí ìdè tí opó tàbí obìnrin tí a kọ̀sílẹ̀ bá ṣe yóò wà lórí rẹ̀.

10 “Bí obìnrin tí ó ń gbé pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ tàbí de ara rẹ̀ ní ìdè lábẹ́ ìbúra, 11 tí ọkọ rẹ̀ bá sì gbọ́, ṣùgbọ́n tí kò sọ̀rọ̀, tí kò sì kọ̀, nígbà náà ni ẹ̀jẹ́ rẹ̀ yóò dúró. 12 Ṣùgbọ́n tí ọkọ rẹ̀ bá sọ wọ́n dasán, nígbà tí ó gbọ́, nígbà náà kò sí ẹ̀jẹ́ tàbí ìdè tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde tí yóò dúró, ọkọ rẹ̀ ti sọ wọ́n dasán, Olúwa yóò tú u sílẹ̀. 13 Ọkọ rẹ̀ lè ṣe ìwádìí tàbí sọ ọ́ dasán ẹ̀jẹ́ tàbí ìbúra ìdè tí ó ti ṣe láti fi de ara rẹ̀. 14 Ṣùgbọ́n tí ọkọ rẹ̀ kò bá sọ nǹkan kan sí í nípa rẹ̀ ní ọjọ́ dé ọjọ́, nígbà náà ni ó ṣe ìwádìí nípa ẹ̀jẹ́ àti ìbúra ìdè tí ó dè é. Kí ọkùnrin náà ṣe ìwádìí lórí rẹ̀ láìsọ nípa rẹ̀ si nígbà tí ó gbọ́ nípa rẹ̀. 15 Bí ó ti wù kí ó rí, bí ọkùnrin náà bá sọ ọ́ dasán, ní àkókò kan lẹ́yìn tí ó ti gbọ́ wọn, nígbà náà ó jẹ̀bi ọ̀rọ̀ náà.”

16 Èyí ni ìlànà tí Olúwa fún Mose nípa ìbátan láàrín ọkùnrin àti obìnrin àti láàrín baba àti ọ̀dọ́mọbìnrin rẹ̀ tí ó sì ń gbé ní ilé rẹ̀.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.