Chronological
Àròyé Jobu tẹ̀síwájú
10 “Agara ìwà ayé mi dá mi tán,
èmi yóò tú àròyé mi sókè lọ́dọ̀ mi,
èmi yóò máa sọ̀rọ̀ nínú kíkorò ìbìnújẹ́ ọkàn mi.
2 Èmi yóò wí fún Ọlọ́run pé: má ṣe dá mi lẹ́bi;
fihàn mí nítorí ìdí ohun tí ìwọ fi ń bá mi jà.
3 Ó ha tọ́ tí ìwọ ìbá fi máa ni mí lára,
tí ìwọ ìbá fi máa gan iṣẹ́ ọwọ́ rẹ,
tí ìwọ yóò fi máa tàn ìmọ́lẹ̀ sí ìmọ̀ ènìyàn búburú.
4 Ojú rẹ kì ha ṣe ojú ènìyàn bí?
Tàbí ìwọ a máa ríran bí ènìyàn ti í ríran?
5 Ọjọ́ rẹ ha dàbí ọjọ́ ènìyàn,
ọdún rẹ ha dàbí ọjọ́ ènìyàn?
6 Tí ìwọ fi ń béèrè àìṣedéédéé mi,
tí ìwọ sì fi wá ẹ̀ṣẹ̀ mi rí?
7 Ìwọ mọ̀ pé èmi kì í ṣe oníwà búburú,
kò sì sí ẹni tí ó le gbà mí kúrò ní ọwọ́ rẹ?
8 “Ọwọ́ rẹ ni ó mọ mi, tí ó sì da mi.
Síbẹ̀ ìwọ tún yípadà láti jẹ mí run.
9 Èmi bẹ̀ ọ́ rántí pé ìwọ ti mọ mí bí amọ̀;
ìwọ yóò ha sì tún mú mi padà lọ sínú erùpẹ̀?
10 Ìwọ kò ha ti tú mí dà jáde bí i wàrà,
ìwọ kò sì mú mí dìpọ̀ bí i wàràǹkàṣì?
11 Ìwọ sá ti fi àwọ̀ ẹran-ara wọ̀ mí,
ìwọ sì fi egungun àti iṣan ṣọgbà yí mi ká.
12 Ìwọ ti fún mi ní ẹ̀mí àti ojúrere,
ìbẹ̀wò rẹ sì pa ọkàn mi mọ́.
13 “Nǹkan wọ̀nyí ni ìwọ sì ti fi pamọ́ nínú rẹ;
èmi mọ̀ pé, èyí ń bẹ ní ọkàn rẹ.
14 Bí mo bá ṣẹ̀, nígbà náà ni ìwọ yóò máa ṣọ́ mi
ìwọ kì yóò sì dárí àìṣedéédéé mi jì.
15 Bí mo bá ṣe ẹni búburú, ègbé ni fún mi!
Bí mo bá sì ṣe ẹni rere,
bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì le gbe orí mi sókè.
Èmi dààmú, mo si wo ìpọ́njú mi.
16 Bí mo bá gbé orí mi ga. Ìwọ ń dẹ mí kiri bi i kìnnìún;
àti pẹ̀lú, ìwọ a sì fi ara rẹ hàn fún mi ní ìyànjú.
17 Ìwọ sì tún mun àwọn ẹlẹ́rìí rẹ dìde sí mi
di ọ̀tún, Ìwọ sì sọ ìrunú rẹ di púpọ̀ sí mi;
Àwọn ogun rẹ si dìde sinmi bi igbe omi Òkun.
18 “Nítorí kí ni ìwọ ṣe mú mi jáde láti inú wá?
Háà! Èmi ìbá kúkú ti kú, ojúkójú kì bá tí rí mi.
19 Tí kò bá le jẹ́ pé èmi wà láààyè,
À bá ti gbé mi láti inú lọ isà òkú.
20 Ọjọ́ mi kò ha kúrú bí? Rárá!
Dáwọ́ dúró, kí ó sì yí padà kúrò lọ́dọ̀ mi.
Nítorí kí èmi lè ni ayọ̀ ní ìṣẹ́jú kan.
21 Kí èmi kí ó tó lọ sí ibi tí èmi kì yóò padà sẹ́yìn mọ́,
Àní si ilẹ̀ òkùnkùn àti òjìji ikú.
22 Ilẹ̀ òkùnkùn bí òkùnkùn tìkára rẹ̀,
Àti ti òjìji ikú àti rúdurùdu,
Níbi tí ìmọ́lẹ̀ dàbí òkùnkùn.”
Sofari fi ẹ̀sùn irọ́ pípa àti àìṣòótọ́ kan Jobu
11 Ìgbà náà ni Sofari, ará Naama, dáhùn, ó sì wí pé:
2 “A ha lè ṣe kí a máa dáhùn sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀?
A ha lè fi gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí da ènìyàn láre?
3 Ṣé àmọ̀tán rẹ le mú ènìyàn pa ẹnu wọn mọ́ bí?
Ṣé ẹnikẹ́ni kò ní bá ọ wí bí ìwọ bá yọ ṣùtì sí ni?
4 Ìwọ sá à ti wí fún Ọlọ́run pé,
‘ìṣe mi jẹ́ aláìléérí, èmi sì mọ́ ní ojú rẹ.’
5 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ìbá jẹ́ sọ̀rọ̀,
kí ó sì ya ẹnu rẹ̀ sí ọ;
6 Kí ó sì fi àṣírí ọgbọ́n hàn ọ́ pé, ó pọ̀ ju òye ènìyàn lọ;
Nítorí náà, mọ̀ pé Ọlọ́run ti
gbàgbé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kan.
7 “Ìwọ ha le ṣe àwárí ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run bí?
Ìwọ ha le ṣe àwárí ibi tí Olódùmarè dé bi?
8 Ó ga ju àwọn ọ̀run lọ; kí ni ìwọ le è ṣe?
Ó jì ju jíjìn isà òkú lọ; kí ni ìwọ le mọ̀?
9 Ìwọ̀n rẹ̀ gùn ju ayé lọ,
ó sì ní ibú ju Òkun lọ.
10 “Bí òun bá rékọjá, tí ó sì sé ọnà,
tàbí tí ó sì mú ni wá sí ìdájọ́, ǹjẹ́, ta ni ó lè dí i lọ́wọ́?
11 Òun sá à mọ ẹlẹ́tàn ènìyàn;
àti pé ṣé bí òun bá rí ohun búburú, ṣé òun kì i fi iyè sí i?
12 Ṣùgbọ́n òmùgọ̀ ènìyàn ki yóò di ọlọ́gbọ́n,
bi ko ti rọrùn fún ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó láti bí ènìyàn.
13 “Bí ìwọ bá fi ọkàn rẹ fún un,
tí ìwọ sì na ọwọ́ rẹ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀,
14 Bí ìwọ bá gbé ẹ̀ṣẹ̀ tí ń bẹ ní ọwọ́ rẹ jù sọnù,
tí ìwọ kò sì jẹ́ kí aburú gbé nínú àgọ́ rẹ.
15 Nígbà náà ni ìwọ ó gbé ojú rẹ sókè láìní àbàwọ́n,
àní ìwọ yóò dúró ṣinṣin, ìwọ kì yóò sì bẹ̀rù,
16 Nítorí pé ìwọ ó gbàgbé ìṣòro rẹ,
ìwọ ó sì rántí rẹ̀ bí omi tí ó ti sàn kọjá lọ.
17 Ọjọ́ ayé rẹ yóò sì mọ́lẹ̀ ju ọ̀sán gangan lọ,
bí òkùnkùn tilẹ̀ bò ọ́ mọ́lẹ̀ nísinsin yìí, ìwọ ó dàbí òwúrọ̀.
18 Ìwọ ó sì wà láìléwu, nítorí pé ìrètí wà;
àní ìwọ ó rin ilé rẹ wò, ìwọ ó sì sinmi ní àlàáfíà.
19 Ìwọ ó sì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú, kì yóò sì sí ẹni tí yóò dẹ́rùbà ọ́,
àní ènìyàn yóò máa wá ojúrere rẹ.
20 Ṣùgbọ́n ojú ìkà ènìyàn yóò mófo;
gbogbo ọ̀nà àbáyọ ni yóò nù wọ́n,
ìrètí wọn a sì dàbí ẹni tí ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́.”
Ìdáhùn Jobu
12 Jobu sì dáhùn, ó sì wí pé:
2 “Kò sí àní àní níbẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni àwọn ènìyàn náà,
ọgbọ́n yóò sì kú pẹ̀lú yín!
3 Ṣùgbọ́n èmi ní ìyè nínú gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin:
èmi kò kéré sí i yín:
àní, ta ni kò mọ gbogbo nǹkan wọ̀nyí?
4 “Èmi dàbí ẹni tí a ń fi ṣe ẹlẹ́yà lọ́dọ̀ aládùúgbò rẹ̀,
tí ó ké pe Ọlọ́run, tí ó sì dá a lóhùn:
à ń fi olóòtítọ́ ẹni ìdúró ṣinṣin rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà.
5 Ó rọrùn fún ènìyàn láti fi ìbànújẹ́ ẹlòmíràn ṣe ẹlẹ́yà,
gẹ́gẹ́ bí ìpín àwọn ẹni tí ẹsẹ̀ wọn ṣetán láti yọ̀.
6 Àgọ́ àwọn ìgárá ọlọ́ṣà wá láìní ìbẹ̀rù;
àwọn tí ó sì ń mú Ọlọ́run bínú wà láìléwu,
àwọn ẹni tí ó sì gbá òrìṣà mú ní ọwọ́ wọn.
7 “Ṣùgbọ́n nísinsin yìí bí àwọn ẹranko léèrè, wọn o kọ́ ọ ní ẹ̀kọ́,
àti ẹyẹ ojú ọ̀run, wọn ó sì sọ fún ọ.
8 Tàbí ba ilẹ̀ ayé sọ̀rọ̀, yóò sì kọ́ ọ,
àwọn ẹja inú Òkun yóò sì sọ fún ọ.
9 Ta ni kò mọ̀ nínú gbogbo nǹkan
wọ̀nyí pé, ọwọ́ Olúwa ni ó ṣe nǹkan yìí?
10 Ní ọwọ́ ẹni tí ẹ̀mí ohun alààyè gbogbo gbé wà,
Àti ẹ̀mí gbogbo aráyé.
11 Etí kì í dán ọ̀rọ̀ wò bí
tàbí adùn ẹnu kì í sì í tọ́ oúnjẹ rẹ̀ wò bí?
12 Àwọn arúgbó ni ọgbọ́n wà fún,
àti nínú gígùn ọjọ́ ni òye.
13 “Ti Ọlọ́run ni ọgbọ́n àti agbára:
Òun ló ni ìmọ̀ àti òye.
14 Kíyèsi i, ó bì wó, a kò sì lè gbe ró mọ́;
Ó sé ènìyàn mọ́, kò sì sí ìtúsílẹ̀ kan.
15 Kíyèsi i, ó dá àwọn omi dúró, wọ́n sì gbẹ;
Ó sì rán wọn jáde, wọ́n sì ṣẹ̀ bo ilẹ̀ ayé yípo.
16 Tìrẹ ni agbára àti ìṣẹ́gun;
Ẹni tí ń ṣìnà àti ẹni tí ń mú ni ṣìnà, tirẹ̀ ni wọ́n ń ṣe.
17 Ó mú àwọn ìgbìmọ̀ lọ ní ìhòhò,
A sì sọ àwọn onídàájọ́ di òmùgọ̀.
18 Ó tú ìdè ọba,
Ó sì fi àmùrè gbà wọ́n ní ọ̀já.
19 Ó mú àwọn àlùfáà lọ ní ìhòhò,
Ó sì tẹ orí àwọn alágbára ba.
20 Ó mú ọ̀rọ̀ ẹnu ẹni ìgbẹ́kẹ̀lé kúrò,
Ó sì ra àwọn àgbàgbà ní iyè.
21 Ó bu ẹ̀gàn lu àwọn ọmọ ọlọ́lá,
Ó sì tú àmùrè àwọn alágbára.
22 Ó hú ìdí ohun ìjìnlẹ̀ jáde láti inú òkùnkùn wá,
Ó sì mú òjìji ikú wá sínú ìmọ́lẹ̀.
23 Òun a mú orílẹ̀-èdè bí sí i, a sì run wọ́n;
Òun a sọ orílẹ̀-èdè di ńlá, a sì tún ṣẹ̀ wọn kù.
24 Òun a gba òye àwọn olórí àwọn ènìyàn aráyé,
A sì máa mú wọn rin kiri nínú ijù níbi tí ọ̀nà kò sí.
25 Wọn a máa fi ọwọ́ ta ilẹ̀ nínú òkùnkùn níbi tí kò sí ìmọ́lẹ̀,
Òun a sì máa mú ìrìn ìsìn wọn bí ọ̀mùtí.
Jobu gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run
13 “Wò ó, ojú mi ti rí gbogbo èyí rí,
etí mí sì gbọ́, ó sì ti yé mi.
2 Ohun tí ẹ̀yin mọ̀, èmi mọ̀ pẹ̀lú,
èmi kò kéré sí i yin.
3 Nítòótọ́ èmi ó bá Olódùmarè
sọ̀rọ̀, èmi sì ń fẹ́ bá Ọlọ́run sọ àsọyé.
4 Ẹ̀yin fi irọ́ bá mi sọ̀rọ̀,
oníṣègùn lásán ni gbogbo yín.
5 Háà! ẹ̀yin kì bá kúkú dákẹ́!
Èyí ni kì bá sì ṣe ọgbọ́n yín.
6 Ẹ gbọ́ àwíyé mi nísinsin yìí;
ẹ sì fetísílẹ̀ sí àròyé ẹnu mi.
7 Ẹ̀yin fẹ́ sọ ìsọkúsọ fún Ọlọ́run?
Ki ẹ sì fi ẹ̀tàn sọ̀rọ̀ gbè é?
8 Ẹ̀yin fẹ́ ṣe ojúsàájú rẹ̀?
Ẹ̀yin fẹ́ gbèjà fún Ọlọ́run?
9 Ó ha dára to tí yóò hú àṣírí yín síta,
Tàbí kí ẹ̀yin tàn án bí ẹnìkan ti í tan ẹnìkejì?
10 Yóò máa bá yín wí nítòótọ́,
bí ẹ̀yin bá ṣe ojúsàájú ènìyàn níkọ̀kọ̀.
11 Ìwà ọlá rẹ̀ kì yóò bà yín lẹ́rù bí?
Ìpayà rẹ̀ kì yóò pá yín láyà?
12 Àwọn òwe yín dàbí eérú;
Bẹ́ẹ̀ ni àwọn odi ìlú yin dàbí amọ̀.
13 “Ẹ pa ẹnu yín mọ́ kúrò lára mi, kí èmi kí ó lè sọ̀rọ̀,
ki ohun tí ń bọ̀ wá í bá mi, le è máa bọ̀.
14 Ǹjẹ́ nítorí kí ni èmi ṣe ń fi eyín mi bu ẹran-ara mi jẹ,
Tí mo sì gbé ẹ̀mí mi lé ara mi lọ́wọ́?
15 Bí ó tilẹ̀ pa mí, síbẹ̀ èmi ó máa gbẹ́kẹ̀lé e;
Ṣùgbọ́n èmi ó máa tẹnumọ́ ọ̀nà mi níwájú rẹ̀.
16 Èyí ni yóò sì ṣe ìgbàlà mi,
Àgàbàgebè kì yóò wá síwájú rẹ̀.
17 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu mi ní ìfarabalẹ̀,
jẹ́ kí ọ̀rọ̀ mí dún ni etí yín.
18 Wò ó nísinsin yìí, èmi ti mura ọ̀ràn mi sílẹ̀;
èmi mọ̀ pé a ó dá mi láre.
19 Ta ni òun ti yóò bá mi ṣàròyé?
Ǹjẹ́ nísinsin yìí, èmi fẹ́ pa ẹnu mi mọ́,
èmi ó sì jọ̀wọ́ ẹ̀mí mi lọ́wọ́.
20 “Ṣùgbọ́n, má ṣe ṣe ohun méjì yìí sí mi,
Nígbà náà ni èmi kì yóò sì fi ara mi pamọ́ kúrò fún ọ:
21 Fa ọwọ́ rẹ sẹ́yìn kúrò lára mi,
má sì jẹ́ kí ẹ̀rù rẹ kí ó pá mi láyà.
22 Nígbà náà ni kí ìwọ kí ó pè, èmi o sì dáhùn;
Ta ni jẹ́ kí ń máa sọ̀rọ̀, ki ìwọ kí ó sì dá mi lóhùn.
23 Mélòó ní àìṣedéédéé àti ẹ̀ṣẹ̀ mi?
Mú mi mọ̀ ìrékọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ mi.
24 Nítorí kí ni ìwọ ṣe pa ojú rẹ mọ́,
tí o sì yàn mí ní ọ̀tá rẹ?
25 Ìwọ ó fa ewé ti afẹ́fẹ́ ń fẹ́ síhìn-ín sọ́hùn-ún ya bi?
Ìwọ a sì máa lépa ìyàngbò?
26 Nítorí pé ìwọ kọ̀wé ohun kíkorò sí mi,
o sì mú mi jogún àìṣedéédéé èwe mi.
27 Ìwọ kàn àbà mọ́ mi lẹ́sẹ̀ pẹ̀lú,
ìwọ sì ń wò ipa ọ̀nà ìrìn mi ní àwòfín;
nípa fífi ìlà yí gígísẹ̀ mi ká.
28 “Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn ń ṣègbé bí ohun ìdíbàjẹ́,
Bi aṣọ tí kòkòrò jẹ.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.